Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
[ Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue ]

·Afise Loroo Benjamen Yi O, Leyin To Jade Lewon Lo Tun Loo Ji Telifisan Pasito
·Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
·Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
·E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
·Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein
·Friday Paro Pe Won Ja Tanka Epo Gba Lowo Oun, Lo Ba Loo Ta a Sona Jebba
·Tunmise Ji Kaadi ATM Ore e Ni Saki, Owo Nla Lo Fi Wo Jade
·Olusiro-owo Gbe Owo Awon Osise Sa Lo L'Akoko
·Dereba Bisoobu Fipa Ba Eni To Ja Lole Lo Po, Ladajo Ba Ran an Lewon N'Ilori

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Nibi tawon oga soja Ibo ti n muti lawon soja Hausa ti gbebon fun won l'Abeo
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Akoroyin Olootu

Nibi tawon oga soja Ibo ti n muti lawon soja Hausa ti gbebon fun won l'Abeokuta, won pa won bii ejo aije

Se aago mejila ni Ogagun-Agba, Aguiyi Ironsi, olori ijoba Naijiria ninu osu keje, odun 1966, gbera kuro ninu yara alejo toun ati Ogagun Francis Adekunle Fajuyi ti i se gomina Western Region igba naa ti n sepade, to kede fun gbogbo awon oga soja to ku nibe pe oun n loo sun ni toun. Aago mejila loru ni, ohun gbogbo ti pa kanrin kese nile ijoba niluu Ibadan, osupa to n ran nigba naa paapaa ko ti i di aranmoju, bee ni ina ijoba ko ti i di yebeyebe, nitori bee, ayika ile ijoba yii paapaa sookun, awon igi ti won si gbin saarin ogba naa je ki ibi gbogbo dudu birimu-birimu, ohun gbogbo dudu kiriji. Lati kutukutu owuro ni Ironsi ti n lo to n bo, o ti ba awon oba nla nla to wa lati ibi gbogbo ni Naijiria soro, bee lo ti lo sileewe Mayflower, nibi ti Tai Solarin ti gba a lelejo, leyin naa ni oun ati Adekunle Fajuyi tun ro gbogbo ejo won.

Eyin ti won ti rojo tan yii ni Ironsi dide, o ti re ara loooto, eru ilu soro o ru, lati aaro titi tile fi su, olori ilu ki i ni isinmi, eni to ru eru ilu, eru agba lo ru, tijoba Ironsi yii tile tun lekenka, ijoba ti ko rese mule ni, ijoba ti okan awon to n se e ko bale, eyi gan-an lo si je ki oro Ironsi olori ijoba ohun mu wahala gidi dani. Awewu-sun ko ti i dopin ise, afapoti-rori kan ko gbadun oorun; ohun ti a ko si mo la o mo o, eni to n singba kan ko lowo lowo, nnkan ko rogbo fun ijoba Ironsi.Nitori bee, nibi ti aaye oro ba ti si sile naa lo ti maa n so o, gbogbo ona lo saa n wa lati fi wa ojutuu si isoro Naijiria, ohun gbogbo lo n fee se lati je ki ijoba re le fese mule, ki ijoba naa ma si se ku sona bii eefin. Sugbon egbinrin ote loro naa, bi won ti n pa okan lokan n ruwe, ohun ti won se pe ipade awon oba si Ibadan ree, ejo oro naa lo si ba Fajuyi ro titi di aago mejila oru.
Mu lele, mu lele, bi omode ba mu lele, awon agbalagba yoo mu un lo sode aisun, sugbon ni fere kile o too mo, apa iru omode bee yoo po ju itan re lo, nitori ko ni i le gbe apa re mo, oorun ti i gba towo omode yoo ti gbe e lo. Bee loro Ironsi ri lojo yii, iyen loru ojo kokandinlogbon, osu keje, odun 1966, leyin to ti rojo tan, oorun bere si i kun un, o si dide, o ni oun n lo si yara, ki awon le mura sile fun awon eto ati irin-ajo ojo keji. Oorun de! Bi oun ti dide, bee naa ni awon oga ologun ti won jo wa si irin-ajo naa, Huilary Njoku, naa dide, Adekunle Fajuyi naa dide, onikaluku koja si ibi ti yoo sun, awon soja ti won n so Ironsi si tele e titi to fi wo yara ti yoo sun, nibi to ti tilekun iyara ohun, to si da wa ninu ile nibe, ti awon soja yii si gbe aga tiwon, ti won jokoo si enu ona, nitori eera kan ko gbodo rin oga won.

Sugbon kinni kan ti n sele, kinni ohun n sele lati ona jinjin wa, lati ilu Abeokuta ni. Lati bii aago mokanla ale ni wahala yii ti bere, nnkan si n se niju ti araale ko gbo rara, omo ku loko iya re paapaa ko gbo nile, nitori ni gbogbo igba ti Ironsi atawon eeyan re fi n mura oju oorun nni, nnkan ti daru niluu Abeokuta. Awon oga soja Hausa ti pari eto tiwon, won si ti mo pe Abeokuta ni awon yoo ti bere ijangbon, bi awon ba si ti bere wahala naa tan, awon yoo gbera Ibadan, nibi tawon yoo ka olori ijoba ologun Naijiria mo, nibe ni awon yoo si ti mu un. Ohun to je ki won bere ipaniyan ti ko le;gbe; latinu baraaki awon soja l'Abeokuta niyen, ona ti won si gbe kinni naa gba ati bi won se se e, ona tawon oga soja ti won pa naa ko le ribi sa lo ni. Bee ni awon oga soja ti won pa yii o, omo Ibo ni gbogbo won, awon Hausa puruntu lo si pa won.

Ogagun kan wa ti won n pe ni Remawa ni baraaki Abeokuta yii, okan ninu awon soja lati ile Hausa ti won je oga nibe ni, Captain loye re. Oun ni awon Danjuma ati Gowon ti ba soro, ti won si gbe ise Abeokuta fun, oun gan-an ni won fe ko bere eto ifibon-gbajoba naa nigba tile ba ti su tan pata. Ohun to se ni pe won tan awon oga baraaki naa wa si ibi ti won ti maa n se faaji, se Ibo ni gbogbo awon oga yii, won si fogbon tan won wa sibi ti faaji gbile si, iyen nile igbafe awon ologun ti won n pe ni ‘Officers' Mess' ninu baraaki yii, nibe lawon wa ti won ti n muti, awon o si mo pe Remawa ti ko awon soja Hausa kan sipamo pelu ibon lowo, o ni ki won duro sinu ookun nibe, to ba ya oun yoo so ohun ti won yoo se. Nigba to di aago mokanla ale, Kapteni Remawa fogbon jade, o si pase fawon soja Hausa yii, o ni ki won sina bole.

N lawon soja yii ba wole o, Mejo John Obienu ni won koko ba nibi tiyen ti jokoo to n muti, ohun ti won si se fun un ko daa. Se oga soja ni, bi awon omoose soja kan ba si wole bee ti won ba ba a nijokoo, gbogbo won yoo bere si i beri ni, nitori ki i se oga kekere rara, boun naa ba si jokoo tawon soja wewe ba wole bee, ko sohun ti yoo ba a leru, nitori iberu ejo ko ni i je ki enikeni so ejo di okun, ko waa ni oun yoo fi ejo di igi bo latona oko, ko see se. Nitori bee, nigba tawon soja Hausa yii wole, Obienu ko mira, ko si mikan, oun ti ro pe ko si ewu, afi bi okan ninu awon soja Hausa naa se duro niwaju re, o si yinbon fun un ni ookan okan re, eyo ibon kan naa lo gbe fun un, Obienu ku leekan naa lai mira ni, oti to mu ku wa niwaju e to n ru ninu tombila. Nje ki won ki Okonweze mole, niyen ba tu.

Okonweze yii, oun ni olori awon omo-ogun gbogbo ni baraaki yii o, oun naa wa nibi ti won ti n se faaji naa, o n mu oti faaji, se oun o tete mo pe ewu n be loko longe, ati pe longe funra re naa, ewu ni. Sugbon nigba to ri i tina ibon dahun lara Obienu ti won jo je omo Ibo, ti won si jo je oga, oun sare dide wuya, ki awon omo soja Hausa yii si too de odo re, o ti rapala bo sita. Bo ti jade lo fere ge e, oro naa si di ejo-sare-iku-nagbonnagbon.

Sugbon bo ti wu komode le sare to, eyin naa ni yoo maa fi gigise si, awon soja Hausa ti yi ibi ti won ti n se faaji yii po, won si ti reti pe enikeni to ba sare jade nibe ninu awon oga soja Ibo yii, ina yoo mo on.

Bee lo se pe nigba ti Okonweze be sita to n sare lo, awon soja kan n le e bo latinu ile, awon kan n sare bo waa pade e, nibe ni won ti se peki-n-reki e, ni won ba gbebon fun un.

Leyin eyi ni won yinbon pa Orok, won si bere si i sa awon oga soja Ibo kookan to ku ni baraaki Abeokuta yii jade, won n pa won saa ni. Nigba ti yoo fi to aago mejila loru yii, won ti pa gbogbo awon oga soja ti won je Ibo ni baraaki won l'Abeokuta tan, leyin naa ni Remawa ni ki won gbe moto awon soja jade, won gbe moto meji, won ko soja kun inu re fofo, ibon ti wa lowo won pelu ota re, nitori won ti fo ile-iso ti won n ko ibon ati ota won si, won si ti ko eyi ti yoo to won i lo nibe, afi bii igba ti won mura ogun.

Awon soja yii ni won gbera ti won n lo siluu Ibadan, nigba ti yoo si to aago merin ni feere, won de siluu Ibadan, won si n lo sile ijoba lele, nile ijoba nibi ti Ironsi ati Fajuyi wa. Sugbon eti oba nile eti oba loko, eeyan naa lo n je bee, ko too di pe won de ile ijoba yii, awon oga ologun lati Eko, ati Abeokuta, ti pe Ironsi lori ero ibanisoro to wa fawon ologun, won si ti so fun un pe awon soja kan ti pa awon oga won ni Abeokuta o, won si ti gbe moto, won n bo nile ijoba, ero-okan won ko si dara rara. Nigba naa ni Ironsi dide, o si sare mura ologun, o woso oga agba pata ninu ise soja, o ji gbogbo awon olori-ologun to wa lodo re, won jo n reti awon soja apaayan ti won n bo lati Abeokuta.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, April 28 @ 02:14:00 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Nibi tawon oga soja Ibo ti n muti lawon soja Hausa ti gbebon fun won l'Abeo" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: