Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
[ Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise ]

·Ni Ti Ooni, Alaafin Ati Aare Ona Kakanfo
·Sugbon Ta La Ri Ba Wi, Bi Ko Je Baba To Fi Omo Re Foko L'oru
·Ni 1978, Emo N Lo, Afe N Lo, Azikiwe Nikan Ni Ko Ti i Mo Ibi To Fee Gba Lo
·Leyin Odun Mokanla, Bose Fee Ko Oko Re Sile l'Abeokuta: Nitori Orekunrin Re
·Aafaa Abdulraham Ma N Shere Ni Bebe Ewon, Omo Ile-keu Re Fipa Ba Lo Po L'Ed
·Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
·Iyaale Ile To Fi Kokeeni Soyun Ti n Ka Boroboro
·Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin
·Onisowo Ibadan Bo Lowo Awon Ajinigbe Leyin Ojo Marun-un Ninu Ahamo Won

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Oru ojo kokandinlogbon, osu keje, odun 1966, ki i se ojo daadaa kan niluu Ibadan
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Akoroyin Olootu

Oru ojo kokandinlogbon, osu keje, odun 1966, ki i se ojo daadaa kan niluu Ibadan, ojo ti Aguiyi Ironsi ti oju oorun de oju iku ni

Ko seni to mo pe won yoo pa Ogagun Aguiyi Ironsi lojo naa ti awon oba nla nla peju gbogbo. Ko seni to tile ro o ninu awon ijoye nla nla ti won wa nibe pe won yoo pa olori ijoba Naijiria yii, won ko ro iku ro o rara. Se lojo ti a o ba sonu, gaga lara a ya ni. Ilu Ibinni ni Ironsi atawon oga ologun ti won jo n sejoba ti n bo, bii aago mesan-an ku die ko lu ni won gunle siluu Ibadan, ipade awon oba gbogbo ati ijoye nla kaakiri origun mereerin Naijiria ti won fee se ni ilu naa lo tori e wa, oro lo waa ba won so pe ki won ba awon eeyan won soro ni ilu ti kaluku won ti wa pe omo orile-ede yii kan naa ni gbogbo wa, a ko si gbodo je ki oro ti ko to oro so wa di ota ara wa. Eleyii ni Ironsi atawon eeyan re sare tori e gbera lati Binni, won n fee tete de si ibi ipade naa, ko ma di pe won yoo da awon oba ati awon ijoye yii jokoo pe titi.

Se lati ojo ti ipade naa ti ku ola ni awon oba wonyi ti n de si ilu nla yii, awon atawon ero repete ti kaluku won ko leyin, won si ti gba gbogbo ile itura ilu naa tan, bee ni awon miiran de sodo awon ore won. Ibadan n se rotiroti, orisiirisiiri moto si gba gbogbo ilu naa, o fere je pe ko si iru ipade bee ri, asiko Ironsi lawon oba to po to bayii koko pade ara won.Nigba ti Ironsi atawon eeyan re yoo si fi de si ilu yii paapaa, awon oba naa ti peju wamu, won si ti n lo si gbongan nla ti won yoo ti se ipade nla ti won waa se. Bi Ironsi ti bo sile ninu eronpileeni kekere to gbe e wa lati Binni paapaa, ibale okan re tubo po si i nigba to ri awon soja ti won je omo-ogun Batalionu Kerin ti won fi Ibadan yii se ibugbe nigba naa, awon ti baraaki won wa, awon ni won si waa pade re ni papa-oko-ofurufu, nibi to ti yan laarin won gege bii oga ologun.
Sugbon iku n ba omo rin omo o fura ni o, nitori Joe Akahan ni olori awon omo-ogun yii patapata, oun si ti gbo hulehule ohun to n lo laarin awon soja Hausa, o mo pe loru ojo naa, bi nnkan kan ko ba yi i pada, won yoo pa Ironsi. Theophilous Yakubu Danjuma to je okan ninu awon olori eso fun Ironsi lo n dari eto naa, awon ti won si je oga won bii Muritala Muhammed ati Yakubu Gowon wa ni koro ti awon ko ti i mori jade, sugbon won ti so ohun ti awon oga soja ti won wa ni Batalionu Kerin yii yoo se, niwon igba to ti je awon soja Hausa lo po nibe ju awon eya miiran lo. Sugbon bi Ironsi ti bo sile ni Joe Akahan pade re, o yan lo niwaju re, o si yan bo, ko too gbe bata re soke to si fi sole koo, leyin naa lo fi ariwo rara bonu, to si so fun un pe o kaabo siluu awon, ati pe tire ni oun ati gbogbo awon omo- ogun oun n se.

Inu eda jin, o jin ju koto lo, koda o jin, o jin ju inu omi okun lo. Tabi bawo waa ni Ironsi yoo ti se mo pe Joe Akahan to n se sogun-sogun leyin oun bii igba ti agutan ba ri olowo re yoo wa ninu awon ti won ti gbe koto iku sile foun lojo naa gan-an. Se bo ba se pe o mo ni, ko ni i duro, yoo ti tete ba ese re soro, yoo maa bo ni Eko, nibi ti yoo ti soro ki apa awon olote naa too ka a. Sugbon oun ko mo, o fi inu wenu, lo ba je iwo. Nitori bi won ti ki i kaabo bee tan ni papa-oko-ofurufu ni won gbe e sinu moto to je ti ijoba, oun ati gomina Iwo-Oorun igba naa ni won si jokoo, se Adekunle Fajuyi ti i se gomina yii naa lo gba a lalejo, ile ijoba ni won si n lo lele. Bi won ti wo ile ijoba, Joe Akahan yii ko fi won sile naa, won si jo seto ibi ti won yoo fi Ironsi si, ati omo re to tele won to n je Tom ni, leyin ti won ti se gbogbo eyi tan ni won sese lo sodo awon oba.

Bi Ironsi ati awon eeyan re ti wo inu ipade naa, bee ni gbogbo awon oba dide duro, oniruuru ni gbogbo won. Awon oba ile Hausa wa nibe pelu lawani bamba-bamba lori, awon oba Yoruba wa nibe pelu ade won, bee ni awon oba ile Ibo naa si wa nibe ti won roso modii, pelu fila ate ti won de sori won. Ojo naa da bii ojo eye nla, gbogbo won lo wo aso ibile won, eleyii si fi han bi won ti ka ojo naa ni pataki to, nitori loooto loooto, ojo nla lojo naa, ojo kejidinlogbon, osu keje, odun 1966, lojo ti gbogbo awon oba Naijiria peju siluu Ibadan, ti won waa feti si ohun ti olori ijoba ologun to n je Ironsi fee so. Aso ti won wo ati imura won naa lo fi ibi ti kaluku ti wa han, nitori aso won ko jo ara won, afi to ba je awon ti won jo wa lati agbegbe kan naa, kinni kan to kan je ki won jo ara won ni pe gbogbo won lo gbe abebe nla dani, abebe ti won fi n fera.

Leyin ti Ironsi ti jokoo lawon oba naa too jokoo pada, okunrin olori Naijiria naa si dide lati ba won soro ko too di pe won bere ipade won. Ironsi soro, eemeji lo si soro. Okoko ti ba won soro lati inu iwe, iyen iwe apileko to ti ko wa, leyin to si ka kinni naa tan lo waa ti iwe naa bo apo ara re, lo waa bere si i soro lai wowe, o so fun won pe oun fee ba awon oba naa soro lati okan oun wa, oun fee so ohun to wa lokan oun fun won. Osalaye fun won pe ki won wo oun daadaa, oun mo pe bo se n se oun naa lo n se awon naa, pe awon paapaa mo pe ko si orile-ede mi-in, tabi ilu kan ti won tun ni to ju Naijiria lo, ati pe ohun kan naa to le gbe Naijiria ga ni ki gbogbo awon jo wa ni isokan, ki won si sise fun isokan ilu naa. Oni bi kinni kan ba ru won loju, ki won waa beere lowo oun, ko si seni to ba wa oun wa ninu awon oba naa ti oun ko ni i ri.

Leyin ti oga awon soja naa ti soro tan, inu awon oba yii dun, bi eeyan si gun esin ninu won, ko le kose, nibi ti idunnu won de. Gbogbo won lo patewo, gbogbo won lo dide, nigba ti won si bo segbee kan bayii, gbogbo won lo n lakaka lati ya foto pelu olori ijoba naa, won n so pe awon ko mo pe bayii ni okunrin soja naa se eeyan to, won ni omoluabi ni Ironsi. Inu awon oga soja gbogbo ti won ba nibe paapaa lo dun, iyen awon ti ko si nidii ote lati pa a, awon yii ni o ti han bayii pe awon oba yoo duro ti ijoba awon, ohun ti awon ba si fee se fun idagbasoke ilu, ko si eyi ti ko ni i see se nibe, ko si eyi ti awon ko ni i le se ni aseyori, nitori awon ti ni atileyin awon ti won niluu, iyen awon oba Naijiria. Laarin aago mewaa owuro si mokanla ni gbogbo eleyii ti sele, leyin ti won si ti ya foto tan, Ironsi fi won sile lati lo.

Ki i se pe o n pada si Eko o, nitori ko le pada si Eko bee, apeje kan wa ti ijoba Adekunle Fajuyi seto re fun awon oba yii lati ki won kaabo ko si so pe won se e, owo ale ni won fi kinni naa si, alejo pataki ti won si ni nibe ni Ogagun Agba Ironsi. Nitori bee, nigba to ba won ya foto tan losan-an, eronpileeni lo wo, ibomi-in lo tun gbera lo, oun ati Adekunle Fajuyi, pelu okan ninu awon olori ogun re ti won jo n sejoba, Hillary Njoku.

Ilu Ikenne ni won n lo, ninu ileewe Mayflower, nibi ti Tai Solarin ti n se olori won. Awon meta pere ti won lo naa niyen o, Ironsi, Adekunle Fajuyi, ati Njoku. Bee ni ki i se pe awon soja tabi eso kan ti duro sohun-un de won ko o, bee ni won ko si ko awon eso kankan lo, awon meta pere naa ni won lo. Bo ba je asiko yii ni, awon soja ati olopaa pelu SSS yoo ti da ile laamu jinna, won yoo maa pariwo pe olori ijoba fee waa ki won Sugbon iyen ko si lasiko naa, ohun gbogbo niwon-tun-wonsi, ko si seni kan to fee na owo ijoba ni inakunaa, bee ni ko si enikan ti yoo maa ko moto bii ogun bii ogbon jana nitori pe olori ilu n lo sibi kan.

Helikoputa kekere kan naa ni won gbe lo, nigba ti won si de Mayflower ti won bo sile ninu re, ariwo so laarin awon omoleewe gbogbo. Awon omo ileewe yii ti mura ijo, won n lu ilu lorisiirisii lati ki Olori Naijiria naa kaabo, bee ni won wo aso oke ati aso ibile mi-in, won si n fi orin ati ere to gbe asa Yoruba jade dabira fun olori ijoba. Tai Solarin ti i se oga agba ileewe naa ti ko awon tisa re, awon naa ti duro wamu si aarin fiidi ti won ti n gba boolu ti won de si, nigba ti Ironsi si sokale bayii, Tai rin sunmo on, o si gba a lowo, eni ba si ri okunrin naa yoo ti ri bi inu re ti dun to, nitori nnkan kekere ko ni ki olori ijoba Naijiria se abewo sibi kan.

Ki i se pe won deede wa si ileewe yii, o ni ohun ti Ironsi fee fa yo. Oun fee wo ileewe naa to ti ka orisiirisii nipa re, o fee foju ara re ri i, o fee wo Tai Solarin ati bo se se oro ileewe naa si, ati ogbon to fi gbe e kale to fi yato si ileewe tawon alawo-funfun gbe kale fun wa. Ohun ti Ironsi se n se gbogbo eleyii ni pe o fee wo o boya oun le da iru awon ileewe bee si gbogbo Naijiria, ki iru ileewe naa kookan wa ni ipinle kookan, ki oun si seto ki Tai Solarin ko gbogbo awon tisa to ba fee maa sise ni awon ileewe naa. Idi to fi lo niyen, nigba ti won yoo si fi yi gbogbo ileewe naa po tan, ohun to ri nibe tun dara ju iroyin to ti gbo lo, ko si se iyemeji to fi so fun Solarin pe ise wa ti oun fe ko ba oun se, o ni oun fe ki okunrin naa ka ara re si okan ninu awon ore oun pataki, oun si fe ko waa ba oun nile ijoba, ki oun le so fun un ise ti oun fee gbe fun un se.

Nibi ti won foro ti si niyi ti okunrin naa ati awon oga soja meji ti won tele e lo fi n pada bo nile, won tun ko si eronpileeni won, iyen si gbe won lo siluu Ibadan laarin ogoji iseju pere. Gbogbo ohun ti won se yii, nigba ti yoo fi to aago meji koja die, won ti tun pada de o, leyin naa ni won si sese jeun, ti won ni ki awon sinmi die, ko too di owo irole ti won yoo tun lo si ibi ti awon oba ti fee se apeje won. Gbogbo bi won ti n jeun yii naa ni Ironsi n salaye ileewe Mayflower, to si n so fawon eeyan re pe ti ileewe gbogbo ba le ri bayii, tabi ti awon ba ni ileewe nla kookan bii Mayflower yii ni awon ipinle kookan, nigba ti yoo ba fi to odun mewaa, awon yoo ti ni awon omowe lorisiirisii, awon yoo si ni awon akosemose ti awon le maa lo fun gbogbo ise- ero ati ise-ogbin, ti gbogbo aye yoo si pada maa waa ko eko ise naa lodo wa ni Naijiria.

Eyi ti won ro titi ti kaluku fi loo reju die ree, won si ti seto pe bo ba ti n di aago marun-un aabo ni won yoo ti pade lati mura, nitori aago mefa ni won yoo de ibi apeje naa, ti won yoo si wa nibe titi di aago mejo, eto gbogbo ko gbodo ju bee lo. Sugbon gbogbo bi awon ti n reju yii, awon ti won fee pa Ironsi ko dake, eto naa ti de ori koko, o si n lo bi won ti se gbe e kale. Awon oga soja Hausa ti won wa l'Ekoo ni won n dari oro naa, awon Muritala ati Gowon ti ranse si awon soja to je Hausa ti won wa ni Abeokuta, won si ti seto fun won pe ibe ni wahala naa yoo ti bere, nitori awon soja ti won wa nibe po die ju ti Ibadan lo, awon ni won yoo koko bere wahala nibe, ti won yoo si maa ko soja pupo ti won je omo Hausa bo ni Ibadan, igba ti won ba si de Ibadan ni awon soja ti won je ti Batalionu Kerin ti won ti n tele Ironsi kiri lati aaro yoo darapo mo won.

Ironsi ko mo, bee naa ni awon oga soja ti won jo wa nibe ko mo, awon ko mo pe awon ti won n dari ifibongbajoba naa lati Eko ti seto pe gbogbo ohun to ba n lo, gbogbo ibi ti Ironsi ba n rin si, gbogbo ibe ni ki won maa so fawon, ki won si maa fi to awon leti, ase ti won si pa fun Joe Akahan ni pe oun ko gbodo fi Ironsi sile nigba kan. Bee ni Joe ko fi Ironsi sile, afi igba ti won lo si ileewe Tai Solarin nikan, eronpileeni ni ko si gba a laaye lati ba won lo, oun naa iba wa ninu awon ti won lo. Sugbon lati igba ti won ti de naa lo ti n tele won, ohun to si n se ni lati fi han pe oun n toju olori ijoba Naijiria, ohun ti awon ti won n ri i naa si n ro niyen pe soja naa ko faaye gba eera lati rin oga re, gbogbo ibi to ba ti lo lo n ba a lo. Bee ki i se nitori bee ni Akahan se n tele Ironsi, oun fee mo ibi to wa ati ibi to n rin si, ko le rorun fun won lati mu un nigba ti wahala ba bere ni.

Ni bii aago mefa irole ni apeje naa bere loooto, awon oba nla nla si pe sibe wamu, awon oba bii Ooni Adesoji Aderemi; Oba Adeyinka Oyekan lati Eko; Oba Gbadebo lati Abeokuta: Alaafin lati Oyo< Olubadan atawon oba mi-in gbogbo. Awon oba nikan ko ni won wa nibe lasiko yii o, awon olori esin paapaa wa sibe lati ba won se apeje, sebi won waa ki awon oba ti won wa lati ile gbogbo ni, won si tun waa ba won sere, ki won le fi ife han si won. Adekunle Fajuyi lo n gba won lalejo, bo si ti n rerin-in lodo awon oba lo n rerin-in lodo awon Emir ti won wa lati ile Hausa, o si n ki won yika ti won jo n rerin-in, ti won si n sere laarin ara won. Koda Tai Solarin paapaa wa, oun ati iyawo re, Sheila, won waa fi oore ti Ironsi se won losan-an han ni gbangba. Bayii ni ibi apeje naa kun fofo, ti onikaluku si gbadun ara won.

Ni bii aago mejo ni apeje naa pari, nigba ti Ironsi ti dide pe oun fee wole ni toun, se itosi ile ijoba naa kuku ni ariya ranpe naa ti n waye, nigba to si ti wole tan lawon alejo naa ti n lo lokookan, ko si ju iseju meeedogun ti gbogbo won fi lo tan. Bi Ironsi si ti wole ni Adekunle Fajuyi tele e, won waa loo jokoo sori aga nla ninu palo ile naa, nibe ni won ti n se ayewo awon ohun gbogbo ti won se lojo naa, ti won si n gbiyanju lati ko awon eto ti won yoo se ni ojo keji sinu iwe, ati bi Ironsi yoo se rin irin re pada si Eko, ti ko si ni i si wahala kankan nibi kan. Se imura to ku ni okan Ironsi ti oun atawon eeyan re n se naa ni lati waa pada lo si ile Ibo, niwon igba to ti de ile Hausa, to si ti de ile Yoruba, o ti tun lo si Mid-West naa, ibi kan naa to ku ti yoo lo ti yoo fi jokoo si ofiisi re pada ni ile Ibo, iyen lo n mura.

Nitori bee, gbogbo bi won ti jokoo lale ojo naa lo n seto irin-ajo yii, to si so pe bi awon ba ti de si Eko lawon yoo tun tete gbera ile Ibo, ki awon le yanju ohun gbogbo ki osu naa too pari pata. Leyin to ti se bee ni won dide lati loo jeun ale, se Ironsi ko ba won jeun nibi ti won ti se apeje ranpe yii, oba ki i saa i jeun ni gbangba.

Adekunle Fajuyi ti seto ounje ti Ironsi atawon ti won ba a wa soto, gbogbo won si lo sori tabili nla, nibe ni won ti jeun te ara won lorun, ti onikaluku si mu ohun to fee mu. Leyin ounje yii ni Ironsi ati Fajuyi jokoo segbee kan ti awon bere si i soro to se koko, oro nipa gbogbo apase ijoba Naijiria nigba naa, ati awon ohun to ye ki won se ni won jo n so. Won rojo yii fun igba die, ko too di pe Ironsi dide leekan naa, to si so pe oorun ti ya, nitori ipade awon oba naa yoo maa tesiwaju lola, oun ko si fee da won lagara, oun gbodo wa nibe pelu won.

Aago mejila niyen o, laago mejila oru geere, Ironsi ni oun n loo sun, oun n loo fi oju ra oorun fun igba die, ko too tun di pe ise bere lojo keji perewu. Sugbon oorun naa ki i se oorun daadaa kan o, nitori lojo naa ni Aguiyi Ironsi ti oju oorun doju iku. E maa ka a lo lose to n bo.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, April 28 @ 01:26:31 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Oru ojo kokandinlogbon, osu keje, odun 1966, ki i se ojo daadaa kan niluu Ibadan" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: