Gbagede Yoruba
 



Nibi ipade awon minisita ni Western Region, Akintola loun loga, Awolowo loun log
 
Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
Lati Owo Akoroyin Olootu


Nibi ipade awon minisita ni Western Region, Akintola loun loga, Awolowo loun loga agba, ija ti won koko ja ni gbangba niyen


Bi Obafemi Awolowo ko ba mo tele, oun naa ti foju ara re ri i bayii pe ko si ohun meji ti omoose oun tele, Ladoke Akintola, fe ju ki oun maa da se ijoba oun lo, ko fe ki oga re maa da si ohun ti oun ba n se, o fe ki okunrin naa fi oun sile ki oun se ijoba toun bi agbara ati ogbon ori oun ba ti gbe e mo. Awolowo ko fe eyi, paapaa nigba ti kinni naa lodi si ofin egbe won, ati pe yoo tun so oun funra oun di eeyan yepere ti enu re ati apa re ko ka egbe re mo, oun ko si ni i je kinni kan loju awon asaaju egbe to ku, ati loju awon ondibo, ati awon araalu gbogbo. Bawo ni eeyan yoo se waa se eleyii ti ko ni i mu ija dani, ibo ni eeyan yoo gbe awon oro yii gba ti ko ni i di ariwo, awon ohun ti Awolowo n ro lokan ara tire niyi, nitori nibi ti oro naa ti de duro, afaimo ko ma pada waa di nnkan ariwo.


Akintola ti so bayii pe oun ti yan awon minisita oun, bee ibi ti Awolowo duro de e tele lati fi han an pe oun si ni olori egbe Olope ree, ati pe oun ni asaaju gbogbo won. Akintola mo ohun to n se o, bo tile je pe ona to n gbe kinni naa gba n bi oga re ninu. Akintola fe ki gbogbo agbara ijoba oun wa lowo oun ni, bakan naa lo si fee lo ipo ara re gege bii olori ijoba, ati pe eni to ni elede lo labule, eni to ba je olori ijoba naa lo ye ko je olori egbe oselu won, nitori bi Awolowo se se nigba to n sejoba niyen. Ohun to fa a to fi n gbe gbogbo awon igbese yii niyi, nitori oun naa ti mo pe eni to ba yan minisita, oun naa lo lagbara lati yo o kuro nipo, minisita ti ko ba si fe ki won yo oun nipo ti oun wa, ko si ohun ti yoo se naa ju ko je olododo si eni to yan an sipo naa, ko si maa gboro si i lenu ni gbogbo igba lo.



Ohun ti Ladoke Akintola se ri i pe oun loun yan awon minisita oun ree, ki won le je oloooto soun, ko ma di pe won yoo maa loo soro oun fun Awolowo bi awon ba ti sepade kan nile ijoba. Oro naa ka Awolowo lara, nitori bii eni to ye aga nidii re ni. Kin ni yoo waa se nigba ti oro ri bayii@ Awolowo wo Akintola, o so fun un pe ko buru, bo ba je o ti yan awon minisita re, a je pe ko koko mu oruko won wa laaaro kutu ki awon agbaagba egbe ri i, ki won si ba a fowo si i ko too di pe o loo sebura fun won, leyin to ba si sebura fun won tan, ki gbogbo won maa bo nile oun, ki won waa ri awon agbaagba egbe, ko le je pe won tele ilana egbe, ko ma se pe awon agbaagba egbe ko mo nipa bi ijoba se yan awon minisita. Akintola ni ko buru, oun yoo mu oruko wa laaaro, bi awon ba si sebura naa tan, awon yoo maa pada bo nile Awolowo.


Awolowo salaye, o ni oun fe ki won wa sile oun bee, ki oun le ki won ku oriire fun ipo tuntun ti won yan won si, ki oun si le salaye awon ohun ti won gbodo se, ati awon ohun ti won ko gbodo se ni ilana si ofin egbe won. Ohun ti Awolowo se n se eyi ni pe oun naa ti ri i pe oro ti koja ibi ti awon gbe e si tele, ogbon ni agbalagba si fi n sa fun maalu, bi bee ko, maalu yoo fi iwo tu oluware nifun. Bo ti wu ki Akintola lagbara lori awon eeyan yii to, bi won ba wa siwaju awon asaaju egbe, ti won si mo pe awon asaaju egbe lo fowo si yiyan ti won yan awon, won yoo beru awon asaaju egbe ni adugbo kaluku won. Awolowo mo pe bo ba je ona ti Akintola fee gbe e gba yii naa lawon gba, awon minisita yii ko ni i bowo fun asaaju adugbo won kankan, Akintola nikan ni won yoo beru, won yoo saa ti mo pe oun nikan lo lagbara lori awon.


Ni aago mesan-an aabo ni owuro ojo keji, iyen ni ojo kokanla, osu kejo, odun 1960, Akintola de sile Awolowo pelu oruko awon eeyan to fee fi se minisita re gbogbo. Bo ti wa yii, Olorun nikan lo mo bi awon oniroyin ti gbo, ti won si gbe e, won ni Akintola n lo sile Awolowo lati loo pade awon agbaagba egbe won nibe, o fee loo soro awon to fee fi se minisita ninu ijoba re fun awon asaaju Egbe Olope, ki awon agbaagba yii le ba won fowo si i. Iroyin naa ko te Akintola lorun, nitori ko mo bi iroyin ohun ti jade. Ko mo boya awon omoose oun lo gbe e jade ni tabi awon eeyan Awolowo ni won gbe kinni naa jade, o si da bii pe awon Awolowo lo fi ajulo oselu han an nitori bi oro naa ti jade ko ye enikan. Sugbon niwon igba to je ohun ti awon Awolowo fe niyen, ki awon minisita wonyi mo pe Akintola nikan ko lo lase lati yan won tabi lo yan won, iroyin naa te awon lorun daadaa.


Nigba ti Akintola yoo fi de, awon agbaagba egbe ti won ri ara won sa jo ti jokoo, awon ti won si ti de sipade naa ni Anthony Enahoro, Ayotunde Rosiji, Alfred Rewane, S O Gbadamosi ati S O Sonibare. Bo tile je pe Awolowo pe ju awon yii lo, iwonba awon ti won le de si ipade naa ki aago mesan-an ti won fi si too lu niyi, nitori aago mokanla ni Akintola ti mura lati sebura fun won. Awon agbaagba egbe gba iwe ti Akintola mu wa, ohun akoko to si koko se won ni kayeefi ni pe awon ero ti po ju ninu igbimo naa, won fere to ilopo meji iye ti Awolowo n lo tele, oro naa si di isoro fun awon asaaju egbe ti won jokoo naa, nitori won ko mo oruko eni ti won yoo yo kuro ninu awon ti Akintola ko oruko won wa yii ti ko ni i di wahala tuntun, tabi ko tile da egbe paapaa ru.


Ohun to fi le mu oro naa di wahala ni pe gbogbo awon ti Akintola ko oruko won wa yii, gbogbo won lo ti so fun pe oun ti yan won ni minisita, bee lo si ti so fun won ki won mura lati waa sebura won nijo yii gan-an, ta ni won yoo waa fa oruko re yo ti ko ni i bi ede-aiyede nla si inu egbe won. Bee bo ba se pe ilana ti egbe won n lo tele ni, won ki i so fun awon ti won yoo fi se minisita tele, afi leyin ti awon agbaagba egbe ba ti ye oruko won wo, ti won si ti mu awon ti won fee mu ninu won. Enikeni ti won ba ti mu ti won si ti yan ni won yoo sese pe lati so fun un pe oun ni minisita, ko mura lati waa se ibura re. Sugbon eleyii yato gan-an ni, bo tile je pe awon agbaagba ko ti i fowo si awon ti Akintola mu, ti won ko tile ti i mo oruko won, Akintola funra re ti so fun won, o si ti ni ki won mura maa bo nile ijoba.


Nidii eyi, awon agbaagba egbe yii ko le se ohunkohun mo, ko si ohun ti won yoo tun se si oruko to wa niwaju won yii, eyi lo si fa a to je leyin ti won fa oro naa lo ti won fa a bo, ohun ti won fabo si naa ni ki awon fi oruko naa sile o, ki Akintola maa ko awon minisita re lo. Akintola paapaa tile ti so fun won pe ero to wa lokan oun toun fi se kinni ohun ni pe ka rin ka po, yiye ni i ye ni, bi awon ba po tawon ba n sejoba, amojuto yoo wa ni gbogbo ona, awon yoo si le gbo ohun tawon n jiroro lori, ohun gbogbo to ba ye kawon se, ko ni i si pe awon ti ko ni imo to kun ko si ninu ijoba awon. Awon Awolowo ni oro to wa nile yii koja eyi ti Akintola n wi nni, won ni owo ti kinni ohun yoo mu dani nko, ati ona wo ni won yoo gba ti eyi ti won se yii ko fi ni i mu isonu wa loju araalu, ati eebu latodo awon alatako awon.


Loro kan, won ni ki Akintola maa lo, ko loo sebura fun awon to ti yan naa, bi won ba si ti sebura tan, ki won maa pada bo lodo awon. Ojo nla kan lojo naa fun awon minisita tuntun yii, nitori onikaluku ti ko si awon agbada nla, awon ti won wo aso etu wo aso etu won, awon ti won wo aso oke wo aso oke, bee ni lara won wo dansiki to niye lori gidigidi. Tidunnu-tidunnu ni kaluku fi wa nibe, nitori ipo ola tuntun ni fun awon mi-in, iyen awon ti won sese yan, ipo itesiwaju ola si ni fun awon ti won ti wa nibe tele, nitori bee ni ko se si eni ti inu re ko dun laarin won. Ibura ti won se fun won ni pe awon yoo je oloooto, awon yoo sise ilu ni ona ti ko fi ni i mu abuku ba ijoba, bee ni gbogbo asiri ijoba pata lawon yoo pamo. Bi won ti se bee tan lawon onilu ti won ti duro sita ile ijoba nibe fi ilu si i, ariya si sele repete.


Leyin ti won ti se ariya die ni Akintola ta gbogbo won lolobo pe awon n lo sile Awolowo, ki onikaluku tete tele oun bi oun ti n saaju won lo. Bee ni gbogbo won ko reirei, o si di ile Awolowo. Awon agbaagba egbe ti won ti ye iwe Awolowo wo laaaro si wa nibe, awon mi-in naa si ti tun de saarin won, iyen ni pe ese awon agba egbe pe, ko si si omode kan to gbodo ta felefele. Awolowo lo si ipade naa, o si ki gbogbo awon minisita naa ku oriire, o salaye fun won pe ki won too le yan won sipo naa, won ti ri i pe eeyan kan to see mu yangan ni won o, ati pe won ni opolo pipe ti won le fi se ise ilu. Olori egbe Olope naa ni ohun ti oun fe ki won gbe de ile ijoba ree, ki won le fi ogbon ati imo won sise fun araalu, ki won si le ran ijoba lowo lati se ohun gbogbo to ba fee se.


Nibi ti wahala ti bere ni igba ti Awolowo soro de ibi kan, oro to so nipa ihuwasi ati ilana egbe won fun gbogbo eni to ba di ipo minisita mu labe ijoba egbe Action Group. Nibi ipade yii ni Awolowo ati Akintola ti koko dan agbara won wo ni gbangba, awon eeyan ti won si n ro pe odun 1962 ni ija awon mejeeji yii sese bere ko mo bi itan naa ti ri tan, nitori awon ohun kan ti n sele ko too di igba naa. Fun igba akoko ni gbangba, Awolowo pa Akintola lenu mo, o si je ko mo pe oun ni olori egbe oun, ati pe egbe ni oun Akintola n sise fun, ko si lase kankan lori egbe naa ju eyi toun gege bii olori, tabi awon agbaagba egbe ba fowo si lo. Oro naa dun Akintola atawon ti won n tele e, o si ka awon minisita kan paapaa lara, afi awon ti won je ti Awolowo nikan ni kinni naa te lorun.


Alaaji Sule Gbadamosi lo soro kan, o si ni ki egbe da si i, iyen leyin ti Awolowo ti soro re tan ni o. O ni oro ti oun fee so yii, oro to ti bere si i sele latigba ti Akintola ti di olori ijoba ni, oun si fe ki egbe jiroro lori oro naa, ko ma di pe awon n se ohun ti ko ba ofin egbe awon mu. Alaaji Gbadamosi ni teletele, ohun to wa ninu ofin egbe awon ni pe enikeni to ba n se minisita, tabi to ba di ipo pataki mu ninu ijoba ko gbodo gba ile lowo ijoba, iyen ni pe enikeni to ba n se minisita ko gbodo ni ile ni GRA, tabi ni Bodija, tabi ni awon ibomiran to je adugbo tijoba ya soto ti won n pe ni ‘Estate', enikeni to ba se bee, o ti se ohun to lodi sofin Action Group, egbe Olope niyen. Sugbon Gbadamosi so pe latigba ti Akintola ti gbajoba ni awon minisita re ti n nile ni GRA, ti won si n gba ile ijoba kaakiri.


Bi Gbadamosi ti soro naa, bee ni Akintola koro¯ oju, oro naa ko si ba a lara mu rara. Lesekese ni Akintola so pe oun gege bii Peremia, oun lo agbara oun naa lati fagile iru ijiroro bee, oun fagile oro ti Alaaji Gbadamosi so, ko si ni i si ijiroro kankan ti yoo waye lori oro ohun ninu ijokoo ti won wa naa, afi lojo mi-in toun ba faaye gba a. Ohun gbogbo palolo, nitori iru eleyii ko sele ri, erin ki i fon ki omo inu re naa tun fon.


Awolowo wa lori ijokoo, awon agbaagba egbe wa nibe, ki Akintola si so ni gbangba pe oun fagile oro ti S.O Gbadamosi so, oro naa ko; awon omo egbe to ku lokan soke, awon minisita tuntun ti won si sese yan ko le wo oke, ile ni won n wo, ko senikan to le woju enikeni ninu awon agbaagba egbe, kaluku ko tile mo ohun ti yoo sele nibe rara.


Nigba naa ni Awolowo dide, oun naa si soro. Awolowo ni gege bii ofin egbe awon, ni iru ipade bayii, iyen ipade yoowu to ba ti waye to je ipade egbe ti ki i se ipade ijoba, tabi to ba ti le waye nibi yoowu ti ki i se ile ijoba, olori egbe ni yoo maa se alaga ipade bee, oun ni yoo si maa pase ohun gbogbo to ba fe, oun nikan lo si le dari ipade, oun lo le ni ki enikeni soro, oun lo le ni ki enikeni ma soro, oun lo le so ohun ti won yoo jiroro le lori, oun lo si le pase ohun ti won ko ni i jiroro le lori. O ni nitori bee, oun loun letoo lati pase, Akintola ko letoo, ko si le pase nibi toun ba wa rara. Nibe ni Akintola ti jokoo jee, o si dorikodo pelu ibinu, tipatipa ni ko si fi binu dide kuro laarin won. Sugbon ko seni to woju e ninu awon agbaagba egbe, koda, awon kan n so o lokan ara won pe Olorun lo mu un, ila e fee ga ju onire lo ni.


Leyin naa ni Awolowo pase pe ki Gbadamosi tun oro re so, ko tun oro naa gbe kale, ki gbogbo awon asaaju egbe si jiroro le e lori, ki awon minisita naa gbo, ki won le mo ohun ti won yoo se si i. Die lo ku ki ijiroro lori oro ile ijoba yii fo ipade naa si wewe, ohun ti won ba ara won fa nibe ko kere rara ni. E maa ka a lo lose to n bo.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:09:56 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo:
Yoruba Greetings, (Middle) Names In Yoruba Language With Titles Of Obas (Kings)


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo



"Nibi ipade awon minisita ni Western Region, Akintola loun loga, Awolowo loun log" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com