Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo
 
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu Lati Owo Akoroyin Olootu

Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo

Baa ti n koroyin yii, atimole ileese olopaa ipinle Ondo lomokunrin kan toruko re n je Sunkanmi ti n ran awon olopaa lowo lori iku airotele to fi pa okunrin kondokito kan to n je Ojo lasiko tawon mejeeji fija peeta.

Isele naa sele ni gareeji Oloko to wa loju ona marose IlesaÍOwo, niluu Akure, nibi ti won so pe Iya Sunkanmi ti n ta ounje.

Gege bi alaye ti okan ninu awon awako to n sise ni gareeji ohun se fun wa nigba ta a sabewo sibi isele naa, iresi sise nikan ni Iya Sunkanmi n ta ninu gareeji ohun. Sugbon lojo tohun buruku yoo sele ni gareeji naa lo da bii eni pe iresi ti Iya Sunkanmi n ta ko wu Ojo i je, idi si ree to fi lo sile olounje mi-in ti ko fi bee jinna sibe.

Ojo ra iyan to wu i je, bee lo gbe iyan ohun wa segbee soobu Iya Sunkanmi lati je e nibe.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe nibi ti Ojo ti n jeun lowo ni Iya Sunkanmi ti bere si i soko oro si i pe ko letoo lati maa je ounje to loo ra lati ita ni soobu oun, niwon igba to ko lati ra ounje lowo oun.

Oro naa la gbo pe won n fa mora won lowo titi ti esu fi ba won lowo si i, to fi dohun ti won n fowo ba ara won lara. Pelu ibinu ni won ni Iya Sunkanmi fi ranse somo re, iyen Sunkanmi, to n sise foganaisa pe ko tete maa bo waa ba oun da seria fun Ojo to ri oun fin.

Bi Sunkanmi se de gareeji naa lo kolu Ojo ti iya re so pe o wo oun loju mobi to wa, sugbon ti Ojo jewo ohun ti won n pe lokunrin fun un pelu bo se fi lilu dabira si i lara. Ohun tawon eeyan maa ri leyin ti Sunkanmi fi Ojo sile ni igo kan to fo mole poo, kawon eeyan si too mo ohun to n sele, o ti gbe afoku igo ohun le Ojo nikun.

Nigba tawon toro ohun soju won yoo fi gbe Ojo deleewosan, okunrin naa ti dagbere faye, oku e ni won si gbe de osibitu naa, nibi ti dokita ti fidi re mule pe loooto ni Ojo ti ki aye pe o digboose.

Loju-ese la gbo pe awon olopaa ti nawo gan Sunkanmi, akata won lo si wa titi di ba a se n ko iroyin yii jo.

Nigba ta a kan si alukoro ileese olopaa ipinle Ondo, DSP Femi Joseph, lori ago lati fidi isele yii mule, o so pe oun ko si lofiisi lakooko naa, ilu Owo loun wa.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:36:35 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

"Nibi Ti Sunkanmi Ti N Gbeja Iya Re Lo Ti Gun Ojo Nigo Pa l'Ondo" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: