Gbagede Yoruba
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

It's Haram To Aid, Promote Or Participate In The Oodua Nation Agitation
(Itan ni kikun... | 2022 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)



(Itan ni kikun... | 2022 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)
(Itan ni kikun... | 23049 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Abala Ti Akojopo

Gbigba Kadara Gbo - Al-Imaan Bi-l-Qadar (Ayanma Tabi Akosile)

Eko ni soki
Kosi isinmi beeni kosi ifayabale fun eru ayafi ki o ni igbagbo si ebubu Olohun ati kadara re, eleyi ni ki o gbagbo wipe ohun ti Olohun ba fe ki o se, ni yio se,ohun ti ko baa fe ki o se,ki yio se,atiwipe, dajudaju, ti gbogbo aye yii ba parapo lori atifi inira kan-an, won ko lee se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile le lori, ni idakeji, ti won baa korajo lati se e ni anfaani, won ko le se bee, ayafi ohun ti Olohun ba ti ko sile fun-un.

Oripa (Koko Alaiye):

Alayẹ lori paapaa igbagbọ ninu kadara atipe orígun kan lo jẹ ninu awọn orígun igbọlọhun gbọ.
Alayẹ nipa pe kadara kose fise ikẹwọ lọri ẹsẹ dida.
Ojuse ẹniti ohunti ko tẹẹ lọrun ba sẹlẹ sii ninu kadara.
Awọn oore to mbẹ nibi inigbagbọ ninu kadara.
Isọra kuro nibi ìròrí awọn ẹni anù nibi kadara.


Apa Kini

الحمد لله رب العالمين , خلق كل شيئ فقّدره تقديرا, وقال في محكم تنزيله: " إنا خلقنا الإنسان من نطفة أمشاج نبتليه فجعلنه سميعا بصيرا (1) إنا هديناه السبيل إما شاكرا وإما كفورا" وأشهد أن لا إله ألا الله وحده لا شريك له, سبحانه وتعالى عما يقول الظالمون علوا كبيرا , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله بعثه شاهدا وبشيرا ونذيرا, وداعيا إلى الله بإذنه وسراجا منيرا, صلّ الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا – أما بعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, ọba to sẹda gbogbo agbaye. O da gbogbo nkan, O si pebubu rẹ daada , O sọ ninu tira Rẹ rẹ pe: Dajudaju Awa ni A da eniyan lati ara omi gbọlọgbọlọ ti a ropọ mọ ara wọn, ki a le baa dan an wo, nitorinaa ni A se ni olugbọrọ Oluriran. Dajudaju A ti fi mọ ọna ti o tọ taara: O le jẹ oluse ọpẹ, o si le jẹ alaimore” Suratul Insani: 2 – 3.


(Itan ni kikun... | 23049 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara
(Itan ni kikun... | 5616 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Ilu Kan, Oba Marun-Un: Oba Ni Egba Ake, Egba Owu, Egba Agura, Oke Ona Ati Ibara

Ninu isedale ati idasile itan ile Yoruba, okan pataki ni eya Egba je. Eya kan ni to je pe pupo ninu adamo won ko si ninu awon eya to ku nile Yoruba ti Olodumare si fi ebun ife ati isokan jiǹki won.

Yato sa asa ati ise ti a mo won mo, iwa omoluabi, irele ati ikonimora je ki eya yii di ilu-mo-o-ka kaakiri agbanla aye. A ri eleyii nibi eto isejoba, eto oro aje, eto amuluudun, eto oselu, esin ati awon asa miiran ti a fi le gbe oriyin fun omoniyan.

Nibi eto oselu, Egba lo wa loke titi di asiko yii, nitori pe awon bii Oloye Olusegun Obasanjo, Oloye Ernest Sonekan, Oloye Olusegun osoba ni ko see fowo ro ti seyin. Bakan naa nibi eto oro aje, awon bii Oloogbe Moshood Kasimaawo Abiola ni won ń wa loke.

Nibi eto amuluudun, Egba naa le maa ri niwaju nitori pe awon bii Oloogbe Akin ogungbe, Oloogbe Duro Ladiipo atawon miiran ni won so eto amuluudun dirorun. Bee nibi eto eko, ko tii si ilu kan ninu awon eya Yoruba ti won le figagbaga pelu awon omo Egba ti won ti wa loke atawon to sese ń dide bo bii, ojogbon Wole Soyinka ta gba ami eye agbaye, eyi ti enikeni ko tii gba iru e ri nile Yoruba, paapaa lorile-ede Naijiria, Omoba Bola Ajibola to je oludajo agba nile ejo agbaye ti ko tun tii si iru e dasiko yii. ojogbon Akinwunmi Isola, Debo Alebiosu, Alagba J.F Odunjo, Amofin Bola Solańke to je eni to koko gba oye imo ofin lorile-ede Naijiria, Oloogbe Titilayo Ransom Kuti to je obinrin akoko to koko wa oko nile Yoruba ati lorile-ede Naijiria lapapo.


(Itan ni kikun... | 5616 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Ijoba Ipinle Osun Ti Ki Oselu Bo Eto-eko O - Awon Eeyan Iwo-Oorun Osun Ke Gbajar
(Itan ni kikun... | 2079 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Ijoba Ipinle Osun Ti Ki Oselu Bo Eto-eko O - Awon Eeyan Iwo-Oorun Osun Ke Gbajare

Awon olugbe agbegbe Iwo-oorun Osun ti ke si gbogbo awon abiyamo tooto ti won mo pataki eto eko gba won lori igbese tijoba ipinle Osun gbe lati da eto-eko ofe lenu isinmi tawon akekoo agbegbe naa maa n se duro.

Lati odun merin seyin ni ajo kan to n je Alaafia Dotun eleyii ti Omooba Dotun Babayemi nsagbateru re ti maa nseto eko-ofe fawon akekoo ninu olude, eleyii to mu ki ipo eko lawon agbegbe naa muna doko sii

Omooba Babayemi wa ninu egbe oselu APC ni gbogbo asiko yen, ko si si wahala kankan rara, sugbon ni kete ti okunrin naa bo sinu egbe oselu PDP ni oniruuru igbese ti n waye lati dawo ohun gbogbo to n se duro.

Okan lara awon agbenuso fawon eeyan ilu Gbongan, Alhaji Ojewale salaye pe ko si obi ti inu re ki i dun si eto naa latigba to ti bere nitori pe ajo naa ko fi ti egbe oselu kankan se rara.

O ni gbogbo eto ni won tun ti la sile fun ti olude yii, koda, eto-eko ofe naa ti bere lawon ibugbe mejidinlogbon ti won ti fee se e kaakiri ekun idibo naa ko too di pe iwe kan wa lati ileese to n ri si eto eko nipinle Osun pe ki won dawo duro.


(Itan ni kikun... | 2079 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awok
(Itan ni kikun... | 5255 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awokose Igbeaye Ojise-Olorun

Pelu bi awon musulumi jakejado orileede yii se n se ayeye odun Ileya loni, Omooba Dotun Babayemi ti ro won lati ri igbesi aye irele, ife ati ibagbepo alaafia to farahan lara ojise-Olorun, Ibrahim, gege bii awokose.

Ninu oro ikini ku odun re si awon musulumi nipinle Osun, paapaa, niha ekun Iwo-Oorun Osun lo ti parowa yii.

Babayemi, oloselu lati ilu Gbongan ohun woye pe ilana eko Id-el-Adha eleyii to da lorii nini igbagbo ninu Olorun ati gbigbekele ife Re gbodo maa jeyo ni gbogbo igba ninu aye awon elesin Islam.

O ran won leti pe ki i se agbo ti won pa lojo odun tabi eran ti won je lo ni nnkan se pelu Olorun bikose atunhu iwa ati titun igbeaye won yewo.

Babayemi ro won lati mu ife si Allah ati igbagbo ninu Re lokunkundun, ki won si nawo ife yii kan naa sawon alajogbe won nipase eyi ti idagbasoke yoo fi wa nipinle Osun.


(Itan ni kikun... | 5255 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Aku
(Itan ni kikun... | 2173 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Eyi Ni Bi Owo Se Te Alao To Fi Khadija Omo Igbakeji Mimiko Soogun Owo L'Akure

Ileewe girama ni Khadijat Oluboyo ati Adeyemi Alao ti koko bere ere-ife, sugbon won ko gburo ara won mo leyin ti Alao koja silu Abuja nibi to n gbe.

Leyin ti Khadija wo yunifasiti Adekunle Ajasin ti ilu Akungba Akoko ni oro ife won tun wo pada, ti Alao, eni ti inagije re n je QS tun bere sii wolewode pelu Khadija omo Alhaji Lasisi Oluboyo to je igbakeji gomina ipinle Ondo tele, Dokita Mimiko.

Lojo Sannde to koja la gbo pe Alao so pe ki Khadija wa ki oun nile lagbegbe Oke-Aro nilu Akure, omobinrin naa si lo sibe sugbon alo Khadija ni won ri, ko seni to ri abo re.

Lojo kefa ti Khadija di awati la gbo pe oku re dede yo si okan lara awon aburo Alao ninu ile, idi niyen ti onitohun fi bere sii wa vbogbo yara lati mo nnkan to n sele.

Iyalenu lo je faburo Alao nigba to ba oku Khadija labe beedi Alao, o pariwo sita, oro naa si di ti olopaa, bee ni won mu Alao.


(Itan ni kikun... | 2173 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Deji Binu Si Titi Afesona Re, Lo Ba Dana Sun Eeyan Mesan Mole L'Ondo
(Itan ni kikun... | 2087 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Deji Binu Si Titi Afesona Re, Lo Ba Dana Sun Eeyan Mesan Mole L'Ondo

Ileese olopaa ipinle Ondo ti n wa omokunrin kan, Deji Adenuga lori esun pe o dana sun awon molebi orebinrin re, Tutu Sanumi nitori pe iyen so fun un pe oun o se mo.

Deji, eni ti a gbo pe o ti sewon ri ni wahala be sile laarin oun ati Titi, eni ti won ti jo n ba ere aniyan bo lati odun merin seyin, koda, oro naa le debii wi pe won ko ara won lo si agoo olopa, sugbon pabo lo ja si.

Bi Titi se so fun Deji pe o to gee bayii la gbo pe o ti kuro niluu Ondo laije ki Deji mo. Pelu ibinu ni Deji fi lo sile awon Titi to wa loju-ona Igbokoda lojo Tusde, o gbe keegi epo petiroolu lowo, o si dogbon si windo ile naa laarin oru.

O da petiroolu sinu ile, o si ju isana si i, loju ese ni meji ninu awon molebi Titi ku, nigba tawon meje to ku dake nileewosan Trauma Center niluu Ondo.


(Itan ni kikun... | 2087 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Won Ni Akeem Pa Sajenti Opeyemi Iyawo Re, O Ti N Se Faaji Lewon Bayi
(Itan ni kikun... | 1684 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Won Ni Akeem Pa Sajenti Opeyemi Iyawo Re, O Ti N Se Faaji Lewon Bayi

Medinat Adesoye, Osogbo

Adajo kootu kan nilu Osogbo ti pase pe ki won lo fi Abiodun Akeem Oladebo pamo sogba ewon titi ti imoran yoo fi wa lati ileese eto idajo ipinle Osun lori esun ti won fi kan an.

Se lawon olopa so pe Akeem, omo odun mokanlelogoji lo pa iyawo re, Sajenti Opeyemi Ojo lojo keedogbon osu keji odun yii.

Inspekito Tajudeen Mustapha so funle ejo pe se ni Akeem so ori obinrin olopa yi mo ogiri, eleyi to yori si iku ojiji to ku. O ni iwa naa nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun.

Mrs B Y. Dada to duro fun olujejo ro ile ejo lati je koun gba beeli re sugbon Onidajo Ajanaku ni rara, afi ki won lo fi pamo sogba ewon.


(Itan ni kikun... | 1684 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o
(Itan ni kikun... | 2435 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o

Medinat Adesoye

Ile ejo majisreeti ti o tedo si ilu Osogbo ti ni ki arabinrin kan ti oruko re n je Jimoh simiat lo ma gba afefe logba ewon lori esun pe o pa Mama Friday ti won ri oku re ni Oke Osun nilu Osogbo.

Inspekito Mustapha Tajudeen to soju ileese olopa salaye pe lojo kewa osu keji, odun yii ni deede ago meje abo owuro ni agbegbe ile iwe giga Fountain university, ni ilu osogbo ni Simiatu ba Esther Oga to je ore re ja titi ti emi fi bo lenu e.

Inspekito naa so pe afurasi naa ti se lodi si abala 316, ti o si le fi iya je ni abala 319(1), ofin iwa odaran ipinle osun ti odun 2002.

Nigba ti adajo kootu beere oro lowoo Simiatu, o lojo kesan osu keji odun yii ni oun loo ba ologbe naa ni ile lati beere pe se loooto lo so fun oko re, iyen Baba Friday pe olosho ni oun, ti Baba Friday naa si tun so oro naa fun oko toun.

Simiatu ni oro naa lawon loo yanju nidi ogede lojo naa, tawon si tuka.


(Itan ni kikun... | 2435 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Afise Loroo Benjamen Yi O, Leyin To Jade Lewon Lo Tun Loo Ji Telifisan Pasito
(Itan ni kikun... | 1713 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Afise Loroo Benjamen Yi O, Leyin To Jade Lewon Lo Tun Loo Ji Telifisan Pasito

Lagbala iroyin la ti gbo pe adajo majisreeti kan nipinle Eko ti pase pe ki omokunrin eni odun meedogbon kan, Benjamin Akegh loo faso penpe roko oba fun odun kan gbako lori esun ole jija.

Lasiko ti isin irole n lo lowo ninu ijo Redeemed Christian Church of God, Tabernacle of Peace lagbegbe Oluwole Baker, Thomas Estate, Ajiwe, lojo ketadinlogbon osu kinni odun yii la gbo pe olujejo huwa naa.

Benjamen, eni to sese ti ewon de lori esun ole jija kannaa la gbo pe o ti tu telifisan alademogiri ti owo re je egberun lona ogoji naira to si je ti Pasito Ayodeji Adeniyi ni nnkan aago mejo ale ojo naa ko too di pe ara ijo kan ka a mobe.


(Itan ni kikun... | 1713 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Victoria Fi Obe Gun Oko Re Pa; Ladajo Ba Ni Ki Won Loo Yegi Fun Un
(Itan ni kikun... | 687 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Victoria Fi Obe Gun Oko Re Pa; Ladajo Ba Ni Ki Won Loo Yegi Fun Un

Lagbala iroyin la ti gbo pe adajo ile ejo giga kan nipinle Bayelsa, Onidajo Nayai Aganaba ti pase pe ki won loo yegi fun obinrin eni ogbon odun kan, Victoria Gagariga lori esun pe o pa oko re, Henry Gagariga.

Adajo Nayai so pe gbogbo eri to wa niwaju oun lo fidii re mule pe olujejo lo gun oko re lobe pa latari owu-jije to fa wahala laarin won lojo kerin osu keji odun 2015.


(Itan ni kikun... | 687 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba
(Itan ni kikun... | 12607 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Itan Bi Ladoke Akintola She Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba

Oro awon oloshelu, too too too ni. Paapaa ni ile Yoruba yii, oro awon oloshelu too too ni. Ni 1964, opolopo eeyan ko ranti oye Aare Ona Kakanfo mo rara. Elomiiran ko tile gbo o ri, won o si mo ohun ti won n pe bee. Bee agbalagba ni won, awon mi-in ninu won si ti le ni omo adorin (70) odun daadaa. Ko le she ko ma ri bee, nitori eni to je Aare Ona Kakanfo yii gbeyin ko too di 1964 yii, Momodu Obadoke Latoosa, eni ti gbogbo aye pada mo si Aare Latoosa ni. Ojo keta, oshu kewaa, odun 1871, lo di aare naa, oun si ni Aare Ona Kakanfo to je gbeyin, nitori lasiko re ni Ogun Ekiti Parapo ti won tun n pe ni Ogun Kiriji waye, ogun naa ko si pari titi ti awon oyinbo fi de. Awon oyinbo funra won ni won pari ogun naa, ti won si shofin pe ko gbodo tun si ija tabi ogun eleyameya laarin awon Yoruba, tabi ni ibi gbogbo ni Naijiria mo.

Nidii eyi, nigba to she pe o din die ni ogorun-un odun ti won ti je Aare Ona Kakanfo yii gbeyin, opo eeyan ni ko ranti mo, afi awon ti won ba n ka iwe itan ile Yoruba nikan. Sugbon ni 1964, awon oloshelu hu kinni naa yo pada, Alaafin Gbadegeshin Ladigbolu si fi Samuel Ladoke Akintola she Aare ile Yoruba ninu oshu kejo, odun naa, oro naa si mu idunnu pupo ati ironu pupo dani fawon eeyan. Bawon kan ti n dunnu pe kinni naa daa, bee lawon mi-in n ronu pe eeti je, kin nitumo oye yii, ki lo si de to je Ladoke Akintola ni won gbe e fun. Oro naa mu awuyewuye ati opolopo ariyanjiyan dani, kaluku shaa fee mo idi abajo ni. Sugbon boya eni kan fe, boya eni kan ko, Akintola ti di Aare-Ona Kakanfo fun ile Yoruba, ko si si ohun ti enikeni le she si i. Ko tie kuro lori ipo naa titi ti olojo fi de ba a ninu oshu kin-in-ni, odun 1966, o lo oye naa titi digba naa ni.


(Itan ni kikun... | 12607 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O
(Itan ni kikun... | 8039 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O

Alaigboran ni wa. Tabi ki n so pe alaigboran ti po ju ninu iran awa Yoruba. A feran abamo pupo. Bi enikan ba roye kan, tabi to ba soye lori ohun kan, tabi to ba ni iriri kan to fi to awa to ku sona, kaka ka gbo, yeye la oo fi i she, tabi ka maa bu u, awon mi-in aa tie mura lati she e leshe ti won ba le sun mo on. Nigba ti oro naa ba waa shele, to ba je bi eni naa ti wi lo pada ja si, awon yii kan naa ni yoo dide, won yoo ni awon ko mo ni, abamo yoo si dun lenu won bii nnkan. Ko dun mo mi ninu lati maa wi pe oro ti mo wi she tabi ko she, sugbon nigba to waa she pe opo awon to wa nile yii, aletilapa ni won nko! Ki a too dibo odun 2015, mo pariwo to, mo pariwo gan-an, tawon kan si mu mi lotaa, tawon mi-in n shepe le ara won lori ti won ro pe emi ni. Sugbon bi a ti dibo tan lawon ohun ti mo ri ti mo fi soro bere si i she, gbogbo wa si foju ri i.

Nigba naa lawon eeyan bere si i ke abamo, 'baba, a o mo ni, baba, oro ti e wi lo ti n she yii o, baba, e ma binu.' Sugbon anfaani wo lo wa ninu abamo? Oore kin ni abamo yoo she feni to ba she e? Sugbon oore kan wa nibe o, oore naa ni ka lo o lati fi gbaradi fojo iwaju, ka ba ara wa soro pe ti iru nnkan yii ba tun shele lojo mi-in, a oo gboran sira wa lenu. Sugbon ki lo tun shele nigba ti ibo odun yii de? Awon mi-in pe mi ni were danwo, awon mi-in ni ki lo de ti mo koriira Fulani to bee, awon mi-in si so pe Buhari ni mo koriira. Loju awon dindinrin mi-in, won n gbeja APC, egbe oshelu won niyen o, won si ti ri emi gege bii omo PDP. N ko mo ibi ti won ti pade ti won ni won gbo oruko mi ninu egbe kankan, tabi ti mo ba n she oshelu, ko ye ki won ti fi emi naa si ipo nla ni. Ti pe n ko mowe to ni tabi ti pe n ko dagba to, nigba ti won n mu baba odun marundinlaaadorun-un (85) ninu wa lati gbe ile ijoba le won lowo.


(Itan ni kikun... | 8039 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo
(Itan ni kikun... | 7746 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo

Latigba ti mo ti n soro ashaaju Yoruba, igba kan ma fere koja ti n ko ni i gba atejishe lori awon oba ile wa, paapaa awon ashaaju oba meji ta a ni, Ooni ati Alaafin, pelu Aare Ona Kakanfo. Atejishe ti mo n gba naa ni pe iru awon to ye ko she ashaaju fun Yoruba ti mo n wi niyi, iru awon oba to ye ko ko Yoruba lo sibi ti mo fe niyen, awon oba to lashe lenu. Loooto ni. Ko si ohun ti iba wu mi bi ki eni kan ninu awon meteeta yii je ashaaju fun Yoruba. Idi ni pe awon meteeta ni won ti di ipo naa mu ri, ti won si ko Yoruba debi to dara. Ni ibere pepe, Oduduwa ni olori gbogbo wa, ashe ti Oduduwa ba pa ni gbogbo Yoruba to ku yoo tele nibikibi ti won ba wa, bo ba ti pashe bayii, ashe naa yoo mule ni. Eni to ba si fee mo bi agbara yii ti po to ko ranti igba tawon ilu Ibinni (Benin) n wa olori, to je Oduduwa ni won waa ba ko fun won loba.

Tabi ta ni yoo so pe oun ko mo agbara Alaafin nile Yoruba wa yii. Igba kan ti wa to je o fere ma si ibi kan ni ile Yoruba ti agbara oba nla yii ko de, koda awon ti won ko si labe re gan-an, bo ba pashe, won ko to eni ti i da a koja. Alaafin lo nile, oun ni oba, oun naa si ni olori ilu, ohun gbogbo to ba so, ashe ni. Asiko tire ni ile Yoruba ran kaakiri, ti ijoba re bere lati ile awon Tapa, titi to fi de orile-ede Ghana, ti awon ti won ko si sun mo ilu Oyo rara n fi oruko Alaafin she ohun gbogbo ti won ba fee she. Bo tile je pe nigba ti Alaafin yoo fi maa she olori ile Yoruba yii, awon omo Oduduwa ti fonka, sibe, oba yii fi agbara re ko gbogbo won si abe ara e, o si n she akoso ile naa, ti ko si seni to le beere pe bawo lo she she e, tabi ti yoo so pe oun o ni i tele ashe to ba pa. Eyi ni pe bi Alaafin she olori ile Yoruba lasiko ta a wa yii, ko sohun to buru nibe.


(Itan ni kikun... | 7746 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So
(Itan ni kikun... | 7104 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So

Laaro kutu ojo Eti tii se Fraide ana ni iroyin naa jade sita Aare teleri l'orile-ede Zimbabwe, Robert Mugabe ti jade laye. Kayeefi, ati pe lojiji niroyin iku naa ba gbogbo agbaye.

Ohun ta a gbo ni pe osibitu kan lorile-ede Singapore ni Robert Mugabe wa lati bi osu meloo kan seyin nibi to ti n gba itoju, latari aisan ojo ogbo ti won loo koluu, to si je pe nibe lo gba jade laye leni odun marundinlogorun (95years).

Lati odun 1980 lo ti n tuko orileede Zimbabwe titi wo odun 2017 nigba ti igbakeji re ye aga mo nidi pelu atileyin ileese ologun.

Adanu nla n'iku Rubert Mugabe je, Olusegun Obasanjo

Aare orileede Naijiria nigbakan ri, Olusegun Obasanjo ti so pe, iku aare Zimbabwe ana, Robert Mugabe je adanu nla fun gbogbo ile adulawo lapapo.

O salaye pe Robert Mugabe je ajijagbara ti o mo pataki ki eeyan ja fun ominira.


(Itan ni kikun... | 7104 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Ikolu Awon South Africa Si Naijiria - Ekunrere
(Itan ni kikun... | 2504 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Ikolu Awon South Africa Si Naijiria - Ekunrere

Okun kii ho ruru ka wa ruru! Bayii ni ijoba apapo se n parowa fawon omo Naijiria pe ki won ye kolu awon ileese to je ti orilede South Africa to wa ni Naijiria lati gbesan isekupani awon omo Naijiria lorilede naa.

Ijoba ni kikolu awon ileese orileede South Africa ni Naijiria yoo ni ipa ti ko dara lara omo Naijiria ju South Africa lo.

Minisita fun iroyin ati asa, Alhaji Lai Mohammed so ninu atejade kan pe bawon omo Naijiria kan ti fi ibinu kolu awon ileese to je ti orileede South Africa lojo Isegun ku die kaato.

Lai Mohammed ni awon omo Naijiria ni oludokowo lawon ileese orileede South Africa, nitorinaa fifi owo ara eni sera eni ni kawon omo Nigeria maa ba iru awon ileese bee je.

Bakan naa ni minisita eto iroyin ati asa ni omo Naijiria lo poju ninu awon osise ileese South Africa to wa ni Naijiria.


(Itan ni kikun... | 2504 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe
(Itan ni kikun... | 2674 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe

Bi eeyan ba ri ohun to n sele ni awon ile ijoba wa lasiko yii, okan onitohun yoo maa bale pe o da bii pe awon ijoba yii fee to ona to dara, awon oloselu kookan ti won ko moyato laarin oselu ati ijoba sise yoo yose to ba ya.

Sugbon awon ohun to n sele, ati bi awon eeyan naa se n seto ijoba won fihan pe nnkan yoo dara fun wa bo ba n ba bayii lo. Sanwo-Olu, gomina ipinle Eko, ra moto marundinlaaadoje (125), o fi okada marundinlogoji (35) ti i nidii, o ko o fawon olopaa ati awon agbofinro to ku, o ni ki won pin kinni naa laarin ara won, fun eto aabo to peye ni gbogbo ipinle re.

Bi oun ti n ko tire fun won, bee naa ni Dapo Abiodun ti ipinle Ogun naa ko ogorun-un moto, ati ogorun-un meji okada nla fawon olopaa odo tire naa, o ni ki awon naa fi maa seto aabo to peye. Ko si ohun ti eeyan le se ju ka ki awon gomina wonyi lo, paapaa lasiko ti ko sowo lowo ijoba pupo, to si je won sese tun de ile ijoba ni.


(Itan ni kikun... | 2674 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbes
(Itan ni kikun... | 5580 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbesan L'ara South Africa

awon omo Naìjíría ní ìpínle Eko ti gba ìgboro láti koju ìkora eya miran ti awon South Africa ń se fún awon omo Naìjíría.

Ile ìtaja ìgbalóde Shoprite tí agbegbe Lekki ní omobinrin kan ti gbe ìwe ilewo láti bu enu ate lu ìwá akolu ti awon South Africa n se si awon omo Naìjíría.

awon míran tíll ń kigbe pe ki won dáná sun ile itaja náa lójùna ati ranse pada sí awon enìyan South Africa gege bi esan.

Tí e o bá gbagbe awon omo oríle-ede South Africa tí ń ko soobu ti won sì ń pa awon omo Naìjíría ni orile-ede won.

Ìroyìn so pe opo awon tó ń gba ìgboro ló ti padánù awon ebí won nínú wahalá tí awon ará South Africa ń dásíle.


(Itan ni kikun... | 5580 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Eyi Ni Bi Pasito Se Gbe Majele Je Ni Ipinle-Ogun
(Itan ni kikun... | 2637 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Eyi Ni Bi Pasito Se Gbe Majele Je Ni Ipinle-Ogun

Bosun Olaniyi, Abeokuta Gbogbo adugbo Atala to wa niluu Mowe lo fee le daru lojo Fraide ose to koja yi nigba ti won ni Pasito kan to gbajumo daadaa lagbegbe naa, iyen Tunde gbe majele je, to si gbabe soda sorun alakeji.

A gbo pe awon kan ni won lu Tunde ti won ni okan lara awon pasito soosi Deeper Life ni jibiti owo ti ko din legberun lona egbeta (600,000) naira, to si je pe itiju gbese naa lo muu pinu lati gbemi ara re lojiji.

Iroyin to te Iwe Iroyin Yoruba lowo fi ye wa pe ajo ni Tunde n gba kaakiri leyin to padanu ise e lodun bii meji seyin, to si je pe ko seni ti mo ni gbogbo ibi to n gba ajo naa de.

Ohun to ti e n se opo eeyan ni kayeefi ni pe Tunde ti ran iyawo e jade lojo naa, sugbon nigba tiyawo naa maa fi pada wole, oko e lo ba nile nibi to ti n japoro, eyi lo muu sare pe awon ara adugbo lati ran an lowo gbe e lo si osibitu kan to wa nitosi won.


(Itan ni kikun... | 2637 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Sugbon Ta La Ri Ba Wi, Bi Ko Je Baba To Fi Omo Re Foko L'oru
(Itan ni kikun... | 2966 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Sugbon Ta La Ri Ba Wi, Bi Ko Je Baba To Fi Omo Re Foko L'oru

Baba kan wa nigba kan, o gba alejo kan sile re, lowo ale ni alejo naa de, bee lo ko opolopo eru ati iwofa dani. O ni oun n lo si irin-ajo kan ni, sugbon ile ti su awon sona bayii, ki baale je ki awon sun moju. Inu baale dun, o ni oun gba alejo pataki, n lo ba bere si i fi ile ponti lo n fi ona roka, se o si ti ri i pe okunrin to de naa, apo nla nla bii marun-un ti won ko kale nibe, owo lo kun inu re fofo.

Nibi ti won ti n salejo ni okunrin olola naa ti taju kan-an to ri arewa omo baba to gba won sile, n lo ba ni oun yoo fe e, bo ba se towo, oun yoo fe e, ale ojo naa loun yoo si fe e.

Ninu apo owo meje o ko marun-un kale, loru ojo naa lo si feyawo re, n lo ba mu un lo. Ase oko ole ni okunrin ti won ro pe olowo ni yii ti n bo, ni feere to si jana lati maa pada lo pelu awon ero, peki–n-reki lo se pelu awon ode nla nla lati agbegbe ti won ti loo ja won lole, ni won ba fija peeta.


(Itan ni kikun... | 2966 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku
(Itan ni kikun... | 3444 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku

Agutan ti ko ri omo re mo, eran fohun, o ni, 'Nnkan n be!' Nnkan n be loooto fun Naijiria, nitori nigba ti iya nla ba gbe ni sanle, keekeeke a si maa gori eni. Iya nla ti gbe Naijiria sanle bayii, awon keekeeke si n gun ori Naijiria, orile-ede ti gbogbo aye n gbe gege laarin odun 1960 titi wo 1980 waa di orile-ede yeye, orile-ede ti kaluku fi n se eleya kaakiri. Igba kan ti wa to je ko si ohun ti won yoo se ni gbogbo ile Afrika pata, ti Naijiria ko ba ti da si i, ko seni ti yoo bere re, enu Naijiria nikan ni ase wa nigba yen.

Sugbon ohun to n sele ni orile-ede South Afrika bayii ti fihan pe Naijiria ati awon omo orile-ede yii ko je nnkan kan mo nibikibi, eni yeye lasan lawon eeyan orile-ede agbaye gbogbo ka wa si. Ni South Afrika lose to koja, eyin naa kuku ti ka a, e si ti ri i bi awon omo orile-ede ohun ti tu awon omo Naijiria sihooho, ti won n na won, ti won n wo won nile, ti won n dana sun won, ti won si n ko soobu ati eru won, ti won n fo moto won tuu tuu, to si je gbogbo omo Naijiria ti won ba ti ri loju ona ni won n se lese. Oro naa buru jai, koda, won o gbodo se eranko to bi won ti n se wa.


(Itan ni kikun... | 3444 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Ni 1978, Emo N Lo, Afe N Lo, Azikiwe Nikan Ni Ko Ti i Mo Ibi To Fee Gba Lo
(Itan ni kikun... | 12925 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Ni 1978, Emo N Lo, Afe N Lo, Azikiwe Nikan Ni Ko Ti i Mo Ibi To Fee Gba Lo

Titi di ipari osu kewaa, odun 1978, egbe oselu kan soso to wa ti ko loluwa ni egbe NPP. Ki i se pe ko loluwa bee naa, ko kan ni asaaju kan ti gbogbo won jo fowo si ni. Ati nitori eyi, isoro inu egbe naa ju ti egbe yoowu lo. Gbogbo eeyan lo ti gbo oruko egbe Unity Party of Nigerian (UPN), ti won si mo asaaju won pe Obafemi Awolowo ni. Bakan naa ni won mo oruko egbe National Party of Nigeria (NPN), ti won si mo alaga egbe naa pe Alaaji Aliyu Makama Bida ni. Bakan naa ni won mo oruko egbe Movement of the People (MOP), ti won si mo pe Fela Anikulapo Kuti ni olori egbe naa. Won tun mo egbe National Advance Party (NAP), ati pe Tunji Braithwaite lolori won nibe. Bee naa ni won si mo People Redemption Party ati pe olori won ni Aminu Kano. Koda, awon egbe keekeeke to ku paapaa ni olori won, gbogbo aye lo si mo won.

Sugbon ko seni to mo olori egbe NPN tabi eni ti yoo du ipo aare loruko won, bo tile je pe awon oloselu nla nla ni won wa nibe, awon oloselu gidi, awon olowo ati awon eni ti won mo lawujo. Awon bii Adeniran Ogunsanya, Kola Balogun, ati opolopo awon ti won je omoleyin Azikiwe ninu egbe NCNC lasiko ijoba awon oloselu atijo. Eyi ni awon eeyan kan se n so pe Azikiwe lolori egbe naa, ti won si ni oun naa ni won fee lo lati du ipo aare loruko egbe won. Awon oloselu inu egbe naa ti won mo eyi ko sise feni meji ju Azikiwe lo, bo tile je pe eni kan ti wa ninu egbe naa to n nawo gidi ju awon to ku lo. Okunrin oloselu kan toun naa ti se oselu daadaa, to si se minisita laye awon oloselu akoko ni, leyin to si kuro nidii oselu, ibon lo n ta, bee lo n ta etu, ati awon ota ibon, eyi si je ki owo re ya mura lasiko ogun abele. Waziri Ibrahim loruko re. Alaaji ni.


(Itan ni kikun... | 12925 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Bi Iro Ba Lo Logun Odun...
(Itan ni kikun... | 2919 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Bi Iro Ba Lo Logun Odun...

Awon eeyan wa ni ko gbon, bee ni, opolopo ninu awon eeyan wa ko gbon rara. Eni ti a ba tan je leekin-in-ni, iyen see pe ni asise, tabi misiteeki.

Sugbon ti eni to tan-an-yan leekin-in-ni ba tun waa pada tan an je leekeji, iyen ki i se misiteeki mo, eni ti won n tan je ni ko logbon.

Nigba ti won fee dibo to koja yii, ibo aare ti a di ninu osu keji odun,okunrin kan ti won n pe ni Rotimi Amaechi jade, se oun ni minisita fun eto igbokegbodo oko, o ni ki gbogbo aye le mo pe ijoba Buhari n se bebe, awon ti pari oju-ona reluwee Eko si Abeokuta, ki gbogbo aye maa rin in bayii lo ku, oro wahala irinna lati Abeokuta si Eko ti di ohun igbagbe pata, o ni idi ti awon ara Abeokuta ati awon eeyan Eko se gbodo dibo fun Buhari niyen.

Awon ti won mo oro naa so pe irolokunrin yii n pa, ati pe baba nla opuro ni. Won ni ona reluwee yii ko ti i pari, ati pe won ko ra oko oju-irin tuntun kankan, awon aloku, oko ti aye ko lo mo, ni won loo ko wa lati ibi kan ti won si kun loda tuntun. Kia ni Amaechi ati awon Lai Muhammed ti sare jade, won ni oro lati enu awon alatako ti ko feran Buhari ni, awon ole ti won n ji owo ilu ko lo n so bee. Loro kan, nigba to di ojo kejo, osu keji, odun yii, nigba ti ibo didi ku bii ose meji pere, Amaechi gbe Ibikunle Amosun leyin, won ti Alake Egba si aarin, won ni awon ti pari ona reluwee Abeokuta s'Ekoo.


(Itan ni kikun... | 2919 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi
(Itan ni kikun... | 2034 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi

O fere je pe ko si kinni kan ti awon oloselu Naijiria ko ni i fi owo ibaje kan. Eyi to si buru to je yoo pada waa kan gbogbo eeyan ile yii naa ni ti etoidajo. Won ti so awon adajo wa di nnkan mi-in, iba die, iyen to ba tilewa rara, lo ku to n dajo ododo.

Bee ni orile-ede ti ko ba ti si idajo ododo, ibe yoo segbe, ki Olorun ma je ki Naijiria segbe ni. Ohun to ba foju han, ti gbogbo aye ri, ti won si mo pe eleyii ni ododo, awon adajo wa yoo jokoo, leyin tiwon ba ti gbowo lowo awon oloselu tan, tabi ti awon ti won n sejoba ba ti hale mo won, won yoo ni kinni naa ki i se ododo, nitori lasiko to sele, elerii to soro yen ko letoo lati soro.

Ki i se pe won ni elerii yen ko so ododo o,sugbon pe ko letoo lati soro ni. Iyen ni won yoo se pale ododo mo, ti won yoo si fi iro ropo re. Ibo ti gbogbo awon ara Kogi ri, ti won si fi tokan-tara won dibo fun Dino Melaye, awon igbimo ti won gbe dide nibe lati sedajo ni ibo naa ni ko daa, Dino ko lo wole.


(Itan ni kikun... | 2034 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku
(Itan ni kikun... | 2869 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku

Se loro di boolo o yago laaro ojo Aiku Sande oni nigba ti won lawon baale ile meji kan ti won yan ise agbase se laayo nipinle Ekiti ko sinu konga lasiko ti won n gbiyanju lati yo foonu to jabo sinu konga naa.

Abule kan ti won pe Anaye to wa nijoba ibile Emure la gbo pe isele naa ti waye. Foluso Ajayi ti won tun n pe ni Vosco ati okunrin kan topo awon eeyan n pe ni Alaaji, eni ti won lomo Ebira nipinle Kogi ni lawon meji naa ti a gbo pe foonu lo ran won lo sorun alakeji.

Ohun ti a gbo ni pe okan lara awon meji lo n gbiyanju lati pon omi to fee lo lati dana, asiko naa la gbo pe eni kan pe e lori foonu e, bo si se n gbiyanju lati yo o ni foonu naa jabo sinu konga ti won loo jinna gan an.

Bi foonu naa se jabo la gbo pe o gbiyanju lati yo o, sugbon se ni won so pe ese yo geerege to si fee jabo sinu konga naa, eyi lo mu ki ekeji e naa sare debe lati doola e, to si je iyalenu pe se lawon mejeeji jo jabo leekan-naa.


(Itan ni kikun... | 2869 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

Eyi Ni Bi Enu Se Ko Ba Bobrisky, Okunrin To N Se Bii Obirin: Won Ni Awon Olopa D
(Itan ni kikun... | 5890 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Eyi Ni Bi Enu Se Ko Ba Bobrisky, Okunrin To N Se Bii Obirin: Won Ni Awon Olopa Da Ayey Ojoobi E Ru - Bee Loun Naa Ti Salo

Lana-an gan-an ni omokuinrin kan ti oruko e n je Idris Okuneye, eni tawon eeyan tun mo si Bobrsiky pe eni odun mejidinlogon, sugbon dipo ayajo ayeye ohun, nise lawon olopaa kolu ileetura to fe lo, ti oro si di bo o lo o yago.

Oga gba nileese ijoba to n ri si Asa ati isese, Otunba Olusegun Runsewe ni okunrin to n se bii obinrin yii, Bobrisky yaju si, ki oloju si too se e, nise ni nnkan daru mo on lowo, toro si di bi bami-in mo on lowo bayii.

Ohun ta a gbo ni pe, lana-an gan-an ni Bobrisky loun yoo pate ariya nla, nibi to ti fe ko awon tie jo lati sayeye ojoobi, sugbon bo ti se n pete ariya yii lowo, bee lawon olopaa n so, bo si ti se ku dede ki won bere inawo ohun lawon agbofinro yade, bi won se le awon alabase e danu niyen o, ti won ni Bobrisky paapaa na papa bora, tawon eeyan ko si mo ibi to gba lo.


(Itan ni kikun... | 5890 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Leyin Odun Mokanla, Bose Fee Ko Oko Re Sile l'Abeokuta: Nitori Orekunrin Re
(Itan ni kikun... | 1896 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Kayode Omotosho, Abeokuta

Leyin Odun Mokanla, Bose Fee Ko Oko Re Sile l'Abeokuta: Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunsoo

Abileko Bose Oladapo lo ti wo oko re, Oladepo Oladapo, lo si kootu koko-koko to wa ni Agbeloba, niluu Abeokuta, o ni oun fee ko o sile latari pe o ti n hale pe oun yoo jogun ile ti oun ko, bee Oladepo ko tun san owo-ori oun. Obinrin naa ni fun odidi odun mokanla ni oko oun fi n foni-donii, fola-dola lori oro sisan owo-ori oun, idi niyen ti oun si she fee ko o.

Esun meta to ka si oko re lese ni pe oun ko nifee re mo nitori ko nifee oun pelu awon omo oun mejeeji, idunkooko mo emi oun pelu awon omo oun ati ifiya-jeni.

Bose ni opo igba loun ti mu ejo oko oun lo si odo awon ebi re, sugbon ko tori re yiwa pada rara.

Nigba to n fesi, Oladapo ni iro niyawo oun n pa mo oun. O ni oniwahala ni obinrin naa, idi niyen ti awon fi maa n ja.


(Itan ni kikun... | 1896 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure
(Itan ni kikun... | 3002 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Olusheye Iyiade, Akure

Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure

Ileese olopaa ipinle Ondo ni awon ti n wa gbogbo ona lati fi panpe oba gbe toko–taya kan ti won fesun kan pe won lu Testimony Tooke Babalola, omo bibi inu ara won pa l'Akure, l'Ojoruu, Wesidee, ose to koja.

Femi Joseph to je alukoro ileese ohun so lojo Aiku, Sannde, to koja yii pegbogbo igbese to ye lawon n gbe lowo lati ri i daju pe owo te Ogbeni Felix Babalola ati iyawo re laipe rara, ki won le waa so tenu won lori oro iku omobinrin eni odun merin ohun.

O ni opo igba lawon ti de ile ti won n gbe l'Akure, sugbon ti awon ko ba won, sugbon o ni awon ko ni i sinmi titi ti won yoo fi ri awon afurasi mejeeji ohun mu.

Abileko Babalola to je iya omodebinrin ohun ni won lo gbe e digbadigba lo sile-iwosan ijoba to wa l'Akure ni irole Ojoruu, Wesidee, ose to koja, kawon dokita to ba lenu ishe l'ojo naa too fidi re mule pe omo to gbe wa ti ku.


(Itan ni kikun... | 3002 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
(Itan ni kikun... | 2602 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Adefunke Adebiyi

Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete

Awon esun nla bii pipe ara eni lohun ti a ko je, shishe ayederu iwe ajo eleto idibo ile wa (INEC), titan araalu je ati esun merin mi-in ni Akanni Toluwalope n rojo le lori bayii nipinle Eko, leyin ti won mu un pe o she sofin ijoba.

Adugbo kan ti won n pe ni Madogun, nipinle Ogun, ni Akannni, eni ogbon odun n gbe, sugbon Ijaye Ojokoro, nipinle Eko, lo ti lu awon eeyan ni jibiti owo nla gege bi Agbefoba, Augustine Nwabuisi, she shalaye ni kootu Majisireeti to wa ni Yaba, l'Ojobo to koja yii.

O shalaye pe Akanni puro fawon eeyan ninu oshu kefa, odun yii, pe oun ti wole gege bii omo ile igbimo ashoju-shofin (House of Representatives). Koda, ki won le baa gba a gbo, iwe kan ti ibuwolu alaga INEC wa, ti won si ki i ku oriire pe o wole gege bii omo ile igbimo ashofin naa lo fi n han awon eeyan kiri. Bee ayederu niwee naa, okunrin yii lo she e funra e, ki i she INEC rara.


(Itan ni kikun... | 2602 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo
(Itan ni kikun... | 2594 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)

Florence Babashola

L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo

Awon marun-un ti igbagbo wa pe won je omo egbe okunkun toruko won n je Eiye Confraternity, Nasirudeen Jamiu, eni odun metadinlogbon, Ganiyu Saheed, eni odun meeedogbon, Adebisi Idris, eni odun merinlelogun, Adeoye Sodiq eni odun merinlelogun ati Kasali Afeez toun naa je omo odun merinlelogun ti won fesun kan pe won pa Monsuru Lawal ni won ti foju bale-ejo Majisreeti ilu Oshogbo bayii.

Esun meta otooto to ni i she pelu gbigbimo-po huwa buburu, ipaniyan ati jije omo egbe okunkun ni won fi kan awon olujejo yii.

Agbefoba, Inspekito Elisha Oluwashegun, shalaye pe awon olujejo ohun pelu awon mi-in ti owo ko ti i te ni won huwa ohun lagbegbe Isale-Oshun, lojo kesan-an, oshu keje, odun yii.

Oluwashegun so siwaju pe gbogbo esun ti won fi kan awon olujejo ni alakale ijiya won wa labala ikerinlelogota (64) ati okooleleeedegbeta o din merin (516) ofin iwa odaran ti odun 2002 tipinle Oshun n lo.


(Itan ni kikun... | 2594 Awọn baiti Die e sii | Fẹ lati ọrọIwoye? | Idinwo Rẹ Lori Itan: 0)
 


 



Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com