Gbagede Yoruba
 



Eyi Ni Bi Imaamu Ile Ibadan Se Ku Gan-an: Ki Olohun Gba A Si Ogba Idera Alujana
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Eyi Ni Bi Imaamu Ile Ibadan Se Ku Gan-an: Ki Olohun Gba A Si Ogba Idera Alujana

Titi dasiko yii ni gbogbo musulumi ile Yoruba atawon musulumi Yoruba kaakiri orile- ede yii si n sedaro imaamu agba ile Ibadan, Sheik Suara Haruna, eni to je Oloun nipe leni odun metalelaadorun-un.

Laaaro kutu ojo Ojobo, (Tosde), to koja ni Sheik Suara, to tun je aare igbimo awon aafaa ati lemoomu ile Yoruba titi de ipinle Edo ati Delta, dagbere faye leyin aisan ti awon eeyan gba pe o ni i se pelu ogbo;.

Igbakeji aare igbimo awon lemoomu ati aafaa jakejado ile Yoruba, Sheik Bello Kewulere to tun je imaamu agba Ado-Ekiti lo saaju oke aimoye awon musulumi to kirun si oku baba naa lara ni deede aago marun-un ku iseju meeedogbon, nirole ojo Eti, (Fraide), to koja.

Ise nla lawon aafaa to gbe oku Sheik Haruna jade kuro ninu mosalasi nla ti won ti kirun si i lara se ki won too ribi gbe e sinu moto nita, idi ni pe opo eeyan lo n fee fi owo kan oku lemoomu naa, eyi si mu ki gbogbo aaye naa ha gadigadi ti awon eeyan naa si n ti ara won lati le fi agbara kaka sunmo oku naa ki won si gbe e jade.

Ni kete ti won kirun si i lara tan ninu mosalasi nla Oja'ba, n'Ibadan, ni won gbe e lo sile e to wa laduugbo Agbeni, ti won si sin in ni nnkan bii aago mefa irole ojo naa.

Gomina ipinle Oyo, Seneto Isiaq Abiola Ajimobi, sapejuwe Sheik Haruna gege bii eni Olorun, eyi to mu ki opo eeyan feran re, to si mu iku e ka eni gbogbo lara.

Bakan naa ni oludari agba ile-eko Marikaasi, Agege, niluu Eko, Sheik Habeebulahi AdamEl-Ilory, sapejuwe baba naa gege bii asoju rere fun esin Islam, o si ro awon musulumi lati fi igbesi aye re se awokose.

Lara awon to fi edun okan won han lori iku Immam yii ni Ogbeni Abdulrahman Balogun ti i se alaga MMPN, iyen egbe awon osise oniroyin lorile-ede yii; Alhaji Ishaq Sanni ti i se alaga igbimo awon musulumi nipinle Oyo, Alhaja Sururah Oyero ti i se alukoro egbe awon obinrin musulumi orile-ede yii ti won n pe ni FOMWAN.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe nnkan bii odun mokanlelogbon ni Sheik Suara Haruna fi wa imo lodo awon aafaa, to si n sa kubekube tele won kiri ko too di pe oun naa di aafaa nla ti won si fi i je olori awon lemoomu jakejado ile Ibadan lodun 1995. Oun ni eni keta ti yoo di ipo ohun mu leyin ifigagbaga pelu awon aafaa nla nla.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 18 @ 06:57:36 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin



"Eyi Ni Bi Imaamu Ile Ibadan Se Ku Gan-an: Ki Olohun Gba A Si Ogba Idera Alujana" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com