Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.
Onka Ni Oju-Agbo
Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi
E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi
Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran
E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:
Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.
Ona Igba Wole Si Agbo
Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.
Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
Alashewo Lo Po Ju Ninu Tiata - Igbanladogi Ju Bombu Oro Sita
Gbajugbaja oshere tiata nni, Oloye Binta Ayo Mogaji Oduneye, topo awon eeyan mo si Igbanladogi ti ju bombu oro sita, o ni alashewo lo po ju ninu awon oshere tiata lorile-ede Naijiria, eyi to je ki won maa wo asho iwokuwo lori itage.
O ni bi ki i ba a she pe alashewo pombele ni won ni, ko ye ki obinrin to ba ni oko gidi nile, to bimo, to si ni ebi rere de idi ishe tiata, ko wa lo maa shi ara re sile tabi she afihan ihooho re bi Olorun she daa sita.
Ayo Mogaji soro naa lasiko to n kopa lori eto ileeshe telifisan kan ni Naijiria laipe yi, to si tu peere-peere oro nibe.
Binta Mogaji ni imura eeyan kan nigboro ni nkan she peluu idile to ti jade wa ati iwa omoluabi to ni, ti yoo si mu ko le ronu jinle pe iru oju wo ni aye fi n wo oun.
O so siwaju pe oun korira ki obinrin maa shi ara re sile lasiko to ba n shere itage, lati igba ti oun si ti bere ere tiata, aye ko ri ihooho oun ju ejika oun lo.
Nigba to n dahun ibeere to nii she lori awon obinrin onitiata to n shi ara won sile lati polowo oshe tabi ipara to n bo ara, Ayo Mogaji salaye pe, ti eeyan ko ba maa polowo sinima onihooho tabi asho ti won fi n luwe, taa mo si Bikini, ko si idi kankan fun obinrin lati shi ara sile, fi polowo oja kankan tabi fi fa oju awon onibara re mora, nitori oju lasan ti to lati polowo oshe tabi ipara.
O ni iwa ara bibo to wopo laarin awon oshere tiata lokunrin ati lobinrin lode iwoyi, ni ko ba oju mu, awokoshe shaa ni awon je lawujo, bee si ni ohun ti eeyan ba ni lopolo lo ja ju, kii se afihan oyan, idi abi ara bibo.
Igbanladogi to ti n sunmo ogoji odun to bere ishe tiata so pe opo igba ti oun ba wa ni enu ise, ni oun maa n tako abala ere to ba gba koun shi ara sile tabi wa ni ihooho, bee ni enu oun kii duro lati gba awon oje wewe akeegbe oun nimoran pe ki won dekun shishi ara sile, tori eyi ko bojumu fun omoluabi ati asha Yoruba.
Lori awon sinima to nii she pelu afihan ihooho ati iwa jagidi jagan abi lilo ibon, O ni "Asha alasha ni a n ko pelu shishe fiimu onijagidijagan eyi to lodi si asha, ishe ati ohun ajogunba wa lorile-ede Naijiria, idi si ree ti iwa ipanle she n po si lorile-ede yii."
Binta Ayo Mogaji, lasiko to n fesi lori bi awon oshere tiata lode iwoyi she n ri owo nidi ishe naa ju awon oshere tiata aye atijo lo ninu eyi ti Binta wa, osherebinrin naa ni, ohun ti onikaluku fi n jeko, abe ewe lo wa.
"Awon osere tiata ti e ro pe won n ri owo pupo lasiko yii ju asiko tiwa lo, she inu ishe tiata yii naa le ro pe won ti n ri owo pupo naa lati fi ra awon oko nla-nla ati awon ile awoshifila ti e ro pe won ni yii?
"she e ko ro pe 'ebun' ko ni awon ile ati oko naa, ti kii si i she inu ishe tiata ti won n she ni owo ti won fi ra awon ohun meremere yii ti wa?"
Lakotan, o ro awon akeegbe re lati maa she ere to mu ogbon lowo, ti yoo she agbelaruge asha ati ishe wa, ti yoo si ko awon araalu leko gidi, nitori awokoshe rere lo ye ki awon onitiata je lawujo wa.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Sunday, September 01 @ 03:23:03 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.