Prev  

80. Surah 'Abasa سورة عبس

  Next  




Ayah  80:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ


Ayah  80:3  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّهُ يَزَّكَّىٰ
Yoruba
 
Kí sì l'ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)

Ayah  80:4  الأية
    +/- -/+  
أَوْ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ الذِّكْرَىٰ
Yoruba
 
Tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?

Ayah  80:5  الأية
    +/- -/+  


Ayah  80:7  الأية
    +/- -/+  
وَمَا عَلَيْكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ
Yoruba
 
Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).

Ayah  80:8  الأية
    +/- -/+  
وَأَمَّا مَن جَاءَكَ يَسْعَىٰ
Yoruba
 
Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, tó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),



Ayah  80:11  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا إِنَّهَا تَذْكِرَةٌ
Yoruba
 
Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur'ān ni ìrántí.

Ayah  80:12  الأية
    +/- -/+  
فَمَن شَاءَ ذَكَرَهُ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.

Ayah  80:13  الأية
    +/- -/+  
فِي صُحُفٍ مُّكَرَّمَةٍ
Yoruba
 
(Al-Ƙur'ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,

Ayah  80:14  الأية
    +/- -/+  

Ayah  80:15  الأية
    +/- -/+  
بِأَيْدِي سَفَرَةٍ
Yoruba
 
Ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),

Ayah  80:16  الأية
    +/- -/+  

Ayah  80:17  الأية
    +/- -/+  
قُتِلَ الْإِنسَانُ مَا أَكْفَرَهُ
Yoruba
 
Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!

Ayah  80:18  الأية
    +/- -/+  

Ayah  80:19  الأية
    +/- -/+  
مِن نُّطْفَةٍ خَلَقَهُ فَقَدَّرَهُ
Yoruba
 
Nínú àtọ̀ l'Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.

Ayah  80:20  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ السَّبِيلَ يَسَّرَهُ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.

Ayah  80:21  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَمَاتَهُ فَأَقْبَرَهُ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.

Ayah  80:22  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ إِذَا شَاءَ أَنشَرَهُ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.

Ayah  80:23  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا لَمَّا يَقْضِ مَا أَمَرَهُ
Yoruba
 
Rárá o! Ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.

Ayah  80:24  الأية
    +/- -/+  
فَلْيَنظُرِ الْإِنسَانُ إِلَىٰ طَعَامِهِ
Yoruba
 
Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.

Ayah  80:25  الأية
    +/- -/+  
أَنَّا صَبَبْنَا الْمَاءَ صَبًّا
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.

Ayah  80:26  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ شَقَقْنَا الْأَرْضَ شَقًّا
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.

Ayah  80:27  الأية
    +/- -/+  
فَأَنبَتْنَا فِيهَا حَبًّا
Yoruba
 
A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;

Ayah  80:28  الأية
    +/- -/+  

Ayah  80:29  الأية
    +/- -/+  


Ayah  80:31  الأية
    +/- -/+  
وَفَاكِهَةً وَأَبًّا
Yoruba
 
Àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).

Ayah  80:32  الأية
    +/- -/+  
مَّتَاعًا لَّكُمْ وَلِأَنْعَامِكُمْ
Yoruba
 
(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.

Ayah  80:33  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا جَاءَتِ الصَّاخَّةُ
Yoruba
 
Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,

Ayah  80:34  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَ يَفِرُّ الْمَرْءُ مِنْ أَخِيهِ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,


Ayah  80:36  الأية
    +/- -/+  

Ayah  80:37  الأية
    +/- -/+  
لِكُلِّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ يَوْمَئِذٍ شَأْنٌ يُغْنِيهِ
Yoruba
 
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l'ó ti ní ọ̀ràn tó máa tó o ó rán.

Ayah  80:38  الأية
    +/- -/+  
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ مُّسْفِرَةٌ
Yoruba
 
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.

Ayah  80:39  الأية
    +/- -/+  
ضَاحِكَةٌ مُّسْتَبْشِرَةٌ
Yoruba
 
Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.

Ayah  80:40  الأية
    +/- -/+  
وَوُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ عَلَيْهَا غَبَرَةٌ
Yoruba
 
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.

Ayah  80:41  الأية
    +/- -/+  

Ayah  80:42  الأية
    +/- -/+  
أُولَٰئِكَ هُمُ الْكَفَرَةُ الْفَجَرَةُ
Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us