Yoruba
- Ojule    - Koko Mẹwa    - Ẹka Abule    - Ifirohin-Ransẹ    - Iwadi    - Oju-Agbo Yoruba    - Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba    - Agbeyẹwo    - Ifiranṣẹ Ara-ẹni    - Ifimufilẹ    - Iwe Akọọlẹ    - Apoti Akọsilẹ    - Akoonu    - Isopọ Ọpọnlujara    - Ẹgba Ayelujara    - Ibeere Ti Ọwọpọ    - Ipolongo Wa    - Ẹkun Imọ Ọfẹ   

 

 
Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awok
 
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awokose Igbeaye Ojise-Olorun

Pelu bi awon musulumi jakejado orileede yii se n se ayeye odun Ileya loni, Omooba Dotun Babayemi ti ro won lati ri igbesi aye irele, ife ati ibagbepo alaafia to farahan lara ojise-Olorun, Ibrahim, gege bii awokose.

Ninu oro ikini ku odun re si awon musulumi nipinle Osun, paapaa, niha ekun Iwo-Oorun Osun lo ti parowa yii.

Babayemi, oloselu lati ilu Gbongan ohun woye pe ilana eko Id-el-Adha eleyii to da lorii nini igbagbo ninu Olorun ati gbigbekele ife Re gbodo maa jeyo ni gbogbo igba ninu aye awon elesin Islam.

O ran won leti pe ki i se agbo ti won pa lojo odun tabi eran ti won je lo ni nnkan se pelu Olorun bikose atunhu iwa ati titun igbeaye won yewo.

Babayemi ro won lati mu ife si Allah ati igbagbo ninu Re lokunkundun, ki won si nawo ife yii kan naa sawon alajogbe won nipase eyi ti idagbasoke yoo fi wa nipinle Osun.

Dotun Babayemi sabewo kaakiri Iwo-Oorun Osun; lawon araalu ba ni oloselu bii tie sowon

Manigbagbe ni asiko aawe Ramadan to n koja lo yii yoo je fawon eeyan woodu aadofa to wa nijoba ibile meweewa ni ekun idibo Iwo-oorun Osun pelu ọwo ife ti asiwaju kan ninu egbe oselu APC, Omooba Dotun Babayemi na si won lasiko naa.

Kii se awom musulumi nikan ni won janfaani nla naa, ati omode, atagba ni, gbogbo won ni won si n gbosuba nla fun okunrin oloselu naa fun igbese to gbe nitori pe o fun won lanfaani lati so ero won nipa ijoba atawon nnkan ti won n reti lati odo ijoba.

Kaakiri gbogbo igberiko to wa ni korokondu ijoba ibile meweewa ohun ni Babayemi lo pelu iroyin ayo ati ti ireti, bee lo n fun won lebun orisiirisii lati le je ki won ni imolara ife lasiko aawe yii.

Ijoba ibile Ejigbo ni abewo olose meji yii ti bere lojo keedogbon osu karun odun yii. Gbogbo awon mosalasi Jimoh to wa ni Ede, Ejigbo ati Egbedore ni Babayemi atawon eeyan re de, ti won si fun awon olujosin ni oniruuru ebun. Leyin naa ni won sabewo si woodu mefa nijoba ibile Ejigbo.

Lojo Satide, ojo kerindinlogbon osu karun, ijoba ibile Gusu Ede ni won lo, bee ni won de woodu mokanla nijoba ibile Ariwa Ede lojo ketadinlogbon osu karun ohun pelu ebun to joju ni gbese.

Tilu tifon ni won fi ki iko Babayemi kaabo nijoba ibile Egbedore lasiko to sabewo si woodu meweewa to wa nibe lojo kejidinlogbon, bee lawon eeyan woodu meedogun to wa nilu Iwo gba Babayemi towo-tese logbonjo osu karun ti won debe.

Leyin abewo sijoba ibile Egbedore, Omooba Babayemi ni ohun to ya oun lenu ju ni bo se je pe oro ojo-ola rere fawon omode lo mumu laya awon obinrin, to si je pe gbogbo ibeere won lo da lorii bi awon omo won yoo se rowo mu.

O ni abewo naa fun oun lanfaani lati ba awon eeyan igberiko soro lojukoju laisi alagata kankan rara, ori oun si wu fun bi won se tewo gba oun tokantokan, ti won ko si tiju lati sọ ẹdun okan won.

Woodu mewa nijoba ibile Ayedire ni iko Babayemi lo lojo kokanlelogbon osu karun odun yii pelu ebun odun aawe, ijoba ibile Ola-Oluwa ni won si ti tewo gba won lojo kinni osu kefa. Lojo yii kannaa ni won pin ebun fun awon olujosin ni mosalasi nla ilu Iwo, Ayedire ati Ola-Oluwa leyin irun Jimoh.

Pelu ayo lawon eeyan woodu mokanla to wa nijoba ibile Irewole fi gba Babayemi atawon eeyan re lojo kefa osu kefa, bakan naa loro si ri nijoba ibile Isokan lojo keje osu kefa, bee lo si lo si mosalasi Jimoh nijoba ibile Ayedaade, Isokan ati Irewole pelu obitibiti ebun.

Babayemi atawon eeyan re de woodu meje nijoba ibile Ayedaade, bee ni won de woodu merin nigberiko Ode-omu nibi ti won ti rojo ebun fawon eeyan.

Iwadi fi han pe abewo kaakiri awon woodu yii ni eleekerin iru e ti Omooba Dotun Babayemi yoo se kaakiri ekun Iwo-oorun Osun, o si lanfaani lati ba awon eeyan soro nitubi-n-nubi.

Tarugbo-tomidan ni won fon jade lati ki Babayemi atawon eeyan re kaabo ni woodu kokanla, Bara-Ejemu nijoba ibile Ariwa Ede, pelu orin ni awon omo egbe oselu APC fi ki won kaabo sagbegbe naa, bee ni oun naa bo soju ijo, ti ohun gbogbo si sorura nibe. Koda, se lawon obinrin mu kaadi idibo won lowo, ti inu won si n dun senken nigba ti won ri Babayemi.

Leyin eyi lo parowa si gbogbo awon musulumi lati te siwaju ninu igbe aye mimo eleyii ti won n gbe lasiko aawe, ki won si mase dekun iwa ififunni ti Ramadan ko won.

O ni gbogbo igba toun ba sabewo sawon eeyan esekuku ni inu oun maa n dun. O salaye pe ipese ise gidi fawon odo, riro awon obinrin lagbara ati mimu aye derun fawon eeyan agbegbe naa ni yoo je oun logun ti won ba le faaye gba oun lati sojuu won.

Odo Timi ti ilu Ede, Oba Munirudeen Adesola Lawal, Laminisa Kinni ni iko Babayemi pari abewo kaakiri ilu Ede si nibi ti kabiesi naa ti rojo adura le won lori.

Okan lara awon ti won ba Omooba Dotun koworin, Alhaji Ademola Jekayinfa latijoba ibile Ayedaade so pe awon nnkan toun ri lasiko abewo naa fi han pe Olorun funraare lo fi Babayemi jinki ipinle Osun ati orileede Naijiria lapapo.

Nilu Iwo, won sapejuwe Omooba Babayemi gege bii eni to kunju osunwon lati di ipo nla mu nipinle Osun ati lorileede Naijiria. Leyin eyi ni won pari abewo naa si odo Oluwo ti Iwo, Oba Abdulraseed Akanbi.
 
 
 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, October 12 @ 14:29:02 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 
 
 
Comments & Debates :-: التعليقات والمحاورات

 
 
For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا
 
 
:-: Go Home :-: Go Top :-:
 

Awon Itona Ti O Bayi Mu

· Ekunrere Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Irohin Lati Owo MediaYorubaTeam


Eyiti Ti O Je Kika Ju Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwon Didi Lori Atoka

Iyeju Enu Awon Ti O Ni Iwon: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

E Jowo E Fi Iseju Kan Pere Sile Lati Kopa Ninu Ibo Didi Fun Atoka Yii:

O Dara O Lekele Kan O Dara Pupo O Dara Ni Opolopo Igba Tabi Ni Gbogbo Igba Ko Dara

Awon Iyanbo


 Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun Eyi Wa Fun Lilo Printer Ni Irorun


Akole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"Gbogbo Musulumi Jakejado Orileede Naijiriya Ni Babayemi Gba Niyanju Lati Se Awok" | E Se Atewole/Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam | 0 Awon Alaiye
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.

A Ko Fi Aaye Lati Se Alaiye Gba Eniti Ko I Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam, E Jowo E fi Oruko Sile Lati Lo Si EsinIslam Nibiyii
 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

  :-: Go Home :-: Go Top :-: