Gbagede Yoruba
 



Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein
 
Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue Lati Owo Akoroyin Olootu

Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein

Ojo gbogbo ni tole, ojo kan ni tolohun. Owe yii lo se mo awon afurasi odaran merin kan towo ileese olopaa ipinle Kwara te pe won maa n gba ogunlogo owo lowo awon araalu pe awon yoo ba won wa ise ijoba nipinle naa, to si je pe ogbon ati ete lati lu won ni jibiti ni.

Ojo Isegun, Tusde, ose to koja ni ileese olopaa ipinle Kwara safihan awon afurasi odaran mereerin naa fawon akoroyin pelu esun pe nise ni won ka awon ayederu leta igbanisise awon ileese ijoba apapo ati tipinle Kwara mo won lowo.

Lara awon leta naa ni ti ajo to n ri si irin-ajo Hajj lorile-ede yii (Nigeria Hajj Commision), ileese 'Nigeria Port Authority', ileese 'Kwara State Teaching Service Commission', 'Kwara State Universal Basic Education Board', ajo SUBEB atawon mi-in.

Komisanna olopaa nipinle Kwara, Sam Okaula, eni to safihan awon afurasi odaran naa lojo Isegun, Tusde, ose to koja ni olu-ileese awon olopaa to wa nipinle Kwara so pe nise ni owo te awon odaran yii lawon adugbo bii Gaa-Saka ati Oke-Fomo, ti gbogbo re wa niluu Ilorin.

Okaula salaye pe awon afurasi towo olopaa te naa ni: Taiwo Abdulwahab, eni odun mejilelogbon; Ajidagba Ibrahim Abdulrasaq, eni odun mejidinlogoji; Tajudeen Adebayo, eni odun metadinlaaadota; ati Tajudeen Hussein, eni odun mejilelogoji. Komisanna naa salaye pe iwadii ileese olopaa fi han pe awon afurasi naa ti ri to milionu merin naira ninu ise ati iwa odaran ti won yan laayo.

Egberun lona ogoji naira (#40,000.00) si egberun lona aadorin naira (#70,000.00) ni awon afurasi odaran yii maa n gba lowo awon ti won ba fee se ayederu leta igbanisise fun ni awon ileese ijoba ipinle, (state appointments), ti won si maa n gba owo to to egberun lona igba naira (#200,000.00) si egberun lona oodunrun ataabo (#350,000.00) fun ti ileese ijoba apapo fun awon araalu to ba ko si panpe won.

O fi kun un pe ise buruku tawon obayeje eda yii yan laayo ti je ki awon ayederu osise po lo jantirere ni awon ileese ijoba ipinle Kwara, eyi to si je ki ayewo ti ijoba ipinle naa n se fawon osise re bo si asiko to to ati eyi to ye lati gbe iru igbese bee.

Nigba ti Hassan atawon ore re n ba akoroyin wa soro, won salaye pe milionu merin pere ni gbogbo owo tawon ti ri ninu ise ti awon n se naa, ati pe ainiselowo lo mu awon seru nnkan bee.

Sam Okaula to je komisanna olopaa ipinle Kwara ti waa seleri pe oun yoo ri i daju pe oun sin awon obayeje yii de ile-ejo, nibi toun yoo ti rojo tako won.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 21:37:08 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue:
O Ga O! Awon Olopaa Ati Adigunjale Fibon Para Won Loju Ija Niluu Ibadan: Awon Ol


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue



"Milionu Merin Pere La Ri Latigba Ta a Ti n Lu Awon Eeyan Ni Jibiti - Hussein" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com