Gbagede Yoruba
 



Nibo Ni Isokan Yoruba Yoo Ti Wa?
 
Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin Lati Owo Akoroyin Olootu

Nibo Ni Isokan Yoruba Yoo Ti Wa?

Okan ninu awon aburo wa soro kan lose to koja lo yii. Aburo wa naa, Seneto loun tele, Femi Ojudu, lati Ekiti. Amerika lo ti soro ti mo fee so yii o, ohun to si so ni pe lasiko ijoba Buhari yii, bi Yoruba ko ba wa nisokan, won ko ni i ri kinni kan gba kuro ninu ijoba naa.

Iyen tumo si pe gbogbo wahala tawon oloselu Yoruba se leyin Buhari lati je ko de ipo to wa yii, ofo ni yoo ja si. Aburo wa ko le soro naa nile, Amerika lo ti loo so o. Nigba ti awon oniroyin si gbe ohun to so jade, o ni bi oun ti so o ko niyen. Sugbon nigba toun naa ko ohun to so pe oun so jade, oro kan naa ni, ko siyato nibe. Koko ohun ti Femi so ni pe nnkan ti bo mo Yoruba lowo ninu ijoba yii. Femi so nibi ipade naa pe lasiko ti won n mu awon ti won fee se minisita, won ti fi oruko Femi Falana si i tele, sugbon won ni bo ba fe ki oro naa see se foun, ko koko lo si Kaduna lodo enikan to le ba a se e. Ni Falana ba ko, ko lo.

Ta lo waa wa ni Kaduna ti Femi Falana yoo loo ba lati se minista? El Rufai ni. El Rufai to n se gomina ibe lowo bayii, okunrin to fee di ana Buhari bi ohun gbogbo ba lo deede, to si ri omo re fe, oun lo ku ti won n ni kawon bii Falana loo ri ko le ba a soro lodo Buhari atawon ti won jo n sejoba ki won fi i se minisita. Bee, awon El Rufai yii ni ki i won nile Yoruba tele.

Awon ni won n sare kiri, awon ni won n mu Buhari kiri, awon ni won n ba awon oloselu ile Yoruba sepade, awon lawon oloselu wa n gbo tiwon, ti won fi n so fun wa pe ijoba to n bo yii, ba a ba ti le dibo fun Buhari, ijoba wa ni, ijoba ti yoo se Yoruba lanfaani julo ni, nibe ni Yoruba yoo ti ri gbogbo ohun to bo sonu lowo wa lati ojo yii gba. Sugbon ati onile ati alejo bayii, ati awon ti won ta wa sodo awon Buhari funra won, ati awon ti won n so pe awon le pa wa bi a ko ba je ki Yoruba lo sodo awon Fulani, oju gbogbo wa lo ti ja a bayii o.

Tabi eni meloo lo gbo oro lenu Bola mo, afi awon omo re ti won n fibinu kowe sinu awon beba won. Tabi ta lo gboro lenu Bisi, ta lo tie mobi to wa? Fulani ti lo won, won ti ju won sile. Gbogbo awon ti won fi oruko won sile pe ki won fi sipo ni Buhari ju oruko won nu, o si mu awon to mo pe won ko ni i gboro si Bola lenu, nitori Bola ko fe kawon yen de ipo pataki kan mo, oto lawon to fe. Buhari ko mu awon Tunde (Fasola) ati Kayode (Fayemi) nitori pe o feran won o, lati fi kan iye apa awon ti won n pe ara won lasaaju oloselu, ti won si n pe awon lawon gbe e wole ni. Bi Booda Segun se lenu to, ti won si ja raburabu to, gbogbo awon ti won fi oruko won ranse si Buhari, paapaa Lagun, Buhari ko ye won wo. Owo won ti ba eeku ida, won si ti mo pe ko seni to le gba kinni ohun lowo awon. Gbogbo ohun to le di won lowo ni won n yanju ti e n ri yii, tabi e ko ri i ti won fi omo Fulani mi-in se olori ajo to n seto idibo, bee Fulani ni aare wa.

Ohun ti won se n se gbogbo eleyii ni pe nigba ti asiko ibo mi-in yoo ba fi de lodun merin sasiko yii, ko ni i seni ti yoo gbo oruko awon oloselu to ta awon eya Yoruba fun won yii mo, won yoo ti pa won ti bii aso to gbo. Bi awon yen ba fee ja raburabu, awon iwe asemase ti wa lowo won ti won yoo fi han won, bii ki won fi EFCC deruba won, bii ki won fi awon olopaa-inu gbe won, nigba ti owo awon naa ko si mo, won yoo jokoo jee ni. Eleyii ni pe a ti bo sowo ijoba Fulani leekan si i, bi ko si je pe won se kinni naa o su won, tabi ti wahala miin tun de, ojo yoo pe die ki ijoba too bo pada si wa lowo. Iyen ni Femi ati awon ti won jo lo s'Amerika bayii se n soro nipa isokan ile Yoruba, ti won n so pe asiko yii lo ye ka wa nisokan, bi bee ko, ohun gbogbo yoo bo mo wa lowo. Sugbon kin ni ko ti i bo mo wa lowo .

Ki lo tun ku lowo wa ti a ko ti fi oselu ati iwa omugo tiwa gbon danu?

Asiko ti ode ba le omo wale ni yoo mo pe oun ni baba. Igba ti iya ba je omode nita ni yoo mo pe baba oun ti oun ro pe ara-oko ni ki i se omugo bee, nitori ogbon kan lo fi fe iya oun.

Omo ti ko ba gbon, ita ni won yoo ti ko o. Sebi ohun ti awa ti n pariwo ta a fi di ota won naa ree. A so fun won pe bi oselu ba de, ka ma tori iyen da ile ara wa ru, ka ma tori iyen ba ile Yoruba je, ka ma tori oselu ta ara wa fun araata, nitori ko si eya miiran ti i se bee ju awon oloselu ile Yoruba lo. Lati ojo ti Buhari ti wole bayii, o di omo Hausa meloo to pe ara re ni PDP to n bu u, tabi to n tu asiri e, tabi to wi nnkan kan. Gbogbo won ti di APC, eyi ti ko si ti i wo inu egbe naa yoo ti mo ibi ti yoo ti pade Buhari tabi awon eeyan re lale, o pari niyen. Eleyii see se fun won nitori awon ki i ja ija ajadiju nitori oselu, won ki i ta awon baba won lopo, won ki i jokoo sibi kan ki won ni ko si agba niluu awon mo, won ki i fa aso iyi ya lara awon baba won.

Sebi awon Femi to waa n soro l'Amerika yii, atawon eeyan bii tiwon naa ni won ni ka fo ka niso, nitori a ni ki won fi ogbon se oselu, pe bi won ba sore titi, ki won ma gbagbe ojo kan ija, ki won mo pe oju ti a fi yawo ko la fi i san an, awon eda buru, ti won ba n wa nnkan ti won fee gba lowo eni. Oro naa lo dele yii. A ti ba gbogbo nnkan tiwa je nidii oselu oponu, oselu ole, oselu were ti a ni a n se. Sebi egbe Arewa wa nile Hausa ti won si n pase titi doni, ati oloselu APC ati PDP ati awon teni kan ko gboruko lo wa ninu won. Bi ti Arewa ko ba to, sebi awon oba tiwon wa nibe. Tabi oba Hausa wo ni yoo gbo Sultan lenu. Awa ti lu egbe Afenifere tiwa fo, a ti fa Igbimo Agba ya, ko si egbe gidi ti a le toka si nile Yoruba, bee ni ko si agba kan ti a n gboro si lenu, a ti so gbogbo won di yepere. Bee bi ile kan ba wa ti itan-eran ba ti n kan omo kekere nibe, iru ile bee ti baje ni, nitori awon agbalagba ibe ti parun ni.

Nigba ti Ooni Sijuwade wa laye, won ni PDP ni, oloselu ni, oun lo n foselu gba kontiraati, bee won n so gbogbo oro yii nitori ti ko si ninu egbe oselu tiwon ni o, bo ba je lodo won lo wa, awon gan-an ni won yoo maa gbe kontiraati fun un. Tabi oba tiwon wo ni ki i gba kontiraati, oba nla wo lo wa nile Yoruba ti yoo jade pe oun ko gbowo lowo ijoba, nibo loba naa wa? Oba ilu wo ni? Oba Ijebu ni abi Oba Oyo, abi Oba Eko, ti yoo so pe owo ise ti oun se loun n na! Iru ise wo lo n se? Sugbon ki i se oba ile Yoruba nikan lo n gbowo ijoba, awon oba ile Hausa ko ni ise kan rara laye tiwon, owo ijoba Naijiria lawon n na, lojo ti won ba ti joba ni bukaata won ti di tijoba. Sugbon ta ni yoo gbo ariwo nibi kan pe Sultan gba kontiraati, tabi oun ki i gba ni? Tabi oba Kano ni ki i se kontiraati? Sugbon awon oloselu lo n fi oba tiwa wole, tawon oba wa yoo maa ja laarin ara won, ti won yoo maa tu asiri ara won sita.

Sijuwade ti ku lati ojo yii o, ki lawon oba wa ti ko ti i ku ri se si isokan wa? Sijuwade ni won sa so pe o n di won lowo tele. Ni bayii, Yoruba ti ha saarin. Awon Fulani darandaran ni ka fo ka niso, won ko da eran mo, ile wa lo ku ti won fee gba, won kuku fee mu wa leru nile baba wa ni. Iyen la n so lowo lawon Ibo ni awon naa fee maa joba nile Yoruba, omo ale kan ti won ki i joba niran won nibi to ti wa yoo si so ara re di oba, yoo maa mura lati ko aafin. Se a le ba won wi ni? Awa ni ka ye ara wa wo. Sebi awa la n ta ile fun won.

Awa la n ta ile pataki to ye ko je tilu fawon Ibo. Awa la n gba maaluu lowo awon Fulani ti a ko le tori e soro mo, koda ki won maa fiya je awon eeyan wa.

Gege bi Femi ti wi, asiko to ye ka gbagbe oro ana niyi o, nitori bi a ko ba se bee, ogun yoo jo ko wa lo ni.

Asiko ti a gbodo jokoo isokan ree, ka le mo ohun ti a oo se si tawon Fulani ati Ibo yii. Bi a ko ba sa joba, a oo jeba; bi a ko ba ri nnkan gba lowo ijoba, a oo sa le fokanbale nile wa. Bi awon agba Yoruba ba wa nisokan, yoo rorun fun gbogbo Yoruba lati wa nisokan, nitori ise wa ti a fee se o. Ise po gan-an paapaa ti tomode-tagba ile Yoruba gbodo se.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 04:17:22 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin:
Oorun didun igi ododo ti orewa nipa ajulo awon iya awon olugbagbo ododo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin



"Nibo Ni Isokan Yoruba Yoo Ti Wa?" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com