Gbagede Yoruba
 



Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
Lati Owo Akoroyin Olootu


Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo


Kayeefi ni iku to pa pasito kan toruko re n je Bright Daniel to je alakooso ijo isembaye kan niluu Okeigbo, nipinle Ondo, si n je fawon eeyan latari bi agbonrin abami kan se deede ran an lo sorun ojiji l'Ojobo, Tosde, ose to koja yii.


Gege bawon ti iroyin buruku naa soju won se so, okan lara awon omo ijo pasito yii lo waa fi alupupu okada gbe e nirole ojo yii lati loo sise itusile lori oke kan ti won n pe ni Pele, nipinle Ondo, iyen ni won se kuro ni soosi won to wa laduugbo Oke-Jege nibe, ti won si kori sori oke ohun.



Omo ijo yii ni won lo n wa okada nigba ti pasito jokoo seyin. Bi won se de iyana kan ti won n pe ni E¯pe¯ niluu naa ni agbonrin kan sare jade latinu igbo pelu igbe nla lenu re. Bo ti n kigbe ni won lo kawo re mejeeji soke to ko o lori okada ti pasito jokoo seyin re, bee ni eranko naa n ba omo ijo to n wa okada naa woya ija pelu bo se n lo okada mo on lowo, bo se di pe okada takiti niyen, ti pasito si rebo, to fori gbale loju titi nibe.


Obinrin to salaye oro yii fun wa to ni ka foruko boun lasiiri tesiwaju pe bi Pasito Bright se fori gbale yii lo bere si i kigbe oruko Jesu, bee lo n japoro nile, lesekese naa ni agbonrin paapaa subu lule, to si ku lai je pe enikan fowo kan an tabi ba a ja. Eni to wa okada naa wa legbee kan nibe ni tie to n je irora ara to fi pa, ogangan isele naa lawon meteeta si wa tawon olopaa fi de ti won gbe oku agbonrin, pasito atomo ijo e naa lo sileewosan ijoba kan to wa l'Ondo.


Leyin iseju die ti won de ileewosan naa ni pasito je Olorun nipe, won si gbe oku agbonrin naa segbee kan nileewosan ohun, sugbon omo ijo to wa okada naa ko ku ni tie. Loju-ese ti okiki isele yii kan kaakiri ilu naa lawon ero ti bere si i ro girigiri lo sosibitu naa lati foju ri oku abami agbonrin to seku pa Pasito Bright Daniel yii.


Okan lara awon omo ijo pasito naa sapejuwe oloogbe yii bii oluso-aguntan to wulo pupo, ti iwa re si ba tawon omo ijo mu, opo eeyan to wa nibe lo si n so pe iku to pa pasito yii ya ni lenu pupo.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 07:09:38 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo:
Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo



"Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com