Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
[ Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu ]

·Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O
·Bo Se Daa Niyen... Sugbon Kan Naa Lo Wa Nibe
·Bi Iro Ba Lo Logun Odun...
·Sebi Eyin Naa Gbo Ti Dino Melaye Ni Kogi
·Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia
·Awon Asofin Ni Kijoba Apapo Se Afara Elese Si Osodi-Apapa
·E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?
·E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare
·Bee Ni Buhari Ko Wi Nnkan Kan

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Olorun O, Waa Gba Awa Omo Yoruba Lowo Ogun Ainisokan
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Olorun O, Waa Gba Awa Omo Yoruba Lowo Ogun Ainisokan

Olorun o, n ko mo ibi ti oju re wa, Oba nla. Sugbon nibikibi ti oju re ba wa, mo gbadura si o ni kutukutu owuro yii, waa gba awa omo Yoruba la, waa ko wa yo lowo ota ile, waa ko wa yo lowo ota awa ara wa. Olorun, gba wa ka le ni isokan laarin ara wa, ki oro ara wa ye ara wa, ki o ma si se so wa di alatako ara wa. Ma je ka fi owo ara wa se ara wa paapaa, ma je ki oro wa ti baje koja atunse ko too ye wa. Amin.

Bi mo ti se fee soro to, n oo tun senupo die. Bi mo ti se fee binu to, n ko ni i binu bee, nitori ki n ma fun awon abuni loro so. Loooto, mo mo pe gbogbo wa ko ni i sun ka kori si ibi kan naa, bee ni ironu wa ko ni i je eyo kan gege bii iran, sugbon awon oro kan wa to ye ko maa dun wa bakan naa, awon ohun kan wa to ye ko maa ye wa bi a ba se n so o, paapaa oro to ba le ko iran Yoruba si iyonu lojo iwaju, ti yoo si maa fa wa seyin ninu ajose orile-ede wa.Awon ti won n lo wa mo ohun to n se wa, awon ota wa ti won n te Yoruba ri mo isoro wa, awon oloselu aarin wa naa si mo ona ti won fi n mu wa. Ohun kan naa ni awon meteeta ti mo daruko yii n lo, iyen naa si ni ainisokan wa. Bi iwe ti maa n po lowo mi to, ti mo ba ka eyi to je tologbon, ti mo ba ka oro agbalagba, dandan ni ki n mo, dandan si ni ko ye mi. Igba ti mo ba waa ka oro agbalagba, oro to kun fun ogbon, sugbon to ba je ibomiran ni ogbon naa gba lo, oro naa a si dun mi de gongo. Tabi nigba ti agbalagba kan kowe si mi lose to koja, to si so pe emi gangan ni mo n da wahala nile Yoruba sile lowolowo bayii, nitori ko si wahala kan lasiko yii, ko si si wahala kan fun wa lojo iwaju, sugbon iru awa ti a maa n hu oro to ti ku jade bayii la maa n fi ori eku gba teye, nibi awon iwadii, ati awon itopinpin oro ti mo maa n so. O ni oro bi won se fo Afenifere ati OPC ti mo fee so, oro lati ba nnkan je ni.

Baba naa ni bi mo ba ri oro, bi mo ba ri ohun kan, bi mo ba gbo alaye kan, ki n pe Bola si koro ni, ki n pe Bisi segbee kan, ki n salaye fun won, ki won le se ohun to ba ye, sugbon lati maa soro sita gbangba bayii n ba ile Yoruba je ni. Se e ri i, bi nnkan ba wa ti ko ba dara, ti a ko ba si fe ki oro naa baje koja ibe, loooto, ohun to ye ka se ni lati pe ara wa jo, ka ba ara wa soro, ka si fi enu oro ti sibi kan. Sugbon oro awon oloselu wa ko ri bee, ko ri bee rara. Bi won se maa n wo ara won yato si bi awon ti ko ba sunmo won ti n wo won, nitori pe opo eeyan ni ise n se, opo eeyan ni osi n ta, awon miiran si wa to je okanjuwa ati ole ni won, ohun gbogbo ni won fee ni, awon yii lawon oloselu maa n fi yi ara won ka, won yoo si maa pe won ni oruko ti ki i se tiwon, won le pe awon ni Olorun ran, won le pe anobi kan ni won, won le pe laye ati lorun, ko tun seni naa to da bii won mo.

Nidii eyi, gbogbo awon ti won ba ni oro gidi lati so, gbogbo awon ti won ba ni ohun gidi lati wi, won ko ni i ri won ba soro, bi won si ba won soro, oro ti won ba so ko ni i wo won leti.

Awon eeyan ti e si ri yii, won ki i wa si odo awa ti a dagba die ju won lo, nitori ohun ti won maa n so laarin ara won ni pe ogbon lawon fi ti wa seyin, ogbon lawon fi gbe wa subu, ti awon gba ohun to wa lowo wa kuro, bi awon ba tun n loo ba wa, awon fe ki ohun ti awon ti gba lowo wa tun pada si wa lowo ni. N ni erin se n pa mi nigba ti awon kan n da si oro ti won ko mo, ti won n so ohun ti oju won ko to, iyen nipa oro Afenifere ti mo so lose to lo.

Awon kan ni awon Afenifere wo, awon Afenifere to gbowo lowo Jonathan, awon Afenifere to so pe ki Yoruba dibo fun Jonathan, awon Afenifere to n mu Jonathan kiri. Nibi ti ogbon ori won gbe mo niyen, bee ni ogbon naa ko kun to rara.

Kinni kan ni mo fee so fun yin ti mo si fe ko wa lokan yin titi laelae, iyen naa ni pe bo ti wu ki ijoba omo Ibo tabi omo Delta buru to, bo ti wu ki ijoba omo Yoruba ma dara to, eeyan kan ko ni i fi we ti omo Fulani ni Naijiria ti a wa yii o, enikeni to ba n se bee, eni ti oro Naijiria ko ye ni. Idi ni pe gbogbo ibi ti a de lorile-ede yii loni-in, gbogbo awon ohun ti won n pe niwa ibaje loni-in nile yii, ko bere lati ibi meji, odo awon Fulani lo ti bere, lati igba ti ijoba ile yii ti wa lowo won ni nnkan ti daru wa, kinni naa ko si ni atunse nitori awon ko fe ko ni atunse. Won ko si le fe ko ni atunse, nitori nibi idarudapo ibe ni won ti n je. Ijoba Fulani ko ni i je ki eya miiran seto ikaniyan ni aseyori ni Naijiria, awon nikan ni won maa n fee se e, bi won ba si ti se e tan, won yoo ri i pe awon lawon po ju, won yoo so pe awon ju gbogbo eya to ku ni Naijiria lo, won si ti ko kinni naa sori awon eeyan wa, bi o ba salaye fun won, won yoo bu o ni.

Ni gbogbo orile-ede aye yii, Naijiria tiwa yii nikan lo je awon eeyan ti won wa ni asale, nibi ti ko si omi, to je kidaa oorun lo wa nibe, won po ju awon eeyan ti won wa nile omi, nibi ti afefe won ti dara lo. Ko tun si ibi kankan ti iru re ti n sele lagbaaye, Naijiria tiwa yii nikan ni. Iyen lo se je pe gbogbo senso ti a ba se ki i wulo, iyen lo se je pe a ko le fi gbogbo enu so pato bayii pe iye omo Naijiria niyi, iyen naa lo si se je pe ko si eto oro-aje kan, bo ti wu ko dara to ti ijoba kan yoo se ti yoo pada ja si rere, yoo ku sona gbeyin naa ni. Ibi ti iwa ibaje ti won n soro re ti bere gan-an niyen. Lojo ti won ba gba osise mewaa sibi ise ijoba Naijiria ti ki i se omo Hausa Fulani ni yoo je meje, ti awa eya to ku yoo je meta pere, lojo ti won ba gba awon eeyan mewaa si soja tabi si olopaa tabi si kositoomu ti ki i se omo Hausa Fulani ni yoo je meje, ti awa to ku, Yoruba Ibo ati Delta yoo mu meta.

Bee a ko le bo ninu iru awon nnkan wonyi, afi ti Yoruba ba wa nisokan, ti won ni awon oloselu gidi ti won le saaju ogun fun eya to ku ni Guusu Naijiria, iyen la se nilo iru awon egbe bii Afenifere, ati OPC paapaa.

Awon baba ti won n se Afenifere ti awon kan n gbe enu ni igbekugbee pe won gba owo lowo Jonathan, ki waa ni won fee fi owo Jonathan se! Asiko ti gbogbo agbara wa lowo won to ye ki won gba owo, won ko ma gba owo lowo enikeni, bee ni won ko si ni kobo lati fi gbe gbogbo awon gomina ile Yoruba wole lodun 1999, oruko rere ti won ni yii naa ni won lo, iru ohun to si ti mo won lara niyen. Awon alagbara oni to fee gba agbara kuro lowo awon baba yii ni won bere oselu owo nina, ti won n fi owo ijoba ra gbogbo eeyan ilu, owo naa ki i se owo won o, owo ijoba ni o, ti won si ko oro-ilu jo si apo ara tiwon nikan. Owo ti won ji ko lati igba naa, ti won si tun n ji ko si i lowo lowo bayii naa ni won fi doga yii o, ti won fi n pe ara won ni baba. Eni ti yoo ba fi opin si iwa ibaje, apa ibe ni yoo ti bere.

Awon ti won fo egbe Afenifere mo idi ti won se fo o leyin ti won ti lo oruko egbe naa lati gbe won wole tan, awon ti won si fo OPC mo idi ti awon se ba a je leyin ti won ti lo egbe naa lati fi daabo bo ara won ki won too maa waa ri olopaa ijoba lo bayii. N ko so pe awon eeyan yii lo ji Olu Falae gbe, n ko wi bee o. Ohun ti mo so ti ko ye awon kan ni pe bi Yoruba ba duro giri, ti Yoruba ba wa daadaa, ko si aja ti yoo wole gbe omo ekun, ko senikan ti yoo wole mu wa. Igba ti oro naa koko sele, nise lawon kan bere si i pariwo pe ki i se Fulani lo gbe Olu, won ni a kan fee fi da wahala sile ni. Afi nigba ta a ri oun funra e to ni awon Fulani lo gbe oun, won si tun leri pe bi oun ba soro sita, awon tun n pada bo waa gbe oun. Nje eyin naa ri iru arifin bee ri, iwosi nla to ba iran Yoruba niyen. Ko si sohun to fa a ju pe bi a ba ba ara wa soro, a o ki i gbo, a ko ni isokan, oselu ba wa laye je koja idaji.

Awon ki la ti se lati ba awon asaaju ode oni yii soro, awon ipade wo la ti se, awon oro wo la ti ba won so ni koro ti won ko gbo, n oo so won si gbangba lose to n bo, ki awon to ro pe mo n foro da ogun sile le mo pe ko ri bee, ki won le mo pe a ti ba awon oloselu yii soro, won ko gbo ni, ati pe ohun ti mekunnu Yoruba ba fee se funra won, ki won le mo, nitori awon gan-an ni won le gba ara won lowo ewu. Sugbon oro naa su mi, oro awa Yoruba oni su mi. Gbogbo okan ni mo si fi gbadura, ki Olorun waa gba Yoruba lowo ainisokan.

 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 16:54:40 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Olorun O, Waa Gba Awa Omo Yoruba Lowo Ogun Ainisokan" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: