1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
سَأَلَ سَائِلٌ بِعَذَابٍ وَاقِعٍ
Saala sa-ilun biAAathabin waqiAA
Yoruba
Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀
|
Ayah 70:2 الأية
لِّلْكَافِرِينَ لَيْسَ لَهُ دَافِعٌ
Lilkafireena laysa lahu dafiAA
Yoruba
Sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
|
Ayah 70:3 الأية
مِّنَ اللهِ ذِي الْمَعَارِجِ
Mina Allahi thee almaAAarij
Yoruba
Lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.
|
Ayah 70:4 الأية
تَعْرُجُ الْمَلَائِكَةُ وَالرُّوحُ إِلَيْهِ فِي يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُ
خَمْسِينَ أَلْفَ سَنَةٍ
TaAAruju almala-ikatu warroohuilayhi fee yawmin kana miqdaruhu khamseena
alfasana
Yoruba
Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).
|
Ayah 70:5 الأية
فَاصْبِرْ صَبْرًا جَمِيلًا
Fasbir sabran jameela
Yoruba
Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.
|
Ayah 70:6 الأية
إِنَّهُمْ يَرَوْنَهُ بَعِيدًا
Innahum yarawnahu baAAeeda
Yoruba
Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.
|
Ayah 70:7 الأية
وَنَرَاهُ قَرِيبًا
Wanarahu qareeba
Yoruba
A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.
|
Ayah 70:8 الأية
يَوْمَ تَكُونُ السَّمَاءُ كَالْمُهْلِ
Yawma takoonu assamao kalmuhl
Yoruba
(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,
|
Ayah 70:9 الأية
وَتَكُونُ الْجِبَالُ كَالْعِهْنِ
Watakoonu aljibalu kalAAihn
Yoruba
Àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,
|
Ayah 70:10 الأية
وَلَا يَسْأَلُ حَمِيمٌ حَمِيمًا
Wala yas-alu hameemun hameema
Yoruba
ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
|
Ayah 70:11 الأية
يُبَصَّرُونَهُمْ ۚ يَوَدُّ الْمُجْرِمُ لَوْ يَفْتَدِي مِنْ عَذَابِ يَوْمِئِذٍ
بِبَنِيهِ
Yubassaroonahum yawaddu almujrimu lawyaftadee min AAathabi yawmi-ithin bibaneeh
Yoruba
Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
|
Ayah 70:12 الأية
وَصَاحِبَتِهِ وَأَخِيهِ
Wasahibatihi waakheeh
Yoruba
Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,
|
Ayah 70:13 الأية
وَفَصِيلَتِهِ الَّتِي تُؤْوِيهِ
Wafaseelatihi allatee tu/weeh
Yoruba
Àti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
|
Ayah 70:14 الأية
وَمَن فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ يُنجِيهِ
Waman fee al-ardi jameeAAan thummayunjeeh
Yoruba
Àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
|
Ayah 70:15 الأية
كَلَّا ۖ إِنَّهَا لَظَىٰ
Kalla innaha latha
Yoruba
Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).
|
Ayah 70:16 الأية
نَزَّاعَةً لِّلشَّوَىٰ
NazzaAAatan lishshawa
Yoruba
Ó máa bó awọ orí tòró.
|
Ayah 70:17 الأية
تَدْعُو مَنْ أَدْبَرَ وَتَوَلَّىٰ
TadAAoo man adbara watawalla
Yoruba
(Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
|
Ayah 70:18 الأية
وَجَمَعَ فَأَوْعَىٰ
WajamaAAa faawAAa
Yoruba
Ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).
|
Ayah 70:19 الأية
إِنَّ الْإِنسَانَ خُلِقَ هَلُوعًا
Inna al-insana khuliqa halooAAa
Yoruba
Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
|
Ayah 70:20 الأية
إِذَا مَسَّهُ الشَّرُّ جَزُوعًا
Itha massahu ashsharrujazooAAa
Yoruba
Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.
|
Ayah 70:21 الأية
وَإِذَا مَسَّهُ الْخَيْرُ مَنُوعًا
Wa-itha massahu alkhayru manooAAa
Yoruba
Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.
|
Ayah 70:22 الأية
إِلَّا الْمُصَلِّينَ
Illa almusalleen
Yoruba
Àyàfi àwọn olùkírun,
|
Ayah 70:23 الأية
الَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ دَائِمُونَ
Allatheena hum AAala salatihimda-imoon
Yoruba
Àwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;
|
Ayah 70:24 الأية
وَالَّذِينَ فِي أَمْوَالِهِمْ حَقٌّ مَّعْلُومٌ
Wallatheena fee amwalihimhaqqun maAAloom
Yoruba
Àwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn
|
Ayah 70:25 الأية
لِّلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ
Lissa-ili walmahroom
Yoruba
Sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;
|
Ayah 70:26 الأية
وَالَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوْمِ الدِّينِ
Wallatheena yusaddiqoonabiyawmi addeen
Yoruba
Àwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;
|
Ayah 70:27 الأية
وَالَّذِينَ هُم مِّنْ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشْفِقُونَ
Wallatheena hum min AAathabirabbihim mushfiqoon
Yoruba
Àwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,
|
Ayah 70:28 الأية
إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمْ غَيْرُ مَأْمُونٍ
Inna AAathaba rabbihim ghayru ma/moon
Yoruba
Dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
|
Ayah 70:29 الأية
وَالَّذِينَ هُمْ لِفُرُوجِهِمْ حَافِظُونَ
Wallatheena hum lifuroojihim hafithoon
Yoruba
Àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
|
Ayah 70:30 الأية
إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ
مَلُومِينَ
Illa AAala azwajihim awma malakat aymanuhum fa-innahum ghayru maloomeen
Yoruba
Àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
|
Ayah 70:31 الأية
فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ
Famani ibtagha waraa thalikafaola-ika humu alAAadoon
Yoruba
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;
|
Ayah 70:32 الأية
وَالَّذِينَ هُمْ لِأَمَانَاتِهِمْ وَعَهْدِهِمْ رَاعُونَ
Wallatheena hum li-amanatihimwaAAahdihim raAAoon
Yoruba
Àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
|
Ayah 70:33 الأية
وَالَّذِينَ هُم بِشَهَادَاتِهِمْ قَائِمُونَ
Wallatheena hum bishahadatihimqa-imoon
Yoruba
Àwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;
|
Ayah 70:34 الأية
وَالَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ
Wallatheena hum AAala salatihimyuhafithoon
Yoruba
Àti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.
|
Ayah 70:35 الأية
أُولَٰئِكَ فِي جَنَّاتٍ مُّكْرَمُونَ
Ola-ika fee jannatin mukramoon
Yoruba
Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
|
Ayah 70:36 الأية
فَمَالِ الَّذِينَ كَفَرُوا قِبَلَكَ مُهْطِعِينَ
Famali allatheena kafarooqibalaka muhtiAAeen
Yoruba
Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
|
Ayah 70:37 الأية
عَنِ الْيَمِينِ وَعَنِ الشِّمَالِ عِزِينَ
AAani alyameeni waAAani ashshimaliAAizeen
Yoruba
Tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
|
Ayah 70:38 الأية
أَيَطْمَعُ كُلُّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُدْخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٍ
AyatmaAAu kullu imri-in minhum anyudkhala jannata naAAeem
Yoruba
Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
|
Ayah 70:39 الأية
كَلَّا ۖ إِنَّا خَلَقْنَاهُم مِّمَّا يَعْلَمُونَ
Kalla inna khalaqnahummimma yaAAlamoon
Yoruba
Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
|
Ayah 70:40 الأية
فَلَا أُقْسِمُ بِرَبِّ الْمَشَارِقِ وَالْمَغَارِبِ إِنَّا لَقَادِرُونَ
Fala oqsimu birabbi almashariqiwalmagharibi inna laqadiroon
Yoruba
Nítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára
|
Ayah 70:41 الأية
عَلَىٰ أَن نُّبَدِّلَ خَيْرًا مِّنْهُمْ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ
AAala an nubaddila khayran minhum wamanahnu bimasbooqeen
Yoruba
Láti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.
|
Ayah 70:42 الأية
فَذَرْهُمْ يَخُوضُوا وَيَلْعَبُوا حَتَّىٰ يُلَاقُوا يَوْمَهُمُ الَّذِي
يُوعَدُونَ
Fatharhum yakhoodoowayalAAaboo hatta yulaqoo yawmahumu allatheeyooAAadoon
Yoruba
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
|
Ayah 70:43 الأية
يَوْمَ يَخْرُجُونَ مِنَ الْأَجْدَاثِ سِرَاعًا كَأَنَّهُمْ إِلَىٰ نُصُبٍ
يُوفِضُونَ
Yawma yakhrujoona mina al-ajdathi siraAAankaannahum ila nusubin yoofidoon
Yoruba
Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
|
Ayah 70:44 الأية
خَاشِعَةً أَبْصَارُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۚ ذَٰلِكَ الْيَوْمُ الَّذِي كَانُوا
يُوعَدُونَ
KhashiAAatan absaruhumtarhaquhum thillatun thalika alyawmu allatheekanoo
yooAAadoon
Yoruba
Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|