Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin Lati Owo Akoroyin Olootu

Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku

Ibi toro aafaa kan, Olayinka Olawale Abdulateef, to n gbe niluu Ijare, nijoba ibile Ifedore, nipinle Ondo, yoo ja si ni ko ti i seni to le so pelu esun ti won fi kan ojise Olorun naa pe o seyun osu mefa fun orebinrin re, Oyewumi Agbeluyi, eyi to sokunfa iku aitojo fun un lojo Aiku, Sannde, ose to koja.

Gege bi Abileko Funke Isaac, egbon oloogbe yii to fisele naa to Iwe Iroyin Yoruba leti se salaye, ile loun wa lojo ti enikan toruko re n je Omolola fi pe oun pe koun waa wo aburo oun nileewosan ijoba niluu Akure to ti n gba itoju. O ni gbogbo itoju tawon dokita fun Oyewumi ni ko jo pe o sise lara re, nitori igbe inu rirun lo n pa loore-koore, to si n lonu mole bii eni tifun re ti ja si meji.

Funke ni ariwo ti oloogbe naa n pa ni pe ki awon sekilo fawon dokita ki won ma se fa omi soun lara, bee lo be awon eeyan e to duro ti i pe ki won ba oun pe Aafaa Yinka pe ko waa gbe oun lo siluu Ijare, nitori pe oun lo mo agbo ti yoo lo foun tara oun yoo fi ya.

Aafaa ti won pe lomo bibi ilu Osogbo, nipinle Osun, sugbon to filu Ijare, l'Ondo, sebugbe wa nigba ti won ranse pe e. Sugbon ohun kan to n se awon eeyan ni kayeefi ninu oro naa ni pe bi oun ati Oyewumi se foju kan ara won bayii ni Funke so pe ara tu aburo oun pese. O ni oloogbe naa ko kerora gege bo ti n se tele ki aafaa too yoju.

Kete ti Aafaa Yinka kuro losibitu naa to ba tire lo lo ni aburo oun tun bere igbe inu rirun, to n lonu mole lori beedi ko too di pe o waa pada gbemii min ni nnkan bii aago meji osan ojo Aiku, Sannde.

Leyin ti Oyewumi ku ti won si loo sinku re lojo naa lasiiri ohun to fa sababi tu pe Aafaa Yinka lo seyun fun un. Koda, a ri i gbo pe oloogbe yii jewo fun okan lara awon dokita to setoju e pe loooto loun loyun osu mefa aabo ko too di pe Aafaa Yinka lo oogun ibile foun lati fi yo o danu.

Oogun ibile ti won so pe o lo yii lo mu nnkan yiwo. Nigba ti okunrin naa ri i pe oro ti fee beyin yo lo gbe omobinrin yii digbadigba lo sileewosan aladaani kan toruko re je Ayo to wa niluu Ijare. Loju-ese lo da egberun lona ogun naira sile ninu egberun meeedogbon ti won ni ko san.

Sugbon pelu bi won se so pe dokita ohun gbiyanju ba won ko oyun to ti baje naa jade ninu oloogbe, eyi ko so eso rere kan, nise ni inira re tun n peleke si i. Eyi lo mu ki dokita naa gba won nimoran lati tete maa gbe e lo sileewosan ijoba ti won n pe ni 'Caring Heart,' l'Akure.

Ayewo tawon yen se fihan pe aisan to kolu omobinrin yii ki i se eyi tawon le toju, nitori e ni won se gba aafaa niyanju lati gbe e lo sileewosan jenera to wa l'Akure. Leyin to gbe Oyewumi de jenera lo too je kawon ebi re gbo si i.

Ile Oba Ijare la gbo pe awon ebi oloogbe yii koko morile lati fehonu han lori iku to pa omo won, Olujare lo si gba won nimoran pe ki won loo fi oro ohun to ileese olopaa leti.

Lasiko ta a fi n ko iroyin yii jo, a gbo pe olu ileese olopaa to wa loju ona Igbatoro, l'Akure, ni aafaa ohun si wa, nibi to ti n ran awon agbofinro lowo nipa iwadii won.

Ninu iwadii ta a se la ti fidi e mule pe ise isegun ibile ni baba omobinrin to doloogbe yii yan laayo ko too di pe o ku, Aafaa Yinka si je okan lara awon ti baba oloogbe ohun ko nise.

Bee Oyewumi to je omo ogun odun to wa nipele keji (ND 2) nileewe gbogbonise Rufus Giwa, niluu Owo, nijoba ibile Owo, l'Ondo, ni abigbeyin awon obi re.

Irole ojo Aiku, Sannde, tomobinrin yii jade laye ni won sinku e siluu Ijare ti i se ilu abinibi re.

Gbogbo akitiyan wa lati fidi isele ohun mule lodo alukoro olopaa nipinle Ondo, DSP Femi Joseph, ni ko seso rere pelu bo se ko lati gbe ipe wa, bee ni ko tun si nitosi lasiko ta a sabewo sofiisi re.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, May 21 @ 21:40:03 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"Aafaa Wo Gau N'Ijare, Orebinrin Re Lo Seyun Fun, Niyen Ba Gbabe Ku" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: