Tite Wole
  Create an account

Ojule Nyin

Tite Jade

 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
[ Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose ]

·Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibadan
·Nitori Wahala Ojoojumo, Igbeyawo Odun Mefa Tuka L'Osogbo
·Won Ti Ran Oga Ileewe To Fipa Ba Akekoo Re Lo Po Lewon Odun Mewaa L'Ekiti
·Tessy Loyun L'Ondo, Lo Ba Loo Ta Omo To Bi Si Onitsha
·Iya Omo Osu Merin Fee Ko Oko n'Ibadan, O Ni Baba Ikoko Maa n Fipa Ba Oun La
·Pasito Oluso-agutan Femi Olayinka Tijo 'Christ Miracle' Fun Iyawo Omo
·Blessing Gun Orekunrin Re Pa Ni Lekki
·Olopaa Lu Wolii Ijo Sele Bukky Victor Alonge Daku l'Akure, Won Lo Lu Funke
·Awon Omo Egbe Okunkun Yinbon Pa Baba Tee N'Ilorin

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Sunday, February 26
· Yekeen Fee Ko Munira n'Ilorin, O Ni Latigba Tawon Ti Fera Loun Ti n Ru, Tou
· Igbeyawo Odun Merinla Fori Sanpon L'Ore
· Iya Omo Osu Merin Fee Ko Oko n'Ibadan, O Ni Baba Ikoko Maa n Fipa Ba Oun La
· N'Igbokoda, Tegbon-taburo Ri Ore Meji Mole Laaye Nitori Ti Won Ji Iya Won L
· Emi Atoko Mi Ko Ja, Nitori Omo Lawon Ebi Re Se Fee Le Mi Jade - Rafia
· Dereba Bisoobu Fipa Ba Eni To Ja Lole Lo Po, Ladajo Ba Ran an Lewon N'Ilori
· O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo
· Ofo Emi Kan Ree! Eefin Jenereto Pa Segun Alawaye Sinu Yara Ni Sagamu
· Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un
· O Ma Se o: Ile Wo Pa Kafaya Arowosere l'Abeokuta, Bee Obinrin Naa Wa Ninu O
· Pasito Oluso-agutan Femi Olayinka Tijo 'Christ Miracle' Fun Iyawo Omo
· Nitori Bi Won Ko Se Rowo Osu Gba, Awon Osise Di Onibaara Nipinle Oyo
· Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun
· Owo Ileewe Di Wahala Ni Poli Oke-Ogun, Lawon Soja Ba Lu Akekoo Ati Oluko Lalubam
· Bi Minisita Buhari Atiyawo Pelu Omo e Se Ku Sinu Ijamba Moto Ree
· Oko Mi Maa n Lu Mi Ti Mo Ba Ti Ba Awon Omo Wa Wi — Mutiya
· Blessing Gun Orekunrin Re Pa Ni Lekki
· Iyawo Mi n Lepa Emi Mi, E Tu Wa Ka —Alagba Oluwasesan
· Latodun Merin Seyin Loko Mi Ko Ti Ba Mi Lasepo, Mi o Se Mo - Folasade
· Nitori Owo Osu, , Edet Be Ori Omo Oga e N'Ijebu Ife
· Owo Te Oladele To N Ta Ori Eeyan N'Ibadan
· Igbeyawo Ogun Odun Daru L'Osogbo
· Ija Ni Baba Joke La L'Orile-Iganmu, Lo Ba Gbabe Ku
· Aliyu Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po n'Ilorin, Lo Ba Doyun
· Mi o Le Dariji Falilat Lori Eedegberin Naira Mi To Ji, Afi Kile-ejo Tu Wa Ka - A
· Olopaa Lu Wolii Ijo Sele Bukky Victor Alonge Daku l'Akure, Won Lo Lu Funke
· E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare
· Bee Ni Buhari Ko Wi Nnkan Kan
· Odidi Odun Meta Loko Mi Fi Pa Mi Ti, Mi o Se Mo — Taiwo
· 'E Gba Wa Lowo T.B Joshua Atawon Eeyan e o, Ojoojumo Ni Won n Da Wahala Sil

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibadan
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibada

Die lo ku ki ori ko lagbaja yo, Oloun ko ni oluware i yo ninu ewu ni. Patapata ni ori ko omodebinrin eni odun metadinlogun kan, Adegoke Bukola, yo lowo iku ojiji leyin to ti ko sowo awon agbenisowo ti won si ti fun un loogun je.

Bukola, eni ti a fi ojulowo oruko e bo lasiiri lo ko si pampe ife etan lojo Aiku, Sannde, ojo ketadinlogbon, osu keta, odun yii, pelu bo se tele orekunrin re to n je Onuigbo Chibuike atawon ore e jade loo se faaji laimo pe ero iku lawon omokunrin naa n ro si i.

Gege bi oga-agba awon olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade se so fawon oniroyin n'Ibadan lojo Eti, Fraide, to koja, lojo odun Ajinde awon Kristeni to koja yii ni Bukola loo pade orekunrin e laduugbo Iwo Road, n'Ibadan, lasiko to ye ko wa pelu iya e ni soosi fun poposinsin odun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

Owo Te Wahab Nibi To n Ti n Se'Kinni' Fomo Odun Mewaa Legbee Ogiri
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Owo Te Wahab Nibi To n Ti n Se'Kinni' Fomo Odun Mewaa Legbee Ogiri

Bi won ba n wa oniranu aye atorun, omokunrin eni ogun odun kan ti won n pe ni Wahab Abdul Azeez lo ye ki won mu pelu iwa idoti to hu, to tun fi ra awon ebi e lara.

Lose to koja lowo te Wahab ni koro ile kan ti won ko ti i ko pari, nibi to ti n ba omobinrin eni odun mewaa kan lo po. Adugbo kan ti won n pe ni 'Sparkling Estate', ni Isheri Olofin, nisele naa ti waye.Gege bi Omooba Muyiwa Adejobi to je agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun se wi, iya omo naa ran an nise ni ti Wahab fi tan an wo koro ile akopati naa, to si bere si i ba a sun lori iduro.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Umaru Gbe Oogun Wo Kootu, Ladajo Ba Da Igbejo Duro Kia
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Umaru Gbe Oogun Wo Kootu, Ladajo Ba Da Igbejo Duro Kia

Bii iran lawon ero kootu pelu Adajo Omolade Awope n wo olujejo kan, Ibrahim Umaru, nigba to n jejo ni kootu majisreeti to wa l'Ogba, nipinle Eko, pelu bi ara re ko se bale, nigba ti won si ye e wo, won ba oogun orisii meta lara re.

Umaru wo ewu le okan mole ninu awon oogun ohun, o so okan mo ese o si fi sokoto bo o, bee lo tun se okan ribiti bii oruka to si fi i sowo. Awon ohun ti akowe kootu to ye ara re wo gege bii ase adajo ba yii lo mu ki adajo pase pe ki igbejo Umaru wa sopin lesekese nitori Olorun nikan lo mo ohun to gba lero pelu oogun abenugongo to gbe sara ko too maa rojo, bee ese mi-in lo se tele ti won tori e gbe e wa si kootu naa, sugbon ti oloogun de yii tubo mu oro re dojuru si i ni.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia

Ale ojo Eti, Fraide, ose to koja, ti i se ojo keeedogun, osu yii, niroyin gbale pe alaga fegbe oselu PDP nijoba ibile Ipokia, nipinle Ogun, Alaaji Saruku Suraju, tawon eeyan mo si Aro meta ku. Iku naa ko ba si ma mu kayeefi dani ju bee lo ka ni ki i se pe oteeli ni baba eni odun mejidinlaaadorin naa ku si, won ni asewo ni alaga naa ba se sunle-sunle to fi gbona orun lo.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, nnkan bii aago mesan-an ale ojo naa ni gudugbe ja ni oteeli kan ti won n pe ni 'De Lover Hotel' to wa laduugbo Aseko, Ibatefin, ni Ipokia, nibi ti won ni okunrin to je alaga egbe PDP titi di akoko iku ojiji naa dagbere faye si. Ohun tawon tisele naa soju won salaye fun wa ni pe ipade kan ni Suraju n lo lojo naa tobinrin kan ti won pe ni orebinrin re fi pe e lori aago pe ko yoju soun ni oteeli De Lover, won ni bo si se gba ipe naa tan lo yipada ti ko lo sipade ohun mo, odo obinrin to pe e naa lo gba lo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa

Latari ijamba oko to n fopo emi sofo ati bi orisiirisii ajalu mi-in bee se maa n waye loju ona marose Osodi-Apapa, ile igbimo asofin Eko ti ke sijoba apapo lati pese afara elese soju ona naa.

Oro yii lo je yo latenu omo egbe oselu alatako, Onarebu Jude Idimogwu, pe asiko ree fun ile naa lati ta ijoba apapo ji lori pipese afara elese, eyi to ni yoo sadinku sun-kere-fa-kere oko ati ijamba moto nibe. Bee ni Onarebu Sola Giwa ni kijoba koko sewadii na ko too di pe won gbe igbese kankan lori pipese afara sagbegbe ohun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo — Abigail
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Arungun Loko Mi, Gbogbo Irinse Mi Lo Ti Baje, Mi O Fe e Mo — Abigail

"Loooto ni mo maa n mu oti, sugbon igo kan pere ni mo maa n mu loojo, ekookan ni mo maa n mugbo, sugbon oro enu iyawo mi yii ko dara rara, nitori naa ni mo se maa n lu u." Baale ile eni odun merinlelogbon kan, Ayodele lo so bee niwaju ile-ejo lasiko ti iyawo re, Abigail Ojo, wo o lo sile-ejo, to si ro adajo lati tu igbeyawo odun mejo to wa laarin won ka.

Iyaale ile eni odun metadinlogbon ohun so pe gbogbo igba loun pelu oko oun maa n ja, bee lokunrin naa maa n lu oun nilu baara, ati pe omuti paraku ni, ti ija ba si ti sele, gbogbo eru inu ile lokunrin naa maa n baje.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein

Ojo gbogbo ni tole, ojo kan ni tolohun. Owe yii lo se mo awon afurasi odaran merin kan towo ileese olopaa ipinle Kwara te pe won maa n gba ogunlogo owo lowo awon araalu pe awon yoo ba won wa ise ijoba nipinle naa, to si je pe ogbon ati ete lati lu won ni jibiti ni.

Ojo Isegun, Tusde, ose to koja ni ileese olopaa ipinle Kwara safihan awon afurasi odaran mereerin naa fawon akoroyin pelu esun pe nise ni won ka awon ayederu leta igbanisise awon ileese ijoba apapo ati tipinle Kwara mo won lowo.

Lara awon leta naa ni ti ajo to n ri si irin-ajo Hajj lorile-ede yii (Nigeria Hajj Commision), ileese 'Nigeria Port Authority', ileese 'Kwara State Teaching Service Commission', 'Kwara State Universal Basic Education Board', ajo SUBEB atawon mi-in.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

Mumini Lu Magun Lara Iyawo Oloye Ilu n'Iyana-Offa
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Mumini Lu Magun Lara Iyawo Oloye Ilu n'Iyana-Offa

Iku okunrin awako ero kan to n je Mumini niluu Lalupon, nipinle Oyo, ti ko itiju nla ba awon ebi ati ojulumo re bayii pelu bi okiki ti se kan kiri pe aisan ibalopo kan ti won n pe ni magun ni baba naa lu.

Lara iyawo baba oloye kan niluu Iyana-Offa ni won ni Mumini ti lu magun, sugbon ko si eni ti i ba mo pe magun lokunrin awako yii lu bi ko ba se pe oun funra re fi enu ara e so o nitori ojo keje to kan ijangbon ohun ni kinni naa ja si iku fun un.

Awon olugbe ilu Iyana-Offa fidi e mule pe o pe ti Mumini, eni tawon eeyan tun mo si Gidado pelu iyawo baba oloye naa to n je Iya Ade ti jo n se wolewode ikoko. Bo si tile je pe oko-iyawo ko mo si ibasepo yii, sibe, ara fu baba naa nitori irin tiyawo e maa n rin lopo igba ki i ye e, bee lobinrin naa ki i gba ko ba a lajosepo ninu ile.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Iyaale Ile To Fi Kokeeni Soyun Ti n Ka Boroboro
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Iyaale Ile To Fi Kokeeni Soyun Ti n Ka Boroboro

Owo ileese to n ri soogun oloro gbigbe lorile-ede yii, NDLEA, ti te obinrin kan toruko re n je Dorothy Onyekas to fi kokeeni soyun. Nise ni obinrin to ti bimo meta naa to n bo lati orileede Dubai fee gbe kinni ohun wole lati papako ofurufu ile wa to wa n'Ikeja. Lasiko tawon ileese to n gbogun ti oogun oloro n sayewo re ni akara tu sepo.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, isesi obinrin yii ati irisi re jo ti alaboyun, sugbon nigba ti won sayewo re lori ero to maa n -ihan ara eeyan bi ohunkohun ba wa nibe ni won ri i pe ki i se oyun lo wa nibe bi ko se idi kokeeni to fee to giraamu meji.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

Imeh Ha Sowo Olopaa L'Ekoo, Aburo Iyawo e Lo Se Kinni un Fun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Oluyinka Soyemi

Imeh Ha Sowo Olopaa L'Ekoo, Aburo Iyawo e Lo Se Kinni un Fun

Iwadiigidi lo n lo lowo bayii lori iwa ainitiju ti afurasi odaran eni odun merindinlogoji kan, Imeh Akpan, hu latari bo se ba aburo iyawo re lasepo ni tipa. Ose to koja ni ileese olopaa ipinle Eko safihan okunrin naa lolu-ileese won to wa n'Ikeja, nibi to ti n seju pakopako nigba to n so ohun to ri lobe to fi waro owo.

Iwadii Iwe Iroyin Yoruba fi han pe agbegbe Obalende ni afurasi ohun n gbe pelu iyawo re, omo to fipa ba lo po ta a foruko bo lasiiri yii si wa lodo won. Agbo pe lati kekere lomo naa ti n gbe pelu molebi naa, aburo iyawo ni, sugbon o jinna si egbon re gan-an lojo ori.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja

Ko seni to le so pato ohun ti Lucky Bassey, eni odun mokandinlaaadota se fun iyawo re Grace, eni odun mokanlelogbon, ti ko se ro nnkan kan mi-in ro o ju pe ko da emi re legbodo lo pelu bo se fi obe idana dunbu re. Eyi lo mu kadajo ile-ejo majisireeti kan to wa l'EbuteMeta pase pe koun ati orekunrin re ti won jo gbimo-po seku pa oko re ohun si wa latimole ogba ewon to wa ni Ikoyi.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ni nnkan bii aago merin oru ojo keeedogbon, osu kin-in-ni, odun yii, nisele naa waye ni ojule ketalelogun, laduugbo Abari, n'Iyana-Ipaja, niluu Eko, iyen nigba ti Grace gbimo-po pelu orekunrin re to n je Benjamin Otu lati pa oko re ti won jo wa lati Akwa Ibom pelu obe idana. Ohun to si buru ju ninu oro naa ni pe oju oorun ni oko omobinrin yii wa tawon mejeeji fi pitu owo won.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Friday Paro Pe Won Ja Tanka Epo Gba Lowo Oun, Lo Ba Loo Ta a Sona Jebba
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Kayode Omotosho, Ilorin

Friday Paro Pe Won Ja Tanka Epo Gba Lowo Oun, Lo Ba Loo Ta a Sona Jebba

Pelu bi ori se n ta awon omo orile-ede Naijiria fun bi epo bentiroolu se won bii imi eegun, ileese olopaa ipinle Kwara ti mu awako tanka epo kan ti oruko re n je Friday Joseph, eni odun metadinlogbon lori esun pe o paro, o si tun lu jibiti.

Ojo Isegun, Tusde, ose to koja ni ileese olopaa ipinle Kwara wo Friday lo siwaju Adajo K.A Yahaya. Esun ti olopaa to n soju ijoba nile-ejo, Inspekito Matthew Ologbonsaye, fi kan Friday ni pe nise ni okunrin yii fi ese ara re rin wa si tesan olopaa to wa ni Omu-Aran, lojo kerindinlogbon, osu keta, odun yii, ni nnkan bii aago mokanla oru pe awon adigunjale merin kan da oko tanka epo Mack toun n wa, eyi ti nomba re je AKD 518 XL ti epo bentiroolu egberun metalelogbon lita wa ninu re, eyi ti owo re le ni milionu merin ati aabo naira(#4,587,000.00) duro, ti won si ja a gba lowo oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Fasasi Ko Iyawo e Sile N'Ibadan, O Ni Ko Ro Amala Fun Baba Oun
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Fasasi Ko Iyawo e Sile N'Ibadan, O Ni Ko Ro Amala Fun Baba Oun

Ohun to n dun ni ni i po loro eni, ologun eru ku, aso re je okan soso. Bi ki i baa se ooto lowe awon agba yii ni, ko ni i je pe nitori amala lasan lasan ni baale ile kan, Akanji Fasasi, yoo fi ko iyawo e sile ni kootu nitori to ko lati ro amala fun baba e, to ni afebipani obinrin ni i se.

Bo tile je pe iyawo Fasasi, Akanji Odunayo, gan-an lo pe ejo naa, to si ro ile-ejo lati fopin si ibasepo olodun mejo to wa laarin oun atoko e nitori awon ebi oko oun ko feran oun pelu bo se ni won ti folopaa mu oun ri, ati pe eemeji otooto ni iya oko oun binu da gbogbo eru oun sita, bee lawon ebi oko oun tun ti figba kan da eru oun atawon omo oun sita, sibe, o see se ki ile-ejo ba won pari ija naa bi ko se ti ejo toko ro, to ni iyawo oun ko ro amala fun baba oun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure N
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure Ni Moto Te e Pa Si

Surusuru lomije n da loju awon eeyan to wa nibi toko akero kan ti te omokunrin eni odun meeedogbon kan pa l'Akure laaaro Ojobo, Tosde, ose to koja yii.

Gege bi alaye ti okunrin kan tisele naa soju re se fun wa nigba ta a sabewo si geeti ogba Fasiti Imo Ero (FUTA) to wa l'Akure leyin isele naa, o ni jeeje lokunrin toko te pa ti won poruko re ni Johnson Ogah n ta ipekere re nigba ti moto ohun sadeede loo ya ba a nibi to duro si, to si te e pa.

Oko boosi akero naa ti nomba idanimo re je Oyo XC 247 YYY to n bo lati Ileefe lo deede ya kuro loju ona tire nigba to de iwaju geeti Fasiti Imo Ero naa, to si se bee loo kolu awon moto mi-in to n lo ni tiwon, ko too waa te Johnson pa nibi to wa. Loju-ese lo ni omokunrin yii ti ku, bee ni ipekere to n ta fon soju titi nibe kaakiri.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?

Orisiirisii leeyan yoo maa ri, beeyan si n wa olori awon alawada bi ko ba ri i, bo ba ti ri Gomina Ekiti, Ayodele Fayose, ko sinmi a n rin igboro kiri mo, oga awon alawada patapata lo ti ri yen. Ni gbogbo ose bii meji meta seyin, nise ni Fayose n soro to n laagun, to n kuru to n ga, to n bu eebu to n fepe bonu, inu e ko dun rara pe Aare Muhammadu Buhari fee lo si China. 

O ni ki lo n wa lo, oun gbo pe o fee loo yawo, ko jokoo sile ko ma yawo kankan, ati pe nigba ti Naijiria ko fararo, ko si onisowo ile China kan ti yoo wa si Naijiria lati waa fi owo re da ise sile, nigba to ti mo pe oun ko le ri ere kankan je.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin

Afaimo kawon okunrin meta kan, Wasiu Alayande, to je eni odun mejidinlogbon, Fayose Ebenezer to je eni odun mokandinlogun ati Adeleke Adewale, eni odun mejilelogun ti won filu Ekiti sebugbe ma faso penpe roko oba niluu Ilorin pelu bi ileese olopaa ipinle Kwara se wo won lo sile-ejo lori esun igbimo-po lati sise ibi ati nina owo ayederu.

Nigba to n rojo tako won lojo Isegun, Tusde, ose to koja, Inspekito James Wodi to gbenuso fun ileese olopaa so pe arabinrin olutaja kan toruko re n je Funke lo mu esun to ileese olopaa wa pe soobu oun to wa ni Erin-Ile loun wa ti Ebenezer ati Wasiu ti won wa lati ipinle Ekiti fi waa ra miliiki ati ose iwe tiye owo re je igba naira. O ni obinrin naa se e lalaye pe egberun kan naira (N1000) lawon afurasi naa gbe le oun lowo, toun si fun won ni senji egberin naira (N800.00).


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Tunmise Ji Kaadi ATM Ore e Ni Saki, Owo Nla Lo Fi Wo Jade
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Tunmise Ji Kaadi ATM Ore e Ni Saki, Owo Nla Lo Fi Wo Jade

Loooto lowo ti te omobinrin akekoo ileewe gbogbonise Poli Oke-Ogun to wa nipinle Oyo, Tunmise Isola, lori esun pe o ji kaadi ATM omobinrin kan ti won jo n gbe, Suleman Nafisat Oluwatoyin, sugbon oju boro ko gba omo lowo ekuro loro naa komobinrin ohun too pada jewo nigba ti won wo o de odo awon agbofinro.

Omo orukan ni Oluwatoyin ti Tunmise ji kaadi re yii, ko si ti i ju ojo merin lo ti won mora won ti Tunmise fi se bee gba egberun marundinlogota (55,000) ninu egberun lona igba o le die tomobinrin naa ni ninu asuwon re. Alaye ti Nafisat se fakoroyin wa ni pe oun ko ni oluranlowo kankan latigba ti awon obi oun ti ku, kaadi ipe loun n ta toun fi ran ara oun nileewe girama, kaadi ohun loun si ta titi toun fi ni egberun lona igba naira nipamo. O ni owo naa loun lero lati fi pari iwe oun nileewe ti won sese ti mu oun yii.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina

''Oko mi n soogun, o si daju pe o ti fi pata mi soogun owo nitori pe latigba ti pata mi ti di awati ni mi o ti ni ifokanbale ati alaafia mo, se ni mo maa n gbo tenikan maa n pe oruko mi ti mi o si ri onitohun, mo kan maa n gbo oruko mi saa ni.'' Iyaale ile kan, Abileko Igbolanu Philomina, lo so bee lasiko to to ile-ejo ibile kan lo, to si ro aare ile-ejo ohun lati tu igbeyawo olodun merindinlogun to wa laarin oun pelu oko re, Bonaventure, ka.

Obinrin ohun so pe gbogbo igba nija maa n waye laarin awon, bee lokunrin naa maa n se agbere kiri, omuti paraku ni, ko toju oun pelu awon omo, o si maa n se oogun pupo.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Nitori Wahala Ojoojumo, Igbeyawo Odun Mefa Tuka L'Osogbo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Wahala Ojoojumo, Igbeyawo Odun Mefa Tuka L'Osogbo

Kootu ibile keji niluu Osogbo ti tu igbeyawo olodun mefa ka laarin Ogbeni Rasheed Olalekan atiyawo re, Mutiat Olalekan, lori esun wahala ojoojumo.

Ogbeni Rasheed lo mu ejo iyawo re lo sile-ejo, o ni onijagidijagan ati oniwahala niyawo oun to je onisowo, ati pe oun ko le farada wahala re mo lo je koun fee jawee fun un.

O ni, ''Wahala re ti po ju, ki i gbo ibawi rara, ko fi mi lokan bale ninu ile. Mo ti koko figba kan fi olopaa mu un, sugbon awon yen so pe tori pe o n gbe omo kekere lowo, ki n se suuru.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo

Baa ti n koroyin yii, atimole ileese olopaa ipinle Ondo lomokunrin kan toruko re n je Sunkanmi ti n ran awon olopaa lowo lori iku airotele to fi pa okunrin kondokito kan to n je Ojo lasiko tawon mejeeji fija peeta.

Isele naa sele ni gareeji Oloko to wa loju ona marose IlesaÍOwo, niluu Akure, nibi ti won so pe Iya Sunkanmi ti n ta ounje.

Gege bi alaye ti okan ninu awon awako to n sise ni gareeji ohun se fun wa nigba ta a sabewo sibi isele naa, iresi sise nikan ni Iya Sunkanmi n ta ninu gareeji ohun. Sugbon lojo tohun buruku yoo sele ni gareeji naa lo da bii eni pe iresi ti Iya Sunkanmi n ta ko wu Ojo i je, idi si ree to fi lo sile olounje mi-in ti ko fi bee jinna sibe.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Owo Te Happiness To Ji Omo Olomo Gbe Sa Lo L'Ekoo
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Owo Te Happiness To Ji Omo Olomo Gbe Sa Lo L'Ekoo

Ileese olopaa ipinle Eko ti n ba iwadii lo lori bi okunrin kan, Happiness Umah, se ji omodebinrin kekere kan lagbegbe Ijora, sugbon ti owo won te e ko too gbe e sa lo patapata.

Iwadii Iwe Iroyin Yoruba fi han pe omo osu meje pere ni omobinrin toruko re n je Favour ohun, o si ku die ki Happiness ri i gbe sa lo kowo too te e. Ohun ti a ri gbo ni pe awon olopaa ayarasise (Rapid Response Squad) to n sise lagbegbe Eric Moore lo ri okunrin naa ti won si fura si irin ese re. Nigba ti won beere bi omo se je lowo re, o ni omo oun ni, sugbon nigba ti ibeere po lo tun ni se loun ri omo naa ninu igbo nibi to ti n sunkun.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri

Ogba ewon to wa ni Kirikiri ladajo ni ki won fi ayederu looya kan, Emmanuel Uba, to puro gba milionu mejilelogun naira (N22m) lowo okunrin onisowo kan si titi digba tigbejo mi-in yoo fi waye lori iwa arufin to hu.

Odun 2014 ni won ti koko fesun yiyi iwe ati jibiti kan okunrin naa. Igbejo ohun ni won se ti won fi fun un ni beeli idaji milionu naira (N500,000) ati oniduuro meji. Sugbon ti oro yiwo nigba tawon ibatan Emmanuel meji ti won soniduuro fun un mu esun to awon olopaa lo pe awon ko mo ibi ti afurasi yii sapamo si nitori gbogbo igba tawon ba beere e lowo iyawo atawon omo e ni won ki i le so pato ibi to wa. Eyi lo mu kawon agbofinro topinpin re, ti won si ba a nibi to lugo si labe beedi.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Won Ti Ran Oga Ileewe To Fipa Ba Akekoo Re Lo Po Lewon Odun Mewaa L'Ekiti
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Won Ti Ran Oga Ileewe To Fipa Ba Akekoo Re Lo Po Lewon Odun Mewaa L'Ekiti

Oludasile ileewe aladaani kan, Ogbeni Babatunde Ibitoye nile-ejo giga kan to wa niluu Ado-Ekiti pase ewon odun mewaa fun nitori esun fifi ipa ba akekoo ileewe re kan to je omo odun mewaa lo po niluu Ado-Ekiti.

Ibitoye to nileewe alakoobere God's Grace Nursery and Primary School to wa lagbegbe Agric Olope, ni Ajilosun, niluu Ado-Ekiti, lowo te lojo kewaa, osu kefa, odun 2013, lasiko to n ki omodebinrin ohun mole ninu oja ohun.

Gege bi idajo Adajo Toyin Abodunde, eri ti olupejo je fi lele pe lai si tabi-sugbon kan nibe, olujejo fipa ba akekoo naa lo po.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Onisowo Ibadan Bo Lowo Awon Ajinigbe Leyin Ojo Marun-un Ninu Ahamo Won
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Onisowo Ibadan Bo Lowo Awon Ajinigbe Leyin Ojo Marun-un Ninu Ahamo Won

Ori ti ko obinrin onisowo Ibadan kan, Risikat Badiru, yo lowo iku ojiji pelu bo se ko sowo awon agbenisowo ti won mura lati pa a danu, sugbon ti won pada fi i sile leyin to lo odidi ojo marun-un ninu ahamo won.

Obinrin onisowo yii siwo ise fojo naa, iyen lale ojo Aje, Monde, ti i se ojo kerinla, osu keta, odun yii. Funra re lo si wa oko ayokele e lati ibi to ti n taja dele. Sugbon bo se de enu ona ile lawon eruuku ti won gun okada be gija siwaju e pelu ibon. Oko ayokele Honda re ohun naa ni won si fi waa lo sona jinjin rere.

Gege bi oga-agba olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade, se fidi e mule, inu ile nla kan nitosi ilu Imodi, nipinle Ogun, lawon ajinigbe ohun loo gbe Abileko Risikat pamo si. Leyin naa ni won pe awon ebi e lori ero ibanisoro pe owo awon ti ba iya naa, pipa lawon yoo si pa a bi won ko ba tete wa ogun milionu naira wa, bo tile je pe won pada din owo ohun ku si egberun lona eedegbeta naira (N500,000).


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Alake To Fee Ko Oko Dero Ewon N'Ilorin
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Alake To Fee Ko Oko Dero Ewon N'Ilorin

Afi bii igba teeyan n wo sinima ofe loro naa ri ni kootu ibile to wa ni Centa-Igboro, niluu Ilorin, lose to koja nigba tobinrin kan, Adamo Alake, wo oko re, Isiaka Alao, wa si kootu pe oun fee ko o, sugbon to je pe ogba ewon Oke-Kura lo ba ara re nigba to mu adajo ile-ejo naa bu.

Adamo mu esun wa siwaju Adajo Ibrahim Abdulkadri pe latodun marunlelogun toun ti fe Isiaka ni ko ti somo laarin awon, idi niyi toun se fee ko o.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Olusiro-owo Gbe Owo Awon Osise Sa Lo L'Akoko
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Olusiro-owo Gbe Owo Awon Osise Sa Lo L'Akoko

Nnkan ko fararo rara niluu Ikare-Akoko lose to koja lo lohun-un pelu bawon osise eleto ilera niluu naa se fehonu han lori bi won ko se rowo osu kokanla gba leyin ti won nijoba ti sanwo ohun sinu asuwon banki tawon osise naa n lo.

Gege bi ohun ta a gbo, eni ti won lo je olusiro-owo-agba nileewosan ijoba ipinle Ondo to wa niluu Ikare-Akoko, Ogbeni Aminu Kamilu, ni won fesun kan pe o ledi apo po pelu enikan, ti won si jo gbowo ti won lo to bii milionu meje lara owo to ye ki won fi sanwo osu kokanla awon osise eleto ilera nileewosan ohun.

Awon osise ileewosan naa la gbo pe ara n fu, eyi to mu ki won bere si i yo olusiro-owo ohun lenu nipa bi won yoo se rowo osu kokanla gba, sugbon o saa n fi won lokan bale pe ki won ni suuru, laipe lowo won yoo te won lowo. Bee lawon osise ohun ko kuku mo pe ijoba ti sanwo won, sugbon to je pe olusiro-owo naa lo n lo agbara tire le won lori.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Nitori Airomobi, Toko-tiyawo Padanu Milionu Merinlelogun Naira Sowo Ayederu Doki
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Airomobi, Toko-tiyawo Padanu Milionu Merinlelogun Naira Sowo Ayederu Dokita Ati Aafaa N'Ibadan

Bi iya nla ba gbe ni sanle, kekere a maa gori eni, adia fokunrin onisowo kan, Ogbeni Caleb, atiyawo e to n je Funke ti won n sunkun airomobi, won mu ookan kun eeji, won gba ile onisegun oyinbo lo nitori aajo ati dolomo laye, laimo pe owo ayederu dokita lawon ko si.

Nigba toju won yoo si fi la, won ti padanu owo bii milionu merinlelogun naira sowo ayederu dokita naa.

O jo pe ayederu obinrin dokita ohun, Damilola Ojo, eni topo awon to mo on saaba maa n pe ni Dokita Dammy ti mo iru isoro tawon toko-tiyawo yii ni. Isoro ohun lo fi wole si won lara pelu bo se so fun Abileko Funke pe ogboju dokita to mo nipa itoju awon aisan to n fa airomobi loun i se, oun si setan lati ran won lowo ninu isoro naa pelu itoju to peye.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Tope To Pa Lanloodu e L'Ondo Ti Wa Lewon
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Tope To Pa Lanloodu e L'Ondo Ti Wa Lewon

L'Ojobo, Tosde, ose to koja yii, nileese olopaa nipinle Ondo wo okunrin eni odun mejilelogun kan, Akindeji Tope, to pa lanloodu re nitori kanga lo sile-ejo majisreeti kan l'Oke-Eda, niluu Akure.

Gege bi ejo ti Inspekito Martins Olowofeso ti i se agbenuso olopaa ro lasiko ohun lese, nnkan bii aago mefa aabo aaro ojo kokanla, osu ta a wa yii, lojule kerinlelaaadorin, laduugbo Ayeferere, niluu Ondo, nijoba ibile Iwo-Oorun Ondo, ni Tope seku pa lanloodu re, Ogbeni Osunkalu Kayode.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Tessy Loyun L'Ondo, Lo Ba Loo Ta Omo To Bi Si Onitsha
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

Tessy Loyun L'Ondo, Lo Ba Loo Ta Omo To Bi Si Onitsha

Owo ileese olopaa ipinle Ondo ti te toko-taya kan, Ogbeni ati Abileko Sunday Kalu, lori esun pe won ra omo tuntun jojolo lowo obinrin eni odun metadinlogun kan toruko re ni Tessy Obianua.

Awon meji mi-in ti won tun fesun kan pe won sonigbowo bi Tessy se gbomo bibi inu re ta fun toko-taya naa ni Abileko Chibuzor Okoye ati Ogbeni Jude Azuka, ti gbogbo won si jo n ka boroboro lolu ileese olopaa to fikale si Igbatoro, niluu Akure.

Gege bi ohun ta a gbo lori isele to waye niluu Ogbese, nitosi Owo, nijoba ibile Owo, nipinle Ondo ohun, okunrin kan toruko re n je Sola ni won lo fun Tessy loyun lodun 2014, sugbon dipo ki Tessy gboyun feni to ni in, Jude to je alabaagbe awon obi re niluu Ogbese lo sa loo ba niluu Onitsha, ninu osu kin-in-ni, odun to koja.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

E Gba Mi Lowo Iyawo Mi o, O Fee So Mi Di Dindinrin — Rafiu
(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )

 
 
Lati Owo Akoroyin Olootu

E Gba Mi Lowo Iyawo Mi o, O Fee So Mi Di Dindinrin — Rafiu

Se ni gbogbo awon ti won wa ni kootu ibile keji niluu Osogbo n woju ara won lasiko ti okunrin kan, Bakare Rafiu, n so niwaju awon adajo pe ki won tete ba oun tu igbeyawo oun pelu Bakare Kehinde ka ko too di pe obinrin naa yoo so oun di dindinrin gege bo se n leri.

Ogbeni Rafiu ni alaafia ti ko si ninu ile loun koko n dojuko latodo iyawo toun fe lodun mesan-an seyin ko too di pe o tun bere si i leri kiri pe oun yoo so oun di dindinrin patapata.

O ni yato si eleyii, alaarifin niyawo oun, ko niteriba fun enikeni, koda, ki i fojuure wo awon obi oun, epe lo fi maa n ranse si won ni gbogbo igba.


(Lati Ka Siwaju... | More | Se Ẹ fẹ Ṣe Asọye? | Esin )
 
 


 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: