Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
[ Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu ]

·Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O
·Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe
·Bi Iro Ba Lo Logun Odun...
·Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi
·Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia
·Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa
·E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?
·E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare
·Bee Ni Buhari Ko Wi Nnkan Kan

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Lojo Ti Won Sinku Kunle Adepeju, Omo Yunifasiti Ti Won Yinbon Pa N'Ibadan,
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Lojo Ti Won Sinku Kunle Adepeju, Omo Yunifasiti Ti Won Yinbon Pa N'Ibadan, Awon Olopaa Tilekun Mori, Won Ko Le Jade

Loooto, ijoba Yakubu Gowon lawon omo Yunifasiti gbogbo n fee ba fa wahala, sugbon
Adeyinka Adebayo ti i se gomina ni Western State' ni wahala naa wo lorun julo, nitori ni
Yunifasiti Ibadan, ni olu ilu ijoba re gan-an ni daru-dapo naa ti koko seyo. Nitori bee, oun
naa lo kede, to si so fun gbogbo eeyan pe iwadii ti ijoba apapo fee se yii, iyen lori ohun to fa
a tawon olopaa fi yinbon pa akekoo yunifasiti ninu ogba won, gbangba lawon yoo ti se e,
awon ko si ni i fi igba kan bo okan ninu, gbogbo eni ti oro ba soju re, tabi ti inu ba n bi nitori
idi kan tabi omiiran, gbogbo won ni yoo letoo lati wa si gbangba lati waa so tenu won. Se ki
i se Adebayo nikan lo n soro naa, ijoba apapo labe Gowon ti so pe ko si ohun ti awon fee
gbo ju ohun to fa idi oro naa ati bi oro naa kuku se le to bee, ki awon le mo awon to wa nidii
e gan-an.Ki i se ki won wadii re gan-an nikan ko o, ki won le mo ohun ti won yoo se ti iru re ko fi ni
i waye mo ni. Nitori titi di ojo kerin, si ojo karun-un, si ojo kefa, osu keji, odun 1971,
wahala naa ko sinmi, ariwo lotun-un, ariwo losi ni. Awon omo yunifasiti gbogbo ko yee
mura ija, aya awon olopaa funra won si n ja lati maa rin kaakiri, nitori won ri i pe awon omo
naa ko gboju boro, ko si ohun ti won ko le se fun eni ti won ba ri aso olopaa lorun re, bee ni
awon olopaa si ti mo pe awon ko le se kinni kan fun won mo bayii, nitori eyi ti won se naa
lo di wahala repete yii, eni ba si tun daran mi-in ninu won, o ti han pe ori ara re ni yoo fi fa
a. Nitori eyi ni kaluku se n gbe ori ara re sa, nitori bi koko ba n fe ni lefee, eeyan ki i jori
imado, bee ni bi won ba n so pe won yoo sun enikan je gbeyin ni, oluware ko gbodo maa ba
won sere a n duro segbee ina.

Sugbon ki iwadii naa too bere, ohun ti awon ijoba gbogbo tile n mura lati se ni ki won sin
oku omokunrin ti won yinbon pa ni Yunifasiti Ibadan lojo Aje, Monde, ojo kin-in-ni, osu
keji, yii, iyen Kunle Adepeju. Ijoba mo pe ti won ba ti sin in loro naa yoo tile role die, nitori
nigba ti oku ba ti le wole, iba ni awon alagbaja ati abanikedun yoo se wahala mo. Nigba ti
ijoba si ti nawo siwaju fawon omoleewe lati so pe awon yoo da si oro naa ti won ti ko agidi
bale, ijoba ko gba odo won mo, odo awon ebi oku ni won gba, won si ni ki won sin omo
won ki won ma je ki awon akekoo maa fi oro omo naa kewo da wahala sile sigboro.Won ni
gbogbo awon naa ni iku Adepeju dun, sugbon bi won ba fi i sile ti won ko sin in, awon
omoleewe yoo si maa fa wahala kiri ilu, ibi ti awon ba si ti n se eyi, awon omoota yoo wo
aarin won lati ba nnkan je pata.

Eyi ni won se dajo ti won yoo sin oku akekoo omo yunifasiti naa, won ni ko gbodo pe nile
rara. Ni ojo kerin, osu keji yii, ni iroyin deede jade lojiji, won ko fu awon akekoo naa lara
rara, koda, won ko je ki won tete gbo, nitori ijoba ti fogbon si i, won si ti ni ki awon obi
awon omo yii ma gbe gbogbo ara le awon akekoo yii, nitori won le ba nnkan je ju ki won
tun nnkan se lo. Eyi ni won ko se pe awon omo naa sipade kan, won kan gbo ikede lojiji pe
won yoo sin Kunle Adepeju ni ojo Abameta, Satide, ni, iyen ojo kefa to ku. Awon akekoo
yii ko gbo oro naa, o si ti ku ola, nitori nigba ti iwe iroyin gbe e pe won yoo sinku omo naa
lola ni won too mo, kinni ohun si ja lu won kii ni. Won ko saa le so pe ki olokuu ma sin oku
re, bee ni won ko gbodo se bii eni pe inu awon ko dun si i, nigba ti ki i se awon ni won
lomo, sugbon o dun won.

N lawon naa ba yaa sare mura, kia ni won ti bere eto laarin ara won, won si n sa awon
akekoo jo kaakiri, gbogbo yunifasiti si ti gbo oro naa kile too su, won si ti mo ohun ti won
yoo se. Awon egbe akekoo Yunifasiti Eko ni won koko pe ara won jo, won ni awon yoo gba
boosi meje, awon yoo tun wa awon mi-in si i, sugbon gbogbo eni to ba ni moto ni ko gbe e sona ki won si ko ero kun inu re, bee ni ki gbogbo eni to ba le wo moto tete ji laaaro ko loo wo moto, ki won si loo duro de awon ni Osibitu Adeoyo, n'Ibadan, nibi ti won yoo ti gba oku Kunle Adepeju losibitu. Se titi di igba naa, awon omo akekoo Yunifasiti Eko yii ni awon ko ni i lo si kilaasi, awon ko si fee ri oluko kan lodo awon, awon yoo maa jokoo si ileele lasan ni, awon ko ni i di enikeni lowo, sugbon ki enikan ma di awon lowo o.

Leyin ti won ti fa wahala repete lojo keji ti isele naa sele ni Ibadan, nise ni won tun gbera paa ni ojo keta, won ni awon n lo si Eko, ni baraki Dodan lohun-un, se ibe nile ijoba. Ki waa ni won n loo se nile ijoba, awon akekoo naa ni awon ko ba awon soja keekeekee loro, bee ni awon ko si ni oro pelu gomina kankan, boya gomina Eko tabi ti West, awon ko si fee ri olori soja, eni kan soso toro awon je logun ti awon fee ri ni Yakubu Gowon, olori ijoba ologun, bi ko ba si fi le yoju sawon, wahala yoo sele gidigidi ni. N ni won ba gbera, ni won ba de enu ona ogba awon soja yii, won de Dodan Barack, ko seni to da won duro loju ona, afi igba ti won wole ti won ko won sibi kan. Ki i se pe won ti won mole o, won ni ki won duro, won yoo yoju si won laipe rara. N lawon ba farabale, won n reti Gowon. Sugbon ki i se Gowon lo yoju si won, oga ologun kan ti won n pe ni E.O. Ekpo ni, Brigedia loun ninu ise ologun. Bi awon asoju awon akekoo naa ti ri i ni won binu, won ni ki i se soja kankan lawon waa ri, Gowon, olori ijoba, lawon waa ba soro, oun nikan lo le gbo ohun ti awon fee so. Ogagun Ekpo fi ogbon mu won wa sile, o ni ki won ma se bee, ki won ma si fi gbogbo oro se ibinu, Gowon wa ni ipade nla ni ko fi ni i le ri won, eto ilu naa lo si n se lowo, sugbon bi won ba so hulehule ohun ti won ba wa foun, oun atawon elegbe oun kan ti awon yoo jo gboro enu won, Gowon yoo gbo oro naa lesekese, yoo si se ohun ti won ba n fe fun won. Bayii ni awon omo naa farabale, won si gba ki awon jokoo, ki awon so ohun ti awon ba wa fun Ekpo atawon elegbe re, sugbon won fi ohu�n sile pe bi oro naa ko ba yanju, awon ko ni i sinmi ija o.

Oro naa ko yanju bee! Ko le yanju, nitori ohun tawon akekoo yii n wa, Ekpo ni apa oun ko ka a. Awon omo naa ni akoko ohun tawon fe ki ijoba Gowon se ni wara-n-sesa ni ki won yo Purofeso Adeoye Lambo ti i se olori ogba ile-eko Yunifasiti Ibadan, won ni awon ko fee ri i mo, awon ko si fe ko wa bii oga-agba yunifasiti naa. Leekeji, won ni ki Gowon le Arabinrin G. O. Apampa danu, nitori oun gan-an ni eku eda, oun ni odada to da gbogbo eleyii sile, ori re ni wahala yii si ti bere gan-an, bi ko si si tire, ko si bi olopaa yoo se wonu ogba yinbon pa Kunle Adepeju. Won ni bi won ba waa se mejeeji yii tan, ohun ti won yoo tun se fawon ni lati yi oruko ileegbe ti wahala yii ti sele kuro ni ti Azikwe, iyen ni pe ki ibe ma se je Azikiwe
Hall' mo, oruko tuntun ti won fe ki won maa pe ibe ni Kunle Adepeju Hall' latojo naa lo.

Birigedia Ekpo ni gbogbo oro ti won beere yii lo daa o, gbogbo ohun ti won fe yii naa lo le se e se, sugbon apa oun ko ka a, bee ni oun ko si ro pe apa Gowon paapaa ka a lati se bee lesekese lai je pe won se iwadii, ki won si mo ibi ti oro naa yoo fori so. Ekpo so fun awon olori egbe omo Yunifasiti Eko yii pe ko ni i daa ki ijoba kan le awon eeyan naa bee lai je pe won wadii, ki won si mo boya won jebi tabi won ko jebi. Tabi bo ba se pe awon akekoo yii funra won ni won jebi ti won si se aseju nko, se o waa tun ye ki awon tori tiwon da eni ti ko se lebi. Ooto oro bii isokuso ni i ri jare, ogbon omode ko si da bii ogbon agba, gbogbo oro ti Ekpo ologun yii so, eyin eti awon akekoo naa lo bo si. N ni won ba dide, won ni bo ba je ohun ti yoo so ree, awon ko gba ni tawon. Awon yoo pada waa ri Gowon, bi ko si ri awon, awon ko ni i lo si kilaasi kawe.

Ibi ti oro wa niyi ti won fi gbo pe won yoo sin oku Kunle Adepeju lojiji, won ko ronu re rara, won ro pe
oku naa yoo wa ni mosuari nibe ti awon yoo si fi maa ri ohun fa wahala awon lo ni. Nigba ti won si ti gbo pe won yoo sinku yii sa, ara won bale die, won si ro o ninu ara won pe ko si ohun ti awon le se ju ki awon lo si Ibadan, ki awon si se eye ikeyin fun okan ninu awon to ku soju ogun oba atawon omo yunifasiti. Bee ni won mura paapaapaa, won si sare wa awon oko ti yoo ko won. Bi won ti wa boosi meje, bee ni awon mi-in gbe moto tiwon sile loto, bee si ni awon mi-in mura pe awon yoo wo oko lo. Nigbeyin, awon akekoo ti won fee ti Eko lo si ibi isinku naa le ni eedegbeta daadaa, nitori nise ni won n pe ara won kiri, ti won si n so pe awon yoo debe dandan, nitori oku awon ni, awon lawon si gbodo sin in.

Ohun to je ki ero po lapoju lojo ti won n sin oku Kunle Adepeju ree, nitori gbogbo yunifasiti ati ileewe giga Poli, atawon ti olukoni to wa ni agbegbe Western Region', titi to fi de Kwara ati �Mid-West' lawon akekoo yii fi ro wa, oro naa to si ba awon ti won wa lona lojiji ni ko je ki awon naa le maa bo, nitori ki won too de, won yoo ti sinku tan. Sugbon eni to ba so pe owu ko to eru, iwonba ti yoo fi tanna lo mu ni, bi eeyan ba ri ero bi won se to bii maili meta lai ti i duro, oluware yoo mo pe awon omoleewe po kaakiri nigba yen.

Ki i se awon omoleewe nikan ni won wa nibe, awon obinrin oloja gbogbo, awon iyaloja ati awon egbe obinrin ti won wa nitosi, bee ni awon tisa atawon asaaju egbe awon osise, afi bii igba ti won n sin oku gomina nla kan tabi olori ijoba, gbogbo won lo wa nibe, oju won lo se.

Ni kutukutu lawon ero ti bere si i ro de osibitu Adeoyo, n'Ibadan, aago mejo ko si ti i lu ti awon mi-in fi de, paapaa awon ti won wa lati ona jinjin ti won ti fi oru woko, nigba ti yoo si fi di aago mesan-an, osibitu naa ko gbero, ero si ti to latibe fonka si gbogbo adugbo pata. Nigba ti won gba oku naa, awon ero naa ko ba ara won ja, won o si ti ara won bi won ti po to, kaka bee, won to tele moto agbokuu naa ni. Bee ni won si bere irin won lati Yemetu, won gba ona Queen Elizabeth Road, bee ni won si se fese rin de Molete, nibi ti won ti se isin ikeyin fun un. Awon onimoto gbogbo lo mo ojo naa ni ojo iyato, nitori sun-kere-fa-kere ko je ki enikeni le rin, gbogbo moto n lo bii igba ti igbin ba n rin ni, ko senikan to le kanju tabi sare. Bi ko tile si ti awon omo egbe �Scout' ti won kun oju ona fofo, oro naa iba le ju bee lo.

Ninu iwaasu tire lojo naa, Bisoobu ile Ibadan, Eni-Owo Timothy Omotayo Olufosoye, so fun gbogbo awon akekoo atawon obi Kunle Adepeju, ati awon ti won n binu pe ki won ma je ki igbonara ati ibinu dapo mo ironu won, nitori iyen le ba nnkan je ni. Olufosoye ni bi won ba ti n ronu aroju, won yoo maa beere ki lo de ti iku se pa a lona to pa a yii, won yoo si maa fi oro naa se ibinu ati igbonara, eyi yoo si da wahala mi-in sile ni. O ni ki won ri ohun to sele bii amuwa Olorun, ki kaluku si fi oro naa se ogbon ko, nitori oni nikan ko, nitori ojo mi-in fun eni gbogbo ni. Leyin to ti se iwaasu re tan ni won gbe oku omo akekoo Yunifasiti Ibadan yii, won si sin in si ite St. Annes Church', ni Molete nibe, pelu bi gbogbo awon akekoo ti n gbe ara yile, ti won si n korin ninu aso dudu ti won wo pe, "Oro nla le da, oro nla le da, eyin te e pa Kunle, te e je o dagba, oro nla le da."

Bi won ko ba fe eeyan niluu, tohun ko gbodo darin, nitori bo ba da orin naa, kaka ko ri eni ba a gbe e, orin ohun le dija repete ni. Ko si sohun to dara ju ki eniyan mo oju ko tun mo ara. Gbogbo bi awon ero naa ti n wo lo lati ibere titi de opin lati sinku akekoo yii, ati bi won ti di gaga to, ko senikan to ri olopaa eyo kan bayii nibi kan, won fara soko pata ni. Afi bii ilu ti ko si olopaa, bii ilu ti ko si agbofinro kankan ni. Ati soja, ati olopaa o, gbogbo won wa ibi kan jokoo si ni, bi olopaa si wa larin awon ero naa, won ko wo aso rara.

Asoju ijoba paapaa ko wa sibe, nitori won ro pe bi awon akekoo naa ba foju kan olopaa, tabi ti won ba ri enikan to wa lati odo ijoba, ko si iru ara ti won ko le da, ko si ohun ti won ko le se. Eyi lo mu awon olopaa naa yaa sa jinna nibi isinku ohun, ko ma je pe won yoo tun fi enikan rubo ninu won.

Lojo Satide ni won sin oku naa, leyin ti won si ti setan ti ko si wahala, ijoba kede pe awon ti yan Adajo Booyamin Kazeem lati waa se alaga igbimo ti yoo wadii ohun to sele naa, ati idi ti oro kuku fi ri bo ti ri lojo naa. Adajo naa si kede lesekese pe oun yoo bere ijokoo oun ni ojo Monde, iyen ni ojo kejo, osu keji, odun 1971, ojo kejo ti ina oro naa jo de ori koko, lojo ti won yinbon pa Kunle Adepeju gan-an. Bawo waa nijokoo igbimo naa ti se bere, awon looya wo ni won si wa nibe pelu awon elerii gbogbo? Iwe Irohin Yoruba ose to n bo niyen o.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 15:00:14 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Lojo Ti Won Sinku Kunle Adepeju, Omo Yunifasiti Ti Won Yinbon Pa N'Ibadan," | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: