Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin Lati Owo Akoroyin Olootu

Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun

Leyin orisiirisii awuyewuye, ile-ejo giga ipinle Eko to wa ni Igbosere ti dajo iku fun ogbologboo omo egbe okunkun kan, Adigun Oriyomi, lori esun ipaniyan ti won fi kan an.

Ose to koja nidajo naa waye latenu Onidaajo Oluwatosin Taiwo pe ki won loo yegi fun Oriyomi titi ti emi yoo fi bo lara re nitori pe o jebi esun pe o pa Oluwafemi Adekeye to je ore re lodun 2014.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe o pe ti Oriyomi ti maa n paayan, to si maa n mu un je, sugbon aago re to kun a-kun-wo-sile ni ko se mori bo nigba towo te e pe o gbemii ore re.

Iwadii fi han pe odun 2013 lowo koko te e, iyen lojo kesan-an, osu kesan-an. Nigba ti won wo o de kootu majisreeti to wa l'Ebute-Meta, odaran yii jewo pe omo egbe okunkun Black Axe loun loooto, oun si ti pa orisiirisii eeyan laarin odun 2010 si 2013. Won fi i pamo sogba ewon nigba naa lati gba imoran latodo adari eka eto idajo, sugbon se ni won deede fi i sile lona ti enikeni ko mo, leyii to fi raaye sa lo.

Ninu osu kin-in-ni, odun 2014, la gbo pe oun atawon kan lo saduugbo Amodu, ni Mushin, nibi ti won ti pa Musili Bello ati omo re, Suliat, to je omo odun mejila pelu olokada kan to n je Baba Monday.

Ninu osu keji, odun 2014, ni Oriyomi tun ko awon kan leyin lo saduugbo Ewenla, ni Mushin, nibi ti won ti gbemii Agbabiaka (eni odun mejidinlogoji), Aishat (omo osu merin) ati obinrin kan toruko re n je Adeboye.

Bakan naa loro ri losu keta, odun 2014, ti Oriyomi pa Olufemi Adekeye loju omo re to je omo odun merin. O tun pa awon eeyan mi-in, eyi si je ki esun ipaniyan re po jantirere.

Osu kejila, odun 2014, ni won taari odaran naa lo sile-ejo giga fun esun ipaniyan, sugbon awon olopaa ko ni eri fun awon esun ipaniyan mi-in ti won fi kan an, yato si ti Adekeye.

Omo odun merin ti won pa baba re yii lo rojo tako Oriyomi ni kootu, gbogbo bi adajo si se fi oro wa omo ohun lenu wo lati mo boya ohun ti won ko o lo n so lomo yii ko yese.

Leyin opolopo iwadii ni won mu ejo naa wa sopin lose to koja, nibi ti won ti ni eri gidi lo wa pe Oriyomi pa baba omo kekere ohun, iwa odaju gbaa lo si hu. Eyi waye leyin atotonu Abileko Olayemi Sarumi ati R.O Aroyemu ti won soju ijoba pelu Olanrewaju Ajanaku to rojo fun olujejo.

Onidaajo Oluwatosin Taiwo ni dajudaju, iku lo to si Oriyomi, ki won loo yegi fun un, ki Olorun si saanu fun emi re.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:04:23 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"Eru n Bawon Ara Mushin Nitori Oriyomi Ti Won Dajo Iku Fun" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: