Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibadan
 
 
Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibada

Die lo ku ki ori ko lagbaja yo, Oloun ko ni oluware i yo ninu ewu ni. Patapata ni ori ko omodebinrin eni odun metadinlogun kan, Adegoke Bukola, yo lowo iku ojiji leyin to ti ko sowo awon agbenisowo ti won si ti fun un loogun je.

Bukola, eni ti a fi ojulowo oruko e bo lasiiri lo ko si pampe ife etan lojo Aiku, Sannde, ojo ketadinlogbon, osu keta, odun yii, pelu bo se tele orekunrin re to n je Onuigbo Chibuike atawon ore e jade loo se faaji laimo pe ero iku lawon omokunrin naa n ro si i.

Gege bi oga-agba awon olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade se so fawon oniroyin n'Ibadan lojo Eti, Fraide, to koja, lojo odun Ajinde awon Kristeni to koja yii ni Bukola loo pade orekunrin e laduugbo Iwo Road, n'Ibadan, lasiko to ye ko wa pelu iya e ni soosi fun poposinsin odun.

Ile oti ni won koko gbe e lo, leyin ti won si ti gbiyanju lati fipa ba a lasepo sugbon ti igbese ohun ko seso rere ni won fi oogun sinu oti fun un ko too di pe won gbe e lo si ojule karunun, opopona Galili, laduugbo Olodo. Asiko ti oogun ohun bere si i sise lagoo ara e ni Olorun fi awon ode to n so adugbo ohun se angeli re lati ko o yo lowo iku ojiji.

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, Chibuike ti n fi ede Igbo pe onisegun re ti won n pe ni Oladimeji Babatunde Ajala lori ero ibanisoro pe owo oun ti ba enikan laimo pe awon ode agbegbe ohun wa nitosi. Oro yii lo ta si okan ninu awon ode oun leti ti iyen fi yo si won lojiji, to si fi olopaa mu awon afurasi odaran naa.

Nigba to n royin ohun ti oju e ri lowo orekunrin re to n je Chibuike yii pelu awon emewa e, Bukola to je akekoo olodun karun-un nileewe girama kan niluu Abuja, sugbon to waa sodun Ajinde pelu awon ebi e n'Ibadan so pe lasiko ti iya oun wa ni soosi fun odun lokunrin naa pe oun pe ki awon jo loo se faaji odun die nigboro.

''Iwo Road lo ti ni ki n waa pade oun pelu ore e kan. Chibuike lo wa moto, bi won se de ibi ti mo ti n duro de won lo ni ki n wole. Ba a se n lo ni eru bere si i ba mi nitori o da bii eni pe won ti enikan mo inu buutu moto, ti nnkan ohun n runra wuruwuru nibe, sugbon mi o soro nitori eru n ba mi.

''Ba a se de ile oti kan lo so pe ki emi ati ore oun sokale ninu moto ka maa niso nile oti yen ka maa muti lo, pe oun fee sare debi kan. Nigba ti ore e bi mi leere pe kin ni mo fee mu, mo ni Maltina, o ni bawo ni mo se maa mu Maltina nigba ti oti gidi wa nile. O ni kaka ki n mu iyen, oun ko yaa ni i ra nnkan mimu kankan fun mi ni. Mo ni nnkan ti emi maa mu niyen, o te mi lorun ki n kuku ma mu nnkan kan nigba yen. O ni ko si nnkan kan ti sitaotu maa se fun mi ti mo ba mu un, o saa tan mi titi ti mo fi gba lati mu igo sitaotu.

''Nibi ta a ti n muti lowo ni Chibuike atawon meta kan ti de. O ni ore oun ni won, sugbon emi o ri i ri. O ni okan ninu won fee ba mi soro, mo ba dide loo ba a. Iyen ni oun fee ba mi lasepo, nise laya mi la gaara nitori o ya mi lenu pe Chibuike le mo-on-mo fa mi le ore e lowo pe ko ba mi lasepo. Mo saa dogbon puro fun iyen pe mo n ri alejo mi lowo, o ni ko si wahala, pe ki n je ka jade sita loo ba awon yooku nibi ta a ti jo wa. Ase nitori mi lo se gba yara yen pelu egberun meta naira tele.

''Ba a se pada si odo awon yooku ni Chibuike so pe ka kuro nibe, ka maa lo si ibomi-in.

Mo saa mu iyooku oti mi ti mo mu ku tele. Nigba ta a debe, o bere si i pe enikan lori foonu, sugbon nomba iyen ko lo. Nigba to ya lo ni ka pada si ile oti ta a koko lo ni Iwo Road. Okan ninu awon ore e so pe ki n loo ba oun ra nnkan wa, ki n too de, mi o ba Chibuike mo, awon ore e ni o ti lo, o si gbe baagi mi naa lo. Mo pe e, o ni ki n gbe okada waa ba oun nibi kan, bo se juwe ibi to wa fun olokada to gbe mi loo pade e niyen.

''Nigba ti mo de ibi to juwe fun mi, mi o ba a nibe, mo tun pe e, ko tun gbe e. Nibi ti mo ti n duro de e lawon okunrin kan ti waa ba mi ti won bere si i fowo kan mi, bi mo se pariwo niyen. Asiko yen ni mo ri i ti oun naa n bo loookan, bo se fa mi lowo niyen to ni ki n je ka maa lo sile oun, sugbon mo ni mi o lo, mo ni mama mi ti n pe mi nile.

''Gbogbo bi mo se yari pe mi o ni i ba a lo sile yen, nise loun naa faake kori pe mo saa gbodo tele oun ni. Bo se pe enikan lori foonu niyen to bere si i fi ede Ibo soro. Bi okan ninu awon ode to n so adugbo yen se waa ba wa niyen to so pe oun gbo gbogbo nnkan ti Chibuike n so lori foonu. Asiko yen ni mo daku ti mi o mo nnkan to n sele mo.

''Ileewosan ni mo laju si, nibe ni won ti so fun mi pe se ni won fun mi ni nnkan je. Won ni inu oti ti mo mu ni won fi nnkan naa si.'' Sugbon nise ni Chibuike tako gbogbo alaye ti Bukola se, o ni oun ko gbero lati se e nibi, ati pe nigba ti omobinrin yii fi oun atawon ore oun sile nibi tawon ti jo n se faaji to bere si i loo ba ore e kan rojo loun kuro nibe toun si ba a gbe baagi re lowo ko ma baa poora.

Gege bi okunrin eni odun metadinlogoji to pera e ni ontaja awon eroja ikole yii se so, ''Nigba to pe mi, mo ni ko waa gba baagi yen nile. Nibi ti mo ti fee gbe baagi yen fun un lo ti daku.'' Ninu awijare tie, Ajala so pe oun ko mo nnkan kan to pa Chibuike ati Bukola po, oun ko si mo nnkan to sele laarin won ni nnkan bii aago mokanla aabo ale ti omobinrin naa fi daku, ati pe awon agbofinro kan deede waa mu oun nile ni.

Sa, awon afurasi odaran mejeeji yii si wa lahaamo awon olopaa pelu awon oogun abenugongo ti won ka mo won lowo, nibi ti won ti n ran awon olopaa lowo ninu iwadii won.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 21:45:58 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose:
Iru Pasito Radarada Wo Waa Ni Oluso-Aguntan Oyelami Yii Gbogbo Awon Omobinrin Ij


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

"Orekunrin Bukola Fee Fi i Soogun Owo N'Ibadan" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: