Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Iya meji je Tokunbo n'Ibadan: Won ja a lole owo ati foonu, won tun fipa ba
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Akoroyin Olootu


Iya meji je Tokunbo n'Ibadan: Won ja a lole owo ati foonu, won tun fipa ba a lo po


Bi iya nla ba gbe ni sanle, kekere a maa gori eni, eyi lo difa fun obinrin eni odun metalelogun kan, Olatokunbo, eni ta a fi ojulowo oruko e bo lasiiri ti ole kan ja poosi owo e gba, tawon to n ba a se aajo lati mu okunrin ole naa si tun ja a lole ara. Nise ni won dogbon tan an lo soju olomo-o-to-o, won ya sikeeti to wo mo on nidii, won si fipa ba a lasepo.


Lojo Aje, Monde, ose to lo lohun-un nisele ohun waye nigba tawon olubi okunrin kan fipa ba obinrin onisowo yii lasepo laduugbo Academy, lagbegbe Iwo Road, n'Ibadan, leyin bii wakati meta tawon ole kan ti ja poosi e gba laduugbo ohun lojo kan naa.


Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ayoonu iloso ni Tokunbo kiri gba adugbo naa koja ni nnkan bii aago mefa irole to fi bere si eyin fensi ileewe girama kan laduugbo naa lati to¯. Nibi to ti n bo pata lowo lokunrin jaguda ohun to jo pe o ti n so o tele sare gba egbe e koja, o si ja poosi to n pa owo si gba lowo e. Kia ni Tokunbo sare wo pata e to si gba ya okunrin ole yii, sugbon ko sare debi kan ti a-lo-kolohun-kigbe naa fi poora mo on loju.


Egberun mewaa naira ati ero ibanisoro Nokia ti owo e to egberun merindinlogun naira la gbo pe o wa ninu poosi ohun. Ori aajo dukia ti Tokunbo padanu wonyi lo wa tawon okunrin meji kan ti won pe ara won ni ode to n so adugbo naa fi de ba a, ti won si gba lati ran an lowo lati wa ole naa, laimo pe nise lawon eeyan naa tun fee da tiwon kun iya to ti je e tele.Nnkan bii wakati meji la gbo pe awon ti won n pe ara won lode yii fi mu Tokunbo duro segbee oju ona kekere kan tawon eeyan n gba koja laduugbo ohun. Leyin ti won ti woso o¯tu;tu¯ ti won ran ni aran po mo fila kan fun un lati le je ko soro fun enikeni lati da a mo lati ookan ni won so fun un pe ko maa dogbon fi oju wa eni to ja a lole ninu awon to n koja.


Niwon igba to ti so pe oun da eni naa mo, tawon paapaa si fi da a loju pe awon mo eni naa, won ni okan ninu awon ti won maa n sun kiri egbe titi laduugbo naa lo huwa ika ohun, ati pe eni tawon n wi yii ko le sai tun pada gba adugbo naa koja, won jo duro sibe.


Gege bi alaye ti Tokunbo funra e se so, o ni oju kan yii loun atawon okunrin naa wa ti enikan toun ro pe o je ojulowo fijilante adugbo ohun fi ba awon nibe, ti okan ninu won si sare loo soro wuyewuye si i leti leyin to ti pe won nija pe kin ni won n se nibe lasiko ti ile ti su yii. Leyin eyi ni iyen kilo fun awon pe kawon kuro nibe, o si ba tie lo.


Obinrin eni odun metalelogun yii so pe lojiji lawon eeyan yii fi eyin oun lele, nigba toun yoo si fi mo oun to n sele, okunrin kan ti jade wa latinu ileewe to wa legbee ibi tawon jokoo si, iyen ko si se meni se meji to fi fa sikeeti toun wo ya, to si ba oun lasepo pelu tulaasi.


Okunrin eni odun metalelogun ti aworan e wa ninu iroyin yii, Oluwatoyin Ade-Tella to n fi omolanke sise aaru nigboro Ibadan ni won lo fipa ba Tokunbo lasepo. Awon ore e meta, Gafari Alani, Sola Solomon ati Damilare Ajibade ti won jo je omo asunta nigboro Ibadan ni won ba a di omobinrin naa lowo ati ese mu.


Iwe Iroyin Yoruba gbo pe leyin tawon odaju okunrin yii sise ibi ohun tan ni won sa lo, ti won si fi Tokunbo nikan sile nibe. Nigba ti obinrin yii dide to n sunkun to rin de ibi ti awon eeyan po si die, to si keboosi ohun to sele si i lo too ri iranlowo gidi. Awon eeyan yii ni won tele e de ibi tawon omo asunta agbegbe naa n sun ti Tokunbo si toka si Toyin pe oun lo ba oun lasepo ninu won.


Loju-ese lawon araadugbo yii mu Toyin atawon meta mi-in (Gafari, Solomon ati Damilare), won si fa won le awon olopaa lowo.


Bo tile je pe Toyin so pe nitosi ibi ti won ti ja obinrin naa lole owo, ole dukia ati ole ara loun wa toun si n gbo gbogbo oro ti won n so, sibe, oun ko mo nnkan kan nipa oran naa.


Omokunrin alabaaru to n sun egbe titi ati ile ahoro kiri lagbegbe Iwo Road, n'Ibadan, yii salaye pe, "Inu ileewe yen lemi n sun. Bi mo se jeun tan lale ojo yen ti mo jade pada loo ra pio-wota ni mo ri obinrin yen pelu awon okunrin meji ti won jo n soro. Nigba ti mo n pada bo ni okan ninu won to n je Omo Ado so pe won ji poosi omo yen lo. Mo pada si ibi ti mo n sun ni mo gbo ti ode kan de ba won nibe, to si n bi won leere pe kin ni won n se nibe lasiko ti ile ti su. Mo tie gbo ti okan ninu won so pe orebinrin oun ni omo yen je, emi saa pada sinu kilaasi ti emi fee sun ni temi." Okunrin eni odun metalelogun to jewo pe oun maa n mugbo yii royin siwaju pe, "Ori aga nita lemi koko sun si, Gafari ati Dare sun sinu kilaasi. Nibe la ti gbo ti won n pariwo nita ka too maa gbo pe won gba poosi omobinrin kan ti won si tun ba a lasepo. Bi awon araadugbo yen pelu awon fijilante se waa ba wa ti won bere si i lu wa nibi ta a sun si niyen, won ni awa la ba omo yen sun. Omo yen waa nawo si mi pe emi ni mo ba oun lasepo." Nigba to n fidi isele yii mule, alukoro ileese olopaa ipinle Oyo, DSP Adekunle Ajisebutu, so fakoroyin wa pe eka oluwadii ni ileese olopaa ipinle naa, iyen SCID, Iyaganku, n'Ibadan, ti n tesiwaju ninu iwadii oran naa.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:27:24 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Iya meji je Tokunbo n'Ibadan: Won ja a lole owo ati foonu, won tun fipa ba" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: