Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
[ Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin ]

·Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awok
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Ikolu Awon South Africa Si Naijiria - Ekunrere
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbes
·Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
·Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
·Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
·Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
·Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun
·Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Lori Bi Aare Muhammadu Buhari Ti Yan Awon Minisita Re Tuntun, Oun Taye N Wi Ree
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Lati Owo Akoroyin Olootu

Lori Bi Aare Muhammadu Buhari Ti Yan Awon Minisita Re Tuntun, Oun Taye N Wi Ree o (Apa Kinni)

Ko seni ti aya re ko ko soke lojo Isegun, Tusde to koja lohun-un tawon asofin agba orile- ede yii foro wa awon minisita ti Aare Muhammadu Buhari fi sowo si won lenu wo. Bi ojo naa se lagbara fawon minisita yii, bee lo ri fawon omo egbe oselu won, kinni ohun ko si yo awon molebi won paapaa sile. Beeyan ba ri bi oyinbo se n bo lenu Dokita Kayode Fayemi, ti Ogbeni Babatunde Fasola naa n feebo bii opeere, ti Dokita Ngige naa duro wamuwamu niwaju awon asofin, tawon asofin naa n ju awon ibeere kabiti-kabiti sawon minisita tuntun yii, yoo mo pe ojo nla lojo naa o jare. 

Leyin opolopo ibeere ati idahun to yanranti ni olori ile igbimo asofin agba, Dokita Bukola Saraki atawon asofin yooku fowo sawon minisita tuntun ti yoo ba Buhari sise yii. Ireti awon araalu ni pe didun losan yoo so fawon omo Naijiria lasiko Buhari, ti ayipada gidi ti egbe APC so pe awon mu wa yoo si je ti gbogbo wa.

Babatunde Raji Fasola Babatunde 

Raji Fasola Ojo kejidinlogbon, osu kefa, odun 1963, ni won bi Amofin Babatunde Raji Fasola si 'Island Maternity Hospital', n'Isale-Eko. O bere ileewe alakoobere re ni 'Sunny Field Primary School', to wa l'Adelabu, ni Surulere, ko too tesiwaju sileewe girama 'Birch Freeman High school', sugbon Igbobi College lo ti pari eko re.


Lodun 1987 lo kawe gboye onipele akoko ninu imo ofin ni Yunifasiti Benin, nigba to maa fi di osu kokanla, odun 1988, o lo sileewe awon amofin, eyi to fi okunrin naa han gege bii okan ninu awon agbejoro ile yii. Leyin naa lo sise po pelu ileese aladaani ko too di agbejoro agba forile-ede yii.

Pelu bi Fasola se je okan lara awon agbejoro to danto nile-ejo to ga julo ni won se fun un lorisiirisii ami-eye ati iwe-eri olokan-o-jokan.

Gege bi Babatunde Fasola se je baba isale fawon akekoo amofin ni Fasiti Benin lo tun je eni akoko ti won yoo fi ipo agbejoro agba da lola ninu awon ti won jo kekoo-jade nileewe amofin lodun 1988. O je okan lara awon igbimo amofin ile yii ati loke okun, bee lo tun je okan lara awon igbimo ileeko imo ijinle nipa eto owo-ori.

Oun ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu yan gege bii olori awon osise ijoba lasiko tiyen n tuko ipinle Eko gege bii gomina, bee lo tun di ipo komisanna ofiisi gomina mu. Awon ipo mejeeji yii lo di mu leekan naa.

Lara awon ibi ti Fasola ti sise ki won too yan an gege bii gomina ipinle Eko ni: Akowe-agba fun igbimo to n ri si iyipada ijoba lodun 1999; igbimo to ri si iwadii ati pinpin ile ijoba ipinle Eko, Mobolaji Johnson, to wa ni Lekki, lodun 2000; igbimo apase ipinle Eko laarin odun 2002 si 2006;; igbimo eso alaabo ipinle Eko laarin odun 2002 si 2006;; igbimo to n sakoso ohun alumooni ipinle Eko laarin 2002 si 2006;; alaga igbimo atunto ati pinpin nnkan ini ijoba lawon ijoba ibile.

Ojo kokandinlogun, osu karun-un, odun 2007, ni Babatunde Raji Fasola di gomina ipinle Eko. Leyin to lo odun merin akoko tan lawon araalu tun dibo yan an lodun 2011 latari ise takuntakun to gbe se ko too di pe o gbepo naa sile lodun yii fun Gomina Akinwunmi Ambode.

Oun ni minista ti yoo soju ipinle Eko ninu ijoba Buhari nitori ose to koja lo farahan niwaju awon asofin agba, ti won si ni o yege lati di ipo naa mu.

Kayode Fayemi 

Kayode Fayemi Ojo kesan-an, osu keji, odun 1965, la bi Dokita John Kayode Fayemi si idile Alagba Francis Falade Fayemi ati Iyaafin Dorcas Aina Fayemi ti won ti doloogbe bayii. Omo bibi ilu IsanEkiti, nijoba ibile Oye, nipinle Ekiti, ni i se. Laarin odun 1975 si 1980 lo kawe mewaa nileewe girama 'Christ School' to wa niluu Ado-Ekiti, ko too lo sileewe 'Federal School of Arts and Science,' to wa nipinle Ondo, lodun 1982, nibi to ti gba iwe-eri HSC, 'Higher School Certificate'.

Leyin to pari eko mewaa re lo tesiwaju sileewe giga Fasiti ilu Eko, University of Lagos, nibi to ti kawe gboye ijinle ninu imo itan agbaye, iyen History lodun 1985. Nigba to pari nibe lo tun gba ileewe giga Fasiti Ife ti won n pe ni 'University of Ife' nigba naa lohun-un, sugbon ti won yi oruko re pada si Obafemi Awolowo University, OAU, to n je bayii lo. Ileewe giga Ife yii lo ti kawe gboye nipa ibasepo laarin awon orile-ede, eyi tawon oloyinbo n pe ni International Relations lodun 1987.

Fayemi tun kekoo siwaju nileewe 'King's College', niluu London, nibi to ti kawe gboye omowe ninu imo ogun-jija, 'Doctor of Philosophy in War Studies'.

Dokita Kayode Fayemi, oko Arabinrin Bisi Adeleye-Fayemi, ti figba kan je oga-agba ileese 'Centre for Democracy & Development', ileese to n sewadii ati idanilekoo nipa idagbasoke eto ijoba alagbada, eto alaafia laarin ilu ati idagbasoke eto aabo nile Afrika, 'Promotion of democratic development, peace-building and human security in Africa'.

Saaju ko too sedasile ileese ohun lo ti sise oluko nileewe giga ati akoroyin lorile-ede Naijiria ati orile-ede United Kingdom. Awon iwe-iroyin to ti ba sise ri ni 'The Guardian' ati 'City Tempo'. Oun kan naa lo ti figba kan je olootu iwe-iroyin nipa oro oselu kan to maa n jade losoosu toruko re n je 'Nigeria Now'. O ti se oluko nileewe ekose olopaa to wa nipinle Sokoto.

Fayemi gege bii okan gboogi ninu awon asaaju to n tako ijoba ologun nigba naa lohun-un ti je okan pataki ninu awon to n sakoso awon ileese redio meta kan ti won n lo lati tako ijoba ologun nigba naa, iyen 'Radio Freedom', 'Radio Democracy International' ati 'Radio Kudirat'.

O ti ba awon ijoba sise lorisiirisii ipo. O figba kan je oludamoran fun ileese to n sewadii sisi agbara lo laarin awon olori ijoba nigba naa, to si n ja fetoo araalu, 'Nigeria's Human Rights Violations Investigation Commission' ti won n pe ni 'Oputa Panel' nigba naa. O sise lorisiirisii igbimo ijoba bii NEPAD, MDGs, ECOWAS ati bee bee lo.

Ninu osu kerin, odun 2007, lo kopa ninu eto idibo gomina nipinle Ekiti, to si pada jawe olubori nigba tile-ejo to n gbejo awuyewuye leyin esi idibo pase pe oun lo wole ibo.

Leyin to pari saa kan lo tun kopa ninu eto idibo gomina to waye lojo kokanlelogun, osu kefa, odun 2014, labe asia egbe oselu APC, sugbon to fidi-remi. Lasiko eto idibo gbogboogbo odun 2015, oun lo kopa gege bii alaga igbimo to sakoso eto idibo abele lati yan oludije fun ipo aare labe asia egbe oselu APC, leyin eto idibo yii ni won yan an gege bii minisita ti yoo soju ipinle Ekiti ninu ijoba Buhari.

Claudius Omoleye Daramola 

lu Ode-Aye, nijoba ibile Okitipupa, nipinle Ondo, ni won ti bi Ojogbon Daramola si idile Ogbeni ati Abileko Alfred Daramola ni nnkan bii aadorin odun o din die seyin.

Ojogbon Daramola je ogbontarigi ninu imo eto-eko pelu bo se je pe kete leyin to pari nileewe girama lo morile ileewe ekose awon oluko onipo keji. Leyin to kuro nibe lo tesiwaju ninu eko re ni fasiti ijoba apapo to wa ni Sokoto, nibi to ti kekoo gboye onipele akoko nipa imo ibagbepo ti won n pe ni Sociology.

Bakan naa lo tun kekoo gboye omowe ninu eto eko yii kan naa ni fasiti ijoba apapo to wa niluu Jos, nipinle Plateau, ko too waa tesiwaju lati gboye ojogbon ninu imo sayensi yii.

Eka eto eko Sociology ni fasiti ijoba apapo to wa niluu Ilorin, nipinle Kwara, ni Ojogbon Daramola ti n sise oluko, koda o ti figba kan di ipo adari eka eko ohun mu.

Omo egbe oselu ACN ni Daramola, ore timotimo lo si je si oludasile egbe naa, Asiwaju Hammed Bola Tinubu. Oun ni opo awon oloselu ipinle Ondo maa n lo bii ategun lati ri ojurere Tinubu fun ibasepo to jo wa laarin won.

Bi ki i baa se pe egbe oselu ACN atawon egbe oselu mi-in parapo di APC lodun 2013, o see se ko je okunrin yii ni iba di alaga gbogbogboo egbe oselu ACN.

Bee ni Daramola wa lara awon to dupo alaga egbe oselu APC nipinle Ondo ko too di pe won dibo yan Amofin Isaac Kekemeke wa ni ipo ohun nipinle Ondo bayii.

Ojogbon Daramola ni yoo soju ipinle Ondo gege bii minista ninu ijoba Muhammadu Buhari.

Kemi Adeosun Kemi Adeosun 

Arabinrin Kemi Adeosun je okan lara awon ti yoo ba Aare Mohammed Buhari sise po, oun nikan si ni won mu lati ipinle Ogun.

Ninu osu keta, odun 1968, ni won bi i niluu London. Bo tile je pe omo bibi Ogun Waterside, nipinle Ogun ni, ilu oyinbo ni won bi i si, nibe naa lo si ti ka gbogbo iwe to ka.

Ipo keta lo wa ninu awon omo merin tawon obi e bi, o kawe gboye nipa eto oro-aje ni Yunifasiti to wa ni East London, bee lo tun tesiwaju nigba to loo kawe si i nipa eto isuna.

Kemi bere ise gege bii olusiro owo lodun 1989 si 1990, ilu oyinbo naa lo si ti n sise gbowo osu ko too di pe o wale lodun 2011. Bo se de ni won fi i se komisanna feto isuna laarin odun naa si 2015. Oruko e wa lara awon ti Gomina Ibikunle Amosun koko fi ranse lati wa ba a sise po ko too di pe ise minisita yoju bayii.

Lai Mohammed 

Amofin Lai Mohammed ni won bi si idile Alaaji Mohammed Adeleye lodun 1952. O ni iwe-eri akoko (B.A) ninu ede Faranse ni Fasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife lodun 1975, o si gba iwe-eri ninu imo ofin ni Yunifasiti tipinle Eko ati ile eko imo ofin (Nigeria Law school) lodun 1986.

Oloselu to gbajumo bii isana eleeta ni Lai Mohammed i se. O ti sise gege bii alaga ileese 'Optmedia Limited' to je eka 'Afromedia Plc' lati odun 2008. Alaaji Lai Mohammed tun je okan lara awon omo egbe 'Nigerian Institute of Public Relations' (NIPR), to si tun sise gege bii alukoro ajo 'Nigerian Airport Authority' to ti di 'Federal Airport Authority of Nigeria' (FAAN) bayii fun bii odun mewaa.

Losu kewaa, odun 2002, Lai Mohammed ni won yan lati dije dupo gomina nipinle Kwara ninu eto idibo osu kerin, odun 2003, labe asia egbe oselu Alliance for Democracy (AD).

Omo ipinle Kwara ni, sugbon ilu Eko lo fi sebugbe. Gege bi amofin, o wa lara awon to da ile amofin (chambers) Edu and Mohammed sile lodun 1989. Won gba a wole gege bii amofin (called to bar) lodun 1986. O ti figba kan sise gege bii olori osise fun gomina tele nipinle Eko, Bola Tinubu.

Oun ni yoo soju ipinle Kwara ninu ijoba Buhari.

Suleiman Hussain Adamu 

Onimo ero nipa ka kole, se biriji atawon ohun to jo mo bee ni Suleiman Hussain Adamu, ileewe giga Ahmadu Bello Yunifasiti lo ti kawe gboye lodun 1984, oun lo si gba ebun akekoo to peregede julo lodun naa. Ileese Nigerian Port Authority to n mojuto oro papako lo fun un lebun ohun nigba ti esi abajade idanwo re wu won lori gidi. O kawe niluu oyinbo pelu, bo si se sise leka ijoba lo tun je olugbani-nimoran lori oro ile kiko ati oju ona sise, odun 1989 lo si ti n ba eyi bo.

Suleiman ti di agba oje labala ise to yan laayo yii, awon ileese bii PTF to n sabojuto idagbasoke igberiko lo tun ba sise po, o si lowo ninu idasile eka IEA( (Integrated Engineering Associates) lodun 1987. Lowolowo bayii, oun ni igbakeji aare fun ileese to n ri si igbani-nimoran lori imo ero to ni i se pelu ile kiko atawon ohun to ro mo on.

Solomon Dalong 

Ojo kerindinlogbon, osu kesan-an, odun 1964 ni won bi Solomon Dalong ni Sabon Gida. O kawe alakoobere nileewe LEA to wa ni Sabon Gida, laarin odun 1971 si 1977, o si ka ti girama ni Government College, Keffi, to wa nipinle Nassarawa bayii.

Nigba to kawe naa tan lo darapo mo ileese ogba ewon ile wa, eyin igba naa lo lo sileewe giga Yunifasiti Jos, ibe lo ti kekoo nipa imo ofin to si di looya nigba to setan lodun 1999.

Solomon gba ile eko awon agbejoro to wa ni Bwari, niluu Abuja lo, o kekoo yege lodun 2000, ijoba si lu u lonte agbejoro gidi lodun 2001. Amugbalegbee Oloogbe Solomon Lar ni okunrin yii lasiko ti Obasanjo yan Lar gege bii oludamoran agba, odun 2004 lo si di oluko ni Yunifasiti Jos toun naa ti kawe, eka awon agbejoro naa lo ti n ko won lekoo.

Odun 2004 yii kan naa ni won yan an gege bii alaga fun ijoba ibile Guusu Lantang, nipinle Plateau to ti wa.

Dokita Chris Nwabueze Ngige 

Ojo keji, osu kejo, odun 1952 ni won bi Chris Ngige to je omo ipinle Anambra. Ileewe giga University of Nigeria, niluu Nsukka, nipinle Enugu, lo lo, nibi to ti kekoo jade ninu imo isegun lodun 1979.

O bere ise ijoba pelu awon ileewosan ile igbimo asofin ipinle ati tijoba apapo, odun 1998 lo si feyinti gege bii igbakeji adari nileese eto ilera ijoba apapo, Federal Ministry of Health.

Leyin eyi lo bere oselu, o si wa lara awon to da egbe oselu PDP sile. Lodun 1999 lo je igbakeji akowe apapo egbe naa ati akowe iha Guusu-Ila-Oorun ile yii. Odun 2003 lo je gomina ipinle Anambra, odun 2006 lo si fipo naa sile leyin opolopo wahala nigba ti ile-ejo yo o.

Odun 2011 lo di seneto leyin ibo ati atundi ibo laarin oun ati Oloogbe Dora Akunyili, sugbon o fidi-remi ninu idibo todun yii pelu Onarebu Uche Ekwunife.

Amina Mohammed 

Odun 1961 ni won bi obinrin to lokiki ni Naijiria ati lagbaaye yii latari awon ipo to ti di mu.

Saaju akoko yii lo ti da ajo aato ilu kan sile, iyen 'Center for Development Policy Solutions' ati ajo 'AfriProjects Consortium', bee lo se oluko agba nileewe giga Colombia University.

O se amugbalegbee agba fun Aare Umar Musa Yar'adua lasiko isejoba re, bee lo tun di awon ipo nla mi-in mu kaakiri awon orile-ede mi-in. Lasiko ti Aare Muhammadu Buhari yan an yii, o je oludamoran agba fun olori ajo isokan agbaye, Ban-ki Moon, lori idagbasoke awon orile-ede.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 02:39:10 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Lori Bi Aare Muhammadu Buhari Ti Yan Awon Minisita Re Tuntun, Oun Taye N Wi Ree" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: