Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Lati Owo Akoroyin Olootu

E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?

Orisiirisii leeyan yoo maa ri, beeyan si n wa olori awon alawada bi ko ba ri i, bo ba ti ri Gomina Ekiti, Ayodele Fayose, ko sinmi a n rin igboro kiri mo, oga awon alawada patapata lo ti ri yen. Ni gbogbo ose bii meji meta seyin, nise ni Fayose n soro to n laagun, to n kuru to n ga, to n bu eebu to n fepe bonu, inu e ko dun rara pe Aare Muhammadu Buhari fee lo si China. 

O ni ki lo n wa lo, oun gbo pe o fee loo yawo, ko jokoo sile ko ma yawo kankan, ati pe nigba ti Naijiria ko fararo, ko si onisowo ile China kan ti yoo wa si Naijiria lati waa fi owo re da ise sile, nigba to ti mo pe oun ko le ri ere kankan je.


Awon eeyan mi-in ri oro gidi ninu ohun to n ti enu re jade, won ni loooto sa ni, ewo ni agbada guoguo ti Baba Buhari paapaa n ko jade ti ko fidi mole, oro lokunrin Fayose yen n so jare. 

Sugbon nigba ti Fayose funra re yoo fi ainitiju awon oloselu han, ati bi oro won ko se see tele to, oun naa gbera irinajo, okunrin naa ko si ri ibomiran ti yoo lo ju China to n tori e bu Buhari yii naa lo. 

Koda Buhari to n bu ko ti i de ti oun naa ti gbera, afi bii eni pe Buhari lo n wa lo sohun-un, bee ni eto kan ti ko le se Ekiti ni anfaani kan ni oun tori re lo, o ni won n se Trade Fair, afihan oja okoowo fun awon ileese, oun naa waa ni oun n wa awon ti yoo waa da ileese sile l'Ekiti lo.

Se oro niyen nigboro enu! Raurau, kantankantan, ati airikansekan. Fayose, o je yaa sora e, nitori bi awon aja Buhari ba gba o mu, won yoo deyin de o ti o ko ni i ribi yo o, tire yoo si le ju ti Saraki yii lo.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:43:21 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"E Gbo! Kin Ni Fayose Wa Lo Si China?" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: