Gbagede Yoruba
 



Awon soja Hausa fi moto ko ibon wolu Ibadan loru, jinnijinni si mu Aguiyi Ironsi
 
Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo Lati Owo Akoroyin OlootuAwon soja Hausa fi moto ko ibon wolu Ibadan loru, jinnijinni si mu Aguiyi Ironsi ati Adekunle Fajuyi nile ijobaHilary Njoku, oga soja nla ni, oun si ni olori awon omo-ogun nla to wa l'Apapa, l'Ekoo, nigba naa, omo Ibo loun naa, okan ninu awon ti olori ijoba, Ogagun Agba Aguyi Ironsi, fokan tan ni gbogbo igba to fi n sejoba Naijiria laarin osu kin-in-ni si osu keje, odun 1966, ni. Won jo n rin kaakiri ibi gbogbo ti Ironsi n lo ni, won jo lo si Abeokuta ni, won jo wa ni Binni, won si tun jo pada wa si Ibadan ni. Lojo buruku ti ogun le yii, iyen lojo ti wahala sele laarin oru nile ijoba, niluu Ibadan, Hilary Njoku yii wa nibe, oun ati omo Ironsi ti won n pe ni Tom. Hilary yii lo wa pelu Ironsi ati Ogagun Agba Adekunle Fajuyi titi ti Ironsi fi dide pe oun n loo sun, leyin ti Ironsi ti lo naa si ni Hilary dide, toun naa bo sita lati loo sun sile alejo ti won fun un. Bo ti wole ko tete sun, o n rin kaakiri faranda ibi ti won fi i si, o si pe ki oorun too gbe e lo.

Ni deede aago merin ni feere ni telifoonu to wa ni yara ibi to sun dun, o si ta giri dide lojiji bii eni to n reti wahala tele, se ologun kuku loun, bee lokan re ko si bale tele, nitori ariwo iku ati ija ti won ti n so kaakiri ibi gbogbo ni Naijiria lasiko naa. Bo ti ji to laju, telifoonu naa tun dun leekan si i, n loun ba gbe e. Ta ni, bee lo wi. Nigba naa ni okan ninu awon eso to wa leyin Ogagun Agba Ironsi, eni ti won n pe ni Thomas soro sinu ero ohun, o si so fun Hilary Njoku pe ko mura lesekese, ko woso ologun re, ko si maa bo lodo oun kia. Won ko so ju bee lo, bee ni ko se dandan ki won so ju bee lo ti Hilary fi mo pe wahala ti sele niyen, ohun to ba le mu olori-ogun pata pe oun ni aago merin feere, to si je awon sese jo loo sun ni aago mejila ni, to tun waa so pe ki oun woso ologun oun ki oun maa bo, nnkan kan ti sele nibi kan ni.

Oro awon soja ko sese ni pe a n sare sotun-un sosi, tabi a n fi epo bo iyo ninu, bi ogun ba ti ya o ti ya naa ni. Okunrin naa sare wo ileewe to wa nibe, o mu toweli kan, o ti i bo omi, o si fi omi naa boju ki oju re le la daadaa, leyin naa lo si sa pada sinu ile, o woso re, o si gbe ibon kekere kan bayii to le pa to eni mewaa leekan, o gbe e sowo genge, o sare jade nibi to wa, o di odo Ironsi. Titi to fi jade si gbangba, to si rin lati ibi ile kekere toun sun si titi wo ile nla tawon Ironsi wa, ko si kinni kan to ri, ko si sohun kan to sele si i to je nnkan iyanu, ibi gbogbo pa kanrin kese ni, niwon igba ti ko si si ina ninu ile ijoba naa, nise ni gbogbo ayika dudu, aago merin feere ki i se asiko tile n mo rara, agaga nigba ti ki i se asiko osupa aranmoju, ko si bi eeyan se le wo ookan ti yoo ri enikan, ohun gbogbo dudu kirimu.

Nigba ti Hilary wole sibi ti Ironsi wa, enu ya a lati ri i pe oga oun, iyen olori ijoba Naijiria naa ti mura ologun, o si ti woso re, o de; gbogbo oye ogun re mejika, ase ati agbara si ti dowo re lesekese, o n reti ohun ti yoo sele nile ijoba. Adekunle Fajuyi naa wa nibe, se ko senikan ti yoo gbalejo ti okan re yoo bale ti ohun ti ko dara ba fee sele si alejo naa, nitori o n dewaju o n dejo, o n deyin o n daso¯, alaye wo ni babalawo yoo se fawon ebi eni ti won mu lo si igbodu loo te nifa, ti tohun si se bii ere bii ere to ku si igbodu nibe. Kin ni Adekunle Fajuyi yoo so fawon omo Naijiria pe olori orile-ede awon ku sinu yara e, tabi pe ibe ni won ti ji i gbe lo, agaga awon omo Ibo, kin ni yoo so fun won pe o sele somo won nile Yoruba, alaye wo ni yoo se ti yoo si wo eti enikeni ninu won.

Nidii eyi, bi Hilary ti wole to ri Ironsi ninu aso ologun, oun naa mo pe wahala to sele yii ko kere rara. Nigba ti yoo si tun wo ayika, o ri Adekunle Fajuyi ninu yara kan naa nibe tiyen n rin lo to n rin bo, ti ko le duro ti ko le bere, to saa n jowere ara bii eni pe yara ti won wa naa ju bee lo. Ironsi beere pe ki lo de, won si salaye fun un pe wahala ti sele lati Abeokuta, awon soja Hausa ti won wa nibe ti pa gbogbo awon oga won, awon oga won ti won je omo Ibo, won si ti n ko ara won bo nile ijoba Ibadan nibi, ohun ti won fee waa se ko ye enikan. Awon mejeeji mo ohun ti won fee waa se o, nigba ti won si so fun Hilary naa, o mo ohun ti won fee waa se. Abi nigba ti won ba ti pa awon olori won to wa ni Abeokuta, ti awon si mo pe iru nnkan ti won se yii, iku ni yoo ja si fun won, dajudaju bi won ba se bee yo si Ibadan, won yoo pa olori ijoba naa ni.

Hilary beere ibi ti telifoonu wa, oun fee maa telifoonu kaakiri lati mo ohun to n sele, ati ibi ti iranlowo ti le ba awon. Kinni naa dun okunrin oga awon soja yii, iyen Hilary, nitori o mo pe bo ba se pe Eko ni oun wa ni, ti oun wa nidii redio nibi ti ase wa, ti oun si le ba awon eka ologun oun soro yikayika gbogbo Naijiria, oun yoo teri ote naa ba kia. Sugbon ko si ona bi yoo ti ri enikeni, tabi ti yoo fi mo nomba awon ti yoo pe lori.

Sugbon nigba to de ibe loooto, o bere si i telifoonu kaakiri, o si n pe awon to ranti nomba won lori. Eni to koko pe ni olori awon ologun soja Ibadan, iyen Joe Akahan, omo Hausa ni, sugbon oun ni olori oko nibe, o si ti n tele Ironsi kiri latigba to ti de, to n se bii eni pe oga oun tooto ni, ati pe omoose daadaa loun. Nigba ti Njoku pe e, to si salaye oro to n lo fun un, Akahan ni ko si ohun to jo bee lodo oun o.

Hilary tun bi i leekan si i pe se awon soja tie wa ni ipamo ni baraaki, won si ti sun lo, okunrin yii ni bee ni, o ni awon soja toun ti sun, oun ko si le ji won sile, tabi ki oun je kiru oro bee de eti won, ki won ma bere wahala kankan. Okan Hilary bale, o ni oun ti gbo o. Ohun toun ko mo ni pe Akahan yii gan-an wa ninu awon ti won seto iku naa fun Ironsi, o wa ninu awon ti won n dite naa, ati pe awon soja ti awon naa fee lo ti gbera, Theophilus Danjuma si ti de saarin won lati Eko, ko seni to mogba to wole ati bo se de, oun lo si saaju awon soja yii, awon naa gbera ile ijoba. Ase ti won fun awon ti won n bo lati Abeokuta ni pe ki won duro de won, nigba ti won ba ti de lawon ti Danjuma ati Akahan n ko bo yoo too waa ba won, ti won yoo si se ohun ti won fee se ni wara-n-sesa, lai ni i si wahala kankan.

Sugbon Hilary ko mo, oun n telifoonu lo saa ni. Lasiko naa ni Emeka Ojukwu, oga soja to n se gomina ile Ibo telifoonu, o ni koun naa tie gbo ohun to n sele, o si ba Ironsi soro, sugbon ko si iranlowo to le se lati ile Ibo ti yoo de odo Ironsi loru bee. Ogagun David Ejoor ti i se gomina ipinle Midwest naa telifoonu, oun naa ni oun ti gbo bi oro naa ti se sele, sugbon ohun to buru ni pe ko si iranlowo toun naa le se loru bee lesekese bi ile ko ba mo, nitori irin Ibadan si Binni ki i se wasa rara. Nibi ti won ti n soro yii ni ina moto meji kan ti tan yo¯o¯ lati ookan, o si han pe awon moto naa n bo nile ijoba ni. Adekunle Fajuyi lo koko soro, o ni, “Awon niyi, won ti de, won ti yi wa po pata!” Hilary dahun pe afi kawon ye won wo ki awon le mo boya awon ni tabi awon ko, bi bee ko, awon yoo kan maa beru ninu ile ni.

Nigba naa ni Hilary Njoku jade, sugbon ohun to sele si i ni gbangba ode nibe ko daa!

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:04:12 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo:
Yoruba Greetings, (Middle) Names In Yoruba Language With Titles Of Obas (Kings)


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo



"Awon soja Hausa fi moto ko ibon wolu Ibadan loru, jinnijinni si mu Aguiyi Ironsi" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com