Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O
 
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O

Alaigboran ni wa. Tabi ki n so pe alaigboran ti po ju ninu iran awa Yoruba. A feran abamo pupo. Bi enikan ba roye kan, tabi to ba soye lori ohun kan, tabi to ba ni iriri kan to fi to awa to ku sona, kaka ka gbo, yeye la oo fi i she, tabi ka maa bu u, awon mi-in aa tie mura lati she e leshe ti won ba le sun mo on. Nigba ti oro naa ba waa shele, to ba je bi eni naa ti wi lo pada ja si, awon yii kan naa ni yoo dide, won yoo ni awon ko mo ni, abamo yoo si dun lenu won bii nnkan. Ko dun mo mi ninu lati maa wi pe oro ti mo wi she tabi ko she, sugbon nigba to waa she pe opo awon to wa nile yii, aletilapa ni won nko! Ki a too dibo odun 2015, mo pariwo to, mo pariwo gan-an, tawon kan si mu mi lotaa, tawon mi-in n shepe le ara won lori ti won ro pe emi ni. Sugbon bi a ti dibo tan lawon ohun ti mo ri ti mo fi soro bere si i she, gbogbo wa si foju ri i.

Nigba naa lawon eeyan bere si i ke abamo, 'baba, a o mo ni, baba, oro ti e wi lo ti n she yii o, baba, e ma binu.' Sugbon anfaani wo lo wa ninu abamo? Oore kin ni abamo yoo she feni to ba she e? Sugbon oore kan wa nibe o, oore naa ni ka lo o lati fi gbaradi fojo iwaju, ka ba ara wa soro pe ti iru nnkan yii ba tun shele lojo mi-in, a oo gboran sira wa lenu. Sugbon ki lo tun shele nigba ti ibo odun yii de? Awon mi-in pe mi ni were danwo, awon mi-in ni ki lo de ti mo koriira Fulani to bee, awon mi-in si so pe Buhari ni mo koriira. Loju awon dindinrin mi-in, won n gbeja APC, egbe oshelu won niyen o, won si ti ri emi gege bii omo PDP. N ko mo ibi ti won ti pade ti won ni won gbo oruko mi ninu egbe kankan, tabi ti mo ba n she oshelu, ko ye ki won ti fi emi naa si ipo nla ni. Ti pe n ko mowe to ni tabi ti pe n ko dagba to, nigba ti won n mu baba odun marundinlaaadorun-un (85) ninu wa lati gbe ile ijoba le won lowo.

Gbogbo ariwo ti mo pa pe n ki i she oloshelu, ohun ti mo mo nipa Fulani, iriri ohun ti Buhari ti she leyin odun merin yii la fi n soro, ko seni to ba mi gbo o, aigboran to so awon omo Israeli di alarinkiri, ti gbogbo awon iran igba naa si pare sinu aginju, ko kuro lara opo awon omo Yoruba tiwa. O te wa lorun ka feran araata, ka tele awon ti won n ko wa lo si oko eru, ju ka gboran si eni tiwa lenu lo. Oun lo dele yii o, ariwo ti tun bere, 'baba, e ma binu, baba, nibo la fee gba, baba, ohun ti a oo she ni ki e so fun wa.' Kin ni mo fee so fun yin, kin ni mo fee she, she ki n ni ki Buhari ma shejoba leekeji ni. Shebi e ti ti oje bo oloosha lowo, ta lo to bee lati bo o ninu yin. Mo soro titi debii pe mo ni odun merin ti Buhari yoo fi shejoba mi-in yoo le bi e ba dibo fun un, sugbon lesekese lawon eeyan kan ti bere si i shepe, won ni emi ni yoo le mo, nitori emi ni mo n ri irikurii.

Gbogbo awon ti won n so isokuso yii nigba naa, gbogbo awon ti won lo si ori ero ayelujara, lori facebook, ati awon to ku, bi e ba wa won bayii, e ko ni i gburoo won mo. Won ko si lori ero ayelujara, bee ni won ko ni i da si oro to wa nile yii mo. Sugbon ki won too lo yii, won ti ba nnkan je, won ti da oro ru debii pe Yoruba ko i ti i mo ibi ti yoo gba, tabi ona ti yoo fi she e, ti a oo fi bo lowo okun ti a ki bo ara wa lorun yii. Awon ti e n tele, ti won n puro fun yin, ti won n pairwo eke, awon ni won ba wa debi ti a wa yii. Bee ni won ti ha sowo awon Fulani, awon ni won koko ha sibe ki won too fa eyin naa lo. Bi e ba ti ri enikan to loun gbon titi, tabi to ni oun go titi, to waa ko idi sita, to n to sinu ile, eyin ko ti mo pe alakooba ati abatenije eda ni iru eni bee, shebi nishe lo ye ke e jinna si i. Sugbon eyin o je jinna si won, awon lolorun yin.

Nigba ti Egbon Shegun soro lose to lo lohun-un, ti gbogbo ilu n mi titi, erin lemi n rin. Mo n rerin-in nitori pe yoo to odun meta ti mo ti so oro naa seyin. O pe ti mo ti so fun yin pe awon Fulani agbaye n wa ibi ti won yoo fi she ibugbe ati ikorita fun gbogbo won, won si ti ri i pe Naijiria lo shee lo, nitori ainishokan won, ati nitori pe omo Fulani lolori ijoba naa, o si feran awon. Ki Buhari too gbajoba ni won ti mo on, nitori gbogbo ohun to ni lo fi n ja fun Fulani, to fi n gbeja awon onimaalu, oun lo si koko so pe ki ijoba Jonathan fi awon Boko Haram sile, inu lo n bi won ti won fi n she ohun ti won n she. Oun lo so fun ijoba Obasanjo pe awon o ni i sinmi afi igba ti gbogbo Naijiria ba bere si i lo Sharia gege bii ofin wa. Gbogbo awon oro to n so yii lawon Fulani agbaye n ko sile, nitori e lo je bo she gbajoba ni won ti bere si i ya wa si Naijiria, ti won n huwa ibaje, ti Buhari ko lenu lati so pe ohun ti won she ko dara.

Mo so fun yin nigba naa pe ogun Boko Haram ti kuro ni bi awon eeyan ti n pe e, mo ni o ti di nnkan agbaye. Sugbon iro lawon Buhari n pa, eke ni won n she, won ni awon ibi ti awon Fulani n gbe ni won ti n ba won ja, ki i she awon janduku tabi afemishofo lo wo orile-ede wa. Bee, ikede eyo kan shosho bayii lo wulo nigba naa, bo ba je Buhari she e ni, a ko ni i wa bi a ti wa yii. Bo ba kede lowo kan pe ki awon shoja maa yinbon pa Fulani to ba gbebon dani, tabi awon to ba paayan niluu kan, gege bi Egbon Shegun ti she laye OPC, to pashe ki won maa yinbon pa won nibikibi ti won ba ti ri won, awon Fulani yii yoo sa lo bo ba je ohun ti Buhari she niyen. Awon Fulani ti e ri yen, ogboju ni won ni, won ko laya, ojo ni won, bi won ba yinbon pa meji meta ninu won, awon to ku yoo sa lo bamu ni. Amo Buhari ko she bee, oun n fowo ra won lori ni, loju tire, awon omooya oun lo de, awon ko si gbodo fiya je won, awon gbodo gba ile awon omo Naijiria fun won ni.

Lati fihan pe oun feran won daadaa, Buhari fi ogbon ewe so pe awon fee fi reluwee so orile-ede Naijiria po mo Katsina, ki awon le maa ra epo ni Nijee. Oro rirun pata lo jo loju gbogbo eni to gbo o, nitori Nijee ko lepo ti yoo ta fun Naijiria, awon to she ofin naa fee maa fi ogbon ko epo wa fun won lorile-ede naa ni. Mo so nigba naa pe ko daa, mo si shalaye lekun-un-rere bi epo ti won n wa ni Nijee lodidi odun kan ko she to eyi ti Naijiria yoo wa laarin oshu kan. Sugbon esekese lawon omo Yoruba kan ti mu mi bu, enikan tile so pe o ye ki awon DSS waa gbe mi ni, nitori mo n tu ashiri ijoba, oro ti mo si n so yen, oro to le da ilu ru ni. Sugbon pelu iru ife ti Buhari n fi han awon Fulani yii, iyen ni won she bere si i wole si i, ti awon afemishofo si ba Katsina wole, nibi ti Buhari ti loun fee fi reluwee so wa po. Won ti wole bayii, won ko shee le jade mo.

Oro ti mo so nigba naa ni Egbon Shegun pada so yii, ti Egbon Wole naa si ranshe si Buhari pe ko gbo ooto oro lenu aare ile wa tele yii. Sugbon Yoruba loro naa yoo kan gbongbon ju, nitori eya tiwa ati isheda tiwa ki i she onijangbon, a ki i she onijagidijagan. Iyen ni won she n ya wo ile Yoruba yii, ti won n ji wa gbe. Mo fee so fun yin, opo nnkan ashiri lo wa, opo awon olowo ati olola ilu ni won n ji gbe ti won ki i lee so sita, tabi ki won so ohun ti oju won ri. Bi won mu olola kan pelu iyawo re, tabi awon omobinrin re, loju re ni awon Fulani yoo she maa she won shikashika, ti won yoo maa fi ipa ba won lo po, ti ko si ni i le she nnkan kan si i. Iru egbin, ifiniwole ati ibanininuje wo lo tun ju eyi lo laye. Sugbon ohun ti won n she niyen, won si ti yi ile Yoruba po. Loooto lawon agbaagba ile Yoruba ti dide, ti won n kiri lati ri i pe Fulani ko ko wa leru, sugbon nje awon ti won n tori e dide yii mo on fun won bi.

Won ko mo on fun awon baba yii. Shebi awon ti won n bu tele niyen, ti won ni won o ki i she ashaaju Yoruba, ashaaju PDP ni won, won ti gbowo lowo PDP ni. Sugbon lonii yii, bi ara ti n ni Yoruba to yii, awon ti won ko wa debi ko tori e pada leyin Fulani, koda, nishe lore won n le si i, ti won n fi oruko Yoruba jeun ni tiwon. Bee, mo fi Olorun bura, ete ati abuku ni won yoo ba pade nibe, nigba ti aburu ati inira tiwon ba de, yoo ju eyi to n shele si apapo Yoruba bayii lo. Oju wa yii naa ni yoo she. Sugbon ki gbogbo omo Yoruba gboran, ki e she ohun ti awon agba ba ni ki e she ni gbogbo akoko yii, e fowosowopo pelu wa, ki Yoruba ma ko sinu oko eru Fulani awon ajinigbe o.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:33:35 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

"Iwosi Yii Si Ti N Po Ju Fun Yoruba, Ibi Ti Won Ba Wa De Ree O" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: