Tite Wole
  Create an account
Ojule Nyin
Tite Jade
 
 
 
Yoruba

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.

Onka Ni Oju-Agbo

Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi

Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran

E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:


Irohin Nitele-N-Tele


Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
[ Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo ]

·E Waa Wo Simia To Pa Oree Re L'Osogbo o
·Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku
·Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
·Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
·O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
·Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
·Grace Atale Re Pa Oko e N'Iyana-Ipaja
·Oro o, Iku Gbigbona Leleyi o! Nibi Ti Johnson Ti n Taja Loju Titi L'Akure N
·O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo

Ipase Awon Eto L'owoyi

Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.

Ona Igba Wole Si Agbo

Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.

Awon Atoka Ti Atehinwa

Thursday, September 12
· Won Le Awon Omo Nigeria Ni South Afrika Poo!
· O Ma Se O, Eyi Ni Abayomi Adigun, Osise Telifisan AIT Se Ku Sowo Awon Ajinigbe L
· Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
· Amugbalegbe Igbakeji Gomina Ipinle Ogun Se Igbeyawo Alarinrin, Gbegbo Aye Lo N R
· Xenophobia (Ikorira-Ajeji): Irinwo Omo Naijiria Ni Won Ti Gbaradi Lati Fi Orile-
· O Ma Se O, Olajumoke Di Awati N'Ilorin
· Nitori Esun Gbajue, Purofeso Fasiti Foju Bale Ejo L'ekoo
· Won Ju Ayomide Sewon L'Abuja Nitori Esun Jibiti
Sunday, September 01
· Ija Ti Waye Ni Papa Oko - Ofuurufu Ti Abuja: Hammed Tewon De
· Arabinrin Ti Fi Iya Je Omo odo Re Nitori O Ke Pe Iranlowo
· Baba Ti Omo Re Pa Fun Ogun Odun Nitori Warapa
· Nibi Ti Pasito Ti N Waasu Lo Tun Ti Ji Foonu N'Ibadan: Oro Buruku Toun Teri
· Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
· Won Le Awon Omo Naijiria Metalelogun Kuro Ni Saudi Arabia: Iyaale Ile Omo Naijir
· Aye o! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji: O Ma
· Eyi Ni Ashiri Bi Won Se Tan Ismaila Pa L'ojo Odun Ileya
· Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lor
· Hausa Ati Yoruba Koju Ija Sira Won L'ekoo: O Ma She O, Awon Omo Egbe Okunku
· O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
· Arewa Omoge Ji Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Id
· O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
· O Ma She O! Awon Baba Arugbo Fipa Fa Idi Won Omodun Merin Ya Ninu Ile Akoku
· Lojo Odun Ileya, Awon Fijilante Banuje Nitori Okan Lara Nwon To D'Oloogbe
· Nitori Orekunrin Re Ko O Sile, Omodun Merinla Pokunso Ni Delta: Won Ti tu Yewand
· E wo Oju Awon Omo Yahoo Ti Won N Foruko Oshinbajo Ati Aisha Buhari Lu Jibiti
· Ileewe Alakobere Ni Mo Ti N Gbadun Ibalopo, Ko Jo Mi Loju Mo Rara - Oshere Tiata
· Ijoba Ko She E Da She Lai Si Iriri Awon Agbaagba nibe - Gomina Abiodun
· Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
· Aye O! Won Fipa Ba Omoge Arewa Sun Niwaju Shoosshi, Lo Ba Soda Sorun Alakeji
· Aalo Onitan: Ijapa T'ohun Ti Ikarahun Re

Awon Atoka Ti O Ti Pe

Yor b

- Ojule
- Koko Mẹwa
- Ẹka Abule
- Ifirohin-Ransẹ
- Iwadi
- Oju-Agbo Yoruba
- Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba
- Agbeyẹwo
- Ifiranṣẹ Ara-ẹni
- Ifimufilẹ
- Iwe Akọọlẹ
- Apoti Akọsilẹ
- Akoonu
- Isopọ Ọpọnlujara
- Ẹgba Ayelujara
- Ibeere Ti Ọwọpọ
- Ipolongo Wa
- Ẹkun Imọ Ọfẹ


Nitori Airomobi, Toko-tiyawo Padanu Milionu Merinlelogun Naira Sowo Ayederu Doki
 
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise Lati Owo Akoroyin Olootu

Nitori Airomobi, Toko-tiyawo Padanu Milionu Merinlelogun Naira Sowo Ayederu Dokita Ati Aafaa N'Ibadan

Bi iya nla ba gbe ni sanle, kekere a maa gori eni, adia fokunrin onisowo kan, Ogbeni Caleb, atiyawo e to n je Funke ti won n sunkun airomobi, won mu ookan kun eeji, won gba ile onisegun oyinbo lo nitori aajo ati dolomo laye, laimo pe owo ayederu dokita lawon ko si.

Nigba toju won yoo si fi la, won ti padanu owo bii milionu merinlelogun naira sowo ayederu dokita naa.

O jo pe ayederu obinrin dokita ohun, Damilola Ojo, eni topo awon to mo on saaba maa n pe ni Dokita Dammy ti mo iru isoro tawon toko-tiyawo yii ni. Isoro ohun lo fi wole si won lara pelu bo se so fun Abileko Funke pe ogboju dokita to mo nipa itoju awon aisan to n fa airomobi loun i se, oun si setan lati ran won lowo ninu isoro naa pelu itoju to peye.

Awon toko-tiyawo yii n sanwo, Dokita Dammy naa si da opolopo abere bo won nidii laimo pe oogun ori fifo lo fi n wo inu rirun fun won.

Pelu bi dokita gbaju-e yii se mo pe Caleb atiyawo e lowo lowo, o woye pe itoju aisan airomobi toun n se fun won ki i se ona toun le gba ri won lu ni jibiti owo nla, nitori naa lo se fi oro okoowo kan lo won, o ni bi won ba le kowo sile, oun mo ileese to le maa ba won fi owo naa sowo epo lasejere nla, ti ipin ere ti yoo maa kan awon nikan ko ni i din ni milionu kan naira. N lawon eeyan naa ba tun la ori mo on.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe ki i sojulasan ni Dokita Dammy fi n lu awon toko-tiyawo yii ni jibiti.

Ogboju oloogun kan bayii to n je Asifu Ajinikirun, eni to maa n se bii aafaa ni igileyin ogba re. Oogun ti aafaa isonu yii maa n se fun un ni ki i je kawon eni eleni le yi enu pada nigba yoowu to ba ti beere owo lowo won.

Nigba ti Olorun yoo tubo waa fi awon ololufe meji yii le obinrin onijibiti yii lowo pata, otooto lo fi oro okoowo naa lo won, ko si si eni to fi oro naa lo ara won ninu awon mejeeji ti won fi ba a dowo po, ti jagunlabi fi ribi wole si won lara to bee to fi ba won kanle patapata.

Gege bi Abileko Funke funra re se salaye, o ni, ''Nibi eto isin soosi kan ti mo maa n lo nigba kan ni mo ti pade Dokita Dammy. Dokita lo pera e fun mi nigba yen, o ni ileewosan UCH loun ti n sise gege bii dokita to mo nipa itoju airomobi daadaa. Odun kejila ree ti mo ti wa nile oko sugbon ti mo si n woju Olorun fomo, mo si gba pe ko toju mi, o si bere si i fun emi atoko mi labere.

O gba egberun mejilelaaadosan-an naira (N172,000) lowo mi, o gba egberun merindinlaaadorun-un ati igba naira (N86,200) lowo oko mi. Gbogbo igba lo maa n gun emi ati oko mi labere saa. Abere mejila (abere mefa fun okookan won) lo fun awa mejeeji, sugbon mi o tori e loyun ataaro dale ri.

''Nigba to ya lo fi okoowo epo kan lo mi, o ni ki n san milionu kan ati egberun lona igba naira o le aadota (N1.25M) lati fi gba foomu ti mo fi maa le ba ileese yen dowo po. Lojo keta ni mo fun un ni milionu kan ati egberun lona irinwo naira din aadota (N1.35M). Latigba yen lo ti di pe ki n pe e ko ma gbe ipe mi. Nigba to ya lo tie bere si i hale mo mi pe oun maa tu asiri ohun ta a jo dapo foko mi, nitori o mo pe mi o fi oro yen lo oko mi ki n too ba a ni adehun pe ka jo maa sowo epo. Emi naa ko waa duro de igba to maa tu mi lasiiri ti mo fi so foko mi funra mi, mo si toro idariji lowo won.≈ Ase ko tie too di pe Funke pelu Damilola jo dowo po ni oko e ti ko sowo obinrin ayederu dokita yii. Ogbeni Caleb paapaa jewo pe latigba toun pelu Dokita Dammy ti jo n gbe adugbo kan naa loun ti mo on, toun si ba a dowo po nigba to fi kinni ohun lo oun, ati pe nnkan bii milionu mejilelogun naira loun padanu sowo obinrin onibiti yii.

Okunrin to ko sowo ayederu dokita ati ayederu onisowo yii so pe o soro foun lati salaye bi ibasepo oun pelu Damilola se bere nitori okoowo ohun ko wu oun i se nigba naa lohun-un to fi lo oun, sugbon ni kete toun ti orun bo kinni naa loun ti bere si i kowo nla nla le e, ko si sigba tobinrin gbaju-e yii beere owo lowo oun toun ko fun un ko too di pe iyawo oun fi ejo e sun oun nigba to ko si i lowo.

Ogbeni Caleb lo loo fi oro yii to awon agbofinro leti. Kia ni ara ti fu dokita eke yii, n lo ba sa kuro n'Ibadan, o di ilu Ikorodu, nipinle Eko. Sugbon awon olopaa wa a kan nibi to fara pamo si, won si gbe e pada s'Ibadan janto, o di jua latimole.

Ninu iwadii tawon olopaa se fun Damilola lo ti jewo pe aafaa kan to n je Ajinikirun lo maa n ba oun soogun, ati pe oun pelu okunrin naa lawon jo maa n pin owo toun ba gba lowo Caleb atiyawo e nitori okunrin oloogun yii lo ko oun nise jibiti lilu leyin to ti lu oun paapaa ni jibiti opolopo milionu owo naira.

Gege bo se so, ''Mo ti koko lo sileewe Poli ijoba ipinle Ondo, mo si gboye oje wewe (ND) ninu imo ayewo eto ilera. Leyin naa ni mo lo sileewe 'Baptist Medical Centre', to wa niluu Saki (nipinle Oyo) lati kekoo imo nipa ise noosi, sugbon mi o pari nibe ti mo fi pa a ti nigba ti aisan kan kolu mi lo ku bii osu meji ka pari, iyen ni ko je ki n le ba awon egbe mi sedanwo asekagba. Mi o saa pada lo sileewe yen mo.

''Okan ninu awon oga wa to n je Dokita Oyebade nileewe ti mo lo ni Saki lo so pe ki n wa maa ba awon sise gege bii noosi losibitu awon to wa niluu Oyo. Awon naa mo pe mi o kekoo gba iwe-eri ise noosi ti mo fi kuro nileewe. Leyin iyen ni mo waa da osibitu kan sile laduugbo Ologuneru, n'Ibadan. Latigba naa lawon eeyan ti maa n pe mi ni Dokita Dammy. Mo gba dokita kan to n je Olaoye sibe lati maa ba mi toju awon alaisan to ba wa. Egberun meeedogbon naira ni mo n fun un losu.

''Nibi eto ijosin kan ti mo n lo ni soosi kan lodun 2014 ni won ti so mi loruko yen nitori Dokita Dammy ni eni to mu mi lo si soosi yen pe mi fun awon eeyan, oruko ti gbogbo awon omo ijo yen si mo mi si naa niyen.

Ni soosi naa ni mo ti pade eni ti mo koko fun ni itoju aisan kokoro airomobi.

''Mo fi oro obinrin yen lo enikan ti mo mo pe o je akosemose dokita, eni naa ni ki n mu owo wa koun le ba won ra oogun. Nigba ti osibitu ti mo da sile ko lo deede mo ni mo loo ba Aafaa Ajinikirun pe ko ba mi sadura ti osibitu yen fi maa di nla. Aafaa yen lo fi oro okoowo epo lo mi laimo pe gbaju-e loun naa. Owo ti mo fun un to milionu mejidinlaaadota aabo naira (N48.5).

''Nigba ti mo loyun gan-an to je pe ojoojumo ni eje n jade lara mi, mo so fun aafaa, o si gba owo lowo mi, o ni ti oun ba ti toju mi tan, lojo bayii, bayii ni mo maa bimo, sugbon mi o bimo. Aafaa yen kan lu mi ni jibiti ni, oun lo ko mi ni ohun ti mo n se yii.'' Eyi lo mu kawon agbofinro loo fi panpe oba gbe okunrin oloogun ti won n pe ni aafaa yii. Eegun to da bii egungun agbon eeyan pelu orisiirisii egungun gbigbe ni won ba ninu ile re pelu ere ati posi onigi kekere kan.

Nigba to n ba awon oniroyin soro, oga-agba awon olopaa nipinle Oyo, CP Leye Oyebade, salaye pe okan ninu awon gbaju-e ti won fi agbegbe Itire, l'Ekoo, sebugbe ti won n soro fawon ara ibe ko too di pe o ko wa s'Ibadan lokunrin naa. O ni osanyin to n lo ina ni okunrin naa fi n tan awon to ba ba isoro kan tabi omi-in lo sodo e je.

Sugbon Ajinikirun tako oro Damilola, o ni obinrin dokita eke yii gan-an ni onijibiti, oun ko si ba a se okoowo kankan to je mo epo ni toun, ati pe gbogbo owo toun gba lowo e ko ju egberun lona marundinlogorin naira (N75,000) lo. O ni loooto loun maa n soogun nitori boun se je aafaa naa loun tun n se nnkan ibile, ati pe owo baba oun loun ti jogun owo atawon sigidi tawon olopaa ba nile oun.

Okunrin eni odun mejidinlogoji yii salaye pe, ''Nigba ti Damilola waa sadura fun ilosiwaju osibitu re ni mo mo on. Mi o gbo nnkan kan nipa oro okoowo epo, afi lodun to koja tobinrin yen so fun mi pe oun gba milionu mejilelogun naira lowo awon kan ti oun n ba sowo, won si ti n yo oun lenu pe ki oun mu awon lo sodo awon to ni ileese toun so pe won n sowo naa. Bo se so o ni mo ti mo pe iro lo n pa nitori mo mo pe ko see se keeyan kowo to to bee yen sile fun okoowo kan lai da eni ti won jo n sowo ohun mo.

''Nnkan to fe ki n se foun nigba yen ni oogun ti ko ni i je kawon eni yen le beere owo won lowo e mo. Awon eeyan si ti so fun mi tele pe gbaju-e lobinrin yii, nitori e lemi ko se yaa gba kobo lowo e. Owo ti mo gba lowo e ko ju owo ti mo fi ba a sadura lori osibitu re lo.'' Nje bawo ni eegun eeyan ti awon olopaa ba ninu ile e se je, okunrin aafaa to tun n soogun yii so pe niluu Benin loun ti ra eegun naa pelu awon nnkan etutu mi-in, ati pe oogun etutu ola lo wulo fun, bo tile je pe oun ko ranti ise ti eegun eeyan ohun n se daadaa mo nitori o pe toun ti ra a sile toun ko lo o.

Sa, CP Oyebade ti i se oga-agba awon olopaa nipinle Oyo ti so pe laipe ni oun yoo foju ayederu dokita ati ayederu aafaa yii ba ile-ejo.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:28:13 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

"Nitori Airomobi, Toko-tiyawo Padanu Milionu Merinlelogun Naira Sowo Ayederu Doki" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: