Gbagede Yoruba
 



Esther Na Omo Oko Re Fo Loju, Lawon Olopaa Ba Wo o Dewaju Adajo
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu Lati Owo Akoroyin Olootu

Esther Na Omo Oko Re Fo Loju, Lawon Olopaa Ba Wo o Dewaju Adajo

Nitori esun biba omo oko re wi lona ti ko to ni won se wo obinrin kan toruko re n je Arabinrin Esther Williams lo si kootu majisreeti to wa ni Surulere lose to koja. Obinrin yii la gbo pe o seesi fegba gun omo oko re, Boluwatife Williams to je omo odun merindinlogun loju lasiko to n ba a wi.

Okan ninu awon esun mejeeji ti won fi kan obinrin ti won so pe oun lo fo omo oko re loju ni adajo ile-ejo yii pada wogile latari bi agbejoro re, Dr. Ubiwe Eriye, se so pe ki i se eyi ti abileko naa mo-on-mo se, bi ko se pe biba to n ba omo naa wi lori iwa aigboran re legba seesi wonu oju osi e lo.

Gege bi ohun ti a gbo, Boluwatife niyawo baba re ja lore lori esun pe o ko lati bojuto awon aburo re nigba ti ko si nile. Sugbon bo ba se pe iyaale ile yii mo pe ibi toro ohun yoo yori si ree, boya iba ti se suuru. Aini suuru obinrin naa lo mu un fi lilu da batani somo yii lara nile won to wa lojule kerin, laduugbo Owodunni, Onipanu, l'Ekoo, lowo nnkan bii aago merin irole. Ileewosan ti won sare gbe omo yii lo leyin to di mimo pe egba ba a loju ni won ti mo pe oju Boluwatife ti rele ogo.

Esekese ni won fa Esther le awon olopaa lowo ko too di pe awon yen ru u wa si kootu lati waa wi tenu e lori ohun to mo nipa esun ti won fi kan an.

Bee ni agbejoro obinrin yii ro adajo kootu lati siju aanu wo onibaara e lati fagile esun fifo omo re loju ti won fi kan an. O ni aitele ase awon obi e lo sokunfa iru ajalu to ja lu omode yii.

O ni biba tobinrin olujejo naa ba omo oko re wi ki i se igbese to lodi sabala ofin karundinlogoje(135) iwe ofin iwa odaran tipinle Eko, todun 2011, bi ko se lati to o sona.

Ninu oro iya to bi Boluwatife, Abileko Modupe Olawunmi, o ni iba wu oun pupo bi ile-ejo naa ba le gba awon laaye lati loo yanju oro naa nitubi-inubi laarin ara awon.

Ju gbogbo e lo, Adajo A. Ipaye-Nwachukwu fagile okan ninu esun naa to so pe obinrin ohun lo fo omo oko re loju gege bii agbejoro re ti wi. O sun igbejo mi-in lori esun yii di ojo kinin-ni, osu kejila, odun yii.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 04:47:53 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu



"Esther Na Omo Oko Re Fo Loju, Lawon Olopaa Ba Wo o Dewaju Adajo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com