Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.
Onka Ni Oju-Agbo
Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi
E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi
Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran
E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:
Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.
Ona Igba Wole Si Agbo
Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.
Ohun to n sele si awon omo Naijiria ti won wa ni orile-ede South Afrika bayii ni ko sele nibi kan ri, gbogbo arinrin-ajo to je omo orile-ede Naijiria ko lo sibi kan ti won ti n pa won, ti won si n fi kumo ati ohun ija oloro mi-in le won jade. Loooto ni bii odun 1970, nigba to di pe eto oro aje won fee maa denu kole ni orile-ede Ghana, won le awon omo Naijiria ti won wa nibe, won ni ki won maa pada lo si ile won. Won le won tiletile ati teruteru won, awon miiran to si ri se daadaa nibe, won o je ki won gbe awon ileese won. Nigba naa ni kinni naa di orin bayii ni ile Yoruba pe: 'Kin ni n oo je gbagbe ile mi, kin ni n oo je gbagbe ile mi, ero Ghana ti ko mi logbon, ero Ghana ti ko mi logbon, kin ni n oo je gbagbe ile mi!' Awon ara Oke-Ogun si so orin naa di ijo, ti won n ko o pe 'Tile-tile loko ko won wa o, tile-tile loko ko won wa, ero to lo si Ghana, tile-tile loko ko won wa!'
Sugbon nibi ti oro naa mo niyi, ko senikan to pa enikan, ko si si eni to fiya je won, ijoba lo sofin pe ki onikaluku maa lo sile re. Bee naa loro si ri ni odun 1984 si 1985, nigba ti eto oro aje Naijiria funra re sese fee maa denukole, ti ijoba ologun awon Muhammadu Buhari ati Tunde Idiagbon si sofin pe ki awon omo Ghana ti won ti kun Naijiria fofo nigba naa maa waa lo sile. Ijoba Naijiria se e debii pe won wa moto ti yoo ko awon eeyan naa, koda won tun fun awon mi-in lowo ninu won. Ko senikan to lu omo Ghana kan, tabi ti won gun won lobe, ka ma ti i so pe won yoo pa won. Ohun to se n ya gbogbo aye lenu pe awon omo orile-ede South Afrika n se bayii si awon eeyan wa, ti won mura lati pa won ti won ba ri won, ti won si n fiya to ba wu won je won, latari pe won ni ki won kuro ni orile-ede awon. Iyato eyi ni pe ki i se ijoba South Afrika lo sofin.
Ohun ti awon eeyan n so saa ni pe ijoba orile-ede naa ko le so pe oun ko mo tabi pe oun ko lowo si ohun ti awon eeyan yii n se. Koda, awon egbe ijo Katoliiki nibe so pe ki ijoba ma puro mo pe oro naa ki i se ti eleyameya, tabi oniluumolu, won ni ki won fi iro ti won n pa sile pe awon odaran ni won n le jade. Won ni bo ba je odaran ni won n wa, se ko si odaran omo orile-ede South Afrika ni, bo ba si je awon ti won n ta oogun oloro ni won n wa, ki lo de ti won ko lo si odo awon omo South Afrika to je gbogbo eeyan mo pe ise ti won n se niyen. Ki i se awon ijo Katoliiki yii nikan ni won soro ni South Afrika, awon mi-in naa da si i, won si fesun kan ijoba won pe o n gbe leyin awon adaluru ti won n fiya je awon omo Naijiria, ti won si n pariwo pe ki won jade. Sugbon nibi ti oro naa le de bayii, ko jo pe apa ijoba paapaa ka a mo rara, iyen ijoba won lorile-ede South Afrika.
Won ti n se kinni naa tipe, sugbon eyi ti won se gbeyin yii le die, nitori won ba nnkan je ju bo ti ye lo, bee ni won si pa opo eeyan, ijoba orile-ede naa ko si ri awon odaran kan mu. Ni awon ilu to wa ni agbegbe Johannesburg, ni ija naa ti bere ni ojo kin-in-ni osu ta a wa yii, sugbon won o pana re titi di ojo keji, osu yii, nigba ti yoo si fi di ojo keta, awon onijangbon naa ti wo ilu Johannesburg, ilu kan to da bii Eko tiwa yii, to je nibe ni okoowo orisiirisii ti n lo. Nigba ti won de Johannesburg yii, nnkan yipada lesekese, nitori bi won ti n kan awon soobu to je ti awon omo Naijiria ni won n duro, ti won si n kolu awon soobu yii, ti won n fo won, ti won si n ji gbogbo oja to ba wa ninu re ko lo. Awon kookan ninu awon omo oniwahala yii ti won ti da awon omo Naijiria kan mo, ile won, tabi soobu won, tabi idi moto won ni won n lo.
Ki oloju too seju, won yoo ti ba moto naa je, tabi ki won ji gbogbo ohun ti won ba le ta lara re yo, onimoto to je omo Naijiria naa yoo si ti sa lo. Bee ni won fi bii ojo merin si marun-un ja ija naa, ti awon ijoba orile-ede naa ko si ri enikeni mu ninu awon omo won to n dalu ru, ti won si n fiya ainidii je awon alejo to wa lodo won. Oro naa dija laarin awon orile-ede mejeeji paapaa, nitori ijoba Naijiria binu. Awon omo Naijiria mi-in funra won naa binu, ti won kolu ileese ti won ro pe ti awon ara South Afrika ni, iyen Shoprite ati MTN, won si mura lati ba won je. Ohun ti won ko mo ni pe opolopo awon ti won n sise ni awon ileese wonyi, awon omo Naijiria bii tiwon ni. Nigba ti awon ara embasi ri i bi kinni naa ti n lo, iyen ileese to n soju ijoba South Afrika ni orile-ede yii, kia ni won ti embasi naa pa, ti awon osise ibe si sa kuro, nitori won o mo ibi ti awon omo Naijiria le gba yo si won.
Ijoba Naijiria naa si ti seto ni embasi tiwon to wa lohun-un pe omo Naijiria to ba setan ti yoo lo sile, awon yoo seto bi won yoo se ko won pada. Nigba naa ni ileese oloko-ofurufu Air Peace ni gbogbo omo Naijiria to ba fee wale pada, ofe lawon yoo ko won lati ohun wale. Awon alase embasi Naijiria ni South Afrika si ti kede pe Ojoruu, Wesidee, ni won yoo maa bere si i ko awon eeyan naa, nitori bii irinwo (400) lo ti foruko sile lale ojo Satide to koja yii pe awon fee lo sile, awon o gbe South Afrika mo, nitori won ti ba gbogbo okoowo ti awon jokoo ti nibe je, awon o si le je ki won waa gbemi awon lojiji. Aare orile-ede naa paapaa, Cyril Ramaphosa, ranse si Aare Muhammadu Buhari pe iru nnkan bee ko ni i sele mo, awon yoo wa ogbon da si i, pe awon aare mejeeji lawon yoo jo yanju re. Nigba ti Buhari si gbo eyi, o mura pe oun yoo se abewo si orile-ede naa losu to n bo.
Sugbon iyen ni won n so lowo nigba ti wahala tun ru jade lojo Sannde. Okunrin ajijagbara kan to tun je olori egbe oselu nibe, Mangosuthu Buthelezi, lo pe ipade, to si ni oun yoo ba awon omo orile–ede naa soro. Nibi ipade yii ni won ti bere si i pariwo le e lori, ti won ni ko fi awon sile, kia lawon ero si ti bere ariwo, n lawon omo South Afrika ba tun ya sigboro, ariwo ti won si n pa ni pe 'A ko fe alejo! A ko fe alejo o! A ko fe alejo nile wa o! Ki onikaluku yin gba ilu e lo!' Kia loro naa ti di rogbodiyan, ti won si ti pa eni kan lesekese, ti awon marun-un mi-in si farapa yannayanna. Iroyin ti ALAROYE gbo ni pe ki i se awon eeyan mi-in lawon omo South Afrika yii dojuko gan-an, Naijiria gan-an ni won fe ki won kuro ni orile-ede awon, won ni awon ko fe won mo. Awon omo Naijiria paapaa naa si mo, ninu iberubojo ni pupo ninu won wa, won n wa gbogbo ona lati pada sile ni.
Awon miiran ninu awon eeyan yii so pe awon ko le waa ku si ilu oniluu, ohun yoowu to ba wa ni South Afrika, awon yoo fi i sile ki awon maa pada bo ni orile-ede tawon. Awon omo South Afrika si ree, awon ti ni awon ko ni i gba ki omo Naijiria kankan duro, won ni awon ko fe alejo bii tiwon. Nigba ti ijoba ko si da si oro naa bayii, emi awon eeyan naa ko de nibe mo, nitori nigbakigba ni ijamba le se won. Ohun to fa a niyi to fi je bi won ba ti bere si i ko awon omo Naijiria yii, Olorun lo mo ojo ti won yoo ko won tan, nitori pupo ninu won lo fee pada sile, won lawon ko gbe ni ile ajoji yii mo o. Bayii ni awon omo South Afrika le awon omo Naijiria ni orile-ede won, ti won si n leri pe eni ti ko ba lo, pipa ni won yoo pa a. Sugbon oro naa ko le tan sibe, awon nnkan kan yoo ti idi re yo, nitori opolopo awon orile-ede Afrika, ati awon orile-ede agbaye ni won koriira ohun ti awon ara South Afrika yii n se. Bi awon naa si gbon ju asarun lo, won yoo jiya ohun ti won n se yii o!
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 06:48:59 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.