Gbagede Yoruba
 



N'Ilu Itori, Christianah fee pa omo iyaale e, nise lo fi nnkan di i lenu
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Akoroyin Olootu


N'Ilu Itori, Christianah fee pa omo iyaale e, nise lo fi nnkan di i lenu


Bi ki i baa se pe Olorun ti ni akoko iku omo odun meji kan ko ti i pe ni Itori, Ewekoro, nipinle Ogun, iyawo baba re, Christianah Faturoti ko ba ti ran an sorun airotele, sugbon Olorun ko o yo.


Eni odun mejidinlogbon ni Christianah, sadeede ni won lo mu omo iyaale e to je omo odun meji to si fi seloteepu le enu e po, o de owo e mejeeji lokun, o si tilekun mo on sinu yara.


Lojo ketadinlogun, osu keji, to koja yii nisele naa waye lojule kerinlelogoji, Agboole Ago Owu, Itori, nijoba ibile Ewekoro, nipinle Ogun.


Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba, a gbo pe Christianah toun naa n to omo odun kan lowo yii mo- on-mo le enu omo kekere ohun pa ko ma baa pariwo, leyin to si sise ibi naa tan lo gba ileepo to ti n sise lo.



Opelope awon araadugbo ti won n koja ni won sakiyesi pe omo kan wa ninu ile nibi to ti n ja pitipiti, loju-ese ni won si sare loo pe awon olopaa.


Agbo pe o gba won lopo iseju ki won too ri ilekun naa ja, ti won si ba omo naa nibi to ti n mi diedie ti ko lagbara mo. Awon olopaa lo sare gbe e lo sileewosan. Awon dokita tie so pe Olorun lo ni ki won tete gbe e wa nitori ka ni o lo wakati meji mi-in nibi to wa ni, ko ba ku fin-in-fin-in ni.


Bi awon olopaa se mu obinrin onise-ibi ohun ni won ti fi i ranse si olu-ileese won, nibi ti won ti n sewadii lori idi to fi fee gbemi omo oko e. Nigba to n jewo fawon oniroyin lose to koja, Christianah ni loooto loun huwa ohun. O ni idi toun fi se bee ni pe oko oun n toju omo naa ju oun atomo oun lo, gbogbo igba loun si maa n soro, sugbon ko satunse.


Iwadii fi ye wa pe arun opolo lo n da iya omo ti Christanah fee pa naa laamu to si wa nibi ti won ti n toju e, idi niyi ti oko e fi ni ki iyawo yii maa toju e.


Nigba to n soro lati fidi isele naa mule, Ogbeni Muyiwa Adejobi to je agbenuso olopaa nipinle Ogun so pe isele naa ya ni lenu, ati pe ki i se nnkan tawon le bo mole rara. O ni laipe ni obinrin naa yoo foju bale-ejo lori esun ohun.


O waa gba awon obi nimoran lati mo eni ti won yoo maa fomo si lodo nitori iwa eranko lo wa lara awon eeyan mi-in.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:56:16 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu



"N'Ilu Itori, Christianah fee pa omo iyaale e, nise lo fi nnkan di i lenu" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com