Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.
Onka Ni Oju-Agbo
Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi
E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi
Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran
E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:
Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.
Ona Igba Wole Si Agbo
Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.
Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
Adefunke Adebiyi
Akanni She Ayederu Iwe INEC, O Lashofin Loun, Lo Ba Fi Gba Awon Eeyan Repete
Awon esun nla bii pipe ara eni lohun ti a ko je, shishe ayederu iwe ajo eleto idibo ile wa (INEC), titan araalu je ati esun merin mi-in ni Akanni Toluwalope n rojo le lori bayii nipinle Eko, leyin ti won mu un pe o she sofin ijoba.
Adugbo kan ti won n pe ni Madogun, nipinle Ogun, ni Akannni, eni ogbon odun n gbe, sugbon Ijaye Ojokoro, nipinle Eko, lo ti lu awon eeyan ni jibiti owo nla gege bi Agbefoba, Augustine Nwabuisi, she shalaye ni kootu Majisireeti to wa ni Yaba, l'Ojobo to koja yii.
O shalaye pe Akanni puro fawon eeyan ninu oshu kefa, odun yii, pe oun ti wole gege bii omo ile igbimo ashoju-shofin (House of Representatives). Koda, ki won le baa gba a gbo, iwe kan ti ibuwolu alaga INEC wa, ti won si ki i ku oriire pe o wole gege bii omo ile igbimo ashofin naa lo fi n han awon eeyan kiri. Bee ayederu niwee naa, okunrin yii lo she e funra e, ki i she INEC rara.
Ohun to tori e n gbe iwe naa kiri fawon eeyan ni pe o loun fee she ajoyo iwole oun naa, sugbon owo to wa lowo oun ko le to, ki awon eeyan ran oun lowo pelu owo diedie. Boun ba wole tan toun bere ishe nile igbimo ashoju-shofin, oun yoo ba won washe sodo ijoba apapo, oun yoo si tun da owo won pada fun won.
Agbefoba tesiwaju pe nibi ti kinni ohun ka olujejo yii lara de, to si fe kawon eeyan gba oun gbo, o ko awon kan lo s'Abuja, o ni ki won waa loo wo bi won yoo she bura foun wole sile igbimo naa, sugbon opin gbogbo e naa, iro ni.
"Oluwa mi, olujejo yii gba egberun lona irinwo ati ogbon Naira (430,000) lowo obinrin kan, Abileko Dolapo Tunner. O gba egberun lona aadoje din marun-un (125,000) lowo Ogbeni Odunlami, owo to gba lowo Omidan Jessica Eyimofe ku die ko wo milionu kan ni (665,000). Leyin naa lo tun gba foonu tuntun Samsung S9 ti won n ta legberun lona igba ati ogota Naira(260,000) lowo omobinrin naa, o loun yoo ba a washe s'Abuja. O gbowo lowo awon ara shooshi e kan naa, bee lo tun pe ara e ni looya fun won. Gbogbo eyi lodi sofin ipinle yii." Bee ni agbefoba Nwabuisi so nipa Akanni Toluwalope.
Gbogbo esun yii ni Akanni loun ko jebi e pelu alaye. Eyi ni Adajo S.O Obasa she faaye beeli sile fun un pelu idaji milionu Naira ati oniduuro meji jiye kan naa.
O pashe pe awon oniduuro naa gbodo ti ju eni ogoji odun lo, won si gbodo maa gbe lagbegbe kootu. O ni won gbodo le shafihan iwe owo-ori sisan won fodun meta gbako funjoba ipinle Eko, okan ninu won si gbodo je molebi olujejo.
Igbejo mi-in di ogunjo oshu yii.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 06:54:38 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.