Gbagede Yoruba
 



Oga Olopaa Wo Segun To Fipa Ba Alaaja Lasepo N'Ibadan Lo Si Kootu
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Oga Olopaa Wo Segun To Fipa Ba Alaaja Lasepo N'Ibadan Lo Si Kootu

Fun bo se fi tulaasi ba iya kan to n je Alaaja Serifat Isola, lasepo, to si tun ja a lole owo, ero ibanisoro atawon dukia mi-in, oga agba olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade, ti pe okunrin eni odun mejidinlogoji kan, Segun Muyiwa lejo si kootu.

Ni nnkan bii aago mejila osan Ojoru, Wesde, ojo ketalelogun, osu kesan-an, odun yii, ni Segun ka Alaaja Serifat eni ti a fi ojulowo oruko e bo lasiiri mo oju-olomo-ko-to-o laduugbo ti won n pe ni Eyin Girama, ni agbegbe Iwo Road, n'Ibadan, to si ja a lole awon dukia re, eyi ti apapo re to egberun mejidinlogorun-un naira (N98,000).



Leyin naa ni Segun wo iya yii bo sinu igbo legbee kan nibe, to si tun fipa ba a lasepo karakara ko too di pe owo olopaa te e leyin ti obinrin naa ti kegbajare isele ohun loo ba won.

Hammed Salewa, iyen olopaa to gbe Segun lo si kootu lojo Aje, Monde, ose to koja, salaye niwaju adajo pe ero ibanisoro kan ti won n pe ni Huawal meji ti owo won to egberun marundinlogota naira (N55,000) ni okunrin naa fipa gba lowo Alaaja ohun pelu foonu BlackBerry ti owo e to egberun meeedogbon naira (N25,000) titi dori awo� to fi soju, eyi ti owo e to egberun mejidinlogun naira. Apapo owo awon dukia to gba lowo obinrin naa je egberun mejidinlogorun-un naira (N98,000).

Esun keji ti won ka si afurasi odaran yii lese da lori ifipa-ba-ni-lo-po, eyi ti won so pe o lodi sofin ipinle Oyo todun 2000, eyi to so iwa odaran di eewo fawon araalu, to si la ijiya lo fenikeni to ba te ofin naa loju.

Bi won se ka awon esun ohun si Segun leti lokookan lo dahun pe oun ko jebi eyikeyii ninu won, ati pe oun ni awon awijare kan lati salaye fun ile-ejo lori awon esun ohun.

Sa, Onidaajo A.F. Richard, iyen adajo yara igbejo keji nile-ejo majisreeti Iyaganku, n'Ibadan, nibi ti igbejo naa ti waye sun igbejo ohun siwaju nigba ti kootu yoo maa teti gbo awon awijare ti okunrin afurasi odaran naa so pe oun ni lati se.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 17:08:46 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin



"Oga Olopaa Wo Segun To Fipa Ba Alaaja Lasepo N'Ibadan Lo Si Kootu" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com