Gbagede Yoruba
 



Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise Lati Owo Akoroyin Olootu

Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin

Afaimo kawon okunrin meta kan, Wasiu Alayande, to je eni odun mejidinlogbon, Fayose Ebenezer to je eni odun mokandinlogun ati Adeleke Adewale, eni odun mejilelogun ti won filu Ekiti sebugbe ma faso penpe roko oba niluu Ilorin pelu bi ileese olopaa ipinle Kwara se wo won lo sile-ejo lori esun igbimo-po lati sise ibi ati nina owo ayederu.

Nigba to n rojo tako won lojo Isegun, Tusde, ose to koja, Inspekito James Wodi to gbenuso fun ileese olopaa so pe arabinrin olutaja kan toruko re n je Funke lo mu esun to ileese olopaa wa pe soobu oun to wa ni Erin-Ile loun wa ti Ebenezer ati Wasiu ti won wa lati ipinle Ekiti fi waa ra miliiki ati ose iwe tiye owo re je igba naira. O ni obinrin naa se e lalaye pe egberun kan naira (N1000) lawon afurasi naa gbe le oun lowo, toun si fun won ni senji egberin naira (N800.00).

James tesiwaju pe kete tawon afurasi yii kuro ni soobu Funke lobinrin kan toun naa n taja nitosi soobu e waa ta a lolobo pe awon okunrin meji to sese kuro lodo re yii ti waa raja lodo oun, sugbon oun sese sakiyesi pe owo ayederu ni won na foun ni. Ayewo ti Funke se sowo ti Wasiu ati Ebenezer fun un lo je koun naa mo pe ayederu lowo ohun, leyii to mu un figbe bonu, ko si pe sasiko naa lowo te awon afurasi mejeeji yii, ti won si fa won le ileese olopaa lowo.

Ninu iwadii awon olopaa ni Wasiu ti jewo pe Ebenezer lo fun oun lawon owo ayederu yii pe kawon na an, ti Ebenezer naa si jewo pe okunrin kan to n je Adewale Adeleke to n gbe ni Ikoro-Ekiti lo se awon owo ayederu naa foun.

Sa, ileese olopaa to n topinpin iwa odaran nipinle Kwara fidi re mule pe awon afurasi yii gbadun fifi owo ayederu sowo pelu awon eeyan, esun yii si ni Inspekito James Wodi fi kan awon mejeeji ati eni to se owo naa fun won ni kootu.

Sugbon awon olujejo yii lawon ko jebi esun naa, bee lagbejoro won ro adajo lati siju aanu wo won nitori ti won je omode.

Adajo M.A Ndakene salaye pe esun ti won fi kan won lagbara pupo, bee ni ki i se eyi to see gba beeli si, nitori e lo se pa a lase pe ki won loo fi won pamo satimole ogba ewon Mandala to wa niluu Ilorin. O sun igbejo won sosu to n bo.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:41:30 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise



"Lati Ekiti Ni Wasiu Atawon Ore Re Ti Waa Fi Owo Ayederu Raja n'Ilorin" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com