Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.
Onka Ni Oju-Agbo
Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi
E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi
Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran
E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:
Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.
Ona Igba Wole Si Agbo
Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.
Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So
Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So
Laaro kutu ojo Eti tii se Fraide ana ni iroyin naa jade sita Aare teleri l'orile-ede Zimbabwe, Robert Mugabe ti jade laye. Kayeefi, ati pe lojiji niroyin iku naa ba gbogbo agbaye.
Ohun ta a gbo ni pe osibitu kan lorile-ede Singapore ni Robert Mugabe wa lati bi osu meloo kan seyin nibi to ti n gba itoju, latari aisan ojo ogbo ti won loo koluu, to si je pe nibe lo gba jade laye leni odun marundinlogorun (95years).
Lati odun 1980 lo ti n tuko orileede Zimbabwe titi wo odun 2017 nigba ti igbakeji re ye aga mo nidi pelu atileyin ileese ologun.
Adanu nla n'iku Rubert Mugabe je, Olusegun Obasanjo
Aare orileede Naijiria nigbakan ri, Olusegun Obasanjo ti so pe, iku aare Zimbabwe ana, Robert Mugabe je adanu nla fun gbogbo ile adulawo lapapo.
O salaye pe Robert Mugabe je ajijagbara ti o mo pataki ki eeyan ja fun ominira.
Aare Obasanjo wa kedun iku aare ana ohun, o si tun so pe yoo soro lati ri eni ti yoo lee di alafo ipo ti oloogbe naa dimu nile adulawo gege ajijagbara.
"Mugabe fi ìgboya dáábo bo ile Áfíríka lowo ìmúnisìn
Baa ku laa dere, eeyan ko sunwon laaye.
Awon olori orileede Lagbaye ti n sedaro akeegbe won, Robert Mugabe to siwo ise ni aaro ojo Eti.
Mugabe fi ara re jin fun ironilagba oro aje ati oselu - Aare Naijiria
Nigba to n daro pelu orileede Zimbabwe lori ipapoda akoni asaaju naa, aare ile Naijiria, Muhammadu Buhari ni oloogbe naa je ajijagbara to ja fitafita fun ominira orileede ohun, to si fi opo igba aye re sin omoniyan.
Ninu atejade kan ti amugbalegbe fun eto iroyin re, Femi Adesina fisita, Buhari ni opo ifiraenijin ti Mugabe se, paapa nidi ijijagbara fun ironilagbara awon eeyan re leka oselu ati oro aje ni iran yii ati eyi to n bo ko ni gbagbe laalae.
Buhari wa gbadura pe ki Olorun de ile fun akoni naa, ko si tun tu awon ebi re ninu lori isele adanu nla yii.
Awujo agbaye yoo maa ranti Mugabe gege bii 'eni to ni igboya' - Aare Kenya
Bakan naa ni aare orileede Kenya ti se apejuwe Robert Mugabe gege bii "agba awujo, ajafun ominira orileede ati ololufe ile adulawo to se ojuse ti ko kere lati mu atunse ba ife ile adulawo"
"A maa ranti aare Mugabe gege bii onigboya eda, ti kii beru lati ja fun ohunkohun to ba nigbagbo ninu re, koda araye koo baa lodi si ero naa."
Afirika ti padanu okan lara awon akinkanju asaaju - Aare Tanzania
Loju opo Twitter tie, aare orileede Tanzania, John Mugufuli ti sedaro lede Swahili pe "Ile Afirika ti padanu okan lara awon akinkanju asaaju, eni to tako iwa imunisin lati ipase awon igbese re."
Mugabe fi emi aiberu daabo bo ile Afirika - Aare Zambia
Ko tan sibe, aare ile Zambia Edgar Lungu naa ti kede pe "A maa ranti Mugabe fun bo se 'fi emi aisiberu daabo bo ile Afirika'."
Loju opo Twitter re, o ni "oludasile orileede Zimbabwe ati ololufe ile adulawo" naa ni oruko re ko ni pare ninu itan ile Afirika."
Awon 'ogún burúkú' tí Mugabe fi síle sì wa síbe - Olóselú alátako
Opo awon eeyan lagbo oselu lorileede Zimbabwe, awon olori orileede lagbaye ati awon eekanlu lawujo agbaye ti n so ohun ti won mo nipa Robert Mugabe.
Eyi to ya ni lenu julo ni bi awon eeyan kan se n soro ti ko to nipa oloogbe naa.
Akowe foro ile okeere ni ilu Oba, United Kindom, Emily Thornberry kede pe oun ko lee sun ekun kankan nitori pe Mugabe jade laye.
"O gba akoso orileede to si n se opo ileri...sugbon nigba to ya lo sina patapata, mo si ro pe o seranwo lati ba anfaani ti orileede re ni lojo iwaju lati de ibi giga je."
'Mugabe kuro lati ajijagbara bo si afiyajeni'
Bakan naa ni akojo iroyin kan ni Mugabe ba oro aje awon alawo funfun je ni orileede Zimbabwe nitori pe won ri owo mu ni orileede olora naa.
Iroyin naa n se ni iroyin ayo gba gbogbo orileede Zimbabwe kan nigba ti won fi tipa ye aga mo Mugabe nidi.
'Ogun buruku' ti Mugabe fi sile si wa sibe - Oloselu alatako
David Coltart tii se oloselu alatako latinu egbe oselu MDC lorileede Zimbabwe ti kede pe gbogbo omo orileede Zimbabwe ni ko ni gbagbe Mugabe nitori iwa ipa ati iwa ajebanu to fi sile nile naa.
Coltart, ti Mugabe so ni suna 'ota orileede' , ks soju opo Twitter re pe won ko ni gbagbe oloogbe naa pe ko seese ki eeyan fi oju fo opo asise oloogbe naa lasiko to wa lori oye.
Opo ìtan tí Robert Mugabe ko nígba aye re ree:
Nigba ti Robert Mugabe n se abemi loke eepe, o ko oniruuru itan manigbagbe to koja ero eda,
Bi o tile je pe omo atapata dide ni Mugabe, ti baba re si je Kafinta, sibe ko je ki igbe aye mekunnu yii di oun lowo lati de ibi giga laye.
Robert Mugabe, tii se oluko ni ibere pepe aye re, ni oju re ri mabo lowo awon oyinbo amusin ko to di pe orileede Zimbabwe, taa mo si Rodesia tele, gba ominira.
Die ree lara awon koko ohun ti Mugabe gbe ile aye se:
1924: Ojo ti a bi
Leyin e yi, o di oluko 1964: Ijoba orileede Rhode ju si ewon 1980: O bori ninu idibo to saaju ominira orileede naa 1996: Mugabe fe iyawo re, Grace Marufu 2000: O kuna ninu idibo beeni tabi beeko, awon omo ogun re (pro-Mugabe militias) se ikolu si oko awon eniyan alwo funfun ati egbe alatako lorileede naa 2008: O se ipo keji ninu idibo to gbe Tsvangirai wole ni ipele akoko, amo ti Tsvangirai so wi pe oun ko se mo leyin ikolu si awon alatileyin re 2009: Mugabe bura wole fun Tsvangirai gege bi Olootu ile naa laarin oro aje to denukole fun odun merin 2017: O kowe lo gbe ile re fun Igbakeji re,Emmerson Mnangagwa, eleyii to faye sile fun iyawo re, Grace lati bo si ipo 2017 November: Ile-ise ologun fi ipa gba ipo lowo re 2019 September: Robert Mugabe dagbere fun aye pe o digbose.
"Robert Mugabe, a ko lee gbagbe ìtan rere tó ko ní Zimbabwe"
Bi ode ba ku, ode naa lo n se oro leyin ode.
Ni kete ti iroyin iku aare ana lorileede Zimbabwe gba orileede agbaye kan, ni opo eeyan ti n se idaro iku re.
Niwon igba to si je pe onikangun ni ikangun, aare to wa lori oye lowo-lowo bayii, Emmerson Mnangagwa, lasiko to n kede iku oga re tele naa fi tedun tedun so bi iku Mugabe ti kaa lara to.
Emmerson Mnangagwa, eni to daro loju opo Twitter re salaye pe "akoni fun eto ijijagbara ati alawo dudu to nife ile re tokan-tokan ni Robert Mugabe nigba aye re.
O ni Mugabe fi gbogbo aye re ja fun ominira ati eto ironilagbara awon eeyan re ni, ti orileede Zimbabwe ati ile Afirika lapapo, ko si lee gbagbe ipa manigbagbe to ko ninu itan.
Bee ba gbagbe, Emmerson Mnangagwa lo fi tipa gba ipo aare lowo Robert Mugabe pelu atileyin awon ologun losu Kokanla odun 2017.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:28:33 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.