Gbagede Yoruba
 



Waheed Ni Ismaila N Ba Iyawo Oun Sun, Lo Ba Sa a Pa N'Ilorin
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin Lati Owo Akoroyin Olootu

Waheed Ni Ismaila N Ba Iyawo Oun Sun, Lo Ba Sa a Pa N'Ilorin

Gbogbo eeyan to wa ni kootu majisreeti to wa niluu Ilorin l'Ojoru, Wesde, ose to koja lo n beere kelekele lowo ara won iru ife tabi owu jije ti ogbeni eni ogbon odun kan,Waheed Suleiman, ni to bee to fi wo sunsun, to si fi pa eni to ni o n ba oun du obinrin.

Nigba to n safihan re fun ile-ejo, agbenuso ijoba, Inspekito Mojisola Olamokun, fi esun kan afurasi naa pe se lo se iku pa eeyan, eyi to tako abala kan ninu ti iwe ofin to de iwa odaran lorile-ede yii.

O salaye pe ni ojo kokanlelogun, osu kewaa, odun yii, se ni won mu esun wa lati tesan olopaa to wa ni Afon, ni eka otelemuye, niluu Ilorin, fun iwadii. O ni logunjo, osu kewaa, odun yii, ni nnkan bii aago marun-un irole, se ni ogbeni kan toruko re n je Isiaku Abdulrahaman ti abule Suta to wa nijoba ibile Asa, nipinle Kwara, mu esun to ileese olopaa lo pe awon ko ri arakunrin awon kan, Ismaila Hassan, tawon jo n gbe lati igba to ti kuro nile lojo ketadinlogun, osu kewaa, odun yii.

Nigba ti won bere si i wa Ismaila kiri ni won ri oku re ti won so mo okada Bajaj re to ni nomba Lagos HST 526 QD ninu odo Asa, oju ada si han lagbari re.

Iwadii tawon olopaa otelemuye se fihan pe Waheed ati Ismaila ni gbolohun-aso ninu osu kerin, odun yii, nigba to ka Ismaila mo odo iyawo re, Muslim Aremu, ti won jo n ba ara won lajosepo. Lati igba naa ni Ismaila ati Muslim ti sa kuro nile nitori Waheed n dunkooko mo won pe oun yoo pa won towo oun ba te won.

Agbefoba naa salaye pe awon agbaagba abule naa lo n be Waheed pe ko fowo wonu, kawon si pari oro naa nitubi-inubi, bee ni Waheed so pe oun ti gbo, oun si ti gba.

Sugbon Waheed atawon ore re ti won je agbonrandun jo gbimo-po, won si dena de Ismaila lasiko to n bo lati ona Otte.

Gege bi awon agbofinro se so, won sa Ismaila lori, won si tun fi okun so o mo okada Bajaj re ko too di pe won so o sinu odo Asa.

Nigba tawon agbofinro de ile Waheed, ada meta, obe orisiirisii marun-un ati aake kan ni won ba nibe, won ni awon irinse naa lo fi seku pa Ismaila.

Olopaa to n soju ijoba, Inspekito Mojisola Olamokun waa so pe ileese olopaa si n tesiwaju ninu iwadii won lori esun naa, o si ro adajo lati jowo, ba won fi afurasi naa pamo si ogba ewon titi tawon yoo fi pari iwadii.

Adajo F.O Olokoyo waa pase pe ki afurasi naa si wa latimole ogba ewon to wa ni Mandala, niluu Ilorin, o sun igbejo si ojo kejila, osu yii.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 05:03:37 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin



"Waheed Ni Ismaila N Ba Iyawo Oun Sun, Lo Ba Sa a Pa N'Ilorin" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com