Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia

Ale ojo Eti, Fraide, ose to koja, ti i se ojo keeedogun, osu yii, niroyin gbale pe alaga fegbe oselu PDP nijoba ibile Ipokia, nipinle Ogun, Alaaji Saruku Suraju, tawon eeyan mo si Aro meta ku. Iku naa ko ba si ma mu kayeefi dani ju bee lo ka ni ki i se pe oteeli ni baba eni odun mejidinlaaadorin naa ku si, won ni asewo ni alaga naa ba se sunle-sunle to fi gbona orun lo.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, nnkan bii aago mesan-an ale ojo naa ni gudugbe ja ni oteeli kan ti won n pe ni 'De Lover Hotel' to wa laduugbo Aseko, Ibatefin, ni Ipokia, nibi ti won ni okunrin to je alaga egbe PDP titi di akoko iku ojiji naa dagbere faye si. Ohun tawon tisele naa soju won salaye fun wa ni pe ipade kan ni Suraju n lo lojo naa tobinrin kan ti won pe ni orebinrin re fi pe e lori aago pe ko yoju soun ni oteeli De Lover, won ni bo si se gba ipe naa tan lo yipada ti ko lo sipade ohun mo, odo obinrin to pe e naa lo gba lo.

Abajade oteeli to lo naa ni oku re tawon eeyan pada ri ninu yara toun ati obinrin naa lo, bee ni nigba ti won yoo fi mo pe baba naa ti dagbere faye, obinrin to da wahala ohun sile ti fese fe e. Iyen lawon kan fi so pe ibalopo agbara lo waye laarin Aro meta ati obinrin naa to ja siku, bee lawon mi-in so pe o see se ko je pe won fun un lorun pa sibe ni.

Alaga yii la gbo pe eto ti bere lati we lawani fun gege bii 'Giwa Adinni' Mosalasi apapo Ibatefin, sugbon lojiji ti won gbo iku re ni won dawo eto ohun duro.

Enikan to soro nipa iku to pa Aro meta sugbon to ko lati daruko ara e so pe oju Oluwa nikan lo to iku to pa baba naa, loooto lo je pe obinrin lo pe e to fi lo sileetura, sugbon eni ti ko ba wa de yara ko mo ohun ta a se. O ni obinrin to sa lo naa pelu oku orun funra e lo mo ohun to sele laarin won, boya ibasun lo mu iku wa, boya bee si ko, enikan o mo, sugbon oun ko fee soro buruku nipa okunrin to ku yii. O ni o daa ki kaluku maa wo ohun ti yoo sele leyin iku re ni.

A tile gbo pe Aro meta ko niyawo nile rara ko too salaabapade iku re yii, oun nikan naa si lawon obi re bi. Sugbon awon eeyan kan ko yee naka abuku si awon eeyan ti won jo wa ninu egbe PDP nijoba ibile Ipokia, won ni ipo alaga ti oloogbe naa wa n bi won ninu, ati pe baba naa n gbiyanju ati tun pada sipo naa leekeji, awon mi-in tawon naa si fee di alaga ko fe ki eyi waye, won lo see se ko je odo iru won niku Suraju ti waye.

Ojo keji isele naa ni won ti sin okunrin yii nilana esin Musulumi, sugbon awon eeyan ko yee so pe oteeli ni Suraju, alaga ijoba ibile Ipokia ku si.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 21:40:34 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Won Ni Alaga PDP Ku Sori Asewo N'Ipokia" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: