Gbagede Yoruba
 



Nwon Ni Oku Orun Gba Tope Loju N'Ifaki-Ekiti, Lo Ba Bere Si i Ka Boroboro
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
Lati Owo Taofeek Surdiq

Nwon Ni Oku Orun Gba Tope Loju N'Ifaki-Ekiti, Lo Ba Bere Si i Ka Boroboro

Kayeefi loro okunrin kan, Tope Adigun Omotayo, si n je fawon to gbo nipa isele to sele
si i, nise ni won ni oku okunrin kan, Suraju Fadahunsi, gba a loju, lo ba n ka boroboro pe
oun lowo ninu iku okunrin eni odun metadinlogoji naa.

Isele ohun waye lojo Eti, Fraide, ose to lo lohun-un, nigba ti Omotayo bere si i sa kiri le
yin ti won sin Suraju tan, to si n pariwo pe oku re ko je koun sinmi, to ni gbogbo igba loun
n ri i.



Iwe Irohin Yorubagbo pe eyi lo mu kawon odo ilu so pe o se e se ki Tope lowo ninu iku Suraju,
won ni ariyanjiyan kan ti waye laarin oun ati oloogbe naa ko too ku. Ohun to je ki won
pinnu lati wo omokunrin yii lo saafin oba niyen leyin ti won lu u, ti won si tun ja a sihooho
omoluabi tan.

Gege bi akoroyin wa se gbo, lale Ojobo, Tosde, ti i se ojo keta ti won sin Suraju tan ni
Tope loun lo sibi saare re lati bu yeepe ibe, sugbon boun se bere mole lati bu u loun gbo
igbaju loju oun, toun ko si ri eni to gba oun loju.

Bo se gba igbaju yii lo sare lo sile oti kan ninu ilu naa, nibi to ti ba awon ore kan pade, to si
n so fun won pe oku Suraju ko je koun lalaafia, ki won gba oun o. Nibi to jokoo si lo tun ti n
so fawon to wa nibe pe ki won wo Suraju to jokoo ti oun. Ibe lawon eeyan ti fura pe o se e
se ko lowo ninu iku oloogbe naa.

Sugbon iku Suraju si sokunkun sawon eeyan atawon molebi re. Idi ni pe ko saisan tele,
sadeede lo bere si i so pe o n re oun latinu wa ni nnkan bii aago mesan-an aaro ojo Wesde,
nibi ti won lo ti loo ye ise kan wo lori ile kan to gba ise kongila re. Nigba to maa di nnkan
bii aago mewaa si mokanla ale ojo naa lokunrin yii dake.

Akoroyin wa foro wa iya oloogbe naa, Arabinrin Bimbo Yusuf, toun naa je oniroyin ati
olori eka iroyin nijoba ibile Gbonyin, nipinle Ekiti, lenu wo lati mo bi oro naa se sele ganan.

Ninu alaye obinrin naa lo ti ni oro kan ti waye laarin Suraju pelu Tope tele lori omobinrin kan ti won so pe Tope loun n fe lagboole awon.

Iya Suraju so pe Tope so fomo oun pe omobinrin naa loyun foun, sugbon oun ko ri i mo, o
ti gboyun naa sa lo. Sugbon iyen so pe ko sohun to kan oun ninu oro naa, o loun ko mo bi
won se pade, nitori naa, ki won loo maa yanju e larin ara won.

"Leyin ti omo mi lo siluu Ibadan, nibi to ti loo wo ise kan ni won so pe Tope bere si i yo o
lenu to n pe aago re, sugbon iyen so fun un pe ko ma pe oun mo laelae. Iyalenu lo je fun wa
nigba ta a gbo iroyin iku e. Adanu nla lo si je fun mi paapaa. Eeyan jeje ni, ki i ba eeyan fa
wahala kankan rara.'' Arabinrin Yusuf lo so bee.

Ninu oro aburo oloogbe naa, Ogbeni Aliu Fadahunsi to loun loun gba Suraju lalejo nile oun
niluu Ibadan lasiko to waa wo ise akanse kan ti won gbe fun un lojo Isegun, Tusde, ose to lo
lohun-un, o so pe, "Nigba to di ojo keji ti i se Ojoru, Wesde, to de sodo mi lo so pe oun fee
lo sibi tawon ti fee ye ise kan wo. Ibe lo ti n pe mi pe o n re oun latinu. Saaju ko too jade
laaaro ojo naa ni Tope Omotayo ti n pe foonu re, sugbon tiyen ko lati gbe e titi to fi lo sibi to
ti fee loo ye ise wo.

"Leyin iseju die ti mo pe ero ibanisoro re pada, elomi-in lo gbe e, onitohun lo so fun mi pe
ki n tete maa sare bo o, pe awon ko mo nnkan to n se egbon mi. Bi mo se sare lo sibe niyen,
taa si gbe won lo sileewosan, nibi to pada dake si.''
Iwe Irohin Yorubatun gba aafin Oba ilu Ifaki-Ekiti lo lati mo iru igbese ti aafin gbe lori isele naa.

Okan lara awon oloye ilu, Oloye Elejisu Ojo Ajimoko, salaye pe laaaro ojo Jimoh, Fraide, lawon de aafin tawon si ri awon odo yantuuru ti won ti gba gbogbo inu ogba aafin ati enuona abawole ibe kan. O ni awon gege bii oloye ni lati loo gba ona kan to wa leyin wole lojo naa ni.


"Awon odo ti kun gbogbo iwaju aafin laaaro ojo Eti, Fraide, naa, a ko tie raaye wole rara, eyinkule la gba wole. Nigba taa maa wole la ba okunrin kan tojo ori re le die ni ogbon odun ti won ti ja sihooho, ti won si n so pe awon fee pa a.

"Ko seni to mo ibi tawon ebi okunrin ohun n gbe, sugbon o jewo pe loooto loun segbe okunkun ri lasiko toun wa nileewe giga. Ohun tawon odo ilu n so ni pe omokunrin naa so pe oku ti won sin n da oun laamu.

"Sugbon nitori ati doola emi okunrin naa lowo awon odo ohun la se sare ke si ileese olopaa, taa si tun ke si ileese tilu Ido-Ekiti ati olu ileese olopaa to wa niluu Ado-Ekiti lati waa gba okunrin naa lowo awon odo yii ki won ma pa a. Nibi ti oro ohun lagbara de, komisanna olopaa nipinle Ekiti funra re lo wa sibi isele naa, ti won si gbe Tope lo.''
Akoroyin wa tun gbo pe saaju ni Tope ti gba agboole awon Suraju lo, to si n hale pe oun yoo da wahala sile ti won ko ba ba oun wa omobinrin toun n fee nibe jade.

"Ninu oro egbon baba oloogbe naa, Alaaji Salahu Fadahunsi, o so pe,� Gege bi won se so fun mi nitori pe emi o si nile lasiko tisele naa sele, won ni Tope Omotayo wa si agboole wa nibi to ti n hale pe oun yoo dana sun ile, pe omobinrin to loyun foun gbodo di awari.

"Suraju pelu Tope ki i se ore o, won kan mora lona kan tabi omiiran ni. Nigba ti won ni Tope loo ba Suraju lati foro omobinrin to so pe o loyun foun lagboole wa ni Ilado nibi lo o, iyen so pe oun ko mo nnkan kan nipa e nitori oun ko fun un niyawo. Bo se bere si i fejo Suraju sun kaakiri niyen.

"Oogun buruku po lowo omokunrin taa n so yii, o niwee oogun baba-baba re lowo to n fi hale mo awon eeyan.''
Ohun to tun waa se ni laaanu ni pe omo kan soso ti ko ti i ju omo ose merin lo ni oloogbe naa fi saye lo. Ilu Ado-Ekiti lo n gbe, sugbon ise lo loo se niluu Ibadan ti ko pada sile, to je oku re ni won gbe pada si Ifaki ti i se ilu abinibi re.

Lasiko to n fidi isele naa mule, agbenuso ileese olopaa nipinle Ekiti, Ogbeni Alberto Adeyemi, so pe loooto nisele naa sele. O ni lati ilu Ifaki ni won ti ke si ileese olopaa lati waa doola emi Tope kuro lowo awon odo to fee lu u pa, tawon ko si fakoko fale rara tawon fi lo sibe.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 15:06:38 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise



"Nwon Ni Oku Orun Gba Tope Loju N'Ifaki-Ekiti, Lo Ba Bere Si i Ka Boroboro" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com