Gbagede Yoruba
 



Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku

Se loro di boolo o yago laaro ojo Aiku Sande oni nigba ti won lawon baale ile meji kan ti won yan ise agbase se laayo nipinle Ekiti ko sinu konga lasiko ti won n gbiyanju lati yo foonu to jabo sinu konga naa.

Abule kan ti won pe Anaye to wa nijoba ibile Emure la gbo pe isele naa ti waye. Foluso Ajayi ti won tun n pe ni Vosco ati okunrin kan topo awon eeyan n pe ni Alaaji, eni ti won lomo Ebira nipinle Kogi ni lawon meji naa ti a gbo pe foonu lo ran won lo sorun alakeji.

Ohun ti a gbo ni pe okan lara awon meji lo n gbiyanju lati pon omi to fee lo lati dana, asiko naa la gbo pe eni kan pe e lori foonu e, bo si se n gbiyanju lati yo o ni foonu naa jabo sinu konga ti won loo jinna gan an.

Bi foonu naa se jabo la gbo pe o gbiyanju lati yo o, sugbon se ni won so pe ese yo geerege to si fee jabo sinu konga naa, eyi lo mu ki ekeji e naa sare debe lati doola e, to si je iyalenu pe se lawon mejeeji jo jabo leekan-naa.

Awon Hausa marun otoooto la gbo pe won loo wa lati yo oku awon eeyan naa, to si je pe okun ni won so mo lorun ki won too fi gbe won jade.

Bee la gbo pe iwadii awon olopaa ti bere.

Arewa Omoge Ju Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Idaraya

Arewa Omoge Ju Telifison Nla Ni Oteli: Won Ji Iyaale Ile Nibi To Ti N She Ere Idaraya

Bi ki i ba a she opelope awon eleyinju aanu kan ni, boya won ki ba ti dana sun odomobinrin arewa kan, ti won pe oruko re ni Laurenta, eni ti won loo wo oteeli lo, to si lo o ji okan lara awon amohunmaworan, iyen telifishan ti won lo n lo nibe.

Oteeli kan ti won pe ni Kevleyn, eyi to wa nipinle Delta la gbo pe Laurenta loo ji gbe, ati pe oun peluu orekunrin re kan, tiyen ti na papa bora ni won jo gbimo papo ji telifishan naa gbe.

Iwe Irohin Yoruba gbo pe ose kan gbako ni Laurenta ati orekunrin re fi n gbe ni oteeli naa, latari owo ti won san sibe, ti won si n gbadun ara won daadaa.

Won ni inu baagi nla kan ti won n pe ni "Ghana Must Go" ni Laurenta gbe telifishan naa pamo si, asiko to si n gbe e jade ni lawon esho daa duro lati beere nnkan to wa ninu baagi naa, to si lawon eru tawon gbe debe ni.

Bi won she gba baagi naa lowo e ni tipatipa lo ba bere sii bebe pe ki won she oun jeje. Awon eleyinju aanu la gbo pe won gba won nimonran lati fa Laurenta le awon olopaa lowo.

A ti e gbo pe orekunrin Laurenta naa ti ji asho inura, agboorun (umbrella) ati kokoro to je ti oteeli naa salo peluu etanje wi pe oun fee lo ran nnkan nita. Leyin wakati keta la gbo pe Laurenta naa gbe telifishan, sugbon ti ashiri re pada tu sita.

Bee lawon kan ti e tun so pe Laurenta ti ji milionu kan naira din legberun lona igba (800,000) naira lowo okunrin kan ti won jo sun laipe yi.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:02:06 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo:
Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo



"Nitori Foonu, Baale Ile Meji Jabo Sinu Konga, Loju Ese Ni Won Ku" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com