Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Aafaa Abdulraham Ma N Shere Ni Bebe Ewon, Omo Ile-keu Re Fipa Ba Lo Po L'Ed
 
 
Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise Florence Babashola

Aafaa Abdulraham Ma N Shere Ni Bebe Ewon, Omo Ile-keu Re Fipa Ba Lo Po L'Ede

Won n pe oro ohun lowe, o da bii eni pe o fee maa laro ninu bayii pelu bi omo odun merindinlogun to so pe aafaa kan fipa ba oun lo po she so ni kootu pe ti awon molebi oun ba le gba lati fowo ile to oro naa, she loun yoo pa ara oun si won lorun.

Loshu to koja ni won wo aafaa kan niluu Ede, Habeebullah Abdulraham lo sile-ejo Majisreeti ilu naa lori esun meta otooto. Agbefoba so pe aafaa yii gbe omodebinrin naa pamo, o fipa ba a lajoshepo, o si she e bashubashu.

O shalaye nigba naa pe okan lara awon omo keu aafaa Abdulraham ni omobinrin ti won foruko bo lashiiri ohun, won ni okunrin naa tan an lo sibi eto kan niluu Ilaro, nigba akoko to fipa ba a lashepo.

Nigba ti won beere bi oro she je lowo aafaa, she lo so funle-ejo pe iyawo oun ni omodebinrin to wa ni ipele keta akoko nile-eko girama (JSS 3) ati pe oun ti toro re lowo awon molebi e. Sugbon iya omo yii ati egbon re okunrin to pejo so pe iro pata ni aafaa naa n pa.

Nigba ti won koko wa sile-ejo, Onidaajo Olowolagba gba beeli Aafaa Abdulraham pelu oshishe ijoba to wa ni ipele owo-oshu kejila, to si ni ile sagbegbe ile-ejo, leyin naa ni adajo sun igbejo si ojo keji, oshu kejo, odun yii, nigba ti agbejoro olujejo so pe o she e she ki awon yanju oro naa nitubi-inubi.

Nigba ti won dele-ejo lojo Eti, Furaidee, to koja, awon agbejoro mejeeji so pe awon ko ri oro naa yanju latigba ti awon ti kuro nile-ejo, idi si niyi ti adajo fi so pe ki igbejo kuku bere ni pereu lori esun ti won fi kan olujejo lojo kerinlelogun, oshu kejo ti a wa yii.

Sugbon bi won she bo sita ile-ejo ni omodebinrin naa so fun awon oniroyin pe she lawon agbejoro mejeeji n so tara won o, ati pe ohun ti oun n fe ni toun ni idajo ododo, o ni she ni ki ofin she ishe owo re lori oro naa. O ni nnkan kekere ko loju oun ti ri lori oro naa latigba to ti shele, ati pe enikeni to ba n gbero pe ki won towo ile bo oro naa kan n reti iku oun ni, nitori pe oun le para oun ti won ko ba faaye gba aafaa lati foju winna ofin.

Bakan naa ni egbon omo naa to koko pe ejo gan-an, Muyideen Oloyede, so pe latigba ti awon ti wa sile-ejo gbeyin, enikeni ko yoju si awon fun oro kankan, o ni koda, bi won wa, ohun kan shosho ti awon yoo so pe awon fe ni ki idajo otito fese mule lori oro naa.

O ni loooto loun gbo pe aafaa atawon kan loo shepade pelu awon agbaagba inu molebi awon, sugbon won ko pe oun toun pe ejo sibe, bee naa ni won ko pe omo ti oro kan sibe, won ko si je ki enikan ti won pe lara awon egbon omo ohun soro kankan nibe.

Oloyede ni, 'gbogbo ona ti won yoo fi she oro naa wuruwuru lawon kan n wa, sugbon ohun ti awa fe ni idajo ododo, aafaa gbodo koko gba pe oun jebi awon esun ti a fi kan an ko too di pe a maa mo igbese to ku'.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 06:50:33 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise:
Orin Ewi ni Yoruba - Yoruba Poems: Awon Owe Yoruba Proverbs Alo Oro


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

"Aafaa Abdulraham Ma N Shere Ni Bebe Ewon, Omo Ile-keu Re Fipa Ba Lo Po L'Ed" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: