Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Awon olopaa n wa Bidemi to dana sun Emmanuel nitori egberun kan naira n'Iba
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Akoroyin Olootu


Awon olopaa n wa Bidemi to dana sun Emmanuel nitori egberun kan naira n'Ibafo


Titi di akoko ti a n ko iroyin yii lowo lawon olopaa si n wa okunrin kan ti won n pe ni Lanre Shitu Bidemi Ibrahim lori esun pe o dana sun Emmanuel nitori egberun kan aabo naira.


Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, lojo kerindinlogun, osu to koja nisele naa waye ni oteeli ti won n pe ni Molayo, to wa niluu Ibafo, nipinle Ogun.


Bidemi ni won pe ni manija oteeli ohun, koda won ni baba e lo ni in, sugbon lojo tisele naa waye, ariyanjiyan waye lori owo ti Bidemi fun Emmanuel ti won so pe o maa n tun jenereto se.Iwadii fi ye wa pe ko too di ojo naa ni Bidemi, gege bii manija ti pe omo Ibo yii pe ko waa ba won tun jenereto to baje se. Iyen ye e wo, o si ni nnkan ti won yoo ra ko too di pe o sise je egberun kan aabo naira.


Loju-ese ni Bidemi ti fun un lowo naa to si fi kinni ohun si jenereto, bee niyen bere si i sise pada, sugbon nigba ti yoo fi di ojo keta ni won so pe jenereto naa ko tun sise mo.


Idi niyi ti won fi ni Bidemi yari pe oun gbodo gba owo naa pada nitori nnkan to ra ki i se tuntun. Oro yii ni won so pe won n fa lowo ti emi esu fi gbe manija wo, o ni oun yoo da bentiroolu si Emmanuel lara. Ere ni won pe oro naa, afi bo se so o di ooto to da bentiroolu somo naa lara to tun sana si i.


Gbogbo erongba awon ara agbegbe naa lati gba emi omo naa la lo ja si pabo nitori pe ki won too gbe e de osibitu lo ti je Olorun nipe. Sugbon iyalenu lo je pe se ni Bidemi sa lo ti won ko si ri i titi di akoko yii.


Iwadii ti oniroyin wa se laduugbo naa fi ye wa pe okunrin tawon olopaa n wa naa ko loruko gidi lagbegbe ohun. Orisiirisii iwa ni won so pe o kun owo e to si je pe ti won ba ti mu un de tesan awon olopaa to wa ni Ibafo, se ni won maa n fi i sile.


Lara awon iwa ti won lo maa n hu ni lati fi tipa ba obinrin sun. A tie gbo pe opo ninu awon to n sise loteeli yii lo ti hu iru iwa bee si to si je pe leyin naa ni yoo tun le won danu.


Iwadii kan ti a ko fese e mule daadaa fi ye wa pe laipe yii ni Bidemi fi tipa ba omo odun mewaa kan lo po, sugbon ti won fi se oku oru. Won ni afaimo ko ma je pe awon to ti se iru eleyii si lo ran asasi ati eedi si i.


Gbogbo akitiyan oniroyin wa lati ba agbenuso awon olopaa nipinle Ogun, Omooba Muyiwa Adejobi, soro lo koko ja si pabo. Ko gbe foonu re, sugbon nigba ta a te atejise si i lo fun wa lesi lojo Abameta, Satide, ijerin pe, “Loooto la n wa Bidemi ti a ko ti i ri i, sugbon igbese ta a fee gbe bayii ni lati kede e ninu awon iwe iroyin pe a n wa a, iyen leyin ta a ba ti gbase nile-ejo.” Bee lo ni awon ti da baba e duro ninu egbe PCRC, iyen egbe ibasepo laarin araalu atawon olopaa fodidi osu mefa fun iwa buruku ti omo e hu yii. O ni o da oun loju pe ko sibi to le sa si towo awon ko ni i te e.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:42:00 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Awon olopaa n wa Bidemi to dana sun Emmanuel nitori egberun kan naira n'Iba" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: