Gbagede Yoruba
 



N'Igbokoda, Tegbon-taburo Ri Ore Meji Mole Laaye Nitori Ti Won Ji Iya Won L
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu Lati Owo Akoroyin Olootu

N'Igbokoda, Tegbon-taburo Ri Ore Meji Mole Laaye Nitori Ti Won Ji Iya Won Lowo

Bi ki i baa se ori to ko awon ore meji kan, Igbekele Orisabinuole ati Ogbaro Erinbo, yo ni, o see se ki eleko orun ti polowo fun won pelu bawon okunrin meji kan ti won je omooya kan naa se ri won mole laaye lori esun pe won ji owo iya won.

Lojo Abameta, Satide, ti i se ojo kejila, osu ta a wa yii, laduugbo Omonira, niluu Igbokoda, nijoba ibile Ilaje, nipinle Ondo, nisele yii ti waye leyin towo kan to je tiya awon afurasi naa, Omoniyi Alaleran ati Oluwaseun Enikuomehin, sonu, tawon omooya yii si so pe awon ore mejeeji ohun ti won koja lagbegbe naa ni won ji i.

Enikan toro naa soju re to ba wa soro so pe ninu soobu ibi ti Abileko Ogunnuga to je iya awon afurasi ohun ti n ta oti ni egberun lona aadoje naira (N130,000) ti dawati nibi tobinrin naa ko o pamo si.

Oro owo to sonu yii lobinrin ohun fi to awon omo re mejeeji leti, o si ni Igbekele ati Ogbaro leni toun fura si. Dipo kawon omo iya naa (Omoniyi ati Oluwaseun) loo fejo sun awon olopaa fun iwadii lekun-un-rere, nise ni won n so awon ore meji naa titi ti won fi ri won mu, ki won too fi lilu se tiwon pe won gbodo jewo ibi ti won kowo iya awon si.

Koda gbogbo bi Igbekele ati Ogbaro se n so pe awon ko mu owo kankan, tawon toro ohun soju won si n so fun won pe ki won loo foro naa to awon olopaa leti, eyin eti Omoniyi ati Oluwaseun lo n bo si.

Nigba ti won si ti lu won titi tawon ore mejeeji naa saa n tenumo on pe awon ko mowo mese lori bowo se poora lo mu ki Omoniyi ati Oluwaseun fipa wo won lo seyin odi ilu, nibi ti won gbe koto kan si.

Won de awon mejeeji lowo, ni won ba wo won ju sinu koto ti won gbe ki won too maa ro yeepe da si koto naa titi to fi de ibi orun awon ore meji ti won ri mole laaye ohun.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe opelope awon eeyan kan ti won loo salaye ohun to sele fawon olopaa tawon yen si tete debe lati doola emi won ni ko je ki Omoniyi ati Oluwaseun pa awon ore ohun. Bee ni won fi panpe oba mu tegbon-taburo ohun lo si tesan won.

Ninu oro alukoro ileese olopaa nipinle Ondo, DSP Femi Joseph, o ni oro naa ti wa nikaawo awon olopaa otelemuye fun iwadii to peye. Bee lo ni iwadii awon agbofinro ti fere pari lori esun naa, ati pe kete tiwadii ba kese jari lawon afurasi mejeeji yoo foju bale-ejo.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:15:37 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu



"N'Igbokoda, Tegbon-taburo Ri Ore Meji Mole Laaye Nitori Ti Won Ji Iya Won L" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com