Gbagede Yoruba
 



Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Ore Meji Figo Gun Ara Won Sakasaka L'Ekiti
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Ore Meji Figo Gun Ara Won Sakasaka L'Ekiti

Nitori ede-aiyede ranpe kan to sele laarin awon ore meji ti won jo n gbe inu yara, Yetunde Kolawole, eni ogun odun ati ikeji re, Banke Alonge, toun je omo odun merindinlogbon, ileese olopaa ti wo won lo sile-ejo lori esun pe won figo gun ara won sakasaka.

Gege bi olopaa to soju ijoba, Koburu Monica Ikebuilo, se salaye nile-ejo majisreeti kan niluu Ado-Ekiti, awon olujejo mejeeji ohun koju ija sira won nita gbangba, eyi to mu won fo igo, ti won si fi gun ara won ni gbogbo ara. Isele ohun lo mu ki won da ogbe sira won lara lojo ketala, osu kewaa, odun yii, lagbegbe Irona, niluu Ado-Ekiti. O ni esun ohun tako abala kan ninu ofin to n gbogun ti iwa odaran nipinle Ekiti.

Ikebuilo waa ro ile-ejo lati sun igbejo siwaju, eyi ti yoo fun un laaye die lati mura daadaa fun ejo ohun.

Awon olujejo mejeeji ti Ogbeni Busuyi Ayorinde ati Ogbeni Gbenga Abejide gbejoro fun so pe awon ko jebi esun ti won fi kan awon lasiko tile-ejo ka a si won leti.

Awon agbejoro won ro ile-ejo lati gba oniduuro won pelu ileri pe awon yoo pese awon oniduuro to dangajia lati duro fun won.

Leyin to gbo gbogbo awijare awon mejeeji atawon agbejoro won pelu tijoba, Adajo Idowu Ayenimogba gba beeli won pelu egberun lona aadota naira eni kookan ati oniduuro kookan niye kan naa.

Ewe, iwadii akoroyin wa fi han pe lojo ti isele naa sele, okan lara awon olujejo ohun wa ninu ile, nigba ti eni keji si de to ni ko silekun ni ko dahun, bi eyi to n bo lati ita se fipa ja ilekun wole niyen.

Kete ti won niyen wole nija bere laarin awon mejeeji, ki won si too mo ohun to n sele, won ti bere si i pa igo ti won fi gun ara won yannayanna. Leyin isele ohun ni won gbe awon mejeeji lo sileewosan.

Dokita ilewosan aladaani kan lagbegbe Irona to waa jeri nile-ejo, Dokita Akintade, salaye pe loooto ni won gbe awon olujejo mejeeji wa sileewosan oun pelu opolopo ogbe lara won, sugbon gbogbo asiko toun fi toju won, ko si molebi won kankan to yoju. Titi dasiko toro de ile-ejo, awon mejeeji ko ti i san kobo ninu owo itoju won.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 04:04:38 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu



"Nitori Oro Ti Ko To Nnkan, Ore Meji Figo Gun Ara Won Sakasaka L'Ekiti" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com