Gbagede Yoruba
 



Titilayo foju bale-ejo nitori esun ole
 
Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue Lati Owo Olowoake LatifTitilayo foju bale-ejo nitori esun oleObinrin onisowo eni odun mokandinlogoji kan, Titilayo Ilesanmi, ti n kawo ponyin rojo nile-ejo majisreeti to wa ni Surulere lori esun pipe ara e ni ohun ti ko je lati ya owo to to milionu kan ataabo naira nileefowopamo 'ACCION Microfinance Bank Ltd', pelu ileri lati da a pada fun won, sugbon to ko lati se bee.

Obinrin naa to n gbe lojule kokanlelogorin, laduugbo Akerele, ni Surulere, l'Ekoo ni won wo lo sile-ejo lori esun meta otooto, iyen ole jija, fifipa gba nnkan lowo eni ati fifi iwe sowedowo ti ko wulo kale fun ileefowopamo to yawo lowo e.

Agbenuso ijoba, Koburu Jimah Iseghede, ni isele ohun waye lojo ketadinlogun, osu kokanla, odun to koja, lojule ketadinlogorin, loju ona Ojuelegba, Surulere. Nise ni afurasi naa lo si ofiisi 'ACCION Microfinance Bank Ltd' lati ya milionu kan ataabo naira (N1.5m) pelu ipinnu lati sanwo naa pada fun won lojo kejidinlogun, osu kejila, odun to lo, sugbon to ko lati se bee.

Kaka bee, nise ni Titilayo mu sowe-dowo ti banki Diamond ti nomba idanimo e je 55399195 le won lowo lati gba egberun lona ogofa naira (N120,000), eyi to pada han pe ayederu ni.

Nitori eyi ni asoju ileese naa se pe ero ibanisoro obinrin yii, sugbon nomba ohun ko wole, eyi lo si mu banki naa gba ago olopaa lo.

Ninu iwadii awon olopaa lo ti di mimo pe adiresi ti ki i se ti olujejo yii lo fi sile ni banki to ti yawo, ati pe oruko eni to fi se oniduuro nibe je ayederu, bee ni pe Titilayo ti koko sa lo ko too di pe owo awon olopaa te e.

Gbogbo esun yii ni Iseghede so pe o lodi si abala igba ati marundinlaaadorun-un (285) iwe ofin iwa odaran tilu Eko todun 2011, eyi to n toka si fifi ewon odun meta jura.

Ninu oro re, Adajo Agba A.F. Adeeyo faaye beeli egberun lona eedegbeta naira (N500, 000)

sile fun obinrin naa pelu oniduuro meji niye owo kan naa. O ni iru oniduuro bee gbodo ni iwe-eri pe o san owo-ori odun meta labe isakoso ipinle Eko, o si gbodo nise gidi lowo, ko tun je olugbe ilu Eko, bee ni pe ki agbenuso ijoba sewadii adiresi ile onitohun. O waa sun igbejo sojo kejidinlogun, osu yii.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 05:50:54 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue:
O Ga O! Awon Olopaa Ati Adigunjale Fibon Para Won Loju Ija Niluu Ibadan: Awon Ol


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue



"Titilayo foju bale-ejo nitori esun ole" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com