Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Obafemi Gun Ore Re Pa Ni Yaba, Owo Lo Dija Sile
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Oluseye Iyiade

Obafemi Gun Ore Re Pa Ni Yaba, Owo Lo Dija Sile

Olayinka Adedayo

Awon agba lo maa n so pe owo lo n boju ore je, bee ni owo a tun maa da aarin omo iya
meji ru. Oro yii lo se mo okunrin kan to n se buredi ta, Obafemi Yunus, eni odun
merinlelogoji to n gbe lojule kokanlelogun, laduugbo Church, lagbegbe Makoko, ni Yaba,
lara lori esun pe o gun ore re, Peters Ajayi, eni odun mejidinlogoji nigo lori pa.

Okunrin naa ni adajo ile-ejo Majisireeti kan to wa l'Ebute-Meta, niluu Eko, ti pase pe ko si
wa latimole ogba ewon to wa ni Ikoyi fun iwa ti ko ba ofin mu to hu naa.Gege bi Iwe Irohin Yoruba se gbo, aago mokanla aabo ale ojo kejidinlogun, osu karun-un, odun
yii, nisele naa waye ni ikorita Makoko, niluu Eko, iyen nigba ti ede-aiyede waye laarin awon
ore mejeeji yii nitori owo. Ibi ti won ti n woya ija la gbo pe Obafemi ti ki igo mole, ko si ro
o leemeji to fi figo ohun gun ore re lori pelu obe idana.

Kia lawon eeyan sare gbe Peters lo sileewosan lati doola emi re, sugbon o se ni laaanu pe
okunrin naa pada jepe orun leyin akitiyan awon eeyan wonyi.

Kete ti eyi si ti sele lawon olopaa ti gba olujejo naa mu, leyin iwadii won ni won taari re lo
sile-ejo lati loo so tenu e nibe.

Nigba ti agbenuso ijoba, Sajenti Daniel Ighodalo, n ka esun ipaniyan ti won fi kan afurasi
odaran naa si i leti lo ni iwa to hu naa lodi sofin iwa odaran tipinle Eko ti won gbe kale
lodun 2011, eyi to si tun pe fun ijiya nla.

O so siwaju pe oun ti fi eda iwe esun naa sowo si eka to n ri soro idajo nipinle Eko fun
imoran to peye.

Nigba to n gbe idajo re kale, Adajo-agba A.O. Ajibade gba oro ti agbenuso ijoba naa so
wole, bee lo pase pe ki won loo fi afurasi ohun pamo satimole ogba ewon to wa ni Ikoyi titi
ti won yoo fi gbo imoran latodo oludari to n ri soro igbejo nipinle Eko.O waa sun igbejo miin
si ojo kokandinlogun, osu kewaa, odun yii.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 14:40:24 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Obafemi Gun Ore Re Pa Ni Yaba, Owo Lo Dija Sile" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: