Prev  

19. Surah Maryam سورة مريم

  Next  



1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
كهيعص
Kaf-ha-ya-AAayn-sad

Yoruba
 
Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Ayah  19:2  الأية
ذِكْرُ رَحْمَتِ رَبِّكَ عَبْدَهُ زَكَرِيَّا
Thikru rahmati rabbika AAabdahuzakariyya

Yoruba
 
(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀ (Ànábì) Zakariyyā.

Ayah  19:3  الأية
إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ نِدَاءً خَفِيًّا
Ith nada rabbahu nidaankhafiyya

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀.

Ayah  19:4  الأية
قَالَ رَبِّ إِنِّي وَهَنَ الْعَظْمُ مِنِّي وَاشْتَعَلَ الرَّأْسُ شَيْبًا وَلَمْ أَكُن بِدُعَائِكَ رَبِّ شَقِيًّا
Qala rabbi innee wahana alAAathmuminnee washtaAAala arra/su shayban walam akunbiduAAa-ika rabbi shaqiyya

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi.

Ayah  19:5  الأية
وَإِنِّي خِفْتُ الْمَوَالِيَ مِن وَرَائِي وَكَانَتِ امْرَأَتِي عَاقِرًا فَهَبْ لِي مِن لَّدُنكَ وَلِيًّا
Wa-innee khiftu almawaliya min wara-eewakanati imraatee AAaqiran fahab lee min ladunkawaliyya

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan,

Ayah  19:6  الأية
يَرِثُنِي وَيَرِثُ مِنْ آلِ يَعْقُوبَ ۖ وَاجْعَلْهُ رَبِّ رَضِيًّا
Yarithunee wayarithu min ali yaAAqoobawajAAalhu rabbi radiyya

Yoruba
 
(tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi."

Ayah  19:7  الأية
يَا زَكَرِيَّا إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَامٍ اسْمُهُ يَحْيَىٰ لَمْ نَجْعَل لَّهُ مِن قَبْلُ سَمِيًّا
Ya zakariyya innanubashshiruka bighulamin ismuhu yahya lamnajAAal lahu min qablu samiyya

Yoruba
 
Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A kò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀).

Ayah  19:8  الأية
قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَامٌ وَكَانَتِ امْرَأَتِي عَاقِرًا وَقَدْ بَلَغْتُ مِنَ الْكِبَرِ عِتِيًّا
Qala rabbi anna yakoonu leeghulamun wakanati imraatee AAaqiran waqadbalaghtu mina alkibari AAitiyya

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an."

Ayah  19:9  الأية
قَالَ كَذَٰلِكَ قَالَ رَبُّكَ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٌ وَقَدْ خَلَقْتُكَ مِن قَبْلُ وَلَمْ تَكُ شَيْئًا
Qala kathalika qalarabbuka huwa AAalayya hayyinun waqad khalaqtuka min qablu walamtaku shay-a

Yoruba
 
(Mọlāika) sọ pé: "Báyẹn ni (ó máa rí)." Olúwa rẹ sọ pé: "Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan."

Ayah  19:10  الأية
قَالَ رَبِّ اجْعَل لِّي آيَةً ۚ قَالَ آيَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ النَّاسَ ثَلَاثَ لَيَالٍ سَوِيًّا
Qala rabbi ijAAal lee ayatan qalaayatuka alla tukallima annasa thalathalayalin sawiyya

Yoruba
 
(Zakariyyā) sọ pé: "Olúwa mi, fún mi ní àmì kan." (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi."

Ayah  19:11  الأية
فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوْمِهِ مِنَ الْمِحْرَابِ فَأَوْحَىٰ إِلَيْهِمْ أَن سَبِّحُوا بُكْرَةً وَعَشِيًّا
Fakharaja AAala qawmihi mina almihrabifaawha ilayhim an sabbihoo bukratan waAAashiyya

Yoruba
 
Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

Ayah  19:12  الأية
يَا يَحْيَىٰ خُذِ الْكِتَابَ بِقُوَّةٍ ۖ وَآتَيْنَاهُ الْحُكْمَ صَبِيًّا
Ya yahya khuthialkitaba biquwwatin waataynahu alhukmasabiyya

Yoruba
 
Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré.

Ayah  19:13  الأية
وَحَنَانًا مِّن لَّدُنَّا وَزَكَاةً ۖ وَكَانَ تَقِيًّا
Wahananan min ladunnawazakatan wakana taqiyya

Yoruba
 
(Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  19:14  الأية
وَبَرًّا بِوَالِدَيْهِ وَلَمْ يَكُن جَبَّارًا عَصِيًّا
Wabarran biwalidayhi walam yakun jabbaranAAasiyya

Yoruba
 
(Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa.

Ayah  19:15  الأية
وَسَلَامٌ عَلَيْهِ يَوْمَ وُلِدَ وَيَوْمَ يَمُوتُ وَيَوْمَ يُبْعَثُ حَيًّا
Wasalamun AAalayhi yawma wulidawayawma yamootu wayawma yubAAathu hayya

Yoruba
 
Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).

Ayah  19:16  الأية
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ مَرْيَمَ إِذِ انتَبَذَتْ مِنْ أَهْلِهَا مَكَانًا شَرْقِيًّا
Wathkur fee alkitabimaryama ithi intabathat min ahliha makanansharqiyya

Yoruba
 
Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur'ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn.

Ayah  19:17  الأية
فَاتَّخَذَتْ مِن دُونِهِمْ حِجَابًا فَأَرْسَلْنَا إِلَيْهَا رُوحَنَا فَتَمَثَّلَ لَهَا بَشَرًا سَوِيًّا
Fattakhathat min doonihim hijabanfaarsalna ilayha roohanafatamaththala laha basharan sawiyya

Yoruba
 
Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé.

Ayah  19:18  الأية
قَالَتْ إِنِّي أَعُوذُ بِالرَّحْمَٰنِ مِنكَ إِن كُنتَ تَقِيًّا
Qalat innee aAAoothu birrahmaniminka in kunta taqiyya

Yoruba
 
(Mọryam) sọ pé: "Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu)."

Ayah  19:19  الأية
قَالَ إِنَّمَا أَنَا رَسُولُ رَبِّكِ لِأَهَبَ لَكِ غُلَامًا زَكِيًّا
Qala innama ana rasoolurabbiki li-ahaba laki ghulaman zakiyya

Yoruba
 
(Mọlāika) sọ pé: "Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan."

Ayah  19:20  الأية
قَالَتْ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَامٌ وَلَمْ يَمْسَسْنِي بَشَرٌ وَلَمْ أَكُ بَغِيًّا
Qalat anna yakoonu lee ghulamunwalam yamsasnee basharun walam aku baghiyya

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè."

Ayah  19:21  الأية
قَالَ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٌ ۖ وَلِنَجْعَلَهُ آيَةً لِّلنَّاسِ وَرَحْمَةً مِّنَّا ۚ وَكَانَ أَمْرًا مَّقْضِيًّا
Qala kathaliki qalarabbuki huwa AAalayya hayyinun walinajAAalahu ayatan linnasiwarahmatan minna wakana amran maqdiyya

Yoruba
 
(Mọlāika) sọ pé: "Báyẹn ló máa rí." Olúwa rẹ sọ pé: "Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí (tí ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ.)"

Ayah  19:22  الأية
فَحَمَلَتْهُ فَانتَبَذَتْ بِهِ مَكَانًا قَصِيًّا
Fahamalat-hu fantabathatbihi makanan qasiyya

Yoruba
 
Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan tó jìnnà.

Ayah  19:23  الأية
فَأَجَاءَهَا الْمَخَاضُ إِلَىٰ جِذْعِ النَّخْلَةِ قَالَتْ يَا لَيْتَنِي مِتُّ قَبْلَ هَٰذَا وَكُنتُ نَسْيًا مَّنسِيًّا
Faajaaha almakhadu ilajithAAi annakhlati qalat ya laytaneemittu qabla hatha wakuntu nasyan mansiyya

Yoruba
 
Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: "Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá."

Ayah  19:24  الأية
فَنَادَاهَا مِن تَحْتِهَا أَلَّا تَحْزَنِي قَدْ جَعَلَ رَبُّكِ تَحْتَكِ سَرِيًّا
Fanadaha min tahtihaalla tahzanee qad jaAAala rabbuki tahtakisariyya

Yoruba
 
Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ.

Ayah  19:25  الأية
وَهُزِّي إِلَيْكِ بِجِذْعِ النَّخْلَةِ تُسَاقِطْ عَلَيْكِ رُطَبًا جَنِيًّا
Wahuzzee ilayki bijithAAi annakhlatitusaqit AAalayki rutaban janiyya

Yoruba
 
Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ.

Ayah  19:26  الأية
فَكُلِي وَاشْرَبِي وَقَرِّي عَيْنًا ۖ فَإِمَّا تَرَيِنَّ مِنَ الْبَشَرِ أَحَدًا فَقُولِي إِنِّي نَذَرْتُ لِلرَّحْمَٰنِ صَوْمًا فَلَنْ أُكَلِّمَ الْيَوْمَ إِنسِيًّا
Fakulee washrabee waqarree AAaynanfa-imma tarayinna mina albashari ahadan faqooleeinnee nathartu lirrahmani sawmanfalan okallima alyawma insiyya

Yoruba
 
Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: "Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, èmi kò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní."

Ayah  19:27  الأية
فَأَتَتْ بِهِ قَوْمَهَا تَحْمِلُهُ ۖ قَالُوا يَا مَرْيَمُ لَقَدْ جِئْتِ شَيْئًا فَرِيًّا
Faatat bihi qawmaha tahmiluhuqaloo ya maryamu laqad ji/ti shay-an fariyya

Yoruba
 
Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: "Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan aburú ńlá wá.

Ayah  19:28  الأية
يَا أُخْتَ هَارُونَ مَا كَانَ أَبُوكِ امْرَأَ سَوْءٍ وَمَا كَانَتْ أُمُّكِ بَغِيًّا
Ya okhta haroona ma kanaabooki imraa saw-in wama kanat ommuki baghiyya

Yoruba
 
Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè."

Ayah  19:29  الأية
فَأَشَارَتْ إِلَيْهِ ۖ قَالُوا كَيْفَ نُكَلِّمُ مَن كَانَ فِي الْمَهْدِ صَبِيًّا
Faasharat ilayhi qaloo kayfanukallimu man kana fee almahdi sabiyya

Yoruba
 
Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: "Báwo ni a ó ṣe bá ẹni tó wà lórí ìtẹ́, tó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?"

Ayah  19:30  الأية
قَالَ إِنِّي عَبْدُ اللهِ آتَانِيَ الْكِتَابَ وَجَعَلَنِي نَبِيًّا
Qala innee AAabdu Allahi ataniyaalkitaba wajaAAalanee nabiyya

Yoruba
 
(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: "Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ní Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì.

Ayah  19:31  الأية
وَجَعَلَنِي مُبَارَكًا أَيْنَ مَا كُنتُ وَأَوْصَانِي بِالصَّلَاةِ وَالزَّكَاةِ مَا دُمْتُ حَيًّا
WajaAAalanee mubarakan aynamakuntu waawsanee bissalati wazzakatima dumtu hayya

Yoruba
 
Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé).

Ayah  19:32  الأية
وَبَرًّا بِوَالِدَتِي وَلَمْ يَجْعَلْنِي جَبَّارًا شَقِيًّا
Wabarran biwalidatee walam yajAAalneejabbaran shaqiyya

Yoruba
 
(Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú.

Ayah  19:33  الأية
وَالسَّلَامُ عَلَيَّ يَوْمَ وُلِدتُّ وَيَوْمَ أَمُوتُ وَيَوْمَ أُبْعَثُ حَيًّا
Wassalamu AAalayya yawmawulidtu wayawma amootu wayawma obAAathu hayya

Yoruba
 
Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)."

Ayah  19:34  الأية
ذَٰلِكَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ ۚ قَوْلَ الْحَقِّ الَّذِي فِيهِ يَمْتَرُونَ
Thalika AAeesa ibnu maryamaqawla alhaqqi allathee feehi yamtaroon

Yoruba
 
Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.

Ayah  19:35  الأية
مَا كَانَ لِلَّهِ أَن يَتَّخِذَ مِن وَلَدٍ ۖ سُبْحَانَهُ ۚ إِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُن فَيَكُونُ
Ma kana lillahi anyattakhitha min waladin subhanahu itha qadaamran fa-innama yaqoolu lahu kun fayakoon

Yoruba
 
Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Ayah  19:36  الأية
وَإِنَّ اللهَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ
Wa-inna Allaha rabbee warabbukum faAAbudoohuhatha siratun mustaqeem

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.

Ayah  19:37  الأية
فَاخْتَلَفَ الْأَحْزَابُ مِن بَيْنِهِمْ ۖ فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا مِن مَّشْهَدِ يَوْمٍ عَظِيمٍ
Fakhtalafa al-ahzabumin baynihim fawaylun lillatheena kafaroo min mashhadiyawmin AAatheem

Yoruba
 
Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) sì yapa-ẹnu (lórí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba l'ọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde).

Ayah  19:38  الأية
أَسْمِعْ بِهِمْ وَأَبْصِرْ يَوْمَ يَأْتُونَنَا ۖ لَٰكِنِ الظَّالِمُونَ الْيَوْمَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
AsmiAA bihim waabsir yawma ya/toonanalakini aththalimoona alyawmafee dalalin mubeen

Yoruba
 
Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa! Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ náà ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

Ayah  19:39  الأية
وَأَنذِرْهُمْ يَوْمَ الْحَسْرَةِ إِذْ قُضِيَ الْأَمْرُ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ وَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Waanthirhum yawma alhasrati ithqudiya al-amru wahum fee ghaflatin wahum layu/minoon

Yoruba
 
Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́.

Ayah  19:40  الأية
إِنَّا نَحْنُ نَرِثُ الْأَرْضَ وَمَنْ عَلَيْهَا وَإِلَيْنَا يُرْجَعُونَ
Inna nahnu narithu al-ardawaman AAalayha wa-ilayna yurjaAAoon

Yoruba
 
Dájúdájú Àwa l'A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.

Ayah  19:41  الأية
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِبْرَاهِيمَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صِدِّيقًا نَّبِيًّا
Wathkur fee alkitabiibraheema innahu kana siddeeqan nabiyya

Yoruba
 
Mú (ìtàn) 'Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur'ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.

Ayah  19:42  الأية
إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ يَا أَبَتِ لِمَ تَعْبُدُ مَا لَا يَسْمَعُ وَلَا يُبْصِرُ وَلَا يُغْنِي عَنكَ شَيْئًا
Ith qala li-abeehi yaabati lima taAAbudu ma la yasmaAAu wala yubsiruwala yughnee AAanka shay-a

Yoruba
 
Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan.

Ayah  19:43  الأية
يَا أَبَتِ إِنِّي قَدْ جَاءَنِي مِنَ الْعِلْمِ مَا لَمْ يَأْتِكَ فَاتَّبِعْنِي أَهْدِكَ صِرَاطًا سَوِيًّا
Ya abati innee qad jaanee minaalAAilmi ma lam ya/tika fattabiAAnee ahdika siratansawiyya

Yoruba
 
Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́.

Ayah  19:44  الأية
يَا أَبَتِ لَا تَعْبُدِ الشَّيْطَانَ ۖ إِنَّ الشَّيْطَانَ كَانَ لِلرَّحْمَٰنِ عَصِيًّا
Ya abati la taAAbudi ashshaytanainna ashshaytana kana lirrahmaniAAasiyya

Yoruba
 
Bàbá mi, má ṣe bọ Èṣù. Dájúdájú Èṣù jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé.

Ayah  19:45  الأية
يَا أَبَتِ إِنِّي أَخَافُ أَن يَمَسَّكَ عَذَابٌ مِّنَ الرَّحْمَٰنِ فَتَكُونَ لِلشَّيْطَانِ وَلِيًّا
Ya abati innee akhafu anyamassaka AAathabun mina arrahmanifatakoona lishshyatani waliyya

Yoruba
 
Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ Èṣù (nínú Iná)."

Ayah  19:46  الأية
قَالَ أَرَاغِبٌ أَنتَ عَنْ آلِهَتِي يَا إِبْرَاهِيمُ ۖ لَئِن لَّمْ تَنتَهِ لَأَرْجُمَنَّكَ ۖ وَاهْجُرْنِي مَلِيًّا
Qala araghibun anta AAan alihateeya ibraheemu la-in lam tantahi laarjumannaka wahjurneemaliyya

Yoruba
 
(Bàbá rẹ̀) wí pé: "Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, 'Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi wọ́ọ́rọ́wọ́ ná."

Ayah  19:47  الأية
قَالَ سَلَامٌ عَلَيْكَ ۖ سَأَسْتَغْفِرُ لَكَ رَبِّي ۖ إِنَّهُ كَانَ بِي حَفِيًّا
Qala salamun AAalaykasaastaghfiru laka rabbee innahu kana bee hafiyya

Yoruba
 
('Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi.

Ayah  19:48  الأية
وَأَعْتَزِلُكُمْ وَمَا تَدْعُونَ مِن دُونِ اللهِ وَأَدْعُو رَبِّي عَسَىٰ أَلَّا أَكُونَ بِدُعَاءِ رَبِّي شَقِيًّا
WaaAAtazilukum wama tadAAoona mindooni Allahi waadAAoo rabbee AAasa allaakoona biduAAa-i rabbee shaqiyya

Yoruba
 
Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi."

Ayah  19:49  الأية
فَلَمَّا اعْتَزَلَهُمْ وَمَا يَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ وَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ ۖ وَكُلًّا جَعَلْنَا نَبِيًّا
Falamma iAAtazalahum wamayaAAbudoona min dooni Allahi wahabna lahu ishaqawayaAAqooba wakullan jaAAalna nabiyya

Yoruba
 
Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), 'Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì.

Ayah  19:50  الأية
وَوَهَبْنَا لَهُم مِّن رَّحْمَتِنَا وَجَعَلْنَا لَهُمْ لِسَانَ صِدْقٍ عَلِيًّا
Wawahabna lahum min rahmatinawajaAAalna lahum lisana sidqin AAaliyya

Yoruba
 
Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì fi òdodo sórí ahọ́n gbogbo àwọn ènìyàn nìpa wọn (ìyẹn ni pé, gbogbo ìjọ ẹlẹ́sìn ló ń sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa).

Ayah  19:51  الأية
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ مُوسَىٰ ۚ إِنَّهُ كَانَ مُخْلَصًا وَكَانَ رَسُولًا نَّبِيًّا
Wathkur fee alkitabimoosa innahu kana mukhlasan wakanarasoolan nabiyya

Yoruba
 
Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur'ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.

Ayah  19:52  الأية
وَنَادَيْنَاهُ مِن جَانِبِ الطُّورِ الْأَيْمَنِ وَقَرَّبْنَاهُ نَجِيًّا
Wanadaynahu min janibiattoori al-aymani waqarrabnahu najiyya

Yoruba
 
A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀.

Ayah  19:53  الأية
وَوَهَبْنَا لَهُ مِن رَّحْمَتِنَا أَخَاهُ هَارُونَ نَبِيًّا
Wawahabna lahu min rahmatinaakhahu haroona nabiyya

Yoruba
 
A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa.

Ayah  19:54  الأية
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِسْمَاعِيلَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صَادِقَ الْوَعْدِ وَكَانَ رَسُولًا نَّبِيًّا
Wathkur fee alkitabiismaAAeela innahu kana sadiqa alwaAAdi wakanarasoolan nabiyya

Yoruba
 
Sọ ìtàn (Ànábì) 'Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur'ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.

Ayah  19:55  الأية
وَكَانَ يَأْمُرُ أَهْلَهُ بِالصَّلَاةِ وَالزَّكَاةِ وَكَانَ عِندَ رَبِّهِ مَرْضِيًّا
Wakana ya/muru ahlahu bissalatiwazzakati wakana AAinda rabbihi mardiyya

Yoruba
 
Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀.

Ayah  19:56  الأية
وَاذْكُرْ فِي الْكِتَابِ إِدْرِيسَ ۚ إِنَّهُ كَانَ صِدِّيقًا نَّبِيًّا
Wathkur fee alkitabiidreesa innahu kana siddeeqan nabiyya

Yoruba
 
Sọ ìtàn (Ànábì) 'Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur'ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.

Ayah  19:57  الأية
وَرَفَعْنَاهُ مَكَانًا عَلِيًّا
WarafaAAnahu makanan AAaliyya

Yoruba
 
A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀).

Ayah  19:58  الأية
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ أَنْعَمَ اللهُ عَلَيْهِم مِّنَ النَّبِيِّينَ مِن ذُرِّيَّةِ آدَمَ وَمِمَّنْ حَمَلْنَا مَعَ نُوحٍ وَمِن ذُرِّيَّةِ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْرَائِيلَ وَمِمَّنْ هَدَيْنَا وَاجْتَبَيْنَا ۚ إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُ الرَّحْمَٰنِ خَرُّوا سُجَّدًا وَبُكِيًّا ۩
Ola-ika allatheena anAAama AllahuAAalayhim mina annabiyyeena min thurriyyati adamawamimman hamalna maAAa noohin wamin thurriyyatiibraheema wa-isra-eela wamimman hadayna wajtabaynaitha tutla AAalayhim ayatu arrahmanikharroo sujjadan wabukiyya

Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm àti 'Isrọ̄'īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún.

Ayah  19:59  الأية
فَخَلَفَ مِن بَعْدِهِمْ خَلْفٌ أَضَاعُوا الصَّلَاةَ وَاتَّبَعُوا الشَّهَوَاتِ ۖ فَسَوْفَ يَلْقَوْنَ غَيًّا
Fakhalafa min baAAdihim khalfun adaAAooassalata wattabaAAoo ashshahawatifasawfa yalqawna ghayya

Yoruba
 
Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn adùn. Láìpẹ́ wọn máa pàdé òfò (nínú Iná).

Ayah  19:60  الأية
إِلَّا مَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَأُولَٰئِكَ يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ وَلَا يُظْلَمُونَ شَيْئًا
Illa man taba waamanawaAAamila salihan faola-ika yadkhuloonaaljannata wala yuthlamoona shay-a

Yoruba
 
Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn.

Ayah  19:61  الأية
جَنَّاتِ عَدْنٍ الَّتِي وَعَدَ الرَّحْمَٰنُ عِبَادَهُ بِالْغَيْبِ ۚ إِنَّهُ كَانَ وَعْدُهُ مَأْتِيًّا
Jannati AAadnin allatee waAAada arrahmanuAAibadahu bighaybi innahu kana waAAduhuma/tiyya

Yoruba
 
(Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ.

Ayah  19:62  الأية
لَّا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا إِلَّا سَلَامًا ۖ وَلَهُمْ رِزْقُهُمْ فِيهَا بُكْرَةً وَعَشِيًّا
La yasmaAAoona feeha laghwanilla salaman walahum rizquhum feeha bukratanwaAAashiyya

Yoruba
 
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

Ayah  19:63  الأية
تِلْكَ الْجَنَّةُ الَّتِي نُورِثُ مِنْ عِبَادِنَا مَن كَانَ تَقِيًّا
Tilka aljannatu allatee noorithu min AAibadinaman kana taqiyya

Yoruba
 
Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa.

Ayah  19:64  الأية
وَمَا نَتَنَزَّلُ إِلَّا بِأَمْرِ رَبِّكَ ۖ لَهُ مَا بَيْنَ أَيْدِينَا وَمَا خَلْفَنَا وَمَا بَيْنَ ذَٰلِكَ ۚ وَمَا كَانَ رَبُّكَ نَسِيًّا
Wama natanazzalu illa bi-amrirabbika lahu ma bayna aydeena wama khalfanawama bayna thalika wama kana rabbukanasiyya

Yoruba
 
Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yẹn. Àti pé Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé.

Ayah  19:65  الأية
رَّبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا فَاعْبُدْهُ وَاصْطَبِرْ لِعِبَادَتِهِ ۚ هَلْ تَعْلَمُ لَهُ سَمِيًّا
Rabbu assamawati wal-ardiwama baynahuma faAAbudhu wastabirliAAibadatihi hal taAAlamu lahu samiyya

Yoruba
 
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀?

Ayah  19:66  الأية
وَيَقُولُ الْإِنسَانُ أَإِذَا مَا مِتُّ لَسَوْفَ أُخْرَجُ حَيًّا
Wayaqoolu al-insanu a-itha mamittu lasawfa okhraju hayya

Yoruba
 
Ènìyàn ń wí pé: "Ṣé nígbà tí mo bá kú, wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?"

Ayah  19:67  الأية
أَوَلَا يَذْكُرُ الْإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن قَبْلُ وَلَمْ يَكُ شَيْئًا
Awa la yathkuru al-insanuanna khalaqnahu min qablu walam yaku shay-a

Yoruba
 
Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan?

Ayah  19:68  الأية
فَوَرَبِّكَ لَنَحْشُرَنَّهُمْ وَالشَّيَاطِينَ ثُمَّ لَنُحْضِرَنَّهُمْ حَوْلَ جَهَنَّمَ جِثِيًّا
Fawarabbika lanahshurannahum washshayateenathumma lanuhdirannahum hawla jahannama jithiyya

Yoruba
 
Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn èṣù jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀.

Ayah  19:69  الأية
ثُمَّ لَنَنزِعَنَّ مِن كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمْ أَشَدُّ عَلَى الرَّحْمَٰنِ عِتِيًّا
Thumma lananziAAanna min kulli sheeAAatinayyuhum ashaddu AAala arrahmaniAAitiyya

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan ẹni tí ó le jùlọ nínú wọn níbi ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé.

Ayah  19:70  الأية
ثُمَّ لَنَحْنُ أَعْلَمُ بِالَّذِينَ هُمْ أَوْلَىٰ بِهَا صِلِيًّا
Thumma lanahnu aAAlamu billatheenahum awla biha siliyya

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí wíwọ inú Iná.

Ayah  19:71  الأية
وَإِن مِّنكُمْ إِلَّا وَارِدُهَا ۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ حَتْمًا مَّقْضِيًّا
Wa-in minkum illa wariduhakana AAala rabbika hatman maqdiyya

Yoruba
 
Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀ (àfi kí ó gba ibẹ̀ kọjá). Ó di dandan kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

Ayah  19:72  الأية
ثُمَّ نُنَجِّي الَّذِينَ اتَّقَوا وَّنَذَرُ الظَّالِمِينَ فِيهَا جِثِيًّا
Thumma nunajjee allatheena ittaqawwanatharu aththalimeena feehajithiyya

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.

Ayah  19:73  الأية
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا أَيُّ الْفَرِيقَيْنِ خَيْرٌ مَّقَامًا وَأَحْسَنُ نَدِيًّا
Wa-itha tutla AAalayhim ayatunabayyinatin qala allatheena kafaroo lillatheenaamanoo ayyu alfareeqayni khayrun maqaman waahsanunadiyya

Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: "Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) ló lóore jùlọ ní ibùgbé, ló sì dára jùlọ ní ìjókòó (afẹ́)?"

Ayah  19:74  الأية
وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّن قَرْنٍ هُمْ أَحْسَنُ أَثَاثًا وَرِئْيًا
Wakam ahlakna qablahum min qarnin humahsanu athathan wari/ya

Yoruba
 
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jùlọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí!

Ayah  19:75  الأية
قُلْ مَن كَانَ فِي الضَّلَالَةِ فَلْيَمْدُدْ لَهُ الرَّحْمَٰنُ مَدًّا ۚ حَتَّىٰ إِذَا رَأَوْا مَا يُوعَدُونَ إِمَّا الْعَذَابَ وَإِمَّا السَّاعَةَ فَسَيَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ شَرٌّ مَّكَانًا وَأَضْعَفُ جُندًا
Qul man kana fee addalalatifalyamdud lahu arrahmanu maddan hattaitha raaw ma yooAAadoona imma alAAathabawa-imma assaAAata fasayaAAlamoona man huwasharrun makanan waadAAafu junda

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun.

Ayah  19:76  الأية
وَيَزِيدُ اللهُ الَّذِينَ اهْتَدَوْا هُدًى ۗ وَالْبَاقِيَاتُ الصَّالِحَاتُ خَيْرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابًا وَخَيْرٌ مَّرَدًّا
Wayazeedu Allahu allatheenaihtadaw hudan walbaqiyatu assalihatukhayrun AAinda rabbika thawaban wakhayrun maradda

Yoruba
 
Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn tó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

Ayah  19:77  الأية
أَفَرَأَيْتَ الَّذِي كَفَرَ بِآيَاتِنَا وَقَالَ لَأُوتَيَنَّ مَالًا وَوَلَدًا
Afaraayta allathee kafara bi-ayatinawaqala laootayanna malan wawalada

Yoruba
 
Sọ fún mi nípa ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: "Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!"

Ayah  19:78  الأية
أَطَّلَعَ الْغَيْبَ أَمِ اتَّخَذَ عِندَ الرَّحْمَٰنِ عَهْدًا
AttalaAAa alghayba ami ittakhathaAAinda arrahmani AAahda

Yoruba
 
Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé?

Ayah  19:79  الأية
كَلَّا ۚ سَنَكْتُبُ مَا يَقُولُ وَنَمُدُّ لَهُ مِنَ الْعَذَابِ مَدًّا
Kalla sanaktubu ma yaqooluwanamuddu lahu mina alAAathabi madda

Yoruba
 
Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà.

Ayah  19:80  الأية
وَنَرِثُهُ مَا يَقُولُ وَيَأْتِينَا فَرْدًا
Wanarithuhu ma yaqoolu waya/teenafarda

Yoruba
 
A ó sì jogún ohun tó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan.

Ayah  19:81  الأية
وَاتَّخَذُوا مِن دُونِ اللهِ آلِهَةً لِّيَكُونُوا لَهُمْ عِزًّا
Wattakhathoo min dooni Allahialihatan liyakoonoo lahum AAizza

Yoruba
 
Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára.

Ayah  19:82  الأية
كَلَّا ۚ سَيَكْفُرُونَ بِعِبَادَتِهِمْ وَيَكُونُونَ عَلَيْهِمْ ضِدًّا
Kalla sayakfuroona biAAibadatihimwayakoonoona AAalayhim didda

Yoruba
 
Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn.

Ayah  19:83  الأية
أَلَمْ تَرَ أَنَّا أَرْسَلْنَا الشَّيَاطِينَ عَلَى الْكَافِرِينَ تَؤُزُّهُمْ أَزًّا
Alam tara anna arsalna ashshayateenaAAala alkafireena taozzuhum azza

Yoruba
 
Ṣé ìwọ kò wòye pé dájúdájú Àwa ń dẹ àwọn èṣù sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń gùn wọ́n gan-an (síbi ẹ̀ṣẹ̀)?

Ayah  19:84  الأية
فَلَا تَعْجَلْ عَلَيْهِمْ ۖ إِنَّمَا نَعُدُّ لَهُمْ عَدًّا
Fala taAAjal AAalayhim innamanaAAuddu lahum AAadda

Yoruba
 
Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà.

Ayah  19:85  الأية
يَوْمَ نَحْشُرُ الْمُتَّقِينَ إِلَى الرَّحْمَٰنِ وَفْدًا
Yawma nahshuru almuttaqeena ilaarrahmani wafda

Yoruba
 
(Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn.

Ayah  19:86  الأية
وَنَسُوقُ الْمُجْرِمِينَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ وِرْدًا
Wanasooqu almujrimeena ila jahannamawirda

Yoruba
 
A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì.

Ayah  19:87  الأية
لَّا يَمْلِكُونَ الشَّفَاعَةَ إِلَّا مَنِ اتَّخَذَ عِندَ الرَّحْمَٰنِ عَهْدًا
La yamlikoona ashshafaAAatailla mani ittakhatha AAinda arrahmaniAAahda

Yoruba
 
Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé.

Ayah  19:88  الأية
وَقَالُوا اتَّخَذَ الرَّحْمَٰنُ وَلَدًا
Waqaloo ittakhatha arrahmanuwalada

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ."

Ayah  19:89  الأية
لَّقَدْ جِئْتُمْ شَيْئًا إِدًّا
Laqad ji/tum shay-an idda

Yoruba
 
Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá.

Ayah  19:90  الأية
تَكَادُ السَّمَاوَاتُ يَتَفَطَّرْنَ مِنْهُ وَتَنشَقُّ الْأَرْضُ وَتَخِرُّ الْجِبَالُ هَدًّا
Takadu assamawatuyatafattarna minhu watanshaqqu al-ardu watakhirrualjibalu hadda

Yoruba
 
Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dàwó lulẹ̀ gbì

Ayah  19:91  الأية
أَن دَعَوْا لِلرَّحْمَٰنِ وَلَدًا
An daAAaw lirrahmaniwalada

Yoruba
 
Fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé.

Ayah  19:92  الأية
وَمَا يَنبَغِي لِلرَّحْمَٰنِ أَن يَتَّخِذَ وَلَدًا
Wama yanbaghee lirrahmanian yattakhitha walada

Yoruba
 
Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ.

Ayah  19:93  الأية
إِن كُلُّ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ إِلَّا آتِي الرَّحْمَٰنِ عَبْدًا
In kullu man fee assamawatiwal-ardi illa atee arrahmaniAAabda

Yoruba
 
Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn.

Ayah  19:94  الأية
لَّقَدْ أَحْصَاهُمْ وَعَدَّهُمْ عَدًّا
Laqad ahsahum waAAaddahum AAadda

Yoruba
 
Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà.

Ayah  19:95  الأية
وَكُلُّهُمْ آتِيهِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فَرْدًا
Wakulluhum ateehi yawma alqiyamatifarda

Yoruba
 
Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan.

Ayah  19:96  الأية
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ سَيَجْعَلُ لَهُمُ الرَّحْمَٰنُ وُدًّا
Inna allatheena amanoowaAAamiloo assalihati sayajAAalu lahumu arrahmanuwudda

Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn.

Ayah  19:97  الأية
فَإِنَّمَا يَسَّرْنَاهُ بِلِسَانِكَ لِتُبَشِّرَ بِهِ الْمُتَّقِينَ وَتُنذِرَ بِهِ قَوْمًا لُّدًّا
Fa-innama yassarnahu bilisanikalitubashshira bihi almuttaqeena watunthira bihi qawmanludda

Yoruba
 
Nítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur'ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ tó ń ja òdodo níyàn

Ayah  19:98  الأية
وَكَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّن قَرْنٍ هَلْ تُحِسُّ مِنْهُم مِّنْ أَحَدٍ أَوْ تَسْمَعُ لَهُمْ رِكْزًا
Wakam ahlakna qablahum min qarnin haltuhissu minhum min ahadin aw tasmaAAu lahum rikza

Yoruba
 
Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí?
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us