Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Lati Owo Akoroyin Olootu

E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare

Ohun ti yoo dara ju ni ki won gbe oga awon looya ti EFCC mu timole lojosi wa sile-ejo, ko waa salaye, ko si waa so tenu re, idi to fi n fun adajo lowo. Oro kan lokunrin naa ti won n pe ni Riki Tarfa ti gbe kale. O so pe owo toun fun adajo naa, oun fun un lowo naa ko fi se oku iya re ni. Bo tile je pe eeyan ki i se adajo, ti ki i se looya, eeyan yoo sa mo ohun ti laakaye ba so. 

Ejo wa niwaju adajo kan, looya to wa n gba ejo odaran ti won fesun kan ro lo waa n fun adajo lowo, to ni ko fi soku baba e, owo ti ki i si i se owo kekere. Lara ohun to n ba wa laye je ni Naijiria niyi. 

Olopaa ko see gbojule, looya ko see fokan tan, iwa ibaje, owo kikoje, agbara nilokulo ti ba aye gbogbo won je, o fo won lori, o si da opolopo won lori ru patapata.


Nibi ti won ti n sejoba to dara, oro yii ko la ariwo lo pupo, won yoo ti gba gbogbo iwe-ase ati gbogbo iwe yoowu ti won fi n pe okunrin yii ni looya kuro lowo re, yoo si ti di korofo lasan titi ti won yoo fi sejo re tan. O si daju pe okunrin yii ko le bo ninu iru ejo bayii niluu oyinbo, yoo ba a rin saa ni. 

Sugbon ni Naijiria nibi sa, ohun ti awon alagbara, awon oloselu atawon eeyan won ba se, asegbe naa ni. Iyen ni Obasanjo se so pe EFCC funra re ti di aja to kan n gbo; ti ko le bu ni je, aja to n gbo lasan ti ko leyin, korofo aja ti ko le da nnkan kan.

Sugbon ki EFCC tile hale, ki won daya ja awon onibaje ile yii, ki won ri i pe awon looya yii sewon, ki gbogbo aye le maa pariwo oruko won. Bi looya ba sewon, ti adajo bii meji tele e, Naijiria yoo daa gan-an ni o. 

Sugbon awa mekunnu ile yii ti ha sowo awon olola ati alagbara ita okunkun, ibi ti won ba aye wa de le ri yii o. Olorun o, afi ko o gba wa lowo won!
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 19:44:04 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"E Ko Sekeseke Si Won Lowo Jare" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: