Gbagede Yoruba
 



Lori Oro Ti Ko To Nnkan, Awon Olopaa Fibon Fa Femi Lorun Ya, Ni Won Ba Sa Lo
 
Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun Lati Owo Akoroyin Olootu

Lori Oro Ti Ko To Nnkan, Awon Olopaa Fibon Fa Femi Lorun Ya, Ni Won Ba Sa Lo

Ori lo ko okunrin eni odun marundinlogoji kan, Femi Olajuyin, yo lowo iku airotele lose to koja pelu bi awon olopaa ti Arabinrinn Funmi Fajuyi toun pelu e jo ni aawo ko wa lati gbe okunrin naa se se e basubasu, ti okan si fi irin ara ibon fa orun Femi ya, die lo si ku ko ba isele naa lo.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe aawo kekere kan lo sele laarin Femi ati Funmi ti won jo kole ti ara won lopopona Tope Alabi, lagbegbe G.R.A, niluu Ado-Ekiti, oro ohun lo si pada waa dohun ti won fi olopaa gbe ara won. Isele naa to bere laaaro kutu ojo kokandinlogbon, osu kokanla, odun yii, lo pada waa so Femi dero eka pajawiri nileewosan ekose Fasiti ipinle Ekiti, EKSUTH, nibi ti won sare gbe e lo pelu bi eje se n da sorosoro lorun e.

Sugbon se ni awon olopaa to waa mu Femi na papa bora leyin ti won gbe e lo sileewosan tan, koda won ko duro gba iwe lati fi han pe awon lo gbe e wa si osibitu, bee ni won ko pada loo wo o lati mo boya o si wa laye tabi o ti jade laye. Yato si eyi, Funmi toun pelu Femi jo ni aawo naa fese fe e, ko si seni to mo ibi to wole si titi di bi a se n so yii.

Beeyan ba ri omokunrin ohun bawon dokita se ba a ran orun re, ti won si we aso mo on, yoo ki i ku oriire pe o bo lowo isele ti ko ba fa gogongo re ja, to si see se ko mu emi re lo.

Lasiko ti akoroyin wa sabewo si okunrin ohun lojo Eti, Fraide ose to koja leyin tawon dokita da a sile ti won si ni ko waa maa gbatoju loorekore, bo tile je pe ara re ko ti i mokun to, o salaye pe ni nnkan bii aago mefa aaro ojo Aiku, Sannde, to koja lohun-un nisele naa bere. O ni inawo kan niyawo oun fee se ni soosi, awon si ti pa eran tawon si n dana lowo laaaro ojo naa. Sadeede ni Arabinrin Funmi tawon jo n gbe legbee ara awon, sugbon tawon ki i soro rara nitori aawo kekere kan to ti wa laarin awon ko ina igi tawon n da lowo.

"Nigba ti ina igi ta a n da lowo ti ke ni obinrin naa wa to si loun fee ko ina ta a n da. Mo so fun un pe ko si aaye fun un lati se bee, bo saa se taku pe ko seni to le ni koun ma ko ina naa, o ni baba mi ati iya mi to ti doloogbe gan-an ko le so bee, bi wahala se bere niyen o. Obinrin naa gbiyanju lati fi paanu to fee fi ko ina sa mi lori, sugbon mo ye e, bi paanu naa se loo gba a lori niyen, lo ba gba ile re lo "Bi mo saa se loo foro to agbalagba kan laduugbo tawon eeyan mo si Baba Orege leti niyen.

Ki n too de, obinrin naa ti le gbogbo awon to n ba wa dana, o si ti da gbogbo eran ta a n se lori ina sinu yeepe. Igba ti mo de ile re, o ti gbe gbogbo ilekun ti, bi mo se fibinu la igi mo gilaasi ferese ile re niyen." Femi salaye pe leyin bii ogbon iseju lobinrin ohun ko awon olopaa de lati waa mu oun, sugbon oun sa kuro lojo naa. Sugbon nigba tiyawo oun maa pada de lati ibi to ti loo ra nnkan, awon olopaa mu un lo si ago won ni nnkan bii aago mesan-an aabo, baba iyawo oun lo loo gba beeli e ni nnkan bii aago mejo ale ojo naa.

O ni sugbon awon olopaa ohun ti won wa lati tesan to wa lopopona NTA, niluu Ado-Ekiti, gba foonu iyawo re kale, won ni ti won ba ri oun ki won mu oun wa ki won too le yonda foonu naa.

"Oro fee di wahala laduugbo, sugbon baba mi so pe ki n maa tele awon olopaa lo pe awon yoo tele wa debe. Bi mo se de enu ona lati maa tele awon olopaa yen lo ni okan lara won bere si i ti mi gbon-on-gbo-on, bee ni okan to gbe ibon lowo n fi i hale, afi bii igba ti won ba mu ole tabi odaran ni won se se mi lojo naa. Bi irin ara ibon ti okan gbe lowo se ko isanorun mi niyen, to si fa orun mi ya ti eje bere si i da." O nigba tawon koko de ileewosan aladaani kan to wa nitosi, awon dokita ni o koja agbara awon pe ki won maa gbe oun lo sileewosan EKSUTH. Sugbon ohun tawon olopaa naa so fun dokita nigba tawon de ileewosan naa ni pe oun fi abefele ge ara oun lorun.

Akoroyin wa sakitiyan lati ri obinrin toun pelu Femi jo ba ara won ja yii, sugbon ko seni to mobi to sa gba titi di akoko yii, bakan naa ni akitiyan wa lati ba alukoro ileese olopaa nipinle Ekiti, Ogbeni Alberto Adeyemi, soro ja si pabo, a pe aago re sugbon ko lo.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 19:38:45 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun:
Onka Yoruba - Numbers In Yoruba: Figures And Counting, Kika Ni Yoruba Computes


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun



"Lori Oro Ti Ko To Nnkan, Awon Olopaa Fibon Fa Femi Lorun Ya, Ni Won Ba Sa Lo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com