Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Bi Iro Ba Lo Logun Odun...
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Bi Iro Ba Lo Logun Odun...

Awon eeyan wa ni ko gbon, bee ni, opolopo ninu awon eeyan wa ko gbon rara. Eni ti a ba tan je leekin-in-ni, iyen see pe ni asise, tabi misiteeki.

Sugbon ti eni to tan-an-yan leekin-in-ni ba tun waa pada tan an je leekeji, iyen ki i se misiteeki mo, eni ti won n tan je ni ko logbon.

Nigba ti won fee dibo to koja yii, ibo aare ti a di ninu osu keji odun,okunrin kan ti won n pe ni Rotimi Amaechi jade, se oun ni minisita fun eto igbokegbodo oko, o ni ki gbogbo aye le mo pe ijoba Buhari n se bebe, awon ti pari oju-ona reluwee Eko si Abeokuta, ki gbogbo aye maa rin in bayii lo ku, oro wahala irinna lati Abeokuta si Eko ti di ohun igbagbe pata, o ni idi ti awon ara Abeokuta ati awon eeyan Eko se gbodo dibo fun Buhari niyen.

Awon ti won mo oro naa so pe irolokunrin yii n pa, ati pe baba nla opuro ni. Won ni ona reluwee yii ko ti i pari, ati pe won ko ra oko oju-irin tuntun kankan, awon aloku, oko ti aye ko lo mo, ni won loo ko wa lati ibi kan ti won si kun loda tuntun. Kia ni Amaechi ati awon Lai Muhammed ti sare jade, won ni oro lati enu awon alatako ti ko feran Buhari ni, awon ole ti won n ji owo ilu ko lo n so bee. Loro kan, nigba to di ojo kejo, osu keji, odun yii, nigba ti ibo didi ku bii ose meji pere, Amaechi gbe Ibikunle Amosun leyin, won ti Alake Egba si aarin, won ni awon ti pari ona reluwee Abeokuta s'Ekoo.

Loro kan, won wo reluwee de Abeokuta o. Awon ti won mo bi oro naa tiri ni etan lasan ni, won ni ona reluwee yii ko pari, ati pe reluwee ti won wo yii oku-moto-abero-leyin ni. Kia awon oloselu yii ti ko awon kan jo, awon naa ni awon ti wo reluwee yii, ona Abeokuta lawon n gbe, ko si ohun to dara to o.

Amaechi waa ni ise kekere die bayii lo ku, ise ti ko gbodo gba awon ti won n se e ju osu kan lo ni, nigba ti yoo ba si fi diinu osu keta, reluwee naa yoo bere ise patapata, ise gidi lati owuro titidale. Ni won ba dibo, Buhari si wole.

Osu keta ti Amaechi lawon yoobere reluwee gidi yii, osu naa gan-an, ni ojo keeedogun, osu naa, niawon to n se ona reluwee naa dawo duro, won ni ise ko le lo mo. Iyenti le losu mefa bayii. Amaechi waa bere si i jato lenu lose to koja, o ni aisi owo, ati awon minisita ti ko si ni ko je ki ona naa ti pari.

Ona to sope yoo pari ni osu keta odun, nigba ti awon minisita ko ti i lo sibi kan, ti ko si so fenikeni pe ko sowo nigba to n gbe odidi oba rin irinkurin ninu osu keji odun. Iru awon eeyan ti a ni ti won n sejoba le wa lori le ri yen, awon eeyan ti ko ni adehun, ti won ko le soro ka ba a bee, awon opuro, awon ole, awon eletan, awon akotiwon–ba–teni.

E je ki won maase e lo o, ojo n bo ti awon eeyan yoo beere oro lowo awon yii, lojo naa, awon ti ko mo won ri paapaa yoo ba won sunkun, nitori kinni kan lo daju saka, iyen naa ni pe gbogbo eyi ti won se yii, won ko ni i se e gbe, ohun ti yoo bi won yoo pada bi won bo ba ya.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:04:50 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Bi Iro Ba Lo Logun Odun..." | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  







:-: Go Home :-: Go Top :-: