Ko Si Atoka Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Ẹ Forukọsilẹ Bayi!.
Onka Ni Oju-Agbo
Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi
E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi
Iwadi Ni Yoruba
Tumo Yoruba Sede Miran
E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:
Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.
Ona Igba Wole Si Agbo
Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.
Ijoba Ipinle Osun Ti Ki Oselu Bo Eto-eko O - Awon Eeyan Iwo-Oorun Osun Ke Gbajar
Ijoba Ipinle Osun Ti Ki Oselu Bo Eto-eko O - Awon Eeyan Iwo-Oorun Osun Ke Gbajare
Awon olugbe agbegbe Iwo-oorun Osun ti ke si gbogbo awon abiyamo tooto ti won mo pataki eto eko gba won lori igbese tijoba ipinle Osun gbe lati da eto-eko ofe lenu isinmi tawon akekoo agbegbe naa maa n se duro.
Lati odun merin seyin ni ajo kan to n je Alaafia Dotun eleyii ti Omooba Dotun Babayemi nsagbateru re ti maa nseto eko-ofe fawon akekoo ninu olude, eleyii to mu ki ipo eko lawon agbegbe naa muna doko sii
Omooba Babayemi wa ninu egbe oselu APC ni gbogbo asiko yen, ko si si wahala kankan rara, sugbon ni kete ti okunrin naa bo sinu egbe oselu PDP ni oniruuru igbese ti n waye lati dawo ohun gbogbo to n se duro.
Okan lara awon agbenuso fawon eeyan ilu Gbongan, Alhaji Ojewale salaye pe ko si obi ti inu re ki i dun si eto naa latigba to ti bere nitori pe ajo naa ko fi ti egbe oselu kankan se rara.
O ni gbogbo eto ni won tun ti la sile fun ti olude yii, koda, eto-eko ofe naa ti bere lawon ibugbe mejidinlogbon ti won ti fee se e kaakiri ekun idibo naa ko too di pe iwe kan wa lati ileese to n ri si eto eko nipinle Osun pe ki won dawo duro.
O ni awijare ti won ko sinu leta naa jo gbogbo awon obi loju patapata, "Se ni won so pe ijoba fee tun awon yaara ikawe ti won ti n kekoo se. Ibeere ti a wa n beere ni pe se wpn ko mo ko too di pe won fun awon alakoso lanfaani lati lo ibe tele?
"Omo egbe oselu APC ni mi, sugbon gbogbo eleyii ko sele lasiko ti Babayemi wa ninu egbe wa, oro eko awon omo ki ise nnkan to ye kijoba ki oselu bo rara. Gbogbo wa la janfaani eto yii gege bi obi latigba to ti bere.
"Niwon igba ti ajo naa ko ti beere iranlowo kankan lowo ijoba latigba to ti bere, ko si idi kankan to fi ye ki won da eto naa, ninu eyi to je pe awon akekoo bii egberun merin ni won ti janfaani lati lo kawe ni yunifasiti nipase ajo yii duro rara".
Awon eeyan yii wa ro Gomina Oyetola lati tun ero re pa lori igbese naa, ki awon si maa ba eko naa lo fun ose bii meta to ku ki olude pari.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Saturday, October 12 @ 14:32:19 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
Gbogbo Awon alaiye Je Ti Eniti O Ba Fiwon Ranse. EsinIslam Ki Yio Gbe Ebi Kebi Ti O Ba Ti Ipase Awon Oro Ati Ohun Atoka Ti Kowa Ba Fi Sowo L'ori Alantakun Yii.