Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Amidu sa egbon e ladaa, o tun fee yinbon pa awon ara abule won
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Akoroyin Olootu


Amidu sa egbon e ladaa, o tun fee yinbon pa awon ara abule won


Opo awon ara agboole Obasa to wa labule kan ti won n pe ni Aba-Oje, nijoba ibile Lagelu, nipinle Oyo, ko foju ba oorun moju Ojobo, ti i se ojo karun-un, osu keta, iyen Tosde, ose to koja, pelu bi okunrin eni odun meeedogbon kan, Rafiu Amidu Abiodun, se gbana je, to gun egbon e, Simiyu Rafiu nigo leyin to ti koko sa a ladaa sugbon ti kinni naa ko tu irun lara e. Bee loree e to n je Owolabi naa gun alabaagbe won lobe yannayanna.


Nitori ija kan to ti waye laarin Amidu pelu okunrin kan to n je Tajudeen lati nnkan bii osu meji seyin la gbo pe o fa wahala ohun, pelu bi Amidu se be Owolabi ore e lowe lati ba oun da seria fun Taju. Nibi ti Simiyu to je egbon Amidu ti n gbiyanju lati pana wahala naa ni aburo e ti pa igo mole, to si gun un yannayanna.


Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, baba kan naa lo bi Amidu ati Simiyu, bo tile je pe iya kan ko pa won po. Inu ile won ni Simiyu n gbe, nigba ti Owolabi ni tie je omo abule kan ti won n pe ni Aba Eleran Igbe lagbegbe naa.Oti la gbo pe Amidu ati Owolabi toun naa ko ju eni odun meeedogbon lo fi gbogbo ale Ojoru, Wesde, to koja mu labule kan ti won n pe ni Esu;o¯bi titi di nnkan bii aago kan aabo oru. O jo pe nidii oti ni won ti jiroro lori ona ti won yoo gba gbesan ija ti Amidu ati Taju ja lara eni tawon eeyan tun mo si Oji ohun, bee lokunrin naa ki i segbe enikeni ninu won.


Ni nnkan bii aago meji oru ni won pada sabule Aba-Oje, ti won si loo kanlekun mo Taju lori. Nigba tiyen ko da won lohun ni won wa ogbon tan an jade, ti Amidu si pase fun Owolabi lati fo o leti leralera nisoju oun nibe. Igbiyanju egbon Amidu (Simiyu) lati gba alabaagbe won yii sile lo koba a pelu bo se je pe Amidu aburo e gan-an lo koko sa a ladaa, nigba ti ada ko si ran an lo pa igo mole, to si fi gun un yannayanna nigbaaya ati apa osi bii kiyen tibe ku mo on lowo. Eyi mu ki Owolabi raaye dojuko Taju daadaa, o si bere si i sa a ladaa bii igba ti alapata ba n sa eegun maalu.


Igbe awon eeyan wonyi lo ji awon ara abule latoju oorun, sugbon bi Amidu se ri i pe awon eeyan ti bere si i pe le awon lori lo sare wonu ile loo fa ibon ilewo kan yo, o si yinbon soke gbau lai besu begba, n ni kaluku ba sa asala femii e, o si ku Taju ati Simiyu nikan ti won n jerora ninu agbara eje nibe. Bi Amidu ati Owolabi se wo raaraara ti won ri i pe awon eeyan ti sa lo tan lawon naa kan lugbo, won fese fe e, ko si seni to ri won titi ta a fi pari akojo iroyin yii.


Leyin tawon ipata omo naa ti lo tan lawon ara abule ti won ti sa lo tele yoju si gbangba lati saajo Simiyu ati Taju ko too di pe won loo fi isele ohun to awon olopaa leti ni tesan IyanaOfa, laaaro ojo keji (Ojobo, Tosde, to koja). DPO tesan naa, Justina Ogunleye, lo seto bi awon ti won se lese naa se lo sileewosan aladaani kan to wa niluu naa lati loo gba itoju to peye.


Odo agbe olosin adie kan niluu Iwo, nipinle Osun, la gbo pe Amidu ati Owolabi ti n sise.


Ibon tokunrin oniwahala yii fi n sise ode nibe lo fi deruba awon eeyan abule won leyin ti won ti se Taju ati Simiyu lese tan.


A gbo pe Amidu ti kuro nibi ise naa ni nnkan bii ose meji seyin nitori oun ati oga e ti ja, o si bu oga e naa bii eni layin, eyi to mu ki iyen gbe e sepe ko too le e kuro nibi ise naa.


Ipanle omo kan bayii ni won pe Amidu, won si ti figba kan le e kuro ni Aba-Oje yii nitori ijangbon to maa n fa nigba gbogbo. Sugbon diedie lo rora maa n yo wo inu abule to fi di pe o pada sibe patapata.


Nigba to n salaye bi isele naa se waye fakoroyin wa, Tajudeen so pe ko si ija kankan laarin oun pelu Amidu debi tokunrin naa fi le de eeyan soun. O ni ija toun ranti pe awon ja gbeyin ti sele lati nnkan bii odun meje seyin, iyen nigba tawon aburo oun na an nigba tija pa oun pelu won po, sugbon won ti pari ija ohun fawon nigba naa.


“Ija yen ti to odun meje seyin. Iya ore wa kan la loo ba senawo ni abule keji tija fi be sile laarin wa leyin ti kaluku ti fi nnkan sara (muti) tan. Emi ko wule ba a ja lojo yen, awon aburo mi to wa nibe ni won ni awon ko le maa wo o ko maa ba egbon awon ja, ti won fi jo n ja. Bo se wa n pada bo wa sile lale ojo yen to fee wo moto lawon olopaa ri i ti won beere lowo e pe ki lo de ti oju e pon, o lawon ja ni, sugbon won ni nise lo jale ni won fi na an toju e fi wu. Nigba to mu won pada sabule ti won ti senawo ohun lawon olopaa too gba a gbo. Ko ye ko je ikanra iyen ni yoo tun fi maa ba mi ja lasiko yii, nitori oro yen ti to odun meje bayii.


“Ni nnkan bii aago meji oru ni mo n gbo ohun Amidu ati Owolabi ti won n pe mi. Mo gbo ti Booda Simiyu n so fun won pe ki won fi mi sile pe mo ti sun. Leyin naa ni mo gbo ti won n so pe iya awon Amidu lo n pe mi. Mo ro pe iya lo n pe mi loooto ni mo se jade si won, afi bi Amidu se so pe ki Owolabi maa fo mi leti koun maa wo o.” Ninu oro tie, Simiyu Rafiu fidi e mule pe nitori pe oun ko fe ki aburo oun ati ore e ba Taju ja ni aburo oun se doju ija ko oun, tawon mejeeji si pada se oun ati Taju lese to bee to se pe Olorun ni ko fi emi awon le won lowo.


Gege bi okunrin eni ogbon odun naa se so, “Nibi ti mo ti n gbiyanju lati petu si won ninu ni Amidu ti fa ada yo si mi, to bere si i sa mi ladaa. Nigba to ri i pe ada ko ran mi lo gba igo oti kan to ba mi mu bo lati ile oti lowo mi, o fo o, o si bere si i gun mi nigo. Gbogbo igbaaya mi lo fi igo gun to si n seje pelu apa mi.” Balogun Aba-Oje, Ajagun-feyinti Sabitu Olabowale Busari, eni to tun je egbon fun Baba Amidu ati Simiyu so pe eru ba oun nigba toun ri Simiyu laaaro ojo keji pelu bi eje se bo o latoke dele fun ogbe ti aburo e fi akufo igo da si i lara.


Okunrin ajagun-feyinti ohun waa ro awon agbofinro lati sise won bii ise lori isele naa nitori oun ki i lowo sohunkohun to le da omi alaafia ilu ru, paapaa nigba to se pe Amidu ti fee ya omo tapa enikeni ko ka mo ni gbogbo abule naa.


“Mo n fi asiko yii gba awon odo ilu yii nimoran pe ki kaluku tepa mose to ba mo pe oun fee se. Eyi to ba mo pe igboro loun ti fee maa sise, ko maa loo se e, dipo ki won ya alainise lowo, ki won si tibe maa huwa odaran ti yoo di pe ijoba yoo maa wa won kiri. Bi enikan ba so pe oun yoo maa yo awon ara aba lenu, towo ijoba ba te e, yoo kika abamo bonu.” Nigba to n fidi isele yii mule, agbenuso ileese olopaa ipinle Oyo, DSP Adekunle Ajisebutu, so pe igbese si n lo lowo lati ri Amidu ati Owolabi mu. O waa gba awon ara ipinle Oyo nimoran lati maa mojuto omo won ki won ma baa di eni ti yoo maa da omi alaafia ilu ru nigbeyin.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:34:25 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Amidu sa egbon e ladaa, o tun fee yinbon pa awon ara abule won" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: