Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Owo te Stella atawon egbe e pelu ohun ija oloro ni Kwara
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu Lati Owo Akoroyin Olootu

Owo te Stella atawon egbe e pelu ohun ija oloro ni Kwara

Obinrin afurasi eni odun metalelogoji kan, Stella Momoh, to n gbe lagbegbe ileewe awon olopaa to wa ni Kulende, pelu emewa re kan, David Ogirima Momoh, toun je eni odun mejidinlogbon to fi ojule kokanlelogoji, laduugbo Bolorunduro, lagbegbe Sango, niluu Ilorin, sebugbe lowo ileese olopaa ipinle Kwara te laipe yii pelu ohun ija oloro, won si ti foju bale-ejo.

Awon afurasi ohun ni won fesun meta otooto kan, iyen igbimo-po lati sise ibi, idunkooko mo ni ati gbigbe ohun ija oloro lona to lodi sofin.

Lara awon ohun ija oloro tileese olopaa ka mo won lowo ni ibon ilewo meji ti nomba okookan je AO70782 ati RUHMRG799ABL, ibon agbelero kan, opolopo ota ibon lorisiirisii, ewu akota-min meta, awon ohun idaabobo atawon nnkan mi-in.

Owo palaba awon afurasi ohun segi lojo kefa, osu keji, odun yii, nigba tawon olopaa 'E Division' to wa lagbegbe Kulende, n'Ilorin, nawo gan won lasiko ti won lo si soobu kan lagbegbe Sango lati loo hale mo eni to ni soobu ohun.

Gege bi eni to ni soobu, ArabinrinAl-Amin Lukman, to n gbe lagbegbe Tanke, niluu Ilorin, se salaye fawon olopaa, o ni kete tawon afurasi ohun de soobu oun ni won pase fun gbogbo awon to wa nibe lati jade ni kia, ti won si bere si i fin tajutaju si gbogbo awon to wa nibe, eyi to mu kawon onibaara oun kan farapa lasiko ti won n gbiyanju lati sa jade.

Iwadii eka ileese olopaa to n gbogun ti iwa odaran fi han pe awon ohun ija oloro ti won ri gba lowo awon afurasi yii je ti igbakeji oga olopaa kan, ACP Momoh, eni to padanu emi re lasiko to n sise nipinle Nasarawa.

Bakan naa niwadii tun fi han pe David Momoh to je afurasi keji yii gan-an lo gbe ewu akota-min wo, to si mu ibon ilewo lowo lati loo dunkooko mo awon onibaara olupejo.

Agbejoro fun awon olujejo naa, Ogbeni Abdulsamad Lawal, ro ile-ejo lati gba oniduuro awon onibaara re titi tiwadii yoo fi pari lori esun ti won fi kan won.

Sugbon Insipekito James Odaudu to je agbefoba nile-ejo tako ebe agbejoro ohun. O ni iwadii si n lo lowo lori esun ti won fi kan awon afurasi yii, nitori naa, ki adajo fi won pamo sahaamo ogba ewon titi tiwadii yoo fi pari.

Ninu idajo tire, Arabinrin I.J Bamigboye tako ohun ti olopaa to soju ijoba so, o gba beeli awon afurasi ohun pelu egberun lona ogorun-un kan naira pelu oniduuro meji niye kan naa.

O sun ejo ohun siwaju.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 18 @ 06:32:18 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Owo te Stella atawon egbe e pelu ohun ija oloro ni Kwara" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: