Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin
[ Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin ]

·E Gba Mi Lowo Iyawo Mi o, O Fee So Mi Di Dindinrin Rafiu
·Nibo Ni Isokan Yoruba Yoo Ti Wa?
·TITUBA KURO NIBI ESE (AT-TAWBAH MIN AL-MA'ASIY)
·Kike Alkur'an Ati Awon Eko Re: Alaye Ola (Esan) kike AlKur'an Alaponle
·Kamalat, Omo Odun Mefa To Laisan Okan Ma N Pariwo, O Ni Kawon Omo Naijiria Ran
·IGBEYAWO NINU ISLAM: Itumo Igbeyawo; Kinni Erogba Igbeyawo Ninu Islam?
·Awon ipile meta Esin Islam ati awon Eri won Lati owo Shaikh Muhammad Ibn sulaima
·AKASO ODODO (Al- WASEELAH) - Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi -- Atunyewo
·Alaye lori Aayah (23) ninu Suuratu Furkooni

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Nile Yoruba, ko gbodo sogun, ko gbodo sija o
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Lati Owo Akoroyin Olootu

Nile Yoruba, ko gbodo sogun, ko gbodo sija o

Olorun Oba mo bo se maa n se oro awa omo Naijiria, nitori e lo se je ni gbogbo ibi ti a ba wa, afi ka ki ara wa ku oriire pelu ibo ta a di koja yii. Awon ara Amerika kan ni won ti koko so o ni odun mewaa seyin, won ni bo ba di odun yii geere ni Naijiria yoo pin si wewe, ti a oo fo si opolopo ona, ti a ko si ni i je orile-ede kan mo. Nigba ti ibo yii si ku bii ojo die, opolopo awon ariran bere si i so orisiirisii, won ni eje yoo san ni Naijiria, awon mi-in si so pe oku repete la oo maa ri kaakiri. Sugbon boya aawe ati adura to po ni, ibo ti wa, o ti lo, ko si ti i si wahala kan to ju emi enikeni lo. Iyen lo se je pe oro ti n oo so lose yii, ebe ni yoo po fun gbogbo omo Yoruba pe nibi ti oro ibo ti waa de yii o, ko gbodo si ogun, ko gbodo si ija, iwonba ni ki ote si mo laarin ara wa. Gege bi mo ti se maa n so o, oro oselu ko ri bi opo eeyan ti n mu un, bi a ba si ti mu kinni ohun le koko ju, igbeyin re ki i dara fun enikeni.

Ni gbogbo igba ni mo maa n so o fun wa, pe oro oselu ko ri bi awa mekunnu se maa n se e, ohun ti a si se maa n pa ara wa lara niyi. Ipalara to ba ba wa, awa la maa n wa a. Ko dara ki a maa ro pe egbe oselu kan naa ni gbogbo wa yoo se, iyen ni pe bi a ba fee se PDP, ki gbogbo wa se e, bi a ba si fee se APC, ki gbogbo wa rori sibe leekan. Iyen ko ni i see se laelae, koda ko je inu ile kan naa, tabi ninu iya kan naa ni gbogbo wa ti jade. A ko le sun ka kori si ibi kan naa, ironu wa ko si ni i sokan lae. Bi eeyan naa ba si wo ibo to lo yii, ati bi awon eeyan ti di i to, e oo ri ohun ti mo n so. E wo Ekiti, awon omo PDP ti won dibo nibe ju awon omo APC lo. E wo Ondo, e wo iye awon omo PDP ti won dibo nibe, e wo Osun naa, ki e si wo Oyo ati Eko gan-an alara. Awon ogunlogo eeyan ti won dibo fun PDP yii, won ki i se iran mi-in, Yoruba naa ni won, o kan je pe egbe to wu won ni won se yii ni.

Lodo temi, bi awon kan ti dibo fun APC lawon kan dibo fun PDP, awon mi-in dibo fun SDP, koda, a reni to dibo fun egbe KOWA ninu wa, o sa taku, o ni obinrin loun yoo dibo fun ni toun. Eko kan naa ni gbogbo alaye yii n ko wa, iyen ni pe a ko le se egbe oselu kan laye, a ko ni i si ninu ijo kan naa, nitori ohun ti a fe lokan ara wa yato sira won. Awon oloselu ni won maa n gbe oro gbona, awon ni won maa n so oro lati de wa si ara wa, bi e ba farabale gbo ohun ti awon alukoro fun egbe oselu mejeeji to loruko ju lasiko yii, PDP ati APC n so si ara won, ti won si n so fawon araalu, bi eniyen ba feti si tiwon, to si fee fi tiwon huwa, oku yoo ti maa sun lo ni iru asiko yii, nitori gbogbo oro ti won n so lati ojo yii wa, oro ija, oro ibinu, oro ka rira wa lokeere ka fere le yobon sira wa ni won n so.

Eeyan to ba waa gbon ko ni i je ki awon oloselu da oun riboribo bee, nitori bi idi ba baje, tonidii ni yoo da, eni ti won ba ba nnkan re je, ko seni ti yoo ba a tun un se, eni ti won ba si pa nitori oro oselu bayii, won yoo so pe o ku fun ilu ni, bee awon ti won n se oselu yii ganan lo ye ki won ku fun ilu, awon ati awon omo won, tabi awon araale won, sugbon o ko ni i ri won nitosi, eeyan ko le fa ijangbon ko de odo won, won o le yinbon ko wo ile won, geeti odo won ko see fo, bee ni awon eso ko si ni i je ki e lalaa de ibi ti won wa rara. Awon mekunnu ni yoo yobon, awon ni won yoo yo ada, awon ni won yoo dojuko ara won, ti won yoo si pa ara won daadaa. Okunrin ti won ba pa yoo fi iyawo ati awon omo sile, ko si ni i ri eni ba a toju won leyin to ba ti lo tan, gbogbo ohun to ba fi sile yoo si baje pata ni.

Bee awon oloselu yii yoo pada lo si odo ara won o, won yoo seto bi won yoo se pade ara won, ti won yoo yanju oro to ba wa laarin ara won. Bi a ko ba gbagbe oro, ti a ba ranti awon ibo ti a ti di koja ati orisiirisii ijoba ti a ti ni, oro ti mo n so yii yoo ye wa. Pelu gbogbo wahala ati idaamu ti Egbon Obasanjo fi oju Atiku ri, eeyan waa le so pe Atiku yoo tun pada de odo ebora eeyan yii ndan@ Bi eeyan ba si n kawe itan, to ba ranti ohun ti Bola ni Eko ati Egbon yii naa fi oju ara won ri, ati awon oro randu-randu, oro kobakungbe pelu itan buruku ti won pa fun Egbon, ti omode AC yoo maa bu u, ti agba won yoo maa bu u pelu iwe iroyin won ati telifisan ati redio, ti won si se e titi ti gbogbo awon eeyan fi koriira re bii igbe, se eeyan kan le so pe Bola yoo lo sile OBJ, won yoo waa jo maa jokoo soro kan. Iru oro wo ni won fee so!

E wo ija to sele l'Osun laarin odun 2007 si odun 2009 laarin Rauf ati Lagun, nitori ibo ta ni gomina ta ni ki i se gomina, e wo iye awon eeyan to ku nitori awon mejeeji, e wo bi awon eeyan se yinbon para won nitori pe won ni awon fe ko je Rauf ni yoo sa se gomina, ti awon mi-in si taku pe afi ki Lagun maa ba ise re lo. Won ti so elomiiran di alaaabo ara ti ko le dide naro mo, ti ko si le fi owo re se ise aje kan, bee ni ko seni to ya si i mo, won ti ba ise aje elomiiran je debii pe ko le ko owo gidi kan jo, atije atimu si ti di oran fun un, bee ni won ja ija naa ti aimoye emi si ba a lo. Sugbon loni-in yii, olowo otun Rauf ni Lagun, okan ninu awon ti yoo si fi oro ara re lo ko too gbe igbese l'Osun ni. Awon eeyan to ti waa ku nko, awon eeyan ti nnkan won ti baje yii nko, awon eeyan ti won wa laye bii alaisi yii nko, nibe laye tiwon pari si.

Eni ba ranti ogun awon Ekiti nitori Segun (Oni) ati Kayode (Fayemi), to ranti bi oku ti n sun ati bi ibon ti maa n ro kaakiri Ekiti, ko le gba laye yii pe awon mejeeji yoo tun sore ara won. Bi n ba ranti ojo ti awon iya oniyaa, awon obinrin olobinrin, ti awon Kayode ko won jade lodun naa lohun-un, ti won n rinhooho, ti won ni awon n sepe fun Segun, ti won ni o gbajoba lowo omo awon, bii eni pe Segun ki i se Ekiti, nise ni mo maa n miri fun oro oselu wa nile Yoruba ati bi a se maa n se e, nitori a ko ni eko oselu to, eyi a si maa ko idaamu ati ofo ba opolopo wa. Awon obinrin naa jade ninu oorun lojo naa, bo tile je pe iyawo Kayode ati awon omo tiwon ko si nihooho, ko si omo tie laarin titi ko ni won ko je ki baba tabi oko oun wole ni. Loniin yii nko, Oga ni Segun je fun Kayode ninu egbe won, oun si leni akoko ninu APC nile Yoruba labe ofin egbe, nitori igbakeji alaga ni.

E wo eni to si wa nibi ipade lose to koja to n pe awon kan ni omo ale, oro naa bo si apo ibinu fun mi lojo naa, nitori mo mo pe oro ti ko dara ni. E wo iye awon eeyan to dibo fun PDP nile Yoruba, o wa daa ki omo Yoruba kan pe iru awon eeyan to po to bee lomo ale ni. Se e ri ohun to sele yii, o dara pupo fun eto demokiresi ti a n se, o dara ki araalu mo agbara won, ati bi won se le lo iru agbara bee, bi eleyii ba n sele, awon olori wa, atawon ti won n sejoba yoo le mo pawon araalu n wo awon, won si ni agbara lowo, won si le fi ibo le won, ijoba to ba te won lorun ni won yoo si fi ibo won gbe wole, ti ibo naa ko ba si te won lorun mo leyin odun merin, won yoo tun fi ibo won gbe e jade.

Nidii eyi, bi ibo ti a di lo yii ba waa bo si ibinu enikeni, ki won ma ja o, ki won ma si binu, ki won ma ba nnkan ara won je nibikibi.

Bi eni to wole ko ba te wa lorun, e ma je ki oloselu kan so pe ka da ilu ru tabi ba nnkan je tabi paayan, e so fun iru eni bee ko ni suuru, odun merin ko jinna ju, a oo tun fi ibo wa yo iru eni bee. Bi won ti se n se niluu awon olaju ree, bi awa naa si ti se gbodo maa se lodo tiwa niyen.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 18 @ 07:07:25 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Nile Yoruba, ko gbodo sogun, ko gbodo sija o" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: